ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 4/15 ojú ìwé 21-26
  • Ṣíṣí Ìbòjú Lójú Àgbègbè Tí Kò fi Bẹ́ẹ̀ Lajú ní Alaska

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣíṣí Ìbòjú Lójú Àgbègbè Tí Kò fi Bẹ́ẹ̀ Lajú ní Alaska
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Ìyípadà Onírora Kan
  • Àwọn Ìsapá Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Láti Wàásù
  • Ìrànlọ́wọ́ tí A Kò Retí Dé
  • Nísàlẹ̀ ní Aleut Sísopọ̀mọ́ra
  • Ìyágágá Tí Ó Wáyé Ní Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀
  • Rírékọjá Ibodè
  • Ìsapá Náà Ha Yẹ Fún Un Bí?
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 4/15 ojú ìwé 21-26

Ṣíṣí Ìbòjú Lójú Àgbègbè Tí Kò fi Bẹ́ẹ̀ Lajú ní Alaska

FÚN ọjọ́ méjì nísinsìnyí àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ti fún araawa pọ̀ sínú iyàrá kékeré kan ní ìlú tí ó lókìkí fún ìdàgììrì àwọn ènìyàn tí ń lọ wa wúrà náà, Nome, Alaska. Ní 1898, iye tí ó ju 40,000 àwọn olùwá ohun iyebíye kiri ni wọ́n kóríjọ síhìn-⁠ín láti wá kìkì ohun kan​—⁠wúrà! Àwa, ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ń wá ìṣúra tí ó yàtọ̀.

Ọkàn-ìfẹ́ wa, ní lọ́ọ́lọ́ọ́, jẹ́ nínú “àwọn ohun fífanilọ́kànmọ́ra” tí wọ́n lè máa gbé ní àwọn abúlé àdádó Gambell ati Savoonga ní Erékùṣù St. Lawrence, 300 kìlómítà sí ìwọ̀-oòrùn ní Bering Strait. (Haggai 2:7, NW) Níbẹ̀ ni àwọn Inuit ti ń farada àwọn omi oníyìnyín ti Arctic lati ṣọdẹ àwọn àbùùbùtán níbi tí kò ju bíi ibùsọ̀ mélòókan sí ibi tí a ń pè ní Soviet Union tẹ́lẹ̀rí. Ṣùgbọ́n òjò-dídì tí ń fẹ́ àti kùrukùru aláwọ̀ eérú tí ó bo ojú-ọjọ́ dá wa dúró. Ọkọ̀ òfuurufú wa kò lè gbéra.

Bí a ti ń dúró, mo ronú padà lọ sórí ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa Ọlọrun fún ìbùkún rẹ̀ lórí ìwàásù ní àwọn agbègbè gátagáta tí kò ní olùgbé púpọ̀ náà. Ní Alaska​—⁠èyí tí àwọn kan ń pè ní agbègbè tí kò fi bẹ́ẹ̀ lajú ní àgbáyé​—⁠iye tí ó lé ní 60,000 àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ni wọ́n ń gbé ní èyí tí ó ju 150 àwùjọ, tí ó wà káàkiri inú aginjù tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 1,600,000 kìlómítà níbùú lóròó, tí irú ojú-ọ̀nà kankan kò sì so ó pọ̀ mọ́ra. Nípasẹ̀ ọkọ̀ òfuurufú Watch Tower Society, a ti dé èyí tí ó ju ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn abúlé àdádó wọ̀nyí, ní mímú ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun tọ̀ wọ́n lọ.​—⁠Matteu 24:⁠14.

Láti dé àwọn abúlé wọ̀nyí, ọkọ̀ òfuurufú náà lọ́pọ̀ ìgbà níláti balẹ̀ nínú ìkúukùu àti kùrukùru tí ó lè bo ilẹ̀ náà fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Lẹ́yìn tí ó bá ti balẹ̀, kùrukùru mìíràn ṣì wà tí ó gbọ́dọ̀ là já. Bí ìbòjú kan, ó bo iyè-inú àti ọkàn-àyà àwọn ènìyàn onínúure àti alálàáfíà wọ̀nyí mọ́lẹ̀.​—⁠Fiwé 2 Korinti 3:​15, 16.

Ìyípadà Onírora Kan

Àwọn Inuit, Aleut, àti àwọn India ni wọ́n ń gbé ní àwọn agbègbè gátagàta tí kò ní olùgbé púpọ̀ ní Alaska. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn wọ̀nyí ni ó ní àwọn àṣà àti ìhùwà tí ó jẹ́ àjogúnbá tirẹ̀. Láti la ìgbà-òtútù Arctic já, wọ́n ti kọ́ láti faramọ́ kí wọ́n sì wá ohun tí ẹnu ń jẹ nínú àwọn ohun àmúṣọ̀rọ̀ ilẹ̀ náà nípa ṣíṣọdẹ, pípẹja, àti fífi ẹja àbùùbùtán ṣòwò.

Agbára ìdarí àjòjì wá sórí wọn ní agbedeméjì àwọn ọdún 1700. Àwọn ará Russia tí ń fi awọ-ẹran ṣòwò rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń wọ awọ-ẹran tí òróró kìnnìún-òkun ń run lára rẹ̀, tí wọ́n ń gbé nínú àwọn ilé tí a fi yẹ̀pẹ̀ mọ lábẹ́ ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn òrùlé oníkoríko àti àwọn ẹnu-ọ̀nà tí a kọ́ sí abẹ́ ilẹ̀, kìí ṣe nínú àwọn ilé tí a fi yìnyín mọ. Àwọn oníṣòwò wọ̀nyí mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro tí ó ní nínú àṣà àti àrùn titun wá sórí àwọn ènìyàn asọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́, ẹni pẹ̀lẹ́, síbẹ̀ tí wọ́n rọ́kú wọ̀nyí, èyí tí ó dín iye àwọn ẹ̀yà kan kù sí ìdajì. Láìpẹ́, ọtí wá di ègún fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ọrọ̀-ajé titun fi agbára mú ìyípadà wá láti inú pípèsè oúnjẹ tí ó tó ní tààràtà fún ìdílé sí níná owó. Títí di òní yìí, àwọn kan nímọ̀lára pé ó ti jẹ́ ìyípadà onírora kan.

Nígbà tí àwọn míṣọ́nnárì Kristẹndọm dé, irú ìyípadà mìíràn ni a tún fi agbára mú wá sórí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Alaska. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan fi pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ fi àwọn àṣà ìsìn àtọwọ́dọ́wọ́ wọn sílẹ̀​—⁠ìjọsìn àwọn ẹ̀mí afẹ́fẹ́, yìnyín, beari, idì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ​—⁠àwọn mìíràn mú àwọn àmúlùmálà èrò dàgbà, tí ó yọrísí àjólùpọ̀, tàbí ìdàrúdàpọ̀ ìsìn. Gbogbo èyí lọ́pọ̀ ìgbà máa ń yọrísí ìfura àti àìní ìgbọ́kànlé nínú àwọn àlejò. Àlejò ni a kìí sábà kí káàbọ̀ ní àwọn abúlé kan.

Nítorí náà, ìpènijà tí ó wà níwájú wa ni, Báwo ni a óò ṣe dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọmọ ìbílẹ̀ náà tí wọ́n wà káàkiri ààlà-ilẹ̀ gbígbòòrò yìí? Báwo ni a ṣe lè mú ìfura òdì wọn kúrò? Kí ni a lè ṣe láti ṣí ìbòjú náà kúrò?

Àwọn Ìsapá Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Láti Wàásù

Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1960, àwọn Ẹlẹ́rìí ará Alaska mélòókan tí ara wọn lé dáradára fàyàrán àwọn ipò ojú-ọjọ́ lílekoko​—⁠afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́ kíkankíkan, ojú-ọjọ́ tí ó tutù nini, yìnyín tí ó bo gbogbo ojú-ọjọ́ mọ́lẹ̀​—⁠wọ́n sì gbé àwọn ọkọ̀ òfúúrufú aládàáni wọn, tí ń lo ẹ́ńjìnnì kan, lọ sí ìrìn-àjò fún ìwàásù láàárín àwọn abúlé tí wọ́n wà káákiri ní àríwá. Ní ríronú lórí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ kọjá, àwọn arákùnrin onígboyà wọ̀nyí níti gidi ń ṣi araawọn payá sí ewu lọ́pọ̀lọpọ̀. Ẹ́ńjìnnì tí ó kọṣẹ́ ti lè fa jàm̀bá. Kódà bí ó bá tilẹ̀ ṣeéṣe láti balẹ̀ láìséwu, ọ̀nà wọn ìbá jìn sí ibi tí wọ́n lè ti rí ìrànlọ́wọ́ gbà nínú otútù láìsí ohun ìrìnnà. Lílàájá wọn yóò sinmi lé rírí oúnjẹ àti ibùgbé, èyí tí yóò ṣòro láti rí. A dúpẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kankan kò ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n a kò lè gbójúfo irú àwọn jàm̀bá wọ̀nyẹn dá. Nítorí náà ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society ní Alaska kò fún àwọn ará níṣìírí lati ṣe irú ìwàásù yìí.

Láti máa bá iṣẹ́ náà lọ, àwọn arákùnrin olùṣòtítọ́ ní Ìjọ Fairbanks àti North Pole darí gbogbo àfiyèsí wọn sórí àwọn abúlé ńláńlá, irú bíi Nome, Barrow, ati Kotzebue, àwọn ibi tí àwọn ọkọ̀ òfúúrufú akérò ń lọ. Wọ́n ń lo owó tiwọn fúnraawọn lati fi rìnrìn-àjò lọ sí àwọn àgbègbè wọ̀nyí, tí ó lé ní 720 kìlómítà sí àríwá àti ìwọ̀-oòrùn. Àwọn kan dúró sí Nome fún àwọn oṣù mélòókan láti darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn. Ní Barrow a háyà ilé kan láti jẹ́ ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ otútù tí ó wọ̀n tó -45° lórí ìwọ̀n Celsius. Fún àwọn ọdún mélòókan, àwọn tí wọ́n ń fi àṣẹ Jesu sọ́kàn ti ná iye tí ó ju $15,000 láti wàásù ìhìnrere náà dé òpin ilẹ̀-ayé.​—⁠Marku 13:⁠10.

Ìrànlọ́wọ́ tí A Kò Retí Dé

Ìwákiri fún ọ̀nà láti gbà dé ọ̀dọ̀ àwọn àwùjọ tí wọ́n wà ní àdádó ń bá a lọ, Jehofa sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀. Ọkọ̀ òfuurufú tí ń lo ẹ́ńjìnnì méjì wá di èyí tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó​—⁠ohun náà gan-⁠an tí a nílò láti kọjá láìséwu lórí Alaska Range tí ó rí ṣágiṣàgi. Onírúurú àwọn òkè-ńlá tí ó ga ju 4,200 mítà lọ ni ó wà ní Alaska, ṣóńṣó Òkè-Ńlá McKinley (Denali) tí ó gbajúmọ̀ náà sì fi 6,193 mítà rékọjá ìtẹ́jú òkun.

Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, ọkọ̀ òfuurufú náà dé. Ẹ wo bí ìjákulẹ̀ wa ti pọ̀ tó nígbà tí ọkọ̀ òfuurufú tí ó ti gbó, tí ó ti ṣá, tí ó sì ní àwọ̀ kàlákìnní, balẹ̀ sórí títì ọkọ̀ òfuurufú. Ó ha lè fò bí? A ha lè fa ẹ̀mí àwọn arákùnrin wa lé e lọ́wọ́ bí? Lẹ́ẹ̀kan síi, ọwọ́ Jehofa kò kúrú. Lábẹ́ ìdarí àwọn atẹ́rọṣe tí wọ́n ní ìwé-àṣẹ, iye tí ó lé ní 200 àwọn arákùnrin yọ̀ǹda araawọn, ní lílo ẹgbẹẹgbẹ̀rún wákàtí láti sọ ọkọ̀ òfuurufú náà di titun padà.

Ẹ wo bí ó ti dùnmọ́ni tó lati rí i! Ọkọ̀ òfuurufú dídán kan tí ó dàbí titun tí ó ní nọ́ḿbà 710WT tí a fi dárà síbi ìdí rẹ̀ ti ń gbéra lọ sókè sí òfuurufú Alaska! Níwọ̀nbí a ti lo eéje àti ẹẹ́wàá nínú Bibeli láti ṣàpẹẹrẹ ìpépérépéré, 710 ni a lè gbà pé ó tẹnumọ́ ìtìlẹ́yìn tí ètò-àjọ Jehofa ti fifúnni láti ṣí ìbòjú kúrò lójú àwọn ọkàn-àyà tí òkùnkùn ti bò mọ́lẹ̀.

Nísàlẹ̀ ní Aleut Sísopọ̀mọ́ra

Láti ìgbà tí a ti gba ọkọ̀ òfuurufú náà, a ti kárí 80,000 kìlómítà ní aginjù, ní mímú ìhìnrere Ìjọba naa àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ sí èyí tí ó lé ní abúlé 54. Èyí dọ́gba pẹ̀lú líla àgbáálá ilẹ̀ United States kọjá nígbà 19!

Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni a ti gúnlẹ̀ láàárín àwọn Erékùṣù Aleut tí wọ́n gùn tó 1,600 kìlómítà, tí ó ya Agbami-Òkun Pacific kúrò lára Òkun Bering. Àwọn erékùṣù tí wọ́n sopọ̀mọ́ra náà, tí wọ́n lé ní 200, tí wọn kò sì fi bẹ́ẹ̀ ní igi, jẹ́ ilé fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹyẹ òkun, idì apárí, àti pẹ́pẹ́yẹ olórí funfun bíi yìnyín pẹ̀lú àwọn ìyẹ́ dúdú àti funfun pẹ̀lú, kìí ṣe fún kìkì àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Aleut nìkan.

Bí ó ti wù kí ó rí, ẹwà agbègbè náà tí ń fanimọ́ra, kò ṣaláìní ewu tirẹ̀. Bí a ti ń fò lórí òkun, a lè rí ìgbì-òkun tí ó ga tó mítà 3 sí 5 lórí omi yìnyín tí ń yọ ìfóòfó naa, tí ó tutù nini débi pé nígbà ẹ̀ẹ̀rùn pàápàá kìkì ìṣẹ́jú 10 sí 15 ni ènìyàn lè wàláàyè mọ́ nínú rẹ̀. Bí a bá fi ipá mú un láti balẹ̀, àwọn ibi kanṣoṣo tí awakọ̀ òfuurufú lè yàn láti balẹ̀ sí ni erékùṣù kan tí òkúta yíká, tàbí òkun títutù nini, tí ó lè ṣe ikú pani náà. Ẹ wo bí a ti kún fún ìmoore tó fún àwọn arákùnrin wa ọ̀jáfáfá, àwọn atẹ́rọṣe tí wọ́n ní ìwé-àṣẹ láti tún ara àti ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ òfuurufú ṣe, àwọn tí wọ́n yọ̀ọ̀da araawọn láti mú ọkọ̀ òfuurufú náà wà ní ipò tí ó dára fún fífò!

Nínú ọ̀kan lára àwọn ìrìn-àjò náà, a forílé Dutch Harbor àti abúlé ìpẹja náà Unalaska. A mọ ẹkùn náà fún atẹ́gùn rẹ̀ tí ń yára fẹ́ ní ìwọ̀n 130 sí 190 kìlómítà láàárín wákàtí kan. Lọ́nà tí ń múni láyọ̀, ó rọlẹ̀ lọ́pọlọpọ̀ ní ọjọ́ yẹn ṣùgbọ́n ó ṣì ń rugùdù débi pé ó mú kí èébì gbé wa lọ́pọ̀ ìgbà. Ẹ wo bí ó ti yanilẹ́nu tó nígbà tí a rí ibi tí ọkọ̀ lè balẹ̀ sí​—⁠ibi olókùúta kan lẹ́bàá òkè-ńlá! Ní apá kan ibi tí a lè balẹ̀ sí náà ni àwọn òkúta tí a tò léra wà, ní apá kejì ẹwẹ̀ ni omi yìnyín ti Òkun Bering wà! Nígbà tí ọkọ̀ wa balẹ̀, ó jẹ́ sí ojú ọ̀nà tí ó tutù. Òjò ń rọ̀ níbẹ̀ fún èyí tí ó lé ní 200 ọjọ́ ní ọdún kan.

Ẹ wo bí ó ṣe jẹ́ ìdùnnú wa tó lati bá àwọn tí ń gbé agbègbè náà jíròrò Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti ète rẹ̀! Àwọn arúgbó mélòókan fi ìmọrírì hàn fún ìrètí ayé kan láìsí ogun. Wọ́n ṣì rántí ní kedere bí àwọn ará Japan ṣe ju bọ́m̀bù sí Dutch Harbor nígbà Ogun Àgbáyé II. Àwọn ìrántí irú àwọn ìrìn-àjò oníwàásù bẹ́ẹ̀ tí a ní bákan náà jẹ́ aláìṣeégbàgbé.

Ìyágágá Tí Ó Wáyé Ní Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀

Ní wíwo ojú-ọjọ́ lẹ́ẹ̀kan síi, a ṣàkíyèsí pé ipò ojú-ọjọ́ tí ń sàn díẹ̀díẹ̀. Ìyẹn mú mi ronú nípa iṣẹ́ ìwàásù wa nínú àwọn agbègbè gátagàta tí kò ní olùgbé púpọ̀ náà. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, ara àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ síí yá mọ́ wa.

O gba àkókò láti mú ìfura àti àìnígbọkànlé tí àwọn ènìyàn náà ní nípa àwọn ará ìta kúrò. Nínú àwọn ìgbìyànjú wa àkọ́kọ́, kìí ṣe ohun tí ó ṣàjòjì fún àwọn olórí ṣọ́ọ̀ṣì ní abúlé náà láti wá sí ìdí ọkọ̀ òfuurufú náà, ní bíbéèrè ìdí tí a fi wá síbẹ̀, lẹ́yìn náà tí wọn yóò sì sọ pé kí a máa lọ láìjáfara. Dájúdájú, irú àwọn ìkínikáàbọ̀ bẹ́ẹ̀ ń mú ìjákulẹ̀ báni. Ṣùgbọ́n a rántí ìmọ̀ràn Jesu tí ó wà ní Matteu 10:16: “Gbọ́n bí ejò, kí ẹ sì ṣe oníwà tútù bí àdàbà.” Nítorí náà a padà lọ pẹ̀lú ọkọ̀ òfuurufú wa tí ó kún fọ́fọ́ fún ewébẹ̀, tòmátò, èso tútù, àti àwọn ohun mìíràn tí kò sí lárọ̀ọ́wọ́tó ní àdúgbò náà. Àwọn olùgbé ibẹ̀ tí wọ́n jẹ́ alátakò tẹ́lẹ̀rí ni inú wọn ń dùn nísinsìnyí láti rí ẹrù inú ọkọ̀ òfuurufú wa.

Nígbà tí arákùnrin kan yóò dúró sídìí “ọjà,” ní gbígba ọrẹ fún àwọn oúnjẹ tútù náà, àwọn mìíràn yóò lọ láti ẹnu ilẹ̀kùn dé ẹnu ilẹ̀kùn, ní sísọ fún àwọn onílé nípa dídé oúnjẹ tútù. Lẹ́nu ilẹ̀kùn wọ́n tún máa ń béèrè pé: “Óò, gbọ́ ná, ìwọ ha jẹ́ olùka Bibeli bí? Mo mọ̀ pé ìwọ yóò gbádùn àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli yìí tí ó fihàn pé Ọlọrun ti ṣèlérí paradise fún wa.” Ta ní jẹ kọ irú ìfilọni tí ń fanimọ́ra náà? Gbogbo wọn ni wọ́n mọrírì oúnjẹ nípa ti ara àti nípa ti ẹ̀mí náà. Ìkínikáàbọ̀ náà dùnmọ́ni, a fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé sóde, àwọn ènìyàn díẹ̀ ni a sì mú ní ọkàn yọ̀.

Rírékọjá Ibodè

Lọ́hùn-⁠ún ní Ìpínlẹ̀ Yukon, Ìjọ Whitehorse nawọ́ ìkésíni náà láti “rékọjá wá sí Makedonia” ní Canada láti ṣèbẹ̀wò sí díẹ̀ lára àwọn agbègbè tí wọ́n wọnú ní àwọn Ìpínlẹ̀ ní apá Àríwá Ìwọ̀-Oòrùn. (Iṣe 16:9) Àwa márùn-⁠ún ni a wà nínú ọkọ̀ òfuurufú bí a ti forílé Tuktoyaktuk, abúlé kan nítòsí Ìyawọlẹ̀ Mackenzie ní Òkun Beaufort, ti àríwá Arctic Circle.

‘Báwo ni ẹ ti ń pe orúkọ tí ó ṣàjèjì yìí?’ ni a ń ṣe kàyéfì nígbà tí a dé ibẹ̀.

“Tuk,” ni ọ̀dọ́kùnrin kan dáhùn pẹ̀lú ẹ̀rín mùkẹ̀mukẹ.

“Èéṣe tí a kò fi ronú nípa ìyẹn?” ni a ṣe kàyéfì.

Ó yà wa lẹ́nu láti ríi pé àwọn ènìyàn Tuktoyaktuk mọ Ìwé Mímọ́ dáradára. Nítorí èyí, a ní àwọn ìjíròrò ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́, a sì fi ọ̀pọ̀ ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ síta. Ọ̀kan lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà wa tí ó jẹ́ ọ̀dọ́ ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ kan tí ń lanilóye pẹ̀lú onílé kan.

“Anglikan ni mi!” ni onílé náà sọ.

“O ha mọ̀ pé Ṣọ́ọ̀ṣì Anglikan fọwọ́sí ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ bí? ni aṣáájú-ọ̀nà wa béèrè.

“Ṣe pé wọ́n fọwọ́sí i?” ni ọkùnrin náà dáhùn pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀. “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èmi kìí ṣe Anglikan mọ́ nígbà náà.” A retí pé, ẹlòmíràn tún ti ń ṣí ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ sí ìhìnrere Bibeli nìyẹn.​—⁠Efesu 1:18.

Arúgbó kan ni a mú orí rẹ̀ wú nítorí ìpinnu wa láti dé gbogbo ilé ní agbègbè yẹn. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà a níláti fi ẹsẹ̀ rìn ni. Ìrìn kìlómítà kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni a sábà máà ń rìn láti ibi tí ọkọ̀ wa balẹ̀ sí títí dé abúlé náà. Lẹ́yìn náà, láti dé inú ilé kọ̀ọ̀kan, a níláti rin ìrìn àrìnwọ́dìí lórí òkúta wẹrẹ tàbí àwọn ipa-ọ̀nà onípọ̀tọ̀pọ́tọ̀. Ọkùnrin náà yá wa ní ọkọ̀ akẹ́rù rẹ̀, ẹ sì wo ìbùkún tí ó jásí! Rírékọjá ibodè láti ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ tí ó jẹ́ ti Canada jẹ́ àǹfààní dáradára kan.

Ìsapá Náà Ha Yẹ Fún Un Bí?

Nígbà tí ojú-ọjọ́ kò bá dára tí a sì wà lójúkan tàbí tí a dá wa dúró pẹ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nísinsìnyí, tàbí nígbà tí ọjọ́ gígùn tí a lò nínú ìwàásù bá jọ bí èyí tí kò mú ire kankan wa ju àìnífẹ̀ẹ́ tàbí àtakò pàápàá, nígbà náà a óò bẹ̀rẹ̀ síí ṣe kàyéfì bóyá gbogbo àkókò, okun, àti ìnáwó náà yẹ fún gbogbo ìsapá náà. A lè ronú nípa àwọn tí ó jọ bí ẹni pé wọ́n fi ìfẹ́ hàn tí wọ́n sì ṣèlérí láti kọ̀wé ṣùgbọ́n tí wọ́n kùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà náà ni a óò rántí pé kìí ṣe àṣà ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ni láti kọ lẹ́tà, ìwà bí ọ̀rẹ́ wọn ni a sì lè tètè ṣì lóye gẹ́gẹ́ bí ìfìfẹ́hàn sí ìhìn-iṣẹ́ Bibeli. Nígbà mìíràn ó dàbíi pé ó ṣòro lọ́pọ̀lọpọ̀ láti fojúdíwọ̀n àṣeyọrí.

Àwọn èrò òdì wọ̀nyí yára máa ń pòórá nígbà tí a bá rántí àwọn ìrírí dáradára ti àwọn akéde Ìjọba mìíràn. Fún àpẹẹrẹ, Ẹlẹ́rìí kan láti Fairbanks wàásù ní abúlé Barrow ní àríwá lọ́hùn-⁠ún. Níbẹ̀ ni òun ti ṣalábàápàdé ọ̀dọ́langba kan tí ó wá sílé fún ìsinmi láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga ní California. Arábìnrin náà ń mú ìfẹ́-ọkàn náà tẹ̀síwájú nípa kíkọ̀wé tí ó sì ń bá a lọ láti fún ọmọbìnrin náà ní ìṣírí àní nígbà tí ó padà sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga pàápàá. Lónìí, ọmọbìnrin náà jẹ́ ìránṣẹ́ Jehofa tí ó láyọ̀, tí ó sì ti ṣèrìbọmi.

Kíkàn tí a kan ilẹ̀kùn ta mi jí tí ó sì fi ẹ̀rí mìíràn hàn pé gbogbo rẹ̀ yẹ fún ìsapá náà. Elmer ni ó dúró síwájú ilẹ̀kùn, títí di ìsinsìnyí, oun nìkanṣoṣo ni Ẹlẹ́rìí ọmọ Inuit ní Nome tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́ ati ìrìbọmi.

“Bí o bá lè jáde lọ, mo ha lè tẹ̀lé ọ bí?” ni òun béèrè. Ní gbígbé ní àdádó tí ó sì fi 800 kìlómítà jìnnà sí ìjọ tí ó súnmọ́tòsí jùlọ, òun fẹ́ nípìn-⁠ín nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ nígbà tí àǹfààní rẹ̀ ṣísílẹ̀ fún un.

Ìtànṣán oòrùn bẹ̀rẹ̀ síí là àwọn ìkúukùu kọjá, a sì mọ̀ pé a óò fún wa ní àṣẹ láti gbéra láìpẹ́. Bí Elmer ti gòkè sínú ọkọ̀ òfuurufú náà, ojú rẹ̀ tí ń dán tí ó sì láyọ̀ mú ọkàn wa yọ̀. Àkànṣe ọjọ́ ni èyí jẹ́ fún Elmer. Òun ń tẹ̀lé wa lọ sí abúlé tí a ní lọ́kàn láti lọ wàásù fún àwọn ọmọ Inuit àwọn ènìyàn rẹ̀ fúnraarẹ̀, ní dídarapọ̀ mọ́ wa nínú ìgbìyànjú wa láti ṣí ìbòjú kúrò ní ọkàn-àyà àwọn tí ń gbé ní agbègbè tí kò fi bẹ́ẹ̀ lajú náà.​—⁠A kọ ọ́ ránṣẹ́.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 23]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

1. Gambell

2. Savoonga

3. Nome

4. Kotzebue

5. Barrow

6. Tuktoyaktuk

7. Fairbanks

8. Anchorage

9. Unalaska

10. Dutch Harbor

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Láti dé ọ̀dọ̀ àwọn àwùjọ tí ó wà ní àdádó, ó pọndandan lọ́pọ̀ ìgbà láti rékọjá ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ àwọn òkè gíga fíofío ní Alaska

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Betty Haws, Sophie Mezak, àti Carrie Teeples ní àpapọ̀ iye ọdún tí ó ju 30 nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò-kíkún

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́