ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 6/1 ojú ìwé 19-23
  • Wọ́n Fi Àpẹẹrẹ Lélẹ̀ Fún Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Fi Àpẹẹrẹ Lélẹ̀ Fún Wa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Bibeli
  • Ṣíṣe Aṣáájú-Ọ̀nà ní Australia
  • A Pè É sí Pápá Ilẹ̀ Àjèjì
  • Ìgbéyàwó, Ìfòfindè, àti Ogun
  • Ìgbésí-Ayé nínú Ọgbà Ìṣẹ́niíṣẹ̀ẹ́
  • Òmìnira àti Pípadàwàpapọ̀ Pípẹtẹrí
  • Ní Australia
  • Jehofa Wà Pẹ̀lú Mi
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ibi Tá A Ti Ń Ṣiṣẹ́ Míṣọ́nnárì Di Ilé Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 6/1 ojú ìwé 19-23

Wọ́n Fi Àpẹẹrẹ Lélẹ̀ Fún Wa

GẸ́GẸ́ BÍ CRAIG ZANKER TI SỌ Ọ́

Èmi àti aya mi, Gayle, ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, fún ọdún mẹ́jọ. Fún ọdún mẹ́fà tí ó kọjá, a ń ṣisẹ́sìn ní ìgbèríko Australia láàárín àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ tí ń gbé Australia. A wulẹ̀ ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ dídára tí àwọn òbí mi àti òbí mi àgbà fi lélẹ̀ fún wa.

JẸ́ KÍ n sọ fún ọ nípa àwọn òbí mi àgbà ní pàtàkì. A máa ń fìgbà gbogbo pè wọ́n ní Opa àti Oma lọ́nà ìfẹ́ni, èdè Dutch tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú bàbá àgbà àti màmá àgbà. Bàbá mi àgba, Charles Harris, ṣì ń fi ìtara ṣiṣẹ́sìn ní Melbourne, ibi tí ó ti ń gbé fún nǹkan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 50 ọdún.

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Bibeli

A bí Opa ní ìlú kékeré kan ní Tasmania, erékùṣù ìpínlẹ̀ Australia kan. Ní 1924, nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 14, bàbá rẹ̀ ra àpótí ìtọ́jú ẹrù awakọ̀ òkun kan níbi ìlugbàǹjo ọjà kan. Ó wá jẹ́ àpótí ìṣúra kan níti gidi, kí á sọ ọ́ lọ́nà tẹ̀mí, nítorí o kún fún ọ̀wọ́ àwọn ìwé tí ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Bible and Tract Society, Charles Taze Russell kọ.

Ó dàbí ẹni pé bàbá Opa kò ni ọkàn ìfẹ́ kan ní pàtàkì nínu àwọn ìwé náà, ṣùgbọ́n Opa bẹ̀rẹ̀ sí kà wọ́n ó sì mọ̀ kíákíá pé wọ́n kún fún àwọn òtítọ́ ṣíṣekókó inú Bibeli. Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí wá àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli Jákèjádò Àwọn Orílẹ̀-Èdè kiri, àwọn aṣojú òǹṣèwé náà tí a mọ̀ nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ó fẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀ kí ó baà lè gba àlàyé síi nípa àwọn òtítọ́ Bibeli tí òun ń kọ́.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìfìbéèrè wáni lẹ́nuwò ó rí àwọn obìnrin àgbàlagbà mẹ́ta tí wọ́n gbóṣáṣá nínú kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn. Wọ́n ni ipa lílágbára lórí Charles ọ̀dọ́. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ní 1930, ó ya araarẹ̀ sí mímọ́ fún Jehofa Ọlọrun ó sì ṣe ìrìbọmi nínú omi. Ó fi iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alápatà sílẹ̀ ó sì rìnrìn-àjò lọ sí àríwá Sydney, níbi tí ó ti gba iṣẹ́ àyànfúnni gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere alákòókò kíkún.

Ṣíṣe Aṣáájú-Ọ̀nà ní Australia

Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ tí ó tẹ̀lé e, agbègbè ẹ̀yìn odi ìlú ní etíkun Sydney náà Bondi àti inú àwọn ìgbèríko mìíràn ní ìpínlẹ̀ New South Wales ni ìpínlẹ̀ tí Charles ti ń wàásù. Nígbà tí ó ṣe a tún yàn án sí Perth, Ìwọ̀-Oòrùn Australia, tí ó fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà jìnnà ní òdìkejì kọ́ńtínẹ̀ntì náà. Fún oṣù mẹ́fà o jẹ́rìí ní ìpínlẹ̀ káràkátà ti Perth, àti lẹ́yìn náà, a yan òun àti àwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì mìíràn sí ibi gbígbòòrò tí ó ní olùgbé díẹ̀ ní ìhà àríwá ìwọ̀-oòrùn Australia.

Ibi iṣẹ́ ìwàásù tí a yàn fún àwọn ẹni mẹ́ta wọ̀nyí​—⁠Arthur Willis, George Rollsten, àti Charles​—⁠jẹ́ ibìkan tí o tóbi ju Italy lọ lọ́nà mẹ́rin! Àwọn tí ń gbé ibẹ̀ kò pọ̀, ilẹ̀ ẹ̀yìn ìlú jẹ́ aṣálẹ̀, ooru sì mú gan an. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ó máa ń béèrè pé kí wọ́n rìnrìn-àjò tí ó ju 500 kìlómítà lọ láàárín àwọn gàá, tí a mọ̀ sí àgọ́ màlúù. Ọkọ̀ tí wọ́n ń lò ti di ahẹrẹpẹ, àní bí a bá fi wé bí ọkọ̀ ṣe rí ní 1930, ṣùgbọ́n wọ́n ní ìgbàgbọ́ lílágbára wọ́n sì ní ìpinnu gan-⁠an.

Ọ̀nà eléruku tóóró, tí ó ní kòtò náà ni ọ̀pọ̀ àwọn ràkúnmí là kọjá, àwọn eruku múlọ́múlọ́ (tí a ń pè ní eruku màlúù) sì bo àwọn gbòǹgbò eléwu mọ́lẹ̀ lọ́tùn-⁠ún lósì. Abájọ tí ọ̀pá irin kọ́lọkọ̀lọ agbọ́kọ̀ró náà fi sábà máa ń kán. Ọ̀pá irin tí ń gbé táyà ọwọ́ ẹ̀yìn rẹ̀ kán nígbà méjì, táyà rẹ̀ sì ya láìmọye ìgbà. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà náà sábà máa ń ṣe ìtẹ́nú láti inú táyà tí ó ti gbó tí wọn yóò sì fi bóòtù dè wọ́n mọ́ inú táyà tí wọ́n ní láti lè máa bá ìrìn-àjò wọn lọ.

Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo béèrè lọ́wọ́ Opa ohun tí ó fún wọn ní ìṣírí láti máa báa lọ lábẹ́ iru ipò lílekoko bẹ́ẹ̀. Ó ṣàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn wà ní àdádó àwọn máa ń nímọ̀lára ìsúnmọ́ Jehofa pẹ́kípẹ́kí. Ó sọ pé ohun tí ó máa ń dàbí ìnira nípa ti ara, nígbà mìíràn, yóò wá di ìbùkún nípa tẹ̀mí.

Láìsí èrò ìlọ́lájuni tàbí jíjẹ́ olódodo lójú ara-ẹni, Opa fi ìyàlẹ́nu rẹ̀ hàn lórí bí ó ṣe dàbí ẹni pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń ṣàníyàn púpọ̀ nípa ohun-ìní ti ara. Ó rán mi létí pé, “Ó sàn jù láti gbé ìgbésí ayé oníwọ̀nba ohun-ìní bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó. Bí Jesu bá lè gbà láti sùn ní ìtagbangba nígbà tí ó bá pọndandan, a gbọ́dọ̀ láyọ̀ láti ṣe ohun kan náà bí iṣẹ́ àyànfúnni wa bá béèrè fún un.” (Matteu 8:​19, 20) Òun àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sì ṣe bẹ́ẹ̀ níti tòótọ́.

A Pè É sí Pápá Ilẹ̀ Àjèjì

Ní 1935, Opa gba iṣẹ́ àyànfúnni titun láti máa wàásù​—⁠láti jẹ́rìí fún àwọn olùgbé erékùṣù ti Gúúsù Pacific. Pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn atukọ̀ mẹ́fà mìíràn, ó rìnrìn-àjò lórí òkun nínú ọkọ̀-òkun ti Watch Tower Society tí ó gùn ní ìwọ̀n mítà 16 náà Lightbearer.

Nígbà kan, nígbà tí wọ́n wà ní Òkun Coral ní ìhà àríwá Australia, ẹ́ńjìnì aṣèrànlọ́wọ́ ti Lightbearer bàjẹ́. Afẹ́fẹ́ kọ̀ kò fẹ́, nítorí náà wọ́n tàn sí ibi tí ó fí ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ kìlómítà jìnnà sí ìyàngbẹ ilẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ewu wà pé ọkọ̀ lè fọ́ lórí Òkìtì Barrier Ńlá, ìparọ́rọ́ kíkọyọyọ náà wú Opa lórí. Ó kọ ọ́ sínú ìwé àkọsílẹ̀ ojoojúmọ́ rẹ̀ pé, “Òkun náà parọ́rọ́ gan an. Èmi kì yóò gbàgbé wíwọ̀ oòrùn ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní orí òkun píparọ́rọ́ yẹn. Ìran náà rẹwà tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi ń wà ní ọkàn mi nígbà gbogbo.”

Ó múni láyọ̀ pé, ṣáájú kí wọ́n tó súlọ síhà òkìtì náà, atẹ́gùn bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́, wọ́n sì tukọ̀ pẹ̀lú nína ìgbòkùn jáde tí wọ́n fi dé Port Moresby, Papua New Guinea láìséwu, níbi tí wọ́n ti tún ẹ́ńjìnì ṣe. Wọ́n tukọ̀ láti Port Moresby lọ sí Erékùṣù Thursday àti lẹ́yìn náà lọ sí Java, erékùṣù títóbi ti Indonesia. Opa mú ìfẹ́ jíjinlẹ̀ dàgbà fún orílẹ̀-èdè yìí tí a ti ṣàpèjúwe bí “ẹ̀gbà ọrùn tí a fi pearli ṣe tí ó la agbedeméjì ayé já.” Ní àkókò yẹn, Indonesia jẹ́ orìlẹ́-èdè tí ilẹ̀ Netherlands ń gbókèèrè ṣàkóso, nítorí náà bàbá àgbà kọ́ èdè Dutch àti èdè Indonesian. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó ń filọni nínú ìgbòkègbodò ìwàásù rẹ̀, wà ní èdè márùn-ún: èdè Dutch, Indonesian, Chinese, Gẹ̀ẹ́sì, àti Arabic.

Opa ṣàṣeyọrísírere gan-⁠an ní fífi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli sóde. Nígbà kan a pe Clem Deschamp, ẹni tí ń bójútó ibùdó ìkẹ́rùsí Watch Tower ní Batavia (tí a mọ̀ sí Djakarta nísinsìnyí), wá síwájú òṣìṣẹ́ olóyè ti Netherlands kan tí ó ti ń ṣọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa tọwọ́tẹsẹ̀. Òṣìṣẹ́ olóyè náà béèrè pé, “Ènìyàn mélòó ni ẹ ní tí ń ṣiṣẹ́ lọ́hùn-⁠ún ní Ìlà-Oòrùn Java?”

Arákùnrin Deschamp fèsì pé, “Ẹnìkan péré ni.”

“Ìwọ ha retí pé kí n gba ìyẹn gbọ́ bí?” ni òṣìṣẹ́ olóyè náà jágbe. “Ẹ níláti ní ọ̀pọ̀ yéye àwọn òṣìṣẹ́ níbẹ̀, bí a bá fi ojú ìwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yin tí ẹ pín síbi gbogbo wò ó!”

Opa nímọ̀lára pé ìyẹn ni ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìbuyìn fúnni títẹ́nilọ́rùn jùlọ tí òun tíì gbà rí nínú ìgbésí-ayé òun. Ṣùgbọ́n ó yẹ fún un dájúdájú, níwọ̀n bí kò ti ṣàjèjí fún un láti fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó tó 1,500 sí 3,000 sóde lóṣooṣù.

Ìgbéyàwó, Ìfòfindè, àti Ogun

Ní December 1938, Opa fẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin ará Indonesia kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Wilhelmina, ẹni tí ó wá di ìyá mi àgbà. Oma, tàbí ìyá àgbà, jẹ́ onínúure, ẹni pẹ̀lẹ́, aláápọn, àti ènìyàn jẹ́jẹ́. Mo mọ̀ nítorí pé nígbà tí mo wà lọ́mọdé òun ni ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi jùlọ.

Lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn Opa àti Oma jùmọ̀ ń bá iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà wọn lọ. Nígbà tí yóò fi di ìgbà yẹn àwọn mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ atukọ̀ Lightbearer yòókù ti túká sí apá ibòmíràn lágbàáyé tàbí kí wọ́n ti padà sílé. Ṣùgbọ́n Opa ti sọ Indonesia di ilé rẹ̀, ó sì ti pinnu láti dúró.

Bí Ogun Àgbáyé Kejì ti ń súnmọ́lé, ìjọba Nertherlands tí ń ṣàkóso Indonesia, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí àwọn àlùfáà, bẹ̀rẹ̀ sí ká ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lọ́wọ́ kò, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ wọ́n fòfinde iṣẹ́ wa. Nítorí èyí iṣẹ́ ìwàásù di èyí tí a ń ṣe pẹ̀lú ìṣòro, ní lílo Bibeli nìkan. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ gbogbo ìlú tí Opa àti Oma bẹ̀wò, ní a ti mú wọn lọ síwájú òṣìṣẹ́ olóyè tí wọ́n si jẹ́jọ́. A hùwà sí wọn bí ọ̀daràn. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí ìfòfindè náà bẹ̀rẹ̀ ẹ̀gbọ́n ọkọ Oma ni a fi sẹ́wọ̀n fún ìdúró Kristian aláìdásí tọ̀tún tòsì rẹ̀. Ó kú sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ilẹ̀ Netherlands kan.

Opa àti Oma gbé nínú ọkọ̀ ẹrù kan tí a kọ ilé àgbérìn kan sí lẹ́yìn. Ní lílo ilé àgbérìn yìí, wọ́n wàásù jákèjádò Java. Ní 1940, bí ìhalẹ̀mọ́ni ìgbógunwọlé àwọn ológun ilẹ̀ Japan ti ń rọ̀dẹ̀dẹ̀, a bùkún wọn pẹ̀lú ọmọbìnrin kan, ẹni tí ó wá di ìyá mi. Wọ́n sọ ọmọ jòjòló náà ní Victory (Ìṣẹ́gun), ní ìrántí àkòrí ọ̀rọ̀ àsọyé tí ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society, J. F. Rutherford sọ ní ọdún méjì sẹ́yìn. Wọ́n ń bá ṣíṣe aṣaájú-ọ̀nà lọ la gbogbo àkókò ìbímọ náà já.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ 1942, Opa, Oma, àti Victory wà nínú ọkọ̀ òkun akẹ́rù kan tí ó jẹ́ ti Netherlands tí ń bọ̀ láti Borneo nígbà tí wọ́n gbọ́ ìró ìbọn kíkan kíkan láti inú ọkọ̀ ogun ojú omi ti ilẹ̀ Japan kan. Kò sí ìmọ́lẹ̀ kankan, àwọn ènìyàn sì figbeta. Ní ọ̀nà yìí ogun náà nípa lórí ìgbésí ayé ìdílé mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn padà sí ebútékọ̀ lálàáfíà, àwọn ará Japan gbógunti Java ní ìwọ̀ǹba ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, òṣìṣẹ́ olóyè Netherlands kan sì táṣìríí ibi tí Opa àti Oma wà fún àwọn ṣójà ilẹ̀ Japan.

Nígbà tí àwọn ará Japan náà rí wọn, wọ́n kó gbogbo ohun ìní wọn pátápátá, àní títí kan ohun ìṣeré Victory jòjòló, wọ́n sì gbé wọn lọ sí ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Wọ́n gbà kí Victory dúró sọ́dọ̀ Oma, Opa kò sì fojú kàn wọ́n fún ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ tí ó tẹ̀lé e.

Ìgbésí-Ayé nínú Ọgbà Ìṣẹ́niíṣẹ̀ẹ́

Lákòókò tí ó fi wà ní àhámọ́, Opa ní a ń gbé kiri láti ìlú kan sí òmíràn​—⁠láti Surabaja lọ sí Ngawi, sí Bandung, àti nígbẹ̀yìn gbẹ́yín sí Tjimahi. Ìgbékiri léraléra yìí jẹ́ láti dojú ìsapá àpawọ́pọ̀ṣe èyíkéyìí láti sá jáde délẹ̀. Àwọn ara Netherlands ni wọ́n pọ̀ jù nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà, pẹ̀lú ìwọ̀ǹba àwọn ara Britain àti Australia díẹ̀. Nígbà tí ó wà ní ibùdó náà, Opa kọ́ iṣẹ́ irun gígẹ̀, iṣẹ́ àmúṣe kan tí ó ṣì máa ń ṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ìwé ìsìn kanṣoṣo tí a gbà á láyè láti mú wọlé ní Bibeli​—⁠King James Version rẹ̀.

Lákòókò yìí, Oma àti Victory ni a ń gbé kiri láti ibùdó kan sí òmíràn. Nínú àwọn ibùdó wọ̀nyí ọ̀gágun ibùdó náà máa ń pe àwọn obìnrin láti ṣiṣẹ́ níta fún “iṣẹ́ ìsìn ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbá.” Bí ó ti wù kí ó rí, fún àwọn ìdí kan, a kò yan Oma rí. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ó gbọ́ pé a ń mú àwọn obìnrin náà jáde láti di aṣẹ́wó fún àwọn ṣójà ilẹ̀ Japan.

Níwọ̀n bí àwọn ṣójà ilẹ̀ Japan kìí tií rí àwọn ọmọdébìnrin sójú, Oma máa ń múra fún Victory gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin nígbà gbogbo tí yóò sì gé irun rẹ̀ mọ́lẹ̀. Orúkọ náà Victory dá wàhálà sílẹ̀ nígbà tí ọ̀gágun ibùdó náà fẹ́ mọ ohun tí orúkọ náà dúró fún​—⁠Ìṣẹ́gun fún Aláyélúwà Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ilẹ̀ Japan tàbí Ìṣẹ́gun fún àwọn ara America?

“Ìṣẹ́gun fún Ìjọba Ọlọrun lórí gbogbo ìṣàkóso orí ilẹ̀-ayé!” ni ìyá mi àgbà fi pẹ̀lú ìyangàn dáhùn.

Gẹ́gẹ́ bí ìjìyà fún kíkọ̀ láti sọ pé, “Ìṣẹ́gun fún Aláyélúwà Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ilẹ̀ Japan,” Oma àti ọmọbìnrin rẹ̀ ọlọ́dún márùn-⁠ún ní a fipá mú láti wà ní ìdúró ṣánṣán fún wákàtí mẹ́jọ nínú oòrùn ilẹ̀ olóoru tí ń jóni lara fòfò. Kò sí ibòji, kò sí omi, kò sí jíjókòó, kò sí ṣíṣísẹ̀ síwájú. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànwọ́ Jehofa wọ́n la ìdańwò lílekoko tí ń muniláyà pami yìí já.

Ní ọdún kan lẹ́yìn tí Oma ti wà ní àhámọ́, ọ̀gágun ibùdó náà sọ fún un pé ọkọ rẹ̀ ti kú! Ó gbé fọ́tò Opa sí ìsàlẹ̀ àpótí rẹ̀ tí ó ti já ó sì ń báa lọ, láìka ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ sí.

Ìgbésí-ayé nínú ibùdó ẹ̀wọ̀n kò rọrùn rárá. Oúnjẹ òòjọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ ife sítáàṣì kan fún oúnjẹ àárọ̀, ìwọ̀n 190 gíráàmù búrẹ́dì tí a fi èso sago ṣe fún oúnjẹ ọ̀sán, oúnjẹ alẹ́ ní tirẹ̀ jẹ́, ife ìrẹsì tí a sè sínú ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ olómitooro. Nítorí oúnjẹ tí kò tó nǹkan yìí, àrùn àìjẹunrekánú wọ́pọ̀, tí àwọn tí wọ́n jìyà lọ́wọ́ ìgbẹ́ ọ̀rìn sì ń kú lójoojúmọ́.

Láàárín ìgbà tí Opa fi wà ní àhámọ́, ó jìyà lọ́wọ́ àrùn ara wíwú àti ara yíyó rọ̀tọ́rọ̀tọ́ tí àìjẹunrekánú (àrùn ìjìyà lọ́wọ́ ebi) ń fà. Oma náà fẹ́rẹ̀ẹ́ kú, níwọ̀n bí òun ti máa ń gbé oúnjẹ rẹ̀ fún Victory láti lè dáàbòbo ọmọdébìnrin jòjòló yìí kí ebi má baà lù ú pa. Ìwà òǹrorò àti ìfebipani di ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Wọ́n lè làájá kìkì nípa sísúnmọ́ Jehofa, Ọlọrun wọn pẹ́kípẹ́kí.

Mo rántí ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ àyànláàyò Opa dáradára pé: “Wíwà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ẹni ti Ọ̀run, Jehofa ni ó jẹ́ òmìnira.” Nítorí ìdí èyí, Opa gbà pé òun ní òmìnira níti gidi àní nígbà tí ó ń farada ìfinisẹ́wọ̀n lílekoko. Ìfẹ́ tí òun àti Oma ní fún Jehofa ṣèrànwọ́ fún wọn láti lè ‘farada ohun gbogbo.’ (1 Kọrinti 13:⁠7) Ìbátan tímọ́tímọ́ yẹn pẹ̀lú Ọlọrun ní ohun tí èmi àti Gayle ń gbìyànjú láti dìmú.

Òmìnira àti Pípadàwàpapọ̀ Pípẹtẹrí

Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, Ogun Àgbáyé Kejì parí ní 1945. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí ilẹ̀ Japan túúbá, a mú Opa rin ìrìn-àjò nínú ọkọ̀ rélùwéè. Nínu ìrìn-àjò láti Djakarta sí Bandung, àwọn ṣójà ilẹ̀ Indonesia dá ọkọ̀ rélùwéè náà dúró. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkóguntìni pẹ̀lú àwọn ará Japan ti dópin, àwọn ará Indonesia ṣì ń jà fún òmìnira látọwọ́ àwọn ara Netherlands. Ẹnu ya Opa bí wọn ṣe já a jù sílẹ̀ nínú ọkọ̀ rélùwéè náà tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi gbàgbé láti sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ede Dutch. Sí àwọn ara Indonesia, èdè Dutch jẹ́ èdè àwọn ọ̀tá, ọ̀tá náà ni a sì gbọ́dọ̀ pa.

Ọpẹ́lọpẹ́ pé, bí àwọn ṣójà náà ti ń yẹ ara Opa wò, wọ́n rí ìwé ìwakọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ará Australia, èyí tí òun ti gbàgbé nípa rẹ̀ pátápátá. Ó jẹ́ ayọ̀ wa pé, àwọn ara Indonesia kò bá àwọn ará Australia jagun. Títí di òní olónìí, Opa ka rírí ìwé ìwakọ̀ rẹ̀ tí ó fi í hàn gẹ́gẹ́ bí ọlọ̀tọ̀ ilẹ̀ Australia sí dídásí ọ̀ràn látọ̀runwá, nítorí pé ní wákàtí díẹ̀ síi lójú kan náà yẹn gan-⁠an, àwọn ọmọ ogun wọ̀nyí pa àwọn ọkùnrin 12 ará ilẹ̀ Netherlands tí wọ́n ń kọjá lórí rélùwéè náà.

Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Oma àti Victory ń dúró de ọkọ̀ láti ẹkùn tí ogun ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Bí wọ́n ti jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, wọ́n rí àìmọye ọkọ̀ akẹ́rù tí ń kọjá lọ tí wọ́n tò tẹ̀léra tí wọ́n sì gbé àwọn ṣójà àti ará ìlú. Lójijì, láìmọ ohun tí ó fà á, ìtòtẹ̀léra náà dúró. Ó ṣẹlẹ̀ pé Oma bẹjúwo ẹ̀yìn ọkọ̀ akẹ́rù tí ó súnmọ́ ọn jùlọ, sí ìyàlẹ́nu rẹ̀, níbẹ̀, ní ọkùnrin kan tí ó tètè dámọ̀ tí ó ti rù hangogo jókòó sí. Ọkọ rẹ̀ ni! Kò sí ohun tí a lè sọ tí ó lè fi bí ìmọ̀lára wíwàpapọ̀ wọn ti tó hàn.

Ní Australia

Nígbà tí bàbá àgbà padà sí Australia pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ ní 1946, lẹ́yìn tí ó ti gbé ní Indonesia fún ọdún 11, ìgbésí-ayé kò rọrùn fún wọn. Wọ́n padà bí àwọn olùwá-ibi-ìsádi​—⁠abòṣì, aláìjẹunrekánú, tí àwọn ará àdúgbò ń fura sí. Oma àti Victory níláti jìyà ẹ̀tanú ẹ̀yà-ìran lòdìsí àwọn tí wọ́n ṣí wá láti Asia. Opa níláti ṣiṣẹ́ àṣekára àní fún ọ̀pọ̀ wákàtí láti lè bójútó ìdílé rẹ̀ kí ó sì pèsè ilé kan fún wọn. Láìka àwọn ìnira wọ̀nyí sí, wọ́n lo ìfaradà wọ́n sì pa ipò tẹ̀mí wọn mọ láìyingin.

Ní báyìí, ọdún 48 lẹ́yìn náà, Opa ń gbé ní Melbourne, níbi tí òun ṣì ń nípìn-ín nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé. Òun ti rí Victory àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọn tẹ́wọ́gba òtítọ́, tí wọ́n ya ìgbésí-ayé wọn sí mímọ́ sí Jehofa, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì wọnú iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà alákòókò kíkún.

Des Zanker, tí ó di bàbá mi, àti Victory ṣe ìrìbọmi ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1950, tí Des sì di mẹ́ḿbà ìdílé Beteli ti Australia ní 1958. Lẹ́yìn tí ó fẹ́ Victory, ẹni tí ó ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ìgbà díẹ̀ àti lẹ́yìn náà a pè wọ́n sínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò. Nígbà yẹn ni a bí mi, wọ́n sì níláti fi iṣẹ́ arìnrìn-àjò sílẹ̀ láti lè tọ́ mi dàgbà. Síbẹ̀, lẹ́yìn ọdún 27, Dádì ṣì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ 1990, Oma fọwọ́rọrí kú nílé, nínú ilé kan náà tí a ti tọ́ ìyá mi dàgbà. Inú ilé kan náà yìí ni a ti tọ́ mi dàgbà ni Melbourne, bákan náà sì ni àbúrò mi ọkùnrin àti obìnrin. Ó ti jẹ́ ìbùkún gidigidi fún ìdílé wa láti ṣàjọpín ilé kan papọ̀. Nígbà mìíràn ó máa ń fún jù, ṣùgbọ́n ń kò lè rántí ìgbà kankan tí mo ṣàníyàn nípa rẹ̀. Àní láàárín ọdún mẹ́rin àkọ́kọ́ ìgbéyàwó wa, aya mi, Gayle, fúnraarẹ̀ gbé níbẹ̀ ó sì gbádùn rẹ̀. Nígbà tí a lọ fún iṣẹ́-àyànfúnni wa titun níkẹyìn, mo bú sẹ́kún. Mo ti ri ìtìlẹ́yìn àti ìfẹ́ tí ó pọ̀ gan-⁠an gbà nínú ilé yẹn.

Nísinsìnyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, èmi àti Gayle ní ìdí fún ayọ̀ jaburata, nítorí tí ó ṣeéṣe fún wa láti ṣe ohun tí àwọn òbí mi àti àwọn òbí wọn àgbà ṣe ṣáájú wọn. Nígbà tí a fi ilé sílẹ̀, a rí ìtùnú nínú ìdí tí a fi lọ, èyí tí ó jẹ́ láti ṣe ìfẹ́-inú Jehofa nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. A ń gbìyànjú gidigidi láti tẹ̀lé àpẹẹrẹ dídára ti àwọn bàbá-ńlá wa olùṣòtítọ́, tí wọ́n rí irú ìtùnú tí ó farajọra nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ìpínlẹ̀ lílekoko, nígbà tí wọ́n wà ní ìpò òṣì lílékenkà, àti nígbà tí wọ́n tilẹ̀ tì wọ́n mọ́lé fún ọ̀pọ̀ ọdún nínú ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ilẹ̀ Japan.​—⁠2 Korinti 1:​3, 4.

Opa ti máa ń fìgbà gbogbo rí ìtùnú nínú ọ̀rọ̀ onímìísí Ọba Dafidi sí Jehofa pé: “Ìṣeun-ìfẹ́ rẹ sàn ju ìyè lọ.” (Orin Dafidi 63:⁠3) Ó ti sábà máa ń jẹ́ ìfẹ́-ọkàn jíjinlẹ̀ bàbá-àgbà láti gbádùn ìṣeun-ìfẹ́ yẹn títíláé. Ó jẹ́ ìfẹ́-ọkàn ìdílé rẹ̀ lápapọ̀ láti bá a nípìn-⁠ín nínú rẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Oma àti Opa Harris

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Craig Zanker (lẹ́yìn), pẹ̀lú ìyàwó, àwọn òbí àti àbúrò rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́