Ṣọ́ọ̀ṣì kan Tí Ìyapa Wà—Báwo Ni Ó ṣe Burú Tó?
“GẸ́GẸ́ bí ìdílé ńlá kan tí ẹ̀rù ń bà, tí ń gbé nínú ilé ògbólógbòó kan tí ó ti di ẹgẹrẹmìtì èyí tí ògiri iwájú rẹ̀ yalulẹ̀ lójijì, ó dàbí ẹni pé èdèkòyédè kan ń ṣẹlẹ̀ nínú iyàrá kọ̀ọ̀kan—tí àwọn ọmọ Jesu tí wọ́n ń lu pẹ́rẹ́ṣẹkẹ sì ń lọgun lé àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ onísìn Anglikan arinkinkin mọ́ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Katoliki tí wọ́n wọ aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ onísílíkì lórí.”—The Sunday Times, London, April 11, 1993.
Ṣọ́ọ̀ṣì England ni ìdílé yìí. Èdèkòyédè náà sì dálórí gbígba àwọn obìnrin sínú ipò ẹgbẹ́-àlùfáà. Àpèjúwe kedere náà nípa àìsí ìṣọ̀kan lọ́nà tí ó jinlẹ̀ yìí tún kan gbogbo Kristẹndọm bákan náà. Bí àwọn bíṣọ́ọ̀bù Ṣọ́ọ̀ṣì Orthodox àti póòpù kò ti fọwọ́sí ìpinnu náà pé kí a gba àwọn obìnrin láyè láti jẹ́ àlùfáà, ìròyìn kan parí èrò pé, ìyọrísí náà ní gbogbogbòò ni pé “àlá náà nípa ìtúnsọdọ̀kan pẹ̀lú ìyókù Kristẹndọm túbọ̀ ń di àléèbá síi ju ti ìgbàkígbà rí lọ.”
Báwo ni Ìyapa Inú Ṣọ́ọ̀ṣì náà Ṣe Tó?
Gẹ́gẹ́ bí a ti kà nínú Matteu 7:21, Jesu Kristi wí pé ọ̀pọ̀ yóò jẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ nínú òun gẹ́gẹ́ bí Oluwa ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọn yóò kùnà láti ‘ṣe ìfẹ́-inú baba òun.’ Ìwé ìròyìn Maclean’s ṣàlàyé pé: “Àwọn òǹkàwé ìwé Matteu tí wọ́n ń wá ìgbàlà ni a lè fi ojú àánú hàn sí nítorí ìdàrúdàpọ̀ nípa ohun tí ìfẹ́-inú Ọlọrun jẹ́ níti gidi, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn Kristian, àti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wọn, kò fohùnṣọ̀kan rárá lórí ọ̀ràn náà.” Lẹ́yìn ìwádìí èrò kan tí ó wáyé láàárín àwọn ará Canada, ó parí èrò pé “ìyàtọ̀ tí ó gadabú [wà] nínú èrò-ìgbàgbọ́ àti àṣà àwọn Kristian ará Canada—ìyàtọ̀ tí ó túbọ̀ pọ̀ síi [wà] láàárín àwọn mẹ́ḿbà tí wọ́n jẹ́ ti ẹ̀ka-ìsìn èyíkéyìí, tí ó pọ̀ níti tòótọ́, ju èyí tí ó wà láàárín onírúurú ẹ̀ka-ìsìn náà fúnraawọn lọ.”
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìíkiri rẹ̀ ti fihàn, ìpín 91 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn onísìn Katoliki fọwọ́sí ìlò ìfètòsọ́mọbíbí àtọwọ́dá àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pè ṣọ́ọ̀ṣì wọn dẹ́bi fún un; ìpín 78 nínú ọgọ́rùn-ún ronú pé a gbọ́dọ̀ gba àwọn obìnrin láyè láti di àlùfáà; tí ìpín 41 nínú ọgọ́rùn-ún sì tẹ́wọ́gba ìṣẹ́yún “nínú àwọn àyíká ipò kan ní pàtó.” Maclean’s sọ pé, àìfohùnṣọ̀kan láàárín àwọn ẹ̀ka-ìsìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí “ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀ràn nípa ẹ̀kọ́-ìsìn, nú ẹnu mọ́ àwọn ìyapa tí ń fa ìpínyà náà tí ó wà láàárín àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí ń bẹ lójú ọpọ́n.”
Àwọn Ọ̀pá-Ìdíwọ̀n Èyí-Kàn-Mí-Kò-Kàn-Ọ́
Àwọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n èyí-kàn-mí-kò-kàn-ọ́ àti àwọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n fíforígbárí wà lórí ọ̀ràn ìwàhíhù. Àwọn kan jẹ́wọ́ pé àwọn di ìlànà Bibeli mú, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn ń tẹ́ḿbẹ́lú wọn. Fún àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ ayẹyẹ “ìgbéyàwó” tí a ṣe fún àwọn Obìnrin Abóbìnrinlòpọ̀ méjì ní Ṣọ́ọ̀ṣì Metropolitan ti Toronto, ha wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-inú Ọlọrun bí? Ẹ̀rí fihàn pé àwọn olùkópa náà ronú bẹ́ẹ̀. Wọ́n wí pé, “A fẹ́ láti ṣayẹyẹ ìfẹ́ wa ní gbangba àti níwájú Ọlọrun.”
Akọ̀ròyìn kan béèrè pé báwo ni ó ti rí tí ó fi jẹ́ pé “olórí àwọn bíṣọ́ọ̀bù Katoliki kan tí a ti fẹ̀sùnkàn léraléra, gbé àwọn àlùfáà tí ń bá àwọn ọmọdé lòpọ̀ lọ sọ́dọ̀ ọ̀wọ́ àwọn ọmọdékùnrin mìíràn tí wọ́n ń ṣèránṣẹ́ nídìí pẹpẹ.” Àlùfáà Andrew Greeley ronú pé nǹkan bíi 2,000 sí 4,000 àwọn àlùfáà ti lè fi ìbálòpọ̀ jẹ 100,000 àwọn ọmọdé tí wọn kò tíì tó ọjọ́-orí tí òfin fọwọ́sí fún ìbálòpọ̀ níyà, láìjẹ́ pé a ṣe ohun kan sí i lọ́pọ̀ ìgbà.
Ṣọ́ọ̀ṣì kan tí kò sí ní ìṣọ̀kan ń mú àwọn ènìyàn tí kò sí ní ìṣọ̀kan jáde. Ní àwọn ilẹ̀ Balkan, àwọn “Kristian” ará Serbia àti Croatia ronú pé Kristi wà pẹ̀lú àwọn nínú ogun “òdodo” wọn. Ọ̀pọ̀ gbé àgbélébùú kọ́rùn lójú ogun; a ròyìn rẹ̀ pé ọ̀kan, “máa ń sábà gbé àgbélébùú rẹ̀ kọ́ ẹnu nígbà tí ìjà náà bá le jùlọ.”
“Kí Ìyapa Kí Ó Máṣe Sí Nínú Yín”
Lóòótọ́, Bibeli fi àwọn ọ̀ràn kan lé ẹ̀rí-ọkàn lọ́wọ́, ṣùgbọ́n èyí kò gbọ́dọ̀ fàyègba irúfẹ́ ìyapa bẹ́ẹ̀. Aposteli Paulu sọ ní kedere pé: “Kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ [kí ẹ sì máa hùwà lọ́nà] kan náà, kí ìyapa kí ó máṣe sí nínú yín.”—1 Korinti 1:10; Efesu 4:15, 16.
Fífi ojú àìṣẹ̀tàn wo “Ìsìn Kristian” ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn lẹ́yìn tí aposteli Paulu kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì gbé àwọn ìbéèrè wíwúwo gan-an dìde. Èéṣe tí ìyapa fi pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ láàárín “àwọn Kristian”? Irú ṣọ́ọ̀ṣì tí ìyapa bẹ́ẹ̀ wà ha lè làájá bí? Kristẹndọm kan tí ó wà ní ìṣọ̀kan yóò ha wà láé bí? Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e yóò gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀wò.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Ìwọ́de àwọn àlùfáà lòdìsí ìṣẹ́yún
[Credit Line]
Èpo ẹ̀yìn ìwé àti lókè: Eleftherios/Sipa Press