Àpéjọpọ̀ “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” ní Ethiopia—Àkókò Ìdùnnú Àrà-Ọ̀tọ̀
ÒUN kọ́ ni àpéjọpọ̀ àkọ́kọ́ ní Ethiopia láti ìgbà tí a ti mú ìfòfindè kúrò, ṣùgbọ́n ó jẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ níti gidi. Láti ìgbà tí wọ́n ti gba ìdánimọ̀ lábẹ́ òfin ní November 11, 1991, ìgbà kẹta nìyí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yóò pàdé ní ibi ìṣeré ìdárayá títóbi jùlọ ní orílẹ̀-èdè náà, Ibi Ìṣeré Ìdárayá City, ní àárín gbùngbùn Addis Ababa gan-an. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ojúkò yìí kìí wà lárọ̀ọ́wọ́tó látilẹ̀wá ní àwọn ọjọ́ Sunday tí a kò sì lè rí ilé-lílò mìíràn tí ó tóbi tó, a pa ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà pọ̀ sí ọjọ́ mẹ́ta, láti Thursday sí Saturday, January 13 sí 15, 1994.
Àwọn ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí tunilára kìí ṣe nítorí ojú ọjọ́ lílọ́wọ́ọ́wọ́ lábẹ́ àwọsánmà dídúdú bí aró nìkan bíkòṣe nítorí ìlàlóye tẹ̀mí bákan náá pẹ̀lú ìyọrísí kíkún ti “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá.” Láàárín àwọn òdòdó fífanimọ́ra tí a fi dárà sí pèpéle náà yíká, ẹṣin-ọ̀rọ̀ àpéjọpọ̀ náà farahàn lọ́nà títayọ ní lẹ́tà èdè Amharic.
Ṣùgbọ́n kí ni ó mú àpéjọpọ̀ náà ṣàrà-ọ̀tọ̀? Papọ̀ pẹ̀lú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ dídọ́ṣọ̀, ìrònú àti ìmọ̀lára ẹnìkọ̀ọ̀kan ní a papọ̀ sórí ìfẹ́ ẹgbẹ́ ará wa kárí ayè àti ìfihàn kedere ìbùkún Ọlọrun lórí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ọ̀nà ìdàgbàsókè Ìjọba. Àwọn àyànṣaṣojú bíi 270 tí wọ́n wá láti ilẹ̀-òkèèrè láti ilẹ 16 pésẹ̀ síbẹ̀, títíkan àwọn ará Djibouti àti Yemen. Iye tí ó ju ìdajì lọ wá láti ibi tí ojú ọjọ́ ti tutù ní Europe àti North America. Méjì lára àwọn mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, Lloyd Barry àti Daniel Sydlik wà lára àwọn olùṣèbẹ̀wò náà.
Àṣà ìṣenilálejò tí àwọn ara Ethiopia ní papọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ àtọkànwá fún àwọn ara wọn tí ń ṣèbẹ̀wò yọrísí ayọ̀-ṣìnkìn tí ó borí àìgbédè araawọn. Ìkíni náà kò wulẹ̀ jẹ́ bíbọwọ́ lásán ṣùgbọ́n gbígbánimọ́ra àti fífẹnukonilẹ́nu, ní ìgbà mẹ́fà léraléra! Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣèbẹ̀wò ti kà nípa iṣẹ́ Ìjọba náà ní Ethiopia wọ́n sì mọ̀ pé àwọn ará wọn ní Ethiopia jẹ́ àwọn olùpàwàtítọ́mọ́ tí a ti dánwò tí wọ́n ti lo ìforítì la ìfiniṣẹ́wọ̀n àti irú inúnibíni mìíràn já.a Ṣùgbọ́n ẹnú ya àwọn àyànṣaṣojú tí ń ṣèbẹ̀wò láti rí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí ojú wọn kún fún ayọ̀ àti ìwà ọmọlúwàbí tí ó ti ń wọ̀ọ̀kùn ní àwọn ilẹ̀ púpọ̀ jùlọ lónìí. Ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin ará Ethiopia wọ àwọn ẹ̀wù ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn funfun, tí a fi òye-iṣẹ́ ṣe ọnà sí lára, èyí tí ó fikún ẹ̀mí àjọyọ̀ tòótọ́ kan.
Ìrìbọmi ọjọ́ Friday jẹ́ arùmọ̀lárasókè. Àwọn 530 aṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèyàsímímọ́ tí wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́, láti ẹni ọdún 10 sí 80 la ìdajì pápá ibi ìṣeré ìdárayá náà já bí wọ́n ti gùn tó. Èyí pọ̀ púpọ̀ ju iye tí ẹnikẹ́ni ti lè retí lọ—ó ju ènìyàn 1 lọ fún olúkúlùkù Ẹlẹ́rìí 7 ní orílẹ̀-èdè náà. Ẹ wo ẹ̀rí ìbùkún Jehofa tí èyí jẹ́ lórí àwọn ènìyàn rẹ̀ níhìn-ín! Ìran yìí pẹlu orin títunilára láti ẹnu awọn 40 àyànṣaṣojú láti ilẹ̀ Italy túbọ̀ fikún omijé ayọ̀ tí ń dà lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀. Ọ̀pọ̀ ronú nípa àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ ti Isaiah 60:5 pé: “Nígbà náà ni ìwọ óò ri, ojú rẹ ó sì mọ́lẹ̀, ọkàn rẹ yóò sì yípadà, yóò sì di ńlá: nítorí a óò yí ọrọ̀ òkun padà sí ọ, ipá àwọn Keferi yóò wá sọ́dọ̀ rẹ.”
Àwọn Okùnfà Àrà-Ọ̀tọ̀ fún Ìdùnnú
Ìbùkún Jehofa ni a tẹnumọ́ síwájú síi ní ọjọ́ Friday, nígbà tí a mú ìbẹ̀rẹ̀ ráńpẹ́ iṣẹ́ Ìjọba náà ní Ethiopia wá sí ìrántí nípasẹ̀ ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. Ìwọ̀nyí ni a ṣe pẹ̀lú àwùjọ àwọn míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ tí wọ́n ti ṣiṣẹ́sìn níbẹ̀ ní àwọn ọdún 1950 àti 1970. Iye tí ó fi púpọ̀ ju 8,000 lọ gbọ́ bí Ray Casson, John Kamphuis, àti Haywood Ward ṣe ṣàpèjúwe iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọn, bẹ̀rẹ̀ láti September 14, 1950, nígbà tí wọ́n dé sí Addis Ababa. Ìjọba aláyélúwà ti àwọn àkókò wọnnì béèrè pé wọ́n níláti jẹ́ aláápọn nínú ìmọ̀-ẹ̀kọ́ ní gbogbogbòò. Nítorí náà wọ́n dá ilé-ẹ̀kọ́ kan sílẹ̀ fún ẹ̀kọ́ àgbà ní àárín ìlú, tí ń kọ́ni ní onírúurú kókó-ẹ̀kọ́. Ṣùgbọ́n ní àwọn àkókò tí wọ́n yà sọ́tọ̀, àwọn mísọ́nnárì wọ̀nyí wá ọ̀nà láti mú ìmọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó dálórí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá tẹ̀síwájú. Wọ́n níláti sakun láti kọ́ èdè Amharic, èdè kan tí ó díjú pẹ̀lú álífábẹ́ẹ̀tì onílẹ́tà 250. Nǹkan bí oṣù mẹ́fà kọjá lọ kí wọ́n tó kẹ́sẹjárí ní dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọn àkọ́kọ́. Ní nǹkan bí ọdún 43 lẹ́yìn náà, wọ́n bá àwọn ènìyàn pàdé ní ìgboro tí wọ́n rántí àwọn olùkọ́ wọn tẹ́lẹ̀rí wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, ní àpéjọpọ̀ náà, wọ́n láyọ̀ láti tún wà papọ̀ pẹ̀lú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọn àtijọ́ tí wọ́n ti di alágbára nínú ìgbàgbọ́, tí wọ́n sì ń fi wọ́n hàn àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ tiwọn nípa tẹ̀mí.—1 Tessalonika 2:19, 20.
Àwùjọ olùgbọ́ onídùnnú àti olùtẹ́tísílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ náà pàtẹ́wọ́ fún ìgbà pípẹ́ kìí ṣe kìkì sí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn mísọ́nnárì tẹ́lẹ̀rí náà nìkan ṣùgbọ́n sí àwọn ìròyìn àti ìkíni láti Britain, Canada, Germany, Israel, Italy, Kenya, Netherlands, àti United States—tí àwọn aṣojú láti ilẹ̀ òkèèrè mú wá pẹ̀lú. Èyí pẹ̀lú tún tẹnumọ́ ìfẹ́ ẹgbẹ́ ará kárí ayé ti àwọn ènìyàn Ọlọrun. Àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé pàtàkì tí a sọ láti ẹnu àwọn arákùnrin ẹni-àmì-òróró tí wọ́n jẹ́ ara Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, àti àdúrà àtọkànwá wọn pẹ̀lú, tún ru ìmọ̀lára àwùjọ olùgbọ́ sókè gidigidi. Àwọn ọ̀dọ́ inú ibi ìṣeré ìdárayá náà lè rí araawọn nínú àwọn olùkópa nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà nípa àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rántí Ẹlẹ́dàá wọn, àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà ni a gbékalẹ̀ gẹ́lẹ́ bí ọ̀ràn náà ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ àti lọ́nà tí ó tanijí. Ní àfikún sí àwọn ìtẹ̀jáde titun ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, àwọn ìtẹ̀jáde titun mẹ́ta mìíràn léde Amharic ru ìtara ọkàn wọn sókè lọ́pọ̀lọpọ̀.b
Ní àwọn àkókò ìsinmi ráńpẹ́ àti ní àwọn ìgbà mìíràn, àwọn àǹfààní dídára wà láti di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ẹni ọ̀wọ́n. Fún àpẹẹrẹ, ní ìlà iwájú gan-an, ni Tulu Mekuria akéde tí ó dàgbà jùlọ ní Ethiopia jókòó sí, pẹ̀lú ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ àtọwọ́dá lọ́wọ́ rẹ̀. Ní èṣí, ní ẹni ọdún 113, a baptisi rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ní àpéjọpọ̀ yìí inú rẹ̀ dùn láti rí i tí ìyàwó rẹ̀ ẹni 80 ọdún tẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ní dídi arábìnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí pẹ̀lú. Wíwà níbẹ̀ rẹ̀ ní gbogbo àkókò ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà jẹ́ ìṣírí ńláǹlà fún àwọn ọ̀dọ́. Ọ̀kan lára irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni Yohanes Gorems, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 16 tí ó sì jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ tí ó sì ti ṣiṣẹ́sìn fún ọdún mẹ́rin gẹ́gẹ́ bí akéde aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Òun àti àwọn aṣáájú-ọ̀nà mìíràn tí wọ́n ṣì jẹ́ ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ tí wọ́n tilẹ̀ tún kéré síi lọ́jọ́ orí tí kọ́ láti ra ìgbà padà, fún jíjẹ́rìí ní ọwọ́ òwúrọ̀ kùtù nígbà tí wọ́n bá ń lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ tàbí nípa lílo àkókò ìsinmi ráńpẹ́ àti lẹ́yìn tí wọ́n bá jáde ilé-ẹ̀kọ́.
Ẹ Wo Bí Wọ́n Ṣe Pàwàtítọ́mọ́ Tó!
Ọgọ́rọ̀ọ̀rún lára àwọn àwùjọ olùgbọ́ ti ní ìrírí ìfisẹ́wọ̀n àti ìdálóró lábẹ́ ìjọba àná. Mandefro Yifru rántí irú àwọn ọdún márùn-ún bẹ́ẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ó ń gbádùn ṣíṣiṣẹ́sìn ní Addis Ababa ní ọ́fíìsì titun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dásílẹ̀, tí ń bójútó ìtumọ̀ èdè, ìtẹ̀wé, àti ìkẹ́rùránṣẹ́. Ọ̀dọ́mọkùnrin mìíràn kan tí ń ṣiṣẹ́sìn pẹ̀lú rẹ̀, Zecarias Eshetu, kò pa ìwàtítọ́ rẹ̀ tì ní ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn nígbà tí wọ́n pa baba rẹ̀ fún dídi àìdásí tọ̀túntòsì Kristian rẹ̀ mú láàárín ọdún mẹ́ta tí ó fi ṣẹ̀wọ̀n. Zecarias, ọ̀kan lára àwọn ọmọ márùn-ún, jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá nígbà tí a rán baba rẹ̀ lọ sẹ́wọ̀n. Meswat Girma, àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin, Yoalan, tí wọ́n ti ń súnmọ́ ogún ọdún báyìí tí wọ́n sì wà ní ilé-ẹ̀kọ́, ń rántí baba wọn kìkì nínú fọ́tò, níwọ̀n bí wọ́n ti kéré jọjọ nígbà tí wọ́n pa á lójijì nítorí àìdásí tọ̀túntòsì rẹ̀. Ìṣòtítọ́ rẹ̀ fún wọn ní ìṣírí, àwọn méjèèjì sì ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé, gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti ń ṣe kí ó tó kú.
Olùpàwàtítọ́mọ́ mìíràn ni Tamirat Yadette, tí ń ṣiṣẹ́sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní ẹkùn rírẹwà kan ní Rift Valley. Nítorí àìdásí tọ̀túntòsì Kristian rẹ̀, ó lo ọdún mẹ́ta ní ọgbà ẹ̀wọ̀n méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, nígbà mìíràn pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n lọ́wọ́ tí a sì ń nà án lẹ́gba lọ́nà rírorò. Síbẹ̀, nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ó ran àwọn ènìyàn tí wọ́n ju méjìlá lọ lọ́wọ́ láti mú ìdúró wọn fún Ìjọba Ọlọrun.
Tesfu Temelso, tí ń ṣiṣẹ́sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká, ní wọ́n tì mẹ́wọ̀n nígbà 17 ní àwọn ọdún tí ó fi sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Wọ́n fi lílù dápàá sí i lára, ṣùgbọ́n ó wú u lórí láti rí i pé ìjọ wà ní àwọn ibi iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀ àtijọ́. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn arábìnrin àti arákùnrin láti Ìjọ Akaki jìyà ìfisẹ́wọ̀n àti ìṣèkàsíni, síbẹ̀ ìjọ náà ti tóbi dé ìwọ̀n níní iye akéde tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún. Wọ́n ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àkọ́kọ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Ethiopia. Àwùjọ ẹlẹ́ni márùn-ún kan tí wọ́n dojúkọ ikú tí arákùnrin kan ládùúgbò sì kú níṣojú wọn nítorí ìdálóró tí wọ́n fi jẹ ẹ́ níyà, wá láti Dese, ìlú kan tí ìrísí àyíká rẹ̀ jojúnígbèsè tí ó wà ní nǹkan bí 300 kìlómítà níhà àríwá olú-ìlú náà. Alàgbà kan láàárín wọn, Maseresha Kasa, ṣàlàyé pé òun fàyàrán an láàárín ọdún mẹ́fà tí òun fi wà lẹ́wọ̀n, kìí ṣe nítorí pé òun jẹ́ àkàndá lọ́nà èyíkéyìí, ṣùgbọ́n ó wulẹ̀ jẹ́ nítorí pé òun kọ́ láti gbáralé Jehofa.—Romu 8:35-39; fiwé Iṣe 8:1.
Láìpẹ́ yìí pàápàá, àwọn mìíràn ti fi ìṣòtítọ́ wọn hàn lábẹ́ ìdánwò. Àwùjọ ńlá kan wá sí àpéjọpọ̀ náà láti orílẹ̀-èdè kan tí kò jìnnà púpọ̀, níbi tí wọ́n ti fi ìdáàbòbò àwọn ọlọ́pàá, ìwé-àṣẹ ìrìnnà, ìwé-ẹ̀rí ìgbéyàwó, ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn, àti iṣẹ́ du àwọn Ẹlẹ́rìí, nítorí àìdásí tọ̀túntòsì wọn. Nígbà tí ogun ń gbóná janjan nítòsí Mesewa, èbútékọ̀ Eritrea kan ní Òkun Pupa, gbogbo ìjọ, tí wọ́n jẹ́ 39 lápapọ̀, títíkan àwọn ọmọdé, gbé ní abẹ́ afárá rírẹlẹ̀ kan ní aṣálẹ̀ fún nǹkan bí oṣù mẹ́rin láti lè sá àsálà kúrò lọ́wọ́ wíwó tí ìjọba àná wó ilé wọn palẹ̀. Nínú aṣálẹ̀ olóoru àti ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ yìí, ìjíròrò ẹsẹ̀-ìwé ojoojúmọ́ àti àwọn ìpàdé wọn mìíràn fún wọn ní okun ńláǹlà ó sì mú kí wọ́n ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jehofa àti pẹ̀lú araawọn lẹ́nìkínní kejì. Àwọn arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe méjì tí ń ṣiṣẹ́sìn nítòsí orísun odò Blue Nile farada ìkópayàbáni àwùjọ àwọn ènìyànkénìyàn àti ìhalẹ̀mọ́ni tí Ṣọ́ọ̀ṣì Orthodox súnná sí, ṣùgbọ́n àwọn méjèèjì forítì í wọ́n sì rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli mélòókan tí wọ́n fi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ wọn hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi ní àpéjọpọ̀ yìí.
Arákùnrin kan sọ nípa àdánwò ìdáwàládàádó rẹ̀ ní ibi iṣẹ́ kan ní àárín gbùngbùn ẹkùn ilẹ̀ gbígbẹ Ogaden, tí kò jìnnà sí Somalia. Ó wà láàyè nípa tẹ̀mí nípa wíwàásù àti ṣíṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn, títíkan àwọn dókítà ìṣègùn, tí wọ́n jàǹfààní láti inú ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá tí wọ́n sì ń kọ́ àwọn mìíràn nísinsìnyí. Àpẹẹrẹ dídára ti ìpàwàtítọ́mọ́ mìíràn ni ti aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan ní Addis Ababa, ẹni tí àwọn àwùjọ ènìyàn-kénìyàn kan tí àwọn àlùfáà Orthodox gbé dìde lù bíi kíkú bíi yíyè ní 1992. Lọ́nà tí ó múniláyọ̀, ó kọ́fẹpadà ó sì ń báa nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́sìn ní àgbègbè ìpínlẹ̀ kan náà. Ẹ̀rín mùkẹ̀mukẹ tí ó hàn ní ojú rẹ̀ kò fi àmì ẹ̀dùn ọkàn kankan hàn. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún òun, gbogbo àwọn mìíràn tí a dánwò àti àwọn ẹni titun, Àpéjọpọ̀ “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” yìí jẹ́ àjọyọ̀ onídùnnú.
Ìṣètò àpéjọpọ̀ náà lọ wọ́ọ́rọ́wọ́, tí ó mú kí àwọn olùṣèbẹ̀wò ronú pé àwọn olùyọ̀ọ̀da-ara-ẹni tí ọ̀ràn kàn ti ní ìrírí ọ̀pọ̀ ọdún. Ní tòótọ́, wọ́n ti tẹ̀síwájú lọ́nà yíyára kánkán láàárín ọdún méjì tí ó ti kọjá. Àfi bí ẹni pé kí àpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta náà má parí mọ́. Góńgó iye àwọn tí ó pésẹ̀ ní ọjọ́ Saturday jẹ́ 9,556. Ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n, rédíò, àti oníwèé ìròyìn ti orílẹ̀-èdè pèsè ìròyìn ṣíṣètẹ́wọ́gbà nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Gbogbo wọn lè rí i pé Jehofa ń sọ àwọn ènìyàn rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí. Àwùjọ olùgbọ́ náà ní nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí jàǹfààní láti inú “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá.” Pápá gbígbòòrò kan ṣí silẹ̀ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní orílẹ̀-èdè tí ó ní olùgbé bíi 50 million nínú yìí, àpéjọpọ̀ náà sì fún gbogbo wọn lókun nínú ìpinnu wọn láti lo àkókò tí ó ṣẹ́kù nínú ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí láti ṣèrànwọ́ fún àwọn olóòótọ́ ọkàn láti jàǹfààní pẹ̀lú nínú ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo 1992 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
b Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ, àti Awọn Ẹlẹrii Jehofah—Nfi Pẹlu Isopọṣọkan Ṣe Ifẹ-Inu Ọlọrun Yíká-Ayé.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Addis Ababa, January 13-15, 1994
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwùjọ àwọn aṣáájú-ọ̀nà ní Addis Ababa (lápá ọ̀tún); àwọn olùpàwàtítọ́mọ́ tí a fi gbogbo wọn sẹ́wọ̀n (nísàlẹ̀); Ẹlẹ́rìí ẹni ọdún 113 àti aya rẹ̀