ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 9/1 ojú ìwé 29-31
  • Mọrírì Iṣẹ́-Ìsìn Mímọ́ Ọlọ́wọ̀ Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mọrírì Iṣẹ́-Ìsìn Mímọ́ Ọlọ́wọ̀ Rẹ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Nígbà tí A Kọ́kọ́ Kọ́ Nípa Ọlọrun
  • Wọn Ha Jẹ́ Ìrúbọ Nítòótọ́ Bí?
  • Ronú Nipa Awọn Èrè Naa
  • Ìgbésẹ̀ Ìyàsímímọ́
  • Awọn Èrè Mìíràn fún Iṣẹ́-Ìsìn Tòótọ́
  • Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kejì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ìdí Tí Gbígbé Ìgbésí-Ayé Ìwà-bí-Ọlọ́run Fi Ń Mú Ayọ̀ Wá
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • ‘Gba Ara Rẹ Àtàwọn Tí Ń Fetí Sí Ọ Là’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 9/1 ojú ìwé 29-31

Mọrírì Iṣẹ́-Ìsìn Mímọ́ Ọlọ́wọ̀ Rẹ

KÍ ỌWỌ́ wa baà lè tẹ góńgó kan tí ó níláárí, a gbọ́dọ̀ múratán lati san iye owó kan. Ó ń béèrè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ìkẹ́kọ̀ọ́ ati ìpinnu, ati owó pẹlu, lati di dókítà kan. Eléré-ìdárayá kan tí ó kẹ́sẹjárí ti lo ọ̀pọ̀ jùlọ ninu àkókò ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀ ní ṣíṣiṣẹ́ lórí awọn ọ̀nà ìgbàṣeré tí ń ṣòro síi ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ninu ìlépa rẹ̀ láìsinmi lati ṣe àṣepé. Bákan naa ni ọ̀jáfáfá aludùùrù kan lè bojúwẹ̀yìn wo ọ̀pọ̀ ọdún ìdánrawò tí ó ti fi torí-tọrùn ṣe.

Bí ó ti wù kí ó rí, góńgó kanṣoṣo ni ó wà tí ń mú èrè pupọ jaburata wá ju ohun tí a níláti san lọ. Èwo nìyẹn? Ó jẹ́ àǹfààní ti jíjẹ́ ìránṣẹ́ Ẹni Gíga Julọ naa, Jehofa Ọlọrun. Awọn ìrúbọ yòówù kí a ṣe níti àkókò, owó, tabi okun, àǹfààní ṣíṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wa ń mú èrè tí kò ní àfiwé wá. Òtítọ́ ni awọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu pé: “Ìfọkànsin Ọlọrun ṣàǹfààní fún ohun gbogbo, bí ó ti ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí ati ti èyíinì tí ń bọ̀.” (1 Timoteu 4:8, NW) Ẹ jẹ́ kí a wo bí èyí ṣe jẹ́ òtítọ́.

Nígbà tí A Kọ́kọ́ Kọ́ Nípa Ọlọrun

Ó ṣeéṣe kí ọ̀pọ̀ jùlọ lára awọn tí wọn finúdídùn dáhùnpadà sí ìhìnrere tí wọn sì bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli má mọ bí awọn ìyípadà tí yoo yọrísí ninu ìgbésí-ayé wọn yóò ṣe pọ̀ tó. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli naa lè pàdánù awọn ọ̀rẹ́ díẹ̀ tí kò ṣeéṣe fún lati lóye ìdí tí kò fi máa báa lọ pẹlu wọn mọ́ ninu awọn ìlépa tí oun ti wá mọ̀ nísinsìnyí pé kò bọlá fún Ọlọrun. (1 Peteru 4:⁠4) Awọn kan lè ní ìrírí àtakò lati ọ̀dọ̀ ìdílé ó sì lè bà wọn lọ́kàn jẹ́ lati rí i bí awọn wọnnì tí wọn fẹ́ràn ṣe ń fi ìríra hàn sí wọn, àní ìkórìíra, fún Jehofa pàápàá. (Matteu 10:36) Ìyẹn lè jẹ́ iye-owó kan tí ó ṣòro lati san.

Lẹ́nu iṣẹ́ tabi ní ilé-ẹ̀kọ́, iye owó kan yoo tún wà lati san. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli naa yoo ṣíwọ́ kíkópa ninu awọn àpèjẹ ati awọn ayẹyẹ ayé mìíràn. Kò tún ní fetísílẹ̀ sí awọn ọ̀rọ̀ rírùn tí awọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tabi awọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ rẹ̀ ń sọ mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní bá wọn dápàárá ọlọ́rọ̀ àlùfààṣá mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, yoo gbìyànjú lati fi ìṣílétí tí a rí ninu Efesu 5:​3, 4 sílò pé: “Ṣugbọn àgbèrè, ati gbogbo ìwà-èérí, tabi ojúkòkòrò, kí a má tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ láàárín yín mọ́, bí ó ti yẹ awọn ènìyàn mímọ́; ìbáà ṣe ìwà ọ̀bùn, ati ìsọ̀rọ̀ wèrè, tabi ìṣẹ̀fẹ̀, awọn ohun tí kò tọ́: ṣugbọn ẹ kúkú máa dúpẹ́.”

Irú awọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ lè sọ akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli naa di ará-ìta. Ìyẹn lè ṣòro, ní pàtàkì fún ọ̀dọ́ kan tí ó ṣì wà ní ilé-ẹ̀kọ́. Bí wọ́n ti ń dojúkọ họlidé kan tẹ̀lé òmíràn, ati awọn ẹ̀kọ́ tí ó lòdì sí Ọlọrun, bíi ẹfolúṣọ̀n, ati ìkìmọ́lẹ̀ ìgbà gbogbo lati ṣe ohun tí ẹgbẹ́ ń ṣe, awọn ọ̀dọ́ Kristian gbọ́dọ̀ máa ja ìjà ìgbà gbogbo fún ìgbàgbọ́. Títẹ̀lé awọn ọ̀nà Ọlọrun yoo mú kí wọn yàtọ̀ ó sì lè yọrísí ìpẹ̀gàn lati ọ̀dọ̀ awọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ati awọn olùkọ́. Èyí ní pàtàkì ṣòro lati tẹ́wọ́gbà ní awọn ìgbà àìtọ́mọ-ogún-ọdún tí a tètè máa ń mọ nǹkan lára, ṣugbọn ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun yẹ fún iye-owó yẹn.

Wọn Ha Jẹ́ Ìrúbọ Nítòótọ́ Bí?

Awọn nǹkan mìíràn tí wọn kọ́kọ́ farahàn gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ a máa jásí ìbùkún. Awọn kan níláti jáwọ́ ninu àṣà tábà mímu. (2 Korinti 7:⁠1) Èyí lè jẹ́ ìjàkadì, ṣugbọn ẹ wo bí yoo ti jẹ́ ìbùkún tó nígbà tí wọn bá borí ìwà akóninírìíra yẹn! Ohun kan naa ni a lè sọ nipa bíborí ìwà jíjẹ́ ajòògùnyó tabi ọ̀mùtí paraku. Ẹ wo bí ìgbésí-ayé yoo ṣe túbọ̀ sàn tó láìsí irú awọn àṣà aṣekúpani bẹ́ẹ̀! Awọn mìíràn níláti mú ọ̀ràn ìgbéyàwó wọn tọ́. Awọn wọnnì tí wọn ń gbé papọ̀ láìṣègbeyàwó gbọ́dọ̀ fẹ́ra tabi kí wọn ṣíwọ́ lati máa gbé papọ̀. (Heberu 13:⁠4) Awọn wọnnì tí wọn ń gbé pẹlu aya pupọ faramọ́ aya ìgbà èwe wọn nìkan. (Owe 5:18) Irú awọn àtúnṣebọ̀sípò bẹ́ẹ̀ wémọ́ ṣíṣe ìrúbọ, ṣugbọn wọn ń mú àlàáfíà wá sínú ilé.

Ronú Nipa Awọn Èrè Naa

Nítòótọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣègbọràn sí awọn òfin Jehofa ń jàǹfààní níti gidi. Fún ìgbà àkọ́kọ́ ninu ìgbésí-ayé rẹ̀, akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan lè bẹ̀rẹ̀ síí bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ sọ̀rọ̀ ní fífi orúkọ Rẹ̀, Jehofa pè é. (Orin Dafidi 83:18) Akẹ́kọ̀ọ́ naa wá ń nífẹ̀ẹ́ Jehofa síi bí ó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nipa awọn nǹkan àgbàyanu tí Ó ti ṣe ati èyí tí yoo ṣì ṣe fún aráyé. Ní awọn orílẹ̀-èdè ti ìbẹ̀rù awọn òkú ti wọ́pọ̀, ó sọ ìbẹ̀rù ìgbàgbọ́-nínú-ohun-asán rẹ̀ nú, ní mímọ̀ pé awọn òkú ń sùn ninu orun ikú, ní dídúró de àjíǹde. (Oniwasu 9:​5, 10) Ẹ sì wo bí ó ti tunilára tó lati mọ̀ pé Jehofa kìí dá awọn ènìyàn lóró títíláé ninu hẹ́ẹ̀lì! Bẹ́ẹ̀ni, òtítọ́ sọ ọ́ di òmìnira nítòótọ́.​—⁠Johannu 8:⁠32.

Bí akẹ́kọ̀ọ́ naa ti ń mú ìgbésí-ayé rẹ̀ wà ní ìbámu síwájú ati síwájú síi pẹlu awọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Jehofa, ó ń jèrè ẹ̀rí-ọkàn mímọ́ ati ọ̀wọ̀ ara-ẹni. Kíkẹ́kọ̀ọ́ lati gbé gẹ́gẹ́ bí Kristian tòótọ́ ń ràn án lọ́wọ́ lati bójútó ìdílé rẹ̀ lọ́nà tí ó sàn jù, èyí tí ń mú ìtẹ́lọ́rùn ati ayọ̀ ńlá wá. Ti lílọ sí awọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba sì tún wà níbẹ̀. Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ ìrírí gbígbádùnmọ́ni tó! Níhìn-⁠ín ni a ti lè rí awọn ènìyàn tí wọn ń ṣe ìfisílò ìfẹ́ ọlọ́yàyà tí Bibeli sọ pé a gbọ́dọ̀ fi dá awọn ènìyàn Ọlọrun mọ̀ nítòótọ́. (Orin Dafidi 133:1; Johannu 13:35) Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn mọ́ tónítóní ó sì ń gbéniró bí wọn ti ń sọ̀rọ̀ “iṣẹ́ ìyanu ńlá Ọlọrun.” (Iṣe 2:11) Bẹ́ẹ̀ni, dídara pọ̀ mọ́ “awọn ará” jẹ́ orísun ayọ̀. (1 Peteru 2:17) Irú ìdàpọ̀ rere bẹ́ẹ̀ ń ran akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli naa lọ́wọ́ lati “gbé ọkùnrin titun nì wọ̀, èyí tí a dá nipa ti Ọlọrun ní òdodo ati ní ìwà mímọ́ òtítọ́.”​—⁠Efesu 4:⁠24.

Ìgbésẹ̀ Ìyàsímímọ́

Bí ẹnìkan tí ń tẹ̀síwájú ninu ìmọ̀, ìfẹ́ fún Jehofa yoo sún un ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ lati ya ìgbésí-ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún un kí ó sì fàmìṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ yii nípasẹ̀ ìrìbọmi ninu omi. (Matteu 28:​19, 20) Ìmọ̀ràn Jesu ni pé ṣáájú gbígbé ìgbésẹ̀ yii, kí awọn ọmọ-ẹ̀yìn oun ṣírò iye tí yoo ná wọn. (Luku 14:28) Rántí, Kristian olùṣèyàsímímọ́ kan ń fi ìfẹ́-inú Jehofa ṣáájú ó sì ń dẹ̀yìn rẹ̀ kọ awọn nǹkan ti ara. Ó ń ṣiṣẹ́ kára lati jáwọ́ ninu “awọn iṣẹ́ ti ara” kí ó sì mú “èso ti Ẹ̀mí” dàgbà. (Galatia 5:​19-⁠24) Ìmọ̀ràn tí a rí ninu Romu 12:2 ń kó ipa tí ó túbọ̀ kúnrẹ́rẹ́ ninu ìgbésí-ayé rẹ̀: “Ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yii: ṣugbọn kí ẹ paradà lati di titun ní ìrò-inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọrun, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” Nípa bayii, Kristian kan tí ó ti ṣèyàsímímọ́ ń gbé ìgbésí-ayé rẹ̀ pẹlu ìmọ̀lára tí a ti sọ dọ̀tun nipa ète.

Ṣugbọn, gbé ohun tí ó ń rígbà yẹ̀wò. Ohun kan ni pé, nísinsìnyí oun wà ninu ipò-ìbátan ti ara-ẹni kan pẹlu Ẹlẹ́dàá àgbáyé. A polongo rẹ̀ ní olódodo pẹlu ìfojúsọ́nà fún jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọrun! (Jakọbu 2:23) Pẹlu ìtumọ̀ tí ó túbọ̀ jinlẹ̀, ó ń bá Ọlọrun sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Matteu 6:⁠9) Ìbùkún mìíràn fún ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèyàsímímọ́ naa ni mímọ̀ pé ìgbésí-ayé ní ète ninu níti gidi ati pé oun ń gbé ìgbésí-ayé oun ní ìbámu pẹlu ète yẹn. (Oniwasu 12:13) Ní títẹ̀lé ipò-iwájú ti Jesu, oun lè fi Eṣu hàn gẹ́gẹ́ bí òpùrọ́ nipa dídúró bí olóòótọ́. Ẹ sì wo ayọ̀ tí ìyẹn ń mú wá sínú ọkàn-àyà Jehofa!​—⁠Owe 27:⁠11.

Àmọ́ ṣáá ó, bí Kristian kan ti ń faradà á ní ipa-ọ̀nà ìṣòtítọ́, awọn ìrúbọ síwájú síi wà lati ṣe. Ó gba àkókò lati kópa ninu kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fúnra ẹni ati pẹlu ìjọ. (Orin Dafidi 1:​1-⁠3; Heberu 10:25) A níláti ra àkókò padà fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá lati inú awọn ìgbòkègbodò mìíràn. (Efesu 5:16) Ó tún ń béèrè fún àkókò ati ìsapá lati lọ sí awọn ìpàdé awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ati lati rìnrìn-àjò lọ sí awọn àpéjọ ati àpéjọpọ̀ wọn. Ó lè béèrè fún ìfira-ẹni-rúbọ lati nípìn-⁠ín ninu bíbójútó ọ̀ràn ìnáwó Gbọ̀ngàn Ìjọba ati iṣẹ́ ìwàásù kárí-ayé. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ awọn Kristian ṣe lè jẹ́rìí sí i, fífi tọkàntọkàn lọ́wọ́ ninu irú awọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ń mú ayọ̀ wá. Jesu wí pé: “Ati fúnni ó ní ìbùkún ju ati gbà lọ.”​—⁠Iṣe 20:⁠35.

Èrè ṣíṣètìlẹ́yìn fun iṣẹ́ Jehofa a máa pọ̀ fíìfíì rékọjá iye tí ń náni. Bí a ti ń dàgbà di géńdé, iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa ń di èyí tí ó túbọ̀ ń sèso tí ó sì ń kún fún ayọ̀. Nítòótọ́, kò sí ohun tí ó lè mú ayọ̀ pupọ wá bíi kíkọ́ ẹlòmíràn kan ní òtítọ́ Bibeli kí a sì rí i kí onítọ̀hún tẹ́wọ́gba ìjọsìn Jehofa. Bí olùjọsìn titun naa bá sì jẹ́ mẹ́ḿbà ìdílé kan, bóyá ọmọ kan tí a ti kọ́ “ninu ẹ̀kọ́ ati ìkìlọ̀ Oluwa,” ìyẹn ń mú àkànṣe ayọ̀ wá. (Efesu 6:⁠4) A ń rí awọn ìbùkún jìngbìnnì lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun lórí awọn ìsapá wa lati jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹlu rẹ̀.​—⁠1 Korinti 3:⁠9.

Awọn Èrè Mìíràn fún Iṣẹ́-Ìsìn Tòótọ́

Lóòótọ́, awa yoo ni awọn ìṣòro níwọ̀n ìgbà tí ètò ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii bá ṣì ń bá a lọ. Ó ṣeéṣe, kí awọn ìṣòro naa di èyí tí ó múná síi bí àkókò Eṣu ti túbọ̀ ń kúrú síi. Ó lè ṣeéṣe kí a jìyà inúnibíni tabi farada ìdẹwò. Ṣugbọn ìmọ̀ naa pé Ọlọrun wà pẹlu wa ń tù wá ninu ó sì ń fún wa ni okun naa lati faradà. (1 Korinti 10:13; 2 Timoteu 3:12) Awọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa kan ti farada ọ̀pọ̀ ọdún ìbánilò lọ́nà lílekoko, ṣugbọn wọn ń tẹpẹlẹ mọ́ ọn nitori ìfẹ́ wọn fún Ọlọrun. Awọn wọnnì tí wọn ṣàṣeyọrísírere ní fífarada onírúurú awọn àdánwò ní irú ìmọ̀lára kan naa tí awọn aposteli ní nígbà tí a lù wọn ti a sì jọ̀wọ́ wọn lẹ́yìn naa. Iṣe 5:41 ròyìn pé: “Wọn sì lọ kúrò níwájú àjọ ìgbìmọ̀: wọn ń yọ̀ nitori tí a kà wọn yẹ sí ìyà íjẹ nitori orúkọ rẹ̀.”

Èrè fún ìfaradà ju iye tí yoo náni nísinsìnyí lọ fíìfíì. Ṣugbọn rántí, ìfọkànsin Ọlọrun “ní ìlérí” kìí ṣe fún “ìyè ti ìsinsìnyí” nìkan bíkòṣe “ti èyíinì tí ń bọ̀” pẹlu. (1 Timoteu 4:8, NW) Ẹ wo bí ìfojúsọ́nà ẹnìkan tí ó lo ìfaradà ti ga lọ́lá tó! Bí o bá jẹ́ olùṣòtítọ́, iwọ yoo la ìpọ́njú ńlá naa tí ó sàmì sí òpin ètò ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii já. Tabi bí iwọ bá kú ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ àmúpìtàn yẹn, a óò jí ọ dìde sínú ayé titun kan tí yoo tẹ̀lé e. (Danieli 12:1; Johannu 11:​23-⁠25) Ronú nipa ìmọ̀lára ayọ̀ àṣeyọrí tí iwọ yoo ní nígbà naa tí iwọ yoo lè sọ pé: “Pẹlu ìrànlọ́wọ́ Jehofa, mo yege!” Ẹ wo bí yoo ti múnilóríyá tó lati jogún ìpín kan ninu ilẹ̀-ayé yẹn, èyí tí “yoo kún fún ìmọ̀ Oluwa gẹ́gẹ́ bí omi ti bo òkun.”​—⁠Isaiah 11:⁠9.

Bẹ́ẹ̀ni, ó ń náni ní ohun kan lati ṣiṣẹ́sìn Ọlọrun. Ṣugbọn ní ìfiwéra pẹlu èrè naa, iye tí ó náni kéré jọjọ. (Filippi 3:​7, 8) Lójú-ìwòye gbogbo ohun tí Ọlọrun ń ṣe fún awọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nísinsìnyí tí yoo sì tún ṣe lọ́jọ́ iwájú, a tún awọn ọ̀rọ̀ onipsalmu naa sọ pé: “Kí ni emi ó san fún Oluwa nitori gbogbo oore rẹ̀ sí mi?”​—⁠Orin Dafidi 116:⁠12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́