ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 10/1 ojú ìwé 9
  • Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Ń Sa Agbára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Ń Sa Agbára
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ọlọrun Kìí Ṣe Ojúsàájú Ènìyàn”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 10/1 ojú ìwé 9

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Ń Sa Agbára

“Ọ̀RỌ̀ Ọlọrun wà láàyè ó sì ń sa agbára.” (Heberu 4:12, NW) Awọn ọ̀rọ̀ wọnyi ti jásí òtítọ́ lọ́pọ̀ ìgbà léraléra nígbà tí a bá fi ojú awọn ènìyàn tí ìsìn èké ti tànjẹ mọ òtítọ́ Bibeli. Gẹ́gẹ́ bí ìrírí tí ó tẹ̀lé e lati Dominican Republic ti fihàn, agbára tí Bibeli ní lè yí ìgbésí-ayé awọn ènìyàn padà kí ó sì fún wọn ní ìrètí.

Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ obìnrin onísìn Katoliki kan tí ó yọrí-ọlá tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdánù awọn ọmọ kéékèèké méjì ninu ikú. Ẹ̀dùn-ọkàn bá a ó sì ń kédàárò ọ̀ràn ìbìnújẹ́ rẹ̀ lójoojúmọ́. Awọn Ẹlẹ́rìí fi ohun tí Bibeli sọ nipa ìrètí àjíǹde hàn án ninu Johannu 5:​28, 29. Lẹ́yìn ìjíròrò síwájú síi pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí, kìí ṣe kìkì pé ó rí ìtùnú ninu ìrètí àjíǹde nìkan ni ṣugbọn ó mọ̀ pé awọn aṣáájú ìsìn Katoliki oun ń tan oun jẹ ni.

Kò pẹ́ tí ó fi fi Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki sílẹ̀, tí ó sì tẹ́wọ́gbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bí ó ti wù kí ó rí, ọkọ rẹ̀ kò gbà pẹlu ojú-ìwòye rẹ̀. Níwọ̀n bí oun pẹlu ti jẹ́ onísìn Katoliki kan tí ó yọrí-ọlá gidigidi, ó ṣètò fún awọn ọ̀rẹ̀ rẹ̀ olóṣèlú ati onísìn tí wọn gbajúmọ̀ lati bẹ aya rẹ̀ wò ninu ìgbìdánwò lati dá a lẹ́kun ninu ohun tí ó rawọ́lé kí wọ́n sì mú un padà wá sínú ìsìn Katoliki. Lẹ́yìn naa ni ó fi ìkọ̀sílẹ̀ halẹ̀mọ́ ọn, ní àkókò kan ó tilẹ̀ fi tó awọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ati awọn mẹ́ḿbà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ṣọ́ọ̀ṣì létí pé awọn fẹ́ gba ìkọ̀sílẹ̀.

Ṣugbọn ìwéwèé rẹ̀ kò ṣiṣẹ́. Ní òdìkejì, ìpinnu rẹ̀ lati máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀ nìṣó túbọ̀ pọ̀ síi. Nitori ìdàgbàsókè rẹ̀ nipa tẹ̀mí ati mímú awọn ànímọ́ àtàtà ti Kristian dàgbà, ọkọ naa pinnu lati wà pẹlu rẹ̀ dípò kí ó jáwèé ìkọ̀sílẹ̀. Ní ọjọ́ kan ó tilẹ̀ gba lati ṣàyẹ̀wò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli naa tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀​—⁠ṣugbọn lórí ipò àfilélẹ̀ kan. Ó fẹ́ lati lo ẹ̀dà ìtumọ̀ Bibeli Katoliki tirẹ̀.

Sí ìyàlẹ́nu rẹ̀, pẹlu ìrànlọ́wọ́ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lati ọwọ́ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ó bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ awọn ohun titun tààràtà lati inú Bibeli tirẹ̀. Ó mọ̀ pé aya oun ti yàn ipa ọ̀nà tí ó tọ́, kò sì pẹ́ tí ó fi múratán lati tẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Ní tòótọ́, ó rí àìní naa lati ṣe awọn ìyípadà ninu ìgbésí ayé tirẹ̀ fúnraarẹ̀. Ìpèníjà kan tí ó ṣòro fún un ni lati jáwọ́ ninu sìgá mímu. Lẹ́yìn tí ó ti ka ìtẹ̀jáde January 8, 1990 ti ìwé ìròyìn Jí! tí ó ní àkọlé ẹ̀yìn ìwé naa “Ikú fun Títà​—⁠Awọn Ọ̀nà Mẹ́wàá lati Dáwọ́ Sìgá Mímu Dúró,” ó pinnu lati fi àṣà tí kò bá ìwé mímọ́ mu yii sílẹ̀. Dípò páálí sìgá tí ó sábà máa ń wà ninu àpò rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ síí mú ìtẹ̀jáde Jí! yẹn káàkiri. Ní gbogbo ìgbà tí ó bá ti ṣe é bíi kí ó mu sìgá, oun yoo ka awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ naa lórí sìgá mímu. Ọgbọ́n naa ṣiṣẹ́! Lẹ́yìn kíka awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ naa lọ́pọ̀ ìgbà, ó ṣeéṣe fún un lati dáwọ́ sìgá mímu dúró.

Lónìí tọkọtaya naa ń ṣiṣẹ́sin Jehofa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ tí a ti batisí. Nígbà tí àkókò bá yọ̀ǹda, ọkùnrin naa ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ní yíya èyí tí ó pọ̀ jùlọ ninu àkókò rẹ̀ sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun, ó sì ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ ninu ìjọ àdúgbò ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Oun ati aya rẹ̀ ń fojúsọ́nà fún àjíǹde nígbà tí wọn yoo kí awọn ọmọ wọn káàbọ̀ sí ìwàláàyè ninu ayé titun kan. Bẹ́ẹ̀ni, Bibeli, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, wà láàyè ó sì ń sa agbára!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́