ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 3/1 ojú ìwé 31
  • “Ọlọrun Kìí Ṣe Ojúsàájú Ènìyàn”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ọlọrun Kìí Ṣe Ojúsàájú Ènìyàn”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sọ fún Wọn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Wọn
    Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • ‘Aláyọ̀ Ni Ọkùnrin náà tí Ó Wá Ọgbọ́n Rí’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìdílé Rẹ Lè Láyọ̀
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 3/1 ojú ìwé 31

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

“Ọlọrun Kìí Ṣe Ojúsàájú Ènìyàn”

NÍ ỌGỌ́RÙN-ÚN ọdún mọ́kàndínlógún sẹ́yìn, aposteli Peteru tí a mísí sọ pé: “Ọlọrun kìí ṣe ojúsàájú ènìyàn: ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Iṣe 10:​34, 35) Àwọn ènìyàn láti onírúurú ìran àti ipò àtilẹ̀wá ìsìn wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Wọ́n fẹ́ òdodo, wọ́n sì bẹ̀rù Ọlọrun. Jehofa kí gbogbo wọn káàbọ̀ sínú ẹgbẹ́ ayé titun, fún àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún obìnrin kan ní Chad.

Ìsìn obìnrin yìí kò tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ó ti gba ẹ̀dà kan ìwé náà Igba Ewe rẹ​—⁠Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tẹ̀ jáde, ó sì mọrírì ìmọ̀ràn dídára tí ó wà nínú ìwé náà. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ni a bẹ̀rẹ̀, nígbà gbogbo ni ó sì máa ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí a fún un níṣìírí láti wá sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, kò wá. Èéṣe? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ rẹ̀ kò lòdìsí kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, kò gbà fún un láti pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Nígbà tí ìyàwó rẹ̀ lọ sí àpéjọ àyíká, Ẹlẹ́rìí tí ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ han ọkọ rẹ̀, ní títẹnumọ́ àwọn ìmọ̀ràn rere tí a óò gbékalẹ̀. Ó gbà fún ìyàwó rẹ̀ láti lọ “lẹ́ẹ̀kan péré.” Ó pésẹ̀ síbẹ̀ ó sì gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà dáradára. Lẹ́yìn ṣíṣàlàyé ohun tí ó ti kọ́ fún ọkọ rẹ̀, òun kò tako lílọ rẹ̀ sí àwọn ìpàdé mìíràn. Ó wú u lórí láti ríi pé ìjọ náà ní onírúurú àwọn ènìyàn láti inú oríṣirísi ẹ̀yà tí wọ́n bìkítà lọ́nà jíjinlẹ̀ fún ẹnìkínní kejì wọn. Nígbà tí ó yá, o lọ sí àpéjọ àgbègbè ẹnu sì yà á gidigidi láti rí i tí àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn gbé àwọn ọmọ rẹ sí ẹsẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà fún àwọn ọmọ náà ní oúnjẹ, wọ́n sì ṣe wọ́n bí ẹni pé wọ́n wá láti inú ìdílé wọn. Ibi tí ọ̀ràn ti yípadà fún un nìyí.

Ṣùgbọ́n àtakò tẹ̀lé e. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojo ni lọ́nà ti àdánidá, ó bẹ̀rẹ̀ síí sọ̀rọ̀ ìlóhùnsí ní àwọn ìpàdé tí ó sì ń dúró gbọnyin lòdìsí àwọn ọ̀rọ̀ òdì tí àwọn mọ̀lẹ́bí àti aládùúgbò ń sọ. Nígbà tí o jẹ́ pé ó ti gbé fún ọ̀pọ̀ ọdún pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, kìkì ìgbéyàwó ìjọ́hẹn àwọn méjèèjì níti ìbílẹ̀ ni wọn tíì ṣe. Báwo ni òun yóò ṣe gbé ọ̀rọ̀ ṣíṣègbéyàwó lọ́nà òfin kalẹ̀? Lẹ́yìn fífi òtítọ́-inú gbàdúrà sí Jehofa, ó bá ọkọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, ẹni tí o sọ pé òun yóò gbe é yẹ̀wò. Níkẹyìn ó ṣe bẹ́ẹ̀, tí tọkọtaya náà sì ṣègbéyàwó lọ́nà òfin.

Arábìnrin ọkọ rẹ̀ tí ń gbé lọ́dọ̀ wọn fa ọ̀pọ̀ ìṣòro, ṣùgbọ́n ọkọ náà gbè sẹ́yìn aya rẹ̀. Lẹ́yìn náà ni baba ọkọ náà wá fún ìbẹ̀wò. Ó pàṣẹ fún ọmọ rẹ̀ láti kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, níwọ̀n bí òun ti yí ìsìn rẹ̀ padà. Baba náà sọ fún ọmọ rẹ̀ pé òun yóò san owó orí ìyàwó fún “aya tí o sàn jù.” Èsì tí ọmọ rẹ̀ fún un ni pé: “Bẹ́ẹ̀kọ́, èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀. Aya rere ni òun jẹ́. Bí òun bá fẹ́ láti lọ, ìyẹn yàtọ̀, ṣùgbọ́n èmi kì yóò sọ fún un pé kí ó máa lọ.” Aya náà hùwà ọmọlúwàbí sí baba ọkọ rẹ̀, ìwà rẹ̀ sí obìnrin náà sì tìí lójú. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó padà sí abúlé rẹ̀, ó kọ̀wé sí ọmọ rẹ̀, lọ́tẹ̀ yìí ó fi òté lé e. Ó sọ pé bí ọmọ òun kò bá kọ̀ láti lé aya rẹ̀ lọ, òun kọ̀ ọ́ lọ́mọ. Síbẹ̀ ọmọ náà dúró ti aya rẹ̀. Ṣáà finúro ayọ̀ aya náà ní rírí bí ọkọ rẹ̀ ṣe mú irú ìdúró gbọnyin bẹ́ẹ̀.

Ní báyìí àwọn ọmọkùnrin wọn kékeré méjì fẹ́ràn láti máa bá ìyá wọn lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wọ́n tilẹ̀ béèrè táì ọrùn lọ́wọ́ baba wọn, níwọ̀n bí wọ́n ti rí i lọ́rùn gbogbo àwọn arákùnrin tí wọ́n ń sọ̀rọ̀. Lónìí obìnrin yìí jẹ́ arábìnrin kan tí a ti baptisi.

Òun jẹ́ ọ̀kan lára àwọn 345 Ẹlẹ́rìí aláyọ̀ ní Chad tí wọ́n ń kéde ìhìnrere Ìjọba Jehofa tí wọ́n sì ń mọrírì rẹ̀ pé, níti tòótọ́, “Ọlọrun kìí ṣe ojúsàájú ènìyàn.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́