Àwọn Olùpòki̇̀ki̇́ Ìjọba Ròyi̇̀n
‘Aláyọ̀ Ni Ọkùnrin náà tí Ó Wá Ọgbọ́n Rí’
ÒWE yìí ti jẹ́ òtítọ́ ní Korea, níbi tí ohun tí ó ju ẹgbẹ̀rún mọ́kànléláàdọ́rin àwọn aláyọ̀ Ẹlẹ́rìí Jehofa wà. (Owe 3:13) Sì rò ó wò ná, ìpín méjìlélógójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn òjíṣẹ́ wọ̀nyí wà nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún! Àwọn ìrírí tí ó tẹ̀lé e yìí yóò fihàn pé ayọ̀ ni ìpín àwọn wọnnì tí ó wá ọgbọ́n tòótọ́ rí.
Obìnrin kan ní Pusan ti lọ sí ọ̀kan lára àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm fún ọdún mẹ́rìndínlógún. Ó ti ṣàkíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣà tí kò bá ìwé mímọ́ mu débi pé ó bẹ̀rẹ̀ síí ronú pé kò lè sí Ọlọrun kankan. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, òun kò lè sẹ́ wíwà Ọlọrun, nítorí náà ó fi òtítọ́-inú gbàdúrà sí Ọlọrun pé kí òun lè rí ṣọ́ọ̀ṣì tòótọ́ bí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá wà. Ní orí kókó yìí ó ṣàdédé ronú kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ó sì rántí pé ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ ti fojú tín-ín-rín wọn tí ó sì kìlọ̀ fún àwọn olùre-ṣọ́ọ̀ṣì láti ṣọ́ra fún wọn nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí kò gbàgbọ́ nínú Mẹ́talọ́kan, iná ọ̀run-àpáàdì, àti àwọn ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ mìíràn ti Kristẹndọm. Bóyá àwọn ni ṣọ́ọ̀ṣì tòótọ́? Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ aládùúgbò kan, ó rí ibi tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà. Ní ọjọ́ kejì gan-an, ó lọ sí ìpàdé.
Ẹnú yà á fún ìwàlétòlétò ìpàdé náà. Kò sí igbe onígbawèrèmẹ́sìn tàbí orin elérò-ìmọ̀lára bí ọ̀ràn ti rí ní ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀. A mú un mọ Ẹlẹ́rìí kan tí ó múratán láti bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ sì pẹ́ fún àwọn wákàtí mélòókan nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè rẹ̀. Ní àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ kejì, ó ṣèfilọ̀ pé òun yóò kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì òun sílẹ̀ kí òun sì di Ẹlẹ́rìí kan. Ó sọ fún arábìnrin náà pé kò ní pọndandan kí ó bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ mọ, níwọ̀n bí òun kàn ti lè máa wá sí àwọn ìpàdé lásán. Bí ó ti wù kí ó rí, òun ni a fi ìjẹ́pàtàkì níní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ara-ẹni kan hàn ní àfikún sí wíwá sí àwọn ìpàdé. Ó tẹ́wọ́gba ìdámọ̀ràn náà, ó fi araarẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, nígbà tí ó sì tó àkókò a baptisi rẹ̀.
Nísinsìnyí ó láyọ̀ gan-an pé òun ti rí ọgbọ́n Ọlọrun òtítọ́, Jehofa, ó sì ní ìrétí wíwàláàyè títíláé nínú ayé titun Ọlọrun.
Ọ̀gágun tí Ó Ti Fẹ̀yìntì Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́
Aya ọ̀gágun kan ni a baptisi ní 1962. Ọkọ rẹ̀ ṣàtakò sí i lákọ̀ọ́kọ́, ṣùgbọ́n ó dáwọ́ ṣíṣàtakò sí i dúró nígbà tí ó yá, onírúurú àwọn arákùnrin sì bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n ní ìdákúrekú, ní gbígbìyànjú láti mú un nífẹ̀ẹ́-ọkàn nínú òtítọ́. Ó lọ sí àwọn ìpàdé àti àpéjọpọ̀ díẹ̀, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn wọnnì tí wọ́n ń fàsẹ́yìn láti fọwọ́ pàtàkì mú òtítọ́. Ní 1990 òun àti aya rẹ̀ lọ sí Japan, níbi tí wọ́n ti pésẹ̀ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè kan. Ní àkókò yìí ó fetísílẹ̀ kínní-kínní sí àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé—ohun kan tí òun kò tíì ṣe rí. Òun ni a mú ta kìjí nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé onígboyà tí ń túdìí àṣírí ìsìn èké, ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí dájúdájú la ojú rẹ̀ sí àgàbàgebè Kristẹndọm. A mú orí rẹ̀ wú nípasẹ̀ ìwàlétòlétò àti ayọ̀ àwọn ènìyàn Ọlọrun ní Japan, èyí tí ó wulẹ̀ jẹ́ bákan náà gẹ́gẹ́ bí òun ti rí i ní Korea. Ní pípadà sí Korea, ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ó fọwọ́ pàtàkì mú a sì baptisi rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.
Nítorí náà lẹ́yìn ìrìbọmi rẹ̀ kí ni òun níláti ṣe? Ó kọ̀wé fi ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ hòtẹ́ẹ̀lì àwọn arìnrìn-àjò yíká tí ó lókìkí sílẹ̀ ó sì darapọ̀ mọ́ aya rẹ̀ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà alákòókò kíkún. Ó nímọ̀lára pé jíjẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti fi san àsandípò fún ọdún méjìdínlógún tí òun ti sọnù nígbà tí òun ń fàsẹ́yìn.
Ó wá mọ̀ dájú nísinsìnyí pé òwe náà ‘aláyọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó wá ọgbọ́n rí’ ṣeé fisílò fún òun pẹ̀lú!