Awọn Olupokiki Ijọba Rohin
Awọn Agutan Jesu Fetisilẹ si Ohùn Rẹ̀
BÍ IṢẸ iwaasu naa ti ń gbooro lọ si apa ibi gbogbo ni ilẹ̀-ayé, Jehofa ń tipasẹ awọn angẹli rẹ̀ dari awọn iranṣẹ rẹ̀ sọdọ awọn ẹni bi-agutan. Wọn gbọ́ ohùn Jesu wọn sì kọ́ lati ṣiṣẹsin in pẹlu ifojusọna fun ìyè ainipẹkun niwaju. Jesu sọ ni Johannu 10:27, 28 pe: “Awọn agutan mi ń gbọ́ ohun mi, emi sì mọ̀ wọn, wọn a sì maa tọ̀ mi lẹhin: Emi sì fun wọn ni ìyè ainipẹkun.” Ṣakiyesi bi awọn aláìlábòsí-ọkàn ni Madagascar ti ń fetisilẹ si ohùn Jesu.
Ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fun oniṣegun ti ó wá ṣayẹwo baba rẹ̀ ti ń ṣaisan ni ẹ̀dà iwe Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori llẹ Aye ati lgba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ̀ Julo.
Dokita naa jẹ Protẹstant ó sì jẹ́ alatako gidi si Awọn Ẹlẹ́rìí, ṣugbọn oun ka iwe naa ó sì yẹ awọn ẹsẹ iwe mimọ naa wò ninu Bibeli tirẹ. lyawo rẹ̀, Katoliki ti o sì tún jẹ́ dokita, ka iwe Igba Ewe naa ni àkàtúnkà nitori ti oun wi pe o dabi ẹni pe a kọ iwe naa nitori ti oun ni pataki. Alaye Society ti a gbekari Bibeli nipa ijẹpataki 1914 wọn awọn mejeeji lọ́kàn. Ọkọ naa kàn sí Ẹlẹ́rìí ti o fun un ni awọn iwe naa. Ẹlẹ́rìí naa sì fun un ni iwe Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? ó sì ṣeto lati ṣebẹwo sọdọ oun ati iyawo rẹ̀ lati lè dahun awọn ibeere wọn. Nigba ti o ṣebẹwo si ọdọ wọn, ó bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli deedee pẹlu tọkọtaya naa ati awọn ọmọ wọn mẹta. Itẹsiwaju ninu liloye Bibeli yára kankan.
Lẹhin ikẹkọọ akọkọ, idile naa lodindi bẹrẹ sì lọ si awọn ipade ni Gbọngan Ijọba kò sì pẹ́ lẹhin naa wọn forukọ silẹ ninu llé-ẹ̀kọ́ Iṣẹ-ojiṣẹ Iṣakoso Ọlọrun. Iwahihu awọn ọmọ naa suwọn sii lọna giga. Lati inu ikẹkọọ Bibeli wọn, wọn mọ̀ pe ṣiṣayẹyẹ ọjọ́-ìbí ati awọn ọlidé isin miiran kò bá Kristian mu; nitori bẹẹ, wọn ṣiwọ ninu kikiyesi wọn. Ọkọ naa kọ̀ lati fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ fun mọlẹbi kan, ani bi o tilẹ jẹ pe kókó naa ni wọn kò tíì jiroro lé lori ninu ikẹkọọ Bibeli. Kò pẹ́ kò jinna aṣọ ìjà Karate rẹ̀ di àwátì nibi ìkáṣọsí rẹ̀; ó fi ranṣẹ sí aránṣọ lati fi rán aṣọ fun awọn ọmọ rẹ̀. Ó jó awọn iwe-irohin ati awọn iwe rẹ̀ ti o dalori ìwòràwọ̀ sàsọtẹ́lẹ̀ igbesi-aye ẹni. Lẹhin oṣu mẹta pere ti wọn ti bẹrẹ sii kẹkọọ, ati ọkọ ati iyawo kọwe fi ṣọọṣi wọn silẹ lẹnikọọkan wọn sì sọ ìfẹ̀-ọkàn wọn jade lati nipin-in ninu iṣẹ iwaasu naa. Wọn ti ṣeribọmi bayii.
◻ Obinrin kan ni Thailand ń wá otitọ kiri. Bi o tilẹ jẹ pe onisin Buddha kan ni, kò figbakanri mú ifọkansin fun isin rẹ̀ dagba nitori pe ó ti rí agabagebe ati ojukokoro pupọ. Yatọ si eyi, oniruuru awọn àṣà wà nibẹ tí ń da a lágara. Gbogbo rẹ̀ ti sú u.
Nigba naa, aladuugbo kan damọran pe ki o gbiyanju Kristian ó sì mú un lọ si ṣọọṣi Pentikostal. Bi o ti wu ki o ri, laaarin isin, obinrin naa ni ìfẹ́-ọkàn lati fi ibẹ̀ silẹ ki o sì pada sile nitori ariwo, niwọn bi gbogbo awọn ti ó pésẹ̀ ti ń gbadura pẹlu igbe rara. lyẹn ni ìgbà ikẹhin ti o tẹ ṣọọṣi yẹn.
Lẹhin naa, ó gbiyanju ṣọọṣi Roman Katoliki kan. Bi o ti wu ki o ri, lẹhin lilọ fun ìgbà melookan, ó tún ri agabagebe ati ojukokoro, ati àṣà igbesi-aye onigbẹdẹmukẹ ti alufaa. Ó di ẹni ti a koniriira ti ó sì dawọduro lilọ sibẹ. Alufa naa nifẹẹ itọpinpin lati mọ idi rẹ̀ ti o fi fi ibẹ̀ silẹ. Lẹhin mímọ idi naa, ó sọ lọna ẹlẹya pe: “Bi iwọ bá fẹ́ darapọ mọ awọn eniyan ti kò gba gbẹ̀rẹ́ niti gidi, lọ bá Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.” Oun beere pe: “Nibo ni wọn wà?” Alufaa naa fèsì pe: “Wọn wà nitosi ibi ile-iṣẹ omi.” Ni ọjọ keji ó wá wọn kiri laisi aṣeyọri. A já a kulẹ, sibẹsibẹ ó ń baa lọ lati ronu nipa Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
Ni ọjọ kan ó fetikọ ọ̀rọ̀ ọ̀kan lara awọn aladuugbo rẹ̀ ti ó ń fi ẹlẹya sọ fun ẹnikeji pe: “Laipẹ iwọ yoo di ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa!” Ni gbígbọ́ eyiini, obinrin naa sáré tete lọ sọdọ aladuugbo naa ó sì beere pe: “Ṣe Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wà ni agbegbe wa nihin-in ni?” “Bẹẹni,” ni idahunpada. “Awọn diẹ yoo wá si adugbo ni wiwaasu lati ile de ile. Iwọ lè dá wọn mọ̀ nipasẹ ọ̀nà mímọ́ ati letoleto ti wọn gbà maa ń mura.” Ni gbigbọ iyẹn ó sare jade lọ lati wá wọn. Lakọọkọ oun kò rí wọn, ṣugbọn nigba ti ó ń rin pada sile, ó ṣakiyesi obinrin meji kan ti wọn mura letoleto ti wọn ń bá ẹnikan sọrọ. Ó sunmọ wọn ó sì beere bi wọn bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nigba ti wọn dahun pe Ẹlẹ́rìí ni awọn, ó bẹ̀bẹ̀ pe: “Ẹ jọwọ ẹ wá si ile mi. Mo fẹ́ lati bá yin sọrọ.”
Ikẹkọọ Bibeli kan ni a bẹrẹ, ati laika àtakò ati ifiniṣẹlẹya lati ọdọ awọn mẹmba idile si, obinrin yii ti bẹrẹ sii lọ si awọn ipade ó sì ti ń jẹrii fun awọn ibatan rẹ̀.
Niti tootọ Jesu mọ awọn agutan rẹ̀ ó sì ń kó wọn jọ pọ̀ sinu eto-ajọ rẹ̀ fun lilaaja sinu ayé titun ododo rẹ̀.