ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 4/1 ojú ìwé 9
  • Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà Tí Ń Yin Jehofa Lógo

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà Tí Ń Yin Jehofa Lógo
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ọlọrun Kìí Ṣe Ojúsàájú Ènìyàn”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • ‘Aláyọ̀ Ni Ọkùnrin náà tí Ó Wá Ọgbọ́n Rí’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Awọn Agutan Jesu Fetisilẹ si Ohùn Rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 4/1 ojú ìwé 9

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà Tí Ń Yin Jehofa Lógo

NÍNÚ Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, Jesu sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú awọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí awọn iṣẹ́ àtàtà yín kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní awọn ọ̀run.” (Matteu 5:16) Bákan náà, àwọn Kristian tòótọ́ lónìí ń lọ́wọ́ nínú “awọn iṣẹ́ àtàtà” tí ń yin Jehofa lógo.

Kí ni àwọn iṣẹ́ àtàtà wọ̀nyí? Wọ́n ní wíwàásù ìhìn rere nínú, ṣùgbọ́n ìwà wa àwòfiṣàpẹẹrẹ tún jẹ́ apá pàtàkì kan. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ìwà rere wa ni ó kọ́kọ́ máa ń fa àwọn ènìyàn wá sínú ìjọ Kristian. Àwọn ìrírí tí ó tẹ̀ lé é yìí ṣàpèjúwe bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Martinique ṣe ‘ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn níwájú àwọn ènìyàn.’

◻ Nígbà tí ó ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé dé ilé, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bẹ obìnrin Kátólíìkì kan wò. Fún ọdún 25, obìnrin yìí ti ń gbé pẹ̀lú ọkùnrin kan tí kò bá ṣègbéyàwó. Ó mọ ẹ̀kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dunjú, níwọ̀n bí, ní nǹkan bí ọdún méje ṣáájú, ó ti gba ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.a Obìnrin náà sọ fún Ẹlẹ́rìí náà pé: “Ìsìn tí ó wà ti pọ̀ jù. Èmi kò mọ èyí tí n óò gbà gbọ́ láàárín gbogbo ìdàrúdàpọ̀ yìí.” Ẹlẹ́rìí náà ṣàlàyé pé, kìkì nínú Bibeli ni ó ti lè rí òtítọ́ àti pé kí ó baà lè rí i, ó ní láti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, kí ó sì gbàdúrà sí Ọlọrun fún ẹ̀mí rẹ̀ àti ìtọ́sọ́nà rẹ̀.

Fún àkókò kan, bí ó tilẹ̀ ní ọkàn-ìfẹ́ sí kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, obìnrin náà kọ àwọn ìkésíni mélòó kan tí a fún un láti wá sí àwọn ìpàdé Kristian ni Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Èé ṣe? Ó máa ń tijú gan-an. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn tí a ké sí i lọ sí ibi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi, ó borí ìtìjú rẹ̀ ó sì lọ.

Ohun tí ó wú u lórí jù lọ nípa ìpàdé náà ni ìbáṣepọ̀ onífẹ̀ẹ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kò tí ì ní ìrírí irú ojúlówó ìbádọ́rẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ rí! Lẹ́yìn ìpàdé náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí gbogbo ìpàdé tí àwọn Ẹlẹ́rìí ní àdúgbò ń ṣe, láìpẹ́ ó sì ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkùnrin tí ó ti ń bá gbé. Ó ti di mẹ́ḿbà tí a ti batisí nínú ìjọ nísinsìnyí.

◻ Àwọn ìṣẹ́ àtàtà Ẹlẹ́rìí mìíràn mú èso rere jáde. Ó di ipò pàtàkì mú ní ibi iṣẹ́. Lẹ́yìn tí wọ́n háyà ọkùnrin kan láti erékùṣù Réunion, àwọn òṣìṣẹ́ kan bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí pé ó kúrú. Ó di ohun tí wọ́n fi ń ṣẹ̀rín rín. Ní ìyàtọ̀ gedegbe, Ẹlẹ́rìí náà jẹ́ onínú rere sí ọkùnrin náà, ó sì máa ń bọ̀wọ̀ fún un ní gbogbo ìgbà. Láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí i béèrè ìdí tí ó fi yàtọ̀.

Ẹlẹ́rìí náà ṣàlàyé pé ìwà ọlọ́wọ̀ òún jẹ́ ìyọrísí àwọn ìlànà Bibeli tí òún ti kọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ó tún fi ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn ète Ọlọrun àti ìrètí ayé tuntun hàn-án. Ọkùnrin náà tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé Kristian, ó sì ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú obìnrin tí ó ti ń bá gbé.

Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó padà sí Réunion. Tẹ́lẹ̀ rí, ó ti ní ìrírí ọ̀pọ̀ ìṣòro pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀, ní pàtàkì pẹ̀lú ìdílé ìyàwó rẹ̀. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ìwà rere Kristian rẹ̀ wú wọn lórí. Ọkùnrin náà ti ṣe batisí, ó sì ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nísinsìnyí. Àwọn mélòó kan lára àwọn mẹ́ḿbà ìdílé rẹ̀, títí kan ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì, pẹ̀lú ń ṣiṣẹ́ sìn nínú ìjọ Kristian gẹ́gẹ́ bí akéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́