ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 12/15 ojú ìwé 32
  • “Àlàáfíà Ọlọrun Tí ó Ta Gbogbo Ìrònú Yọ”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Àlàáfíà Ọlọrun Tí ó Ta Gbogbo Ìrònú Yọ”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 12/15 ojú ìwé 32

“Àlàáfíà Ọlọrun Tí ó Ta Gbogbo Ìrònú Yọ”

JÁLẸ̀ ìtàn, àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun ti la àwọn sáà àròdùn ọkàn gbígbóná janjan níti èrò ìmọ̀lára já. Ẹ sì wo bí èyí ṣe jẹ́ òtítọ́ tó lónìí, níwọ̀n bí a ti ń gbé nínú “awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò”! (2 Timoteu 3:1, NW) Aposteli Paulu gba àwọn Kristian nímọ̀ràn láti kó àwọn àníyàn wọn lé Jehofa nípasẹ̀ àdúrà. Pẹ̀lú ìyọrísí wo sì ni? “Àlàáfíà Ọlọrun tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yoo sì máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn-àyà yín ati agbára èrò-orí yín nípasẹ̀ Kristi Jesu.”​—⁠Filippi 4:7, NW.

Kí ni “àlàáfíà Ọlọrun” yìí? Ó jẹ́ ìparọ́rọ́ kan tí ń wá láti inú níní ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá náà. Irúfẹ́ ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ ń fún wa ní ìgbọ́kànlé pé, láìka àwọn wàhálà wa sí, Jehofa “kì yóò pa àwọn ènìyàn rẹ̀ tì; kì yóò kọ àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ sílẹ̀.”​—⁠Orin Dafidi 94:14, Today’s English Version.

Èyí kò túmọ̀ sí pé a ní àjẹsára lòdì sí wàhálà. Onipsalmu náà kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ìpọ́njú olódodo.” (Orin Dafidi 34:19) Ṣùgbọ́n àlàáfíà Ọlọrun lè mú ìtura wá. Báwo?

Àlàáfíà Ọlọrun “ta gbogbo ìrònú yọ,” ni Paulu kọ̀wé​—⁠tàbí gẹ́gẹ́ bí a ti túmọ̀ rẹ̀ nínú Concordant Version, ó “ga ju gbogbo ipò èrò-orí lọ.” Àníyàn lè mú kí a ní ìrírí ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú èrò ìmọ̀lára tí ń kó wàhálà báni. (Oniwasu 7:7) Síbẹ̀, àlàáfíà Ọlọrun lè fi ẹsẹ̀ wa múlẹ̀, ní pàtàkì nígbà tí a bá nílò “agbára tí ó rékọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.”​—⁠2 Korinti 4:⁠7, NW; 2 Timoteu 1:⁠7.

Síwájú sí i, àlàáfíà Ọlọrun jẹ́ ààbò. Ó lè “ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn-àyà yín ati agbára èrò-orí yín,” gẹ́gẹ́ bí Paulu ti kọ̀wé rẹ̀ sí àwọn ará Filippi. Ọ̀rọ̀ Griki náà tí a túmọ̀ sí “ṣọ́ ẹ̀sọ́” jẹ́ èdè àwọn ológun tí ó ṣeéṣe kí ó múni finú yàwòrán àwọn ológun adènà tí wọ́n ń sọ́ ẹ̀sọ́ ní ọ̀sán àti ní òru. Ní ọ̀nà kan náà, àlàáfíà Ọlọrun lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣọ́ oníwákàtí 24 lórí ọkàn-àyà àti agbára èrò-orí wa.​—⁠1 Korinti 10:13; fiwé Efesu 4:⁠26.

Ní ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìpèníjà onípákáǹleke tí a ń dojúkọ lónìí, àlàáfíà Ọlọrun kì í ha ṣe ohun kan tí a níláti ṣọpẹ́ fún bí?​—⁠Orin Dafidi 18:⁠2; fiwé Eksodu 40:⁠38.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́