Ọlọrun Ni Ó Ha Ń ṣàkóso Ayé Bí?
ÒWÚRỌ̀ ọjọ́ Sunday ni. Ọ̀pọ̀ ènìyàn dìde lórí ibùsùn, wọ́n múra, wọ́n jẹ oúnjẹ àárọ̀, wọ́n sì yára lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Níbẹ̀ ni wọ́n ti tẹ́tí sí ìwàásù kan nípa bí Ọlọrun ṣe ń ṣàkóso lọ́nà tí ó ga jùlọ lórí ilẹ̀-ayé, tí kò ní orogún nínú ọlá-àṣẹ. A sọ fún wọn pé ó bìkítà lọ́nà jíjinlẹ̀ fún àwọn ènìyàn. A tún tọ́ka sí Jesu Kristi. Wọ́n lè gbọ́ pé òun ni Ọba àwọn ọba tí gbogbo ènìyàn ń fi pẹ̀lú ìgbọràn tẹ eékún ba fún.
Bí wọ́n ti ń padà délé láti ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n ṣí tẹlifíṣọ̀n wọ́n sì gbọ́ ìròyìn. Wàyí o, wọ́n gbọ́ nípa ìyàn, ìwà-ọ̀daràn, oògùn ìlòkulò, òṣì. Wọ́n sì rí àwọn ìran amúnikáàánú tí ń fi àìsàn àti ikú hàn.
Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì nípa àwọn nǹkan tí wọ́n ti gbọ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì àti ní pàtàkì nípa àwọn ọ̀ràn tí a kò ṣàlàyé níbẹ̀ rárá. Bí Ọlọrun bá jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti alágbára gbogbo, èéṣe tí àwọn nǹkan tí ń kó ìpayà báni fi ń ṣẹlẹ̀? Kí sì ní nípa ti Jesu Kristi? Ó hàn gbangba pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ eékún ní ń bẹ tí kì í fi pẹ̀lú ìgbọràn tẹ̀ba fún un.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Bí Ọlọrun bá ń ṣàkóso ayé, èéṣe tí irú ìjìyà àti rúkèrúdò bẹ́ẹ̀ fi wà?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Cover: NASA photo