ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 54
  • Ṣé Dandan Ni Kí Wọ́n Ṣe Òfin Nínú Ilé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Dandan Ni Kí Wọ́n Ṣe Òfin Nínú Ilé?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ojú tó yẹ kó o máa fi wò ó
  • Ohun tó yẹ kó o ṣe
  • Òfin Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù!
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Òfin Tí Wọ́n Ṣe?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Àwọn Òfin Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù Bí?
    Jí!—2007
  • Kí Ló Dé Táwọn Òbí Mi Ò Fẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 54
Ọmọ kan ń tẹ́tí sí bàbá ẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ

Ṣé Dandan Ni Kí Wọ́n Ṣe Òfin Nínú Ilé?

Ṣé òfin kan wà táwọn òbí ẹ ṣe nínú ilé tí ò bá ẹ lára mu? Àpilẹ̀kọ yìí àti ìwé tó o lè kọ èrò ẹ sí tó bá a wá máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀ ní pa ẹ̀.

  • Ojú tó yẹ kó o máa fi wò ó

  • Ohun tó yẹ kó o ṣe

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Ojú tó yẹ kó o máa fi wò ó

Àròsọ: Tó o bá ti kúrò nílé, o ti di ọ̀gá nìyẹn, kò sófin tó dè ẹ́ mọ́.

Òótọ́ ọ̀rọ̀: Kò sọ́gbọ́n tó o fẹ́ dá sí i, wàá ṣì wà lábẹ́ àṣẹ àwọn kan tó o bá kúrò nílé. Ó lè jẹ́ ọ̀gá ẹ níbi iṣẹ́ tàbí ẹni tó gbà ẹ́ sílé, ó tiẹ̀ lè jẹ́ ìjọba. Danielle tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) sọ pé, “Ìyàlẹ́nu ńlá ló máa jẹ fáwọn ọ̀dọ̀ tí òfin máa ń ni lára nígbà tí wọ́n wà nílé, wọ́n á rí i pé ọ̀rọ̀ ò rí báwọn ṣe rò ó nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í dá gbé.”

Bíbélì sọ pé: “Jẹ́ onígbọràn sí àwọn ìjọba àti àwọn aláṣẹ.” (Títù 3:1) Tó o bá ń tẹ̀ lé òfin táwọn òbí ẹ ṣe, ó máa kọ́ ẹ bó o ṣe máa kojú àwọn nǹkan míì tó o bá bá pà dé lọ́jọ́ iwájú.

Ohun tó o lè ṣe: Àǹfààní táwọn òfin yìí máa ṣe ẹ́ ni kó o máa wò. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jeremy sọ́ pé: “Òfin táwọn òbí mi ṣe ràn mí lọ́wọ́ kí n lè mọ bí màá ṣe yan àwọn tó máa jẹ́ ọ̀rẹ́ mi àti bí màá ṣe máa lo àkókò mi. Kò tún jẹ́ kí n máa fi àkókó ṣòfò nídìí tẹlifíṣọ̀n, kí n sì máa jókòó ti géèmù ṣáá. Mò ń ráyè ṣe àwọn ohun tó n gbádùn mọ́ mi, tó sì ní láárí.”

Ohun tó yẹ kó o ṣe

Àmọ́ tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn òfin kan ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Tamara sọ pé: “Nígbà kan, àwọn òbí mi gbà mí láyè láti rìnrìn àjò lọ́ sórílẹ̀-èdè míì. Àmọ́ ní báyìí tí mo ti pa dà sílé, wọn ò tiẹ̀ jẹ́ kí n gbé mọ́tò lọ sílùú kejì tó wà ní tòsí wa, ibi tó jẹ́ pé àti wa mọ́tò débẹ̀ ò ju ogún ìṣẹ́jú lọ!”

Ká sọ pé irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Tamara yìí ṣẹlẹ̀ sí ẹ, ṣó burú kó o bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà? Kò sóhun tó burú níbẹ̀ rárá. Ìgbà tó o bá wọn sọ ọ́ àti bó o ṣe bá wọn sọ ọ́ ló ṣe pàtàkì.

Ìgbà tó o bá wọn sọ ọ́. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Amanda sọ pé: “O gbọ́dọ̀ ti máa hùwà tó dáa, káwọn òbí ẹ̀ sì ti gbẹ̀rí ẹ jẹ́ kí ẹnu ẹ tó lè gbọ̀rọ̀ láti sọ fáwọn òbí ẹ pé kí wọ́n ṣàtúnṣe sí òfin kan.”

Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Daria gbà pé òótọ́ lohun tí Amanda sọ. Ó sọ pé, “Ìgbà tí mọ́mì rí i pé mo ti ń gbọ́ràn sáwọn lẹ́nu dáadáa ni wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú àti fagi lé àwọn òfin kan.” Má gbàgbé pé o ò lè fipá mú káwọn òbí ẹ fọkàn tán ẹ, ohun tó o bá ń ṣe ló máa mú kí wọ́n fọkàn tán ẹ.

Àwọn ọkọ̀ òfuurufú láti oríṣiríṣi ibi fẹ́ balẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà

Tó ò bá tẹ̀ lé àwọn òfin táwọn òbí ẹ ṣe nínú ilé, nǹkan ò ní lọ bó ṣe yẹ. Ṣe ló máa dà bí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ táwọn tó ń wakọ̀ òfuurufú ò bá tẹ̀ lé òfin ìrìnnà

Bíbélì sọ pé: “Pa àṣẹ baba rẹ mọ́, má sì ṣe ṣá òfin ìyá rẹ tì.” (Òwe 6:20) Tó o bá fi ohun ti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn sọ sílò, wàá lè mú káwọn òbí ẹ fọkàn tán ẹ̀, á sì rọrùn fún ẹ láti bá wọn sọ̀rọ̀.

Bó o ṣe bá wọn sọ ọ́: Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Steven sọ pé, “Téèyàn bá fẹ́ bá òbí ẹ̀ sọ̀rọ̀, ó máa ń dáa gan-an kéèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́, kó sì fi hàn pé òun bọ̀wọ̀ fún wọn dípò kó máa jágbe mọ́ wọn tàbí kó máa ráhùn.”

Daria tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kàn fara mọ́ ohun tí Steven sọ, ó ní: “Tí mo bá tiẹ̀ ń bá mọ́mì mi jiyàn, kì í ran nǹkan. Ìgbà yẹn gan-an ni wọ́n tún wá lè mú káwọn òfin yẹn le sí i.”

Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.” (Òwe 29:11) Téèyàn bá ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń pa nǹkan mọ́ra, inú ilé nìkan kọ́ ló ti máa ṣe é láǹfààní, á ràn án lọ́wọ́ níléèwé, níbí iṣẹ́, ní gbogbo ọ̀nà.

Ohun tó o le ṣe: Máa ronú kó o tó sọ̀rọ̀. Téèyàn ò bá lè pa ọ̀rọ̀ mọ́ra, tó wá da ìbínú bọlẹ̀, ó lè ba orúkọ rere tó ti ní tẹ́lẹ̀ pé ó jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán jẹ́. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé “ẹni tí ó bá lọ́ra láti bínú pọ̀ yanturu ní ìfòyemọ̀.”— Òwe 14:29.

Ìmọ̀ràn: Fi ìwé tó o lè kọ èrò ẹ sí tó bá àpilẹ̀kọ yìí wá ṣàyẹ̀wò òfin táwọn òbí ẹ ṣe, kó o sì ronú lé e lórí. Tó bá sì pọn dandan, ìwọ àtàwọn òbí ẹ lè jọ sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Kimberleigh

“Òfin táwọn òbí máa ń ṣe fáwọn ọmọ wọn máa ń kọ́ wọn láti máa pa nǹkan mọ́ra, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fáwọn míì. Àwọn ànímọ́ yẹn sì máa ń wúlò gan-an téèyàn bá dàgbà. Ká ní kò sófin ni, ayé mi ò lè nítumọ̀, ṣe ni màá sì máa ṣe ohun tó wù mí.”​—Kimberleigh.

Kaley

“Ìgbà tí mo bá ti ṣe nǹkan kan táwọn òbí mi ò fẹ́ tàbí kó jẹ́ pé mo fẹ́ ṣe nǹkan kan tó máa pa mí lára ló máa ń ṣe mí bíi pé àwọn òfin táwọn òbí mi ṣe ti le jù. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ ni pé tèmi náà ni wọ́n ń rò, wọ́n fẹ́ káyé mi dáa.”​—Kaley.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́