Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Àwọn Òfin Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù Bí?
“Ṣe lorí mi máa ń kanrin tí n bá rántí aago táwọn òbí mi ni mo gbọ́dọ̀ máa wọlé lálẹ́! Ó máa ń dùn mí tí n bá ráwọn ọ̀dọ́ míì tí wọn ò ní aago kan pàtó tí wọ́n gbọ́dọ̀ wọlé lálẹ́, témi ò sì lè ṣe bíi tiwọn.”—Allen.
“Nǹkan burúkú gbáà ni kí wọ́n máa ṣọ́ èèyàn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ nítorí bó ṣe ń lo fóònù. Lójú mi, ọ̀nà táwọn obí mi gbà ń bá mi lò ò yàtọ̀ sígbà téèyàn ń tọ́ ọmọ ìkókó!”—Elizabeth.
ṢÉ KÒ máa ṣe ẹ́ bíi pé ìkálọ́wọ́kò táwọn òbí ẹ ń fún ẹ nínú ilé ti pọ̀ jù? Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹ́ rí bíi kó o yọ́ jáde nílé tàbí kó o pe ajá lọ́bọ fáwọn òbí ẹ? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe ẹ ò yàtọ̀ sí bó ṣe ṣe ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan to sọ nípa àwọn òbí ẹ̀ pé àṣejù ti wọ bí wọ́n ṣe ń dáàbò bo òun, ó wá ní: ‘Ṣé wọ́n á tiẹ̀ jẹ́ kí n rímú mí!’
Ó ṣeé ṣe káwọn òbí ẹ tàbí ẹni tó gbà ẹ́ tọ́ ká ẹ lọ́wọ́ kò. Àwọn ìkálọ́wọ́kò wọ̀nyí lè ní nínú àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá, iṣẹ́ ilé àti aago tó o gbọ́dọ̀ wọlé tó fi mọ́ bó o ṣe gbọ́dọ̀ lo fóònù, tẹlifíṣọ̀n tàbí kọ̀ǹpútà. Wọ́n lè má fi mọ sílé nìkan, kó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n tún máa ń ṣọ́ bó o ṣe ń hùwà nílé ẹ̀kọ́ àti irú àwọn tó ò ń bá ṣọ̀rẹ́.
Lemọ́lemọ́ ni ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ máa ń ṣe ohun táwọn òbí ní wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe. Méjì nínú mẹ́ta àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà tá a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé àwọn ti jìyà nítorí pé àwọn ṣe ohun táwọn òbí àwọn kà léèwọ̀, àwọn ìkálọ́wọ́kò yìí ló sì sábà máa ń kó ìyà jẹ àwọn ju ohunkóhun mìíràn lọ.
Àmọ́ ṣá o, èyí tó pọ̀ lára àwọn ọ̀dọ́ ló gbà pé èèyàn nílò àwọn ìkálọ́wọ́kò mélòó kan kéèyàn má bàa kàgbákò. Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ làwọn ìkálọ́wọ́kò yẹn wúlò, kí ló wá dé táwọn kan lára wọn fi máa ń múnú bíni? Báwo lo ṣe lè rí ìtura, bó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn òbí ẹ̀ ti ń ká ẹ lọ́wọ́ kò ju èyí tó o lè fara mọ́?
“N Kì Í Ṣe Ìkókó Kẹ̀”!
Ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kan tó ń jẹ́ Emily béèrè pé: “Kí ni mo lè ṣe táwọn òbí mi á fi mọ̀ pé mo ti kúrò lọ́mọ ọwọ́ tí wọ́n á sì mọ̀ pé dandan ni káwọn jẹ́ kémi náà lómìnira láti ṣe ohun tí n bá fẹ́?” Ṣó ti ṣèwọ náà bẹ́ẹ̀ rí? Bíi ti Emily, ó ṣeé ṣe kí inú ẹ má dùn sáwọn òfin tí wọ́n gbé kalẹ̀ wọ̀nyẹn, èyí tó lè mú kó o máa rò pé ṣe ni wọ́n ń ṣe ẹ bí ìkókó. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn òbí ẹ ò rí ọ̀rọ̀ náà bíwọ ṣe rí i. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí wọ́n ń rò ni pé àwọn ìkálọ́wọ́kò wọ̀nyẹn ṣe pàtàkì láti dáàbò bò ẹ́ àti láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kíwọ náà bàa lè jéèyàn láyé.
Kódà tó o bá tiẹ̀ láwọn òmìnira kan, o ṣì lè máa rò pé òfin tí wọ́n ń gbé lé ẹ lórí yẹn ti le jù. Ó máa dùn ẹ́ wọra àgàgà táwọn òbí ẹ bá máa ń fún àwọn yòókù tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ọmọ ìyá lómìnira tó ju tìẹ lọ. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Marcy sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún, àwọn òbí mi kì í fẹ́ kí ilẹ̀ ṣú bá mi lóde. Bí mo bá ṣe àṣìṣe èyíkéyìí, ìjìyà mi ni pé mi ò gbọ́dọ̀ jáde kúrò nílé, kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ìgbà tí ẹ̀gbọ́n mi wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún bíi tèmi, àsìkò tó bá wù ú ló lè wọlé lálẹ́, kò sì sí ọ̀rọ̀ pé kò gbọ́dọ̀ jáde kúrò nílé torí pé ó ṣàṣìṣe kan.” Nígbà tí Matthew ń sọ nípa ìgbà tóun ò tíì pé ọmọ ogún ọdún, ó rántí ọ̀nà táwọn òbí wọn gbà tọ́ àbúrò rẹ̀ obìnrin àtàwọn ọmọbìnrin èèyàn bàbá ẹ̀, ó ní: “Èèrà kì í rà wọ́n kódà kí wọ́n ṣe ohun tétí ò gbọ́ rí”!
Ṣé Kí Òfin Máà Sí Ló Dáa Jù Ni?
Kò jẹ́ tuntun pé o lè fẹ́ dòmìnira kúrò lábẹ́ àṣẹ àwọn òbí rẹ. Àmọ́ ǹjẹ́ á pé ẹ jù báwọn òbí ẹ ò bá ká ẹ lọ́wọ́ kò? Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn ojúgbà rẹ tí wọ́n lómìnira láti máa wọlé lálẹ́ nígbà tó wù wọ́n, tí wọ́n lómìnira àtimáa múra lọ́nà tí wọ́n bá fẹ́, tí wọ́n sì lè tẹ̀ lé àwọn ọ̀rẹ́ wọn jáde nígbàkugbà, kí wọ́n sì lọ síbikíbi tí wọ́n bá fẹ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe lọwọ́ àwọn òbí wọn dí débi tí wọn ò fi ráyè láti kíyè sí ohun tọ́mọ wọn ń ṣe. Lọ́nàkọ́nà, títọ́mọ nírú ọ̀nà yìí kì í bímọọre. (Òwe 29:15) Ìwà àìnífẹ̀ẹ́ tá à ń rí nínú ayé lónìí kì í ṣẹ̀yìn nǹkan méjì bí ò ṣe àwọn tí ò mọ̀ ju tara wọn nìkan lọ, tó jẹ́ pé ilé tí ò ti sí ìkàlọ́wọ́kò ni wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà.—2 Tímótì 3:1-5.
Ọjọ́ kan á jọ́kan tí èrò rẹ̀ á yí padà nípa ojú tó o fi ń wo ilé tó jẹ́ pé ohunkóhun tó bá wu àwọn ọmọ ni wọ́n lómìnira àtiṣe. Ìwọ wo ìwádìí kan nípa àwọn ọ̀dọ́bìnrin tí wọ́n dàgbà nínú ilé tí ò fi bẹ́ẹ̀ sí ìkálọ́wọ́kò kan pàtó tàbí ká kúkú sọ pé nínú ilé tí ò ti sí àbójútó òbí. Nígbà táwọn ọmọbìnrin náà ń ronú nípa ibi tí ìgbésí ayé wọn wá já sí, kò sí ìkankan nínú wọn tó fọwọ́ sí i pé kí òbí fi ọmọ sílẹ̀ láìsí ìkálọ́wọ́kò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n kà á sí ni pé ṣe làwọn òbí àwọn ò rí tàwọn rò tàbí pé wọn ò mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe ojúṣe wọn.
Dípò táwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n lómìnira àtiṣe ohun tó wù wọ́n á fi máa dá ẹ lọ́rùn, gbìyànjú láti ka kíká táwọn òbí ẹ ká ẹ lọ́wọ́ kò sí àmí ìfẹ́ àti àníyàn wọn fún ẹ. Bí wọ́n bá fi dandan lé e pé o ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn nǹkan kan, Jèhófà Ọlọ́run ni wọ́n ń fara wé, torí ó sọ fáwọn èèyàn ẹ̀ pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.”—Sáàmù 32:8.
Lásìkó yìí, ó ṣeé ṣe kí àwọn ìkálọ́wọ́kò náà máa ga ẹ́ lára. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, o ò ṣe fojú ṣùnnùkùn wo àwọn ìgbésẹ̀ díẹ̀ yìí tó lè jẹ́ kí ilé túbọ̀ tù ọ́ lára.
Àǹfààní Wà Nínú Jíjùmọ̀ Sọ̀rọ̀
Gbogbo ohun tó o nílò ò ju pé kó o ṣàlàyé ara ẹ fáwọn òbí ẹ. Ì báà jẹ́ pé ṣe lò ń fẹ́ òmìnira sí i tàbí pé ṣe ló kàn fẹ́ kí wọ́n dín ọwọ́ líle koko tí wọ́n fi mú ẹ kù. Àwọn kan lè sọ pé: ‘Mo ti sọ títí ó ti sú mi, ibi kọ̀ọ̀ náà ni!’ Bó bá rí bẹ́ẹ̀, bi ara ẹ pé, ‘Àbí ọ̀nà kan wà tó yẹ kí n máa gbà ṣàlàyé ara mi tí wọ́n á fi lè máa gbọ́ mi yé ni?’ Sísọ ohun tó o fẹ́ fáwọn òbí ẹ ṣe pàtàkì torí ó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ bóyá láti (1) rí ohun tó ò ń fẹ́ gbà tàbí láti (2) túbọ̀ lóye ìdí táwọn ohun tó o fẹ́ kì í fi í tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, bó o bá fẹ́ káwọn òbí ẹ fún ẹ láwọn àǹfààní tó tọ́ sí àgbàlagbà, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o kọ́ béèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé onítọ̀hún ti gbọ́n.
◼ Máa kó ara ẹ níjàánu. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.” (Òwe 29:11) Ṣíṣàlàyé ara ẹ lọ́nà tó yẹ kọjá kó o kan máa ṣàròyé nípa ohun tí ò bá ẹ lára mu. Ohun táwọn òbí ẹ tún lè torí rẹ̀ nà ẹ́ lẹ́gba ọ̀rọ̀ ni! Nítorí náà, máa ṣọ́ra fún ohun tó bá máa mú kó o fapá jánú, tó bá máa mú kó o kárí sọ tó sì máa mú kó o fara ya. Kódà, bó bá tiẹ̀ ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o fìbínú tilẹ̀kùn gbàgà tàbí kó o máa fẹsẹ̀ janlẹ̀ káàkiri inú ilé nígbà táwọn òbí ẹ bá ká ẹ lọ́wọ́ kò, rántí pé dípò tírú ìwà bẹ́ẹ̀ fi máa mú kí wọ́n fi kún òmìnira ẹ, ṣe ló máa mú kí wọ́n fi kún àwọn ìkálọ́wọ́kò tó wà nílẹ̀.
◼ Gbìyànjú láti lóye ohun táwọn òbí ẹ ń sọ. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Tracy, ẹni ogún ọdún àmọ́ tó ṣì ń gbé pẹ̀lú ìyá ẹ̀ tó jẹ́ anìkàntọ́mọ sọ pé kékeré kọ́ làǹfààní tóun ń rí. Ó ní: “Mo bi ara mi pé, ‘Ẹ gbọ́ ná, àǹfààní wo ni màmá mi fẹ́ rí nínú àwọn òfin máṣu-mátọ̀ tí wọ́n gbé kalẹ̀ yìí?’ Àṣe ńṣe ni màmá mi fẹ́ ràn mí lọ́wọ́ kí ayé mi bàa lè dáa.” (Òwe 3:1, 2) Bó o bá lè gbìyànjú láti mọ ohun táwọn òbí ẹ ń fẹ́, ó máa jẹ́ kó o lè ṣàlàyé ohun tó wù ẹ́ fáwọn òbí ẹ. Bí àpẹẹrẹ, ká gbà pé kò wu àwọn òbí ẹ pé kó o lọ sóde àríyá kan. Dípò tí wàá fi bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn jiyàn, o lè bi wọ́n pé, ó dáa, ‘Ṣé kémi àtọ̀rẹ́ mi kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ tó sì ṣeé gbọ́kàn lé jọ lọ?’ Síbẹ̀ gbogbo ìgbà kọ́ làwọn òbí á lè máa ṣe ohun tó o fẹ́; ṣùgbọ́n bó o bá mọ èrò wọn, wàá túbọ̀ mọ ọ̀nà tó o lè máa gbà ṣàlàyé ara ẹ.
◼ Túbọ̀ jẹ́ kó rọrùn fáwọn òbí ẹ láti fọkàn tán ẹ. Bí ìgbà téèyàn ń tọ́jú owó sí báńkì ni ọ̀rọ̀ pé kí òbí ẹni fọkàn tánni. Owó tó o bá fi sí báńkì lo máa rí gbà. Bó o bá gbà ju iye tó o tọ́jú sí báńkì lọ, wọ́n máa ní kó o sanwó ìtanràn. Àmọ́, bó bá ṣẹ̀ ń di lemọ́lemọ́ jù, wọ́n á yọ orúkọ ẹ kúrò lára àwọn oníbàárà wọn. Bákan náà ló ṣe jẹ́ pé káwọn òbí ẹ tó lè fún ẹ làwọn àǹfààní kan, o gbọ́dọ̀ ti máa hùwà tó máa fi ẹ hàn bí ọmọlúwàbí, èyí tó dà bí ìgbà téèyàn ń gbà lára owó tó wà ní báńkì.
◼ Má ṣe máa retí ohun tí ò lè ṣeé ṣe. Ojúṣe àwọn òbí ẹ ni pé kí wọ́n mójú tó àwọn ohun tó o bá ń ṣe. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ nípa “àṣẹ bàbá rẹ” àti “òfin ìyá rẹ.” (Òwe 6:20) Síbẹ̀, kò sídìí fún ẹ láti máa rò pé ṣe ni òfin táwọn òbí ẹ gbé kálẹ̀ máa ba ayé ẹ jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, bó o bá fi tinútinú tẹ̀ lé àṣẹ àwọn òbí ẹ, Jèhófà sọ pé, nígbà tó bá yá, “nǹkan á máa lọ déédéé fún ọ”!—Éfésù 6:1-3.
O lè ka pupọ̀ sí i ninú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Èwo ló máa ń ṣòro jù fún ẹ láti tẹ̀ lé nínú àwọn ìkálọ́wọ́kò náà?
◼ Kókó wo lo rí nínú àpilẹ̀kọ yìí tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa fara mọ́ ìkálọ́wọ́kò àwọn òbí ẹ?
◼ Kí lo lè ṣe táwọn òbí ẹ á fi túbọ̀ máa fọkàn tán ẹ?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Bó O Bá Ṣe Ohun Táwọn Òbí Sọ Pó Ò Gbọ́dọ̀ Ṣe
Ó lè jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà lo máa ń pẹ́ níta, lo máa ń ṣàìṣe ojúṣe rẹ nínú ilé tàbí lo máa ń fóònù kọjá àkókó tí wọ́n yọ̀ọ̀da fún ẹ. Àwọn òbí ẹ sì sọ pé kó o wá ṣàlàyé bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ fáwọn! Báwo lo ṣe lè ṣe é tọ́rọ̀ ọ̀hún ò fi ní di ńlá?
◼ Bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ ni kó o sọ. Kò ní dáa kó o máa lo agbárí fáwọn òbí ẹ; òótọ́ ni kó o sọ, má sì ṣe fi ohunkóhun pa mọ́. (Òwe 28:13) Bó o bá yọ́ òjé fún wọn, wọ́n á mọ̀, wọ́n á wá rí ẹ bí ẹni tí ò ṣeé fọ́kàn tán rárá àti rárá. Má ṣe máa wí àwíjàre tàbí kó o máa fojú kéré ohun tó o ṣe. Ní gbogbo ìgbà ni kó o máa rántí pé “ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà.”—Òwe 15:1.
◼ Bẹ̀ wọ́n. Bó o bá fi hàn pé ó dùn ẹ́ pé o ṣe ohun tí ò fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ àti ohun tó dùn wọ́n, tó o sì tún bẹ̀ wọ́n nítorí àfikún iṣẹ́ tó o bá fà, ìyẹn lè dín ìyà tó tọ́ si ẹ kù. (1 Sámúẹ̀lì 25:24) Síbẹ̀, àbámọ̀ náà ò gbọ́dọ̀ jẹ́ ti orí ahọ́n, ó gbọ́dọ̀ dénú ẹ.
◼ Fara mọ́ ohun tójú ẹ bá rí. Bí ìjìyà tó tọ́ sí ẹ bá dà bí èyí tó le jù, ó ṣeé ṣe kó o fẹ́ ṣàròyé. (Òwe 20:3) Àmọ́ bó o bá lè fara mọ́ ohun tó bá tìdí ìwà tó o hù yọ, ìyẹn á jẹ́ àmì pé o ti ń dàgbà. (Gálátíà 6:7) Ohun tí ì bá dáa jù ni pé kó o gbìyànjú láti ṣe gbogbo ohun tó máa jẹ́ káwọn òbí ẹ̀ padà rí ẹ bí ẹni tó ṣeé fọkàn tán.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Gbìyànjú láti mọ ohun táwọn òbí ẹ ń torí ẹ̀ ṣe wàhálà lé ẹ lórí