ORÍ 22
Òfin Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù!
Kọ díẹ̀ lára àwọn òfin tẹ́ ẹ ní nílé yín síbí. ․․․․․
Ṣó o rò pé gbogbo ìgbà làwọn òfin táwọn òbí bá gbé kalẹ̀ máa ń bọ́gbọ́n mu?
□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá
Òfin wo ló nira fún ẹ jù láti pa mọ́? ․․․․․
Ó ṢEÉ ṢE káwọn òbí ẹ ti ka àwọn nǹkan tó ò gbọ́dọ̀ máa ṣe àtàwọn nǹkan tó o gbọ́dọ̀ ṣe fún ẹ. Bóyá àwọn òfin nípa iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún ẹ láti iléèwé, iṣẹ́ ilé, aago tó o gbọ́dọ̀ ti wà nílé, bó o ṣe gbọ́dọ̀ lo fóònù alágbèéká ẹ, ìgbà tó o lè wo tẹlifíṣọ̀n àti iye àkókò tó o lè lò nídìí kọ̀ǹpútà. Àwọn òfin yẹn tiẹ̀ lè kọjá àwọn nǹkan tó ò ń ṣe nílé, ó lè kan bó o ṣe gbọ́dọ̀ máa ṣe níléèwé àtàwọn tó o gbọ́dọ̀ máa bá rìn.
Ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé inú àhámọ́ lo wà? Bóyá bó ṣe rí lára àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí ló ṣe rí lára ìwọ náà:
“Ó máa ń dùn mí gan-an bí mo bá rántí pé ó níye aago tí mo gbọ́dọ̀ wọlé! Inú sì máa ń bí mi bí mo bá ráwọn míì tí wọ́n làǹfààní láti pẹ́ níta jù mí lọ.”—Allen.
“Kò sí kí inú máà bí èèyàn tó bá rántí pé wọ́n ń ṣọ́ bó ṣe ń lo fóònù alágbèéká ẹ̀. Ó máa ń dà bíi pé ojú ọmọdé ni wọ́n ṣì fi ń wò mí!”—Elizabeth.
“Ńṣe ló ń ṣe mí bíi pé àwọn òbí mi ò fẹ́ kí n gbádùn ara mi, pé wọn ò sì fẹ́ kí n lọ́rẹ̀ẹ́!”—Nicole.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin àwọn òbí kì í bára dé fáwọn ọ̀dọ́ kan, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀dọ́ ló gbà pé àwọn nílò àwọn òfin díẹ̀ kí nǹkan má bàa bà jẹ́ fáwọn. Bí òfin inú ilé bá tiẹ̀ wá pọn dandan, kí ló dé táwọn kan kì í fi í tẹ́ni lọ́rùn?
“Mi Ò Kí Ń Ṣọmọdé Mọ́ O Jàre!”
Bóyá ìdí tó o fi ń bínú sáwọn òfin kan ni pé o rò pé àwọn òbí ẹ ń ṣe ẹ́ bí ọmọdé. O sì fẹ́ sọ fún wọn pé: “Mi ò kí ń ṣọmọdé mọ́ o jàre!” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn òbí ẹ rò pé àwọn òfin táwọn gbé kalẹ̀ wúlò fún ẹ káwọn lè dáàbò bò ẹ́, káwọn sì lè múra ẹ sílẹ̀ fáwọn ojúṣe tó máa já lé ẹ léjìká tó o bá dàgbà.
Síbẹ̀, ó lè dà bíi pé àwọn òfin táwọn òbí ẹ ṣe ò yí pa dà látijọ́ tí wọ́n ti gbé wọn kalẹ̀, wọn ò sì bá ọjọ́ orí ẹ mu mọ́. Bóyá bọ́rọ̀ ṣe rí lára ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Brielle náà ló ṣe rí lára tìẹ náà, ó sọ nípa àwọn òbí ẹ̀ pé: “Wọ́n ti gbàgbé bó ṣe máa ń rí láti dọmọge. Wọn ò fẹ́ kí n sọ tẹnu mi, wọn ò fẹ́ kí n yan nǹkan tí mo fẹ́, wọn ò tiẹ̀ fẹ́ kí n ṣe bí àgbà.” Bọ́rọ̀ sì ṣe rí lára ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Allison náà nìyẹn, ó ní: “Kò yé àwọn òbí mi pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] ni mí, pé mi ò kí ń ṣe ọmọ ọdún mẹ́wàá [10] mọ́. Ó yẹ kí wọ́n túbọ̀ fọkàn tán mi!”
Ó lè má rọrùn fún ẹ láti ṣègbọràn sófin táwọn òbí ẹ gbé kalẹ̀, àgàgà tí wọn ò bá le mọ́ àwọn àbúrò àti ẹ̀gbọ́n ẹ bí wọ́n ṣe ń le mọ́ ẹ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Matthew rántí ìgbà tí kò tíì ju ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] lọ, ó sọ nípa àbúrò ẹ̀ obìnrin àtàwọn ọmọ àbúrò dádì ẹ̀, ó ní: “Bí wọ́n tiẹ̀ pààyàn, wọn ò ní torí ẹ̀ bá wọn wí!”
Ká Ní Kò Sófin
Ó dájú pé wàá ti máa wọ̀nà fún ìgbà tó o máa kúrò lábẹ́ àṣẹ àwọn òbí ẹ. Àmọ́, ṣó dá ẹ lójú pé kíkúrò lábẹ́ àwọn òbí ẹ máa ṣe ẹ́ láǹfààní ju báyìí lọ? Bóyá o mọ àwọn ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ pé ìgbà tó bá wù wọ́n ni wọ́n máa ń wọlé, aṣọ tàbí bàtà tó bá wù wọ́n ni wọ́n máa ń wọ̀, ìgbà tó bá sì wù wọ́n ni wọ́n máa ń báwọn ọ̀rẹ́ wọn jáde. Ohun tó ṣeé ṣe kó máa ṣẹlẹ̀ lọ́rọ̀ tiwọn ni pé àwọn òbí wọn ò ráyè tiwọn. Ohun yòówù kó fà á, Bíbélì ti fi dá wa lójú pé àwọn tó ń tọ́mọ lọ́nà yẹn ò lè tọ́mọ yanjú. (Òwe 29:15) Ẹ̀mí tèmi làkọ́kọ́ ni ò jẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ ara wọn mọ́ láyé tá a wà yìí, inú ilé tí wọ́n ti fàyè gbàgbàkugbà lọ̀pọ̀ wọn sì ti wá.—2 Tímótì 3:1-5.
Kàkà kó o máa jowú àwọn ọ̀dọ́ tó ń ṣe bó ṣe wù wọ́n, máa wo òfin táwọn òbí ẹ gbé kalẹ̀ bí ẹ̀rí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹ, wọ́n sì bìkítà gan-an nípa ẹ. Bí wọ́n ṣe fún ẹ lófin pé o ò gbọ́dọ̀ ṣàwọn nǹkan kan jẹ́ kí wọ́n fìwà jọ Jèhófà Ọlọ́run tó sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.”—Sáàmù 32:8.
Nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé òfin táwọn òbí ẹ gbé kalẹ̀ ti pọ̀ jù. Kí lo lè ṣe kára lè tù ẹ́ díẹ̀?
Ọ̀rọ̀ Tó Máa Sèso Rere
Bóyá o fẹ́ káwọn òbí ẹ fún ẹ láyè sí i ni tàbí o fẹ́ kára tù ẹ́ díẹ̀, ohun tó o lè fi gbara ẹ ni pé kó o bá wọn sọ̀rọ̀. Àwọn kan lè máa sọ pé: ‘Mo ti gbìyànjú láti bá wọn sọ̀rọ̀, àmọ́ ọ̀rọ̀ mi ò tà!’ Bó bá jẹ́ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ nìyẹn, bi ara ẹ pé, ‘Ṣé mo lè tún bí mo ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀ ṣe?’ Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dáa gan-an láti (1) jẹ́ káwọn èèyàn lóye ẹ dáadáa tàbí (2) kó jẹ́ kí ìdí tí wọn ò fi yọ̀ǹda àwọn nǹkan kan fún ẹ yé ẹ dáadáa. Ká sòótọ́, bó o bá fẹ́ káwọn òbí ẹ máa fún ẹ láwọn àǹfààní tó tọ́ sáwọn tó ti dàgbà, àfi kíwọ náà máa sọ̀rọ̀ bí àgbà. Báwo lo ṣe lè ṣèyẹn?
Má máa fara ya. Èèyàn gbọ́dọ̀ máa kóra ẹ̀ níjàánu bó bá ń báwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀. Bíbélì jẹ́ kó yé wa pé: “Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.” (Òwe 29:11) Torí náà yé máa kùn sáwọn òbí ẹ, má sì máa fapá jánú bí ọmọdé bí wọ́n bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀. Òótọ́ ni pé ó lè ṣe ẹ́ bíi kó o fìbínú pa ilẹ̀kùn dé tàbí kó o máa fẹsẹ̀ janlẹ̀ láàárín ilé báwọn òbí ẹ ò bá fún ẹ láyè láti ṣe ohun kan. Àmọ́, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ á wulẹ̀ jẹ́ kí wọ́n fi kún àwọn òfin tí wọ́n fún ẹ ni, kò lè jẹ́ kí wọ́n fún ẹ lómìnira sí i.
Gbìyànjú láti lóye ohun táwọn òbí ẹ ń ṣe. Tracy, ọ̀dọ́ Kristẹni kan tí màmá ẹ̀ nìkan tọ́ dàgbà, sọ nígbà tó pé ọmọ ogún ọdún pé: “Mo bi ara mi pé, ‘Kí ni mọ́mì mi tiẹ̀ máa rí gbà nídìí gbogbo àwọn òfin tí wọ́n tò kalẹ̀ yìí?’” Nígbà tí Tracy máa dáhùn ìbéèrè rẹ̀, ó ní: “Wọ́n kàn fẹ́ ràn mí lọ́wọ́ láti jéèyàn ni.” (Òwe 3:1, 2) Bó o bá lóye àwọn òbí ẹ dáadáa, á jẹ́ kó o mọ bí wàá ṣe lè bá wọn sọ̀rọ̀.
Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé àwọn òbí ẹ ò fẹ́ jẹ́ kó o lọ síbi àpèjẹ kan tí wọ́n pè ẹ́ sí. Kàkà kó o máa bá wọn jiyàn, o lè béèrè pé, “Bí àgbàlagbà kan tẹ́ ẹ fọkàn tán bá tẹ̀ lé mi lọ ńkọ́?” Wọ́n lè máà jẹ́ kó o lọ síbẹ̀ náà. Àmọ́, tó o bá mọ ìdí tí ẹ̀rù fi ń bà wọ́n, bóyá o ṣì lè dábàá tó máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, tí wọ́n á sì jẹ́ kó o lọ.
Jẹ́ káwọn òbí ẹ fọkàn tán ẹ. Ká sọ pé ọkùnrin kan jẹ báńkì lówó. Bó bá ń san gbèsè rẹ̀ pa dà bó ṣe yẹ, ó dájú pé báńkì yẹn máa fọkàn tán an, wọ́n á sì lè yá a lówó nígbà míì. Bọ́ràn ṣe rí pẹ̀lú àwọn òbí nìyẹn. Ìwọ náà jẹ àwọn òbí ẹ ní gbèsè ìgbọràn. Bó o bá jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán ẹ lórí nǹkan kékeré pàápàá, ó dájú pé wọ́n á fọkàn tán ẹ lọ́jọ́ iwájú. Bó ò bá gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ lẹ́nu, má jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu pé wọ́n lè dín òmìnira tó o ní tẹ́lẹ̀ kù tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máà fún ẹ láyè kankan mọ́ pàápàá.
Bó O Bá Ti Ṣẹ̀
Bó pẹ́ bó yá, wàá ṣẹ àwọn òbí ẹ. Bóyá nítorí pé o ò ṣiṣẹ́ ilé tí wọ́n ní kó o ṣe, bóyá o pẹ́ jù lórí fóònù, ó sì lè jẹ́ pé o pẹ́ kó o tó wọlé. (Sáàmù 130:3) Bọ́ràn bá rí báyìí, àfi kó o ṣàlàyé ara ẹ! Kí lo lè ṣe tọ́rọ̀ tó ti wọ́ ò fi ní bà jẹ́ pátápátá?
Má purọ́. Má gbé irọ́ kalẹ̀ fún wọn. Bó o bá purọ́, àwọn òbí ẹ ò ní gbà ẹ́ gbọ́ mọ́. Torí náà bọ́rọ̀ bá ṣe rí gan-an ni kó o sọ. (Òwe 28:13) Má ṣe wí àwíjàre. Rántí pé “ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà.”—Òwe 15:1.
Tọrọ àforíjì. Bó o bá jẹ́ káwọn òbí ẹ rí i pé wàhálà tó o ti kó wọn sí nítorí àìgbọràn ẹ dùn ẹ́ gan-an, ó lè jẹ́ kí wọ́n dín ìyà tó o máa jẹ kù. Àmọ́, jẹ́ kó hàn pé ohun tó ṣẹlẹ̀ dùn ẹ́ lóòótọ́.
Ibi tó wù kí ọ̀rọ̀ náà já sí, ṣáà fọwọ́ wọ́nú. (Gálátíà 6:7) Ó ṣeé ṣe kínú ẹ má dùn sí ìyà tí wọ́n fẹ́ fi jẹ ẹ́, bóyá torí pé o rò pé ó ti pọ̀ jù. Àmọ́, gbígba ohunkóhun tó bá tìdí ohun tó o ṣe yọ fi hàn pé ìwọ náà ti ń dàgbà. Ohun tó máa dáa jù ni pé kó o bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lórí báwọn òbí ẹ ṣe lè fọkàn tán ẹ pa dà.
Kọ èyí tó kàn ẹ́ gbọ̀ngbọ̀n lára àwọn kókó mẹ́ta tó wà lókè síbí. ✎
Rántí pé àwọn òbí ẹ láṣẹ láti ṣàwọn òfin kan láti dáàbò bò ẹ́. Ìdí gan-an nìyẹn tí Bíbélì fi sọ̀rọ̀ nípa “àṣẹ baba rẹ” àti “òfin ìyá rẹ.” (Òwe 6:20) Ìyẹn ò wá ní kó o máa rò pé àwọn òfin táwọn òbí ẹ gbé kalẹ̀ nílé lè bayé ẹ jẹ́. Àmọ́, bó o bá ń pa àṣẹ àwọn òbí ẹ mọ́, Jèhófà ti ṣèlérí pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín “nǹkan [á] máa lọ dáadáa fún ọ”!—Éfésù 6:1-3.
KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 3, NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ
Ṣó o ní òbí tí ò lè ṣe kó má mutí tàbí lo oògùn nílòkulò? Kà nípa bó o ṣe lè fara dà á.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ . . . kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ.”—Éfésù 6:2, 3.
ÌMỌ̀RÀN
Bó o bá fẹ́ káwọn òbí ẹ fún ẹ ní òmìnira tó pọ̀ sí i, kọ́kọ́ máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. Bí wọ́n bá ti rí i pé o máa ń gbọ́ tiwọn, ó ṣeé ṣe kí wọ́n yọ̀ǹda fún ẹ láti ṣe ohun tó o fẹ́.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Ìwádìí ti fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ táwọn òbí wọn máa ń fún láwọn òfin onífẹ̀ẹ́ sábà máa ń mókè níléèwé, ara wọn máa ń yọ̀ máwọn èèyàn, inú wọn sì máa ń dùn.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Bí mo bá ṣẹ àwọn òbí mi, màá sọ pé ․․․․․
Àwọn òbí mi màá finú tán mi, bí mo bá ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí nìdí tó fi lè dà bíi pé àwọn òbí ẹ ti ń dáàbò bò ẹ́ ju bó ti yẹ lọ nígbà míì?
● Kí nìdí tó o fi máa ń fara ya tí wọn ò bá fún ẹ láyè láti ṣe ohun kan nígbà míì?
● Báwo lo ṣe lè mú kí ọ̀nà tó o gbà ń bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀ sunwọ̀n sí i?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 183]
“Nígbà tó o ṣì kéré, o máa ń rò pé ìwọ lo gbọ́n jù. Ìdí nìyẹn tó o fi máa ń bínú sáwọn òbí ẹ tí wọ́n bá gbé àwọn òfin kan kalẹ̀. Àmọ́ tìẹ náà ni wọ́n ń ṣe.”—Megan
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 186]
Ṣé Ojúsàájú Ni?
Ṣó o ti rò ó rí pé, ‘Kí nìdí táwọn òbí mi kì í fi í ṣe bákan náà sí gbogbo wa?’ Bó o bá ti rò bẹ́ẹ̀ rí, ohun tó o gbọ́dọ̀ mọ̀ ni pé: Kò bọ́gbọ́n mu pé káwọn òbí yín fọwọ́ kan náà mú gbogbo yín. Ìbéèrè tó tiẹ̀ yẹ kó o bi ara ẹ ni pé, Ṣáwọn òbí mi ń febi pa mí ni, àbí aṣọ ni wọn ò rà sí mi lọ́rùn? Bí àpẹẹrẹ, ṣé wọn kì í fún ẹ nímọ̀ràn, kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n tì ẹ́ lẹ́yìn tó o bá nílò rẹ̀? Bí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣó o wá lè fi gbogbo ẹnu sọ pé, wọ́n ń ṣojúsàájú? Torí pé ìwọ àtàwọn àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n ẹ yàtọ̀ síra yín, kò sí báwọn òbí yín ṣe lè ṣe bákan náà sí yín lẹ́ẹ̀kan náà. Ohun tó wá yé Beth nìyẹn nígbà tó di ọmọ ọdún méjìdínlógún [18]. Ó ní: “Ìwà èmi àti àbúrò mi ọkùnrin ò dọ́gba rárá, wọn ò sì lè tọ́ wa bákan náà. Bí mo bá ronú sẹ́yìn, ó máa ń yà mí lẹ́nu pé ọ̀rọ̀ ò yé mi báyìí nígbà tí mo ṣì kéré.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 189]
Tí mo kọ èrò mi sí
Báwọn Òbí Ẹ Sọ̀rọ̀!
Àwọn orí méjì tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán ti ṣàlàyé ohun tó o lè ṣe tó o bá rò pé àwọn òbí ẹ ń rí sí ẹ ṣáá tàbí tó bá dà bíi pé òfin táwọn òbí ẹ gbé kálẹ̀ ti pọ̀ jù. Tó o bá wá rò pé àwọn òbí ẹ ti tàṣejù bọ̀ ọ́ ńkọ́? Báwo lo ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú wọn lórí ọ̀ràn náà?
● Wá àkókò tara ẹ balẹ̀, tọ́wọ́ àwọn òbí ẹ sì dilẹ̀.
● Sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lọ́kàn ẹ, àmọ́ má sọ ọ́ bó ṣe ká ẹ lára tó. Bọ̀wọ̀ fáwọn òbí ẹ.
Tó o bá rò pé àwọn òbí ẹ ti le koko jù, o lè sọ pé: “Mò ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó tọ́, àmọ́ ó máa ń ṣòro fún mi bí mo bá rí i pé gbogbo ìgbà ni mi ò kì í lè tẹ́ ẹ yín lọ́rùn. Ẹ jọ̀ọ́, ṣá a lè sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ báyìí?”
Kọ bó o ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò lórí ọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú àwọn òbí ẹ sórí ìlà yìí.
․․․․․
✔ ÀBÁ: Tó ò bá mọ bó o ṣe máa bẹ̀rẹ̀, lo ìmọ̀ràn tó wà ní Orí 21. Bóyá àwọn òbí ẹ tiẹ̀ lè jíròrò orí yẹn pẹ̀lú ẹ.
Tó o bá rò pé àwọn òbí ẹ ò fún ẹ ní òmìnira tó bó ṣe yẹ, o lè sọ pé: “Ó wù mí kí n fi hàn nínú ìwà mi pé èmi náà ti ń dàgbà kẹ́ ẹ lè fún mi láyè sí i. Kí lẹ rò pé ó yẹ kí n ṣiṣẹ́ lé lórí?”
Kọ bó o ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò lórí ọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú àwọn òbí ẹ sórí ìlà yìí.
․․․․․
✔ ÀBÁ: Tún Orí 3 kà nínú Apá Kìíní ìwé yìí. Àkòrí rẹ̀ ni “Bawo ni Mo Ṣe Lè Mú Ki Awọn Obi Mi Túbọ Fun Mi Ni Ominira Sii?” Lẹ́yìn tó o bá kà á tán, kọ àwọn ìbéèrè tó o bá ní nípa ohun tó o kà sílẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 184, 185]
Bí ìgbà tó ò ń san gbèsè tó o jẹ báńkì ni pípa àṣẹ àwọn òbí ẹ mọ́, bó o bá ṣe ń pàṣẹ wọn mọ́ tó ni wọ́n á ṣe máa fọkàn tán ẹ tó