ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 6
  • Kí Ló Dé Táwọn Òbí Mi Ò Fẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Dé Táwọn Òbí Mi Ò Fẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí nìdí táwọn òbí mi kì í fẹ́ kí n ṣe ohun tó wù mí?
  • Kí ni mo lè ṣe káwọn òbí mi lè gbà kí n ṣe ohun tó wù mí?
  • Òfin Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù!
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Kí Nìdí Táwọn Òbí Mi Kì Í Fi Í Jẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Kí Nìdí Táwọn Òbí Mi Kì Í Jẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?
    Jí!—2011
  • Kí Ni Kí N Ṣe Báwọn Òbí Mi Bá Ń Jà?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 6
Ọ̀dọ́kùnrin kan ń bá àwọn òbí ẹ̀ sọ̀rọ̀. Àwòrán mẹ́ta tó wà níwájú ẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa géèmù orí kọ̀ǹpútà, àwọn ọ̀dọ́ tó ń jó ní patí àti nǹkan táwọn ọ̀dọ́ fi ń sáré. Àwọn òbí ẹ̀ káwọ́ gbera, wọ́n sì fajú ro.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ló Dé Táwọn Òbí Mi Ò Fẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?

Àwọn ọ̀rẹ́ ẹ ní kẹ́ ẹ jọ jáde lópin ọ̀sẹ̀. O béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí ẹ bóyá o lè lọ, àmọ́ wọn ò rò ó lẹ́ẹ̀mejì kí wọ́n tó sọ pé, “Rárá.” Ìdáhùn wọn ò yà ẹ́ lẹ́nu, torí ohun tí wọ́n máa ń sọ nìyẹn.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí

  • Kí nìdí táwọn òbí mi kì í fẹ́ kí n ṣe ohun tó wù mí?

  • Kí ni mo lè ṣe káwọn òbí mi lè gbà kí n ṣe ohun tó wù mí?

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Kí nìdí táwọn òbí mi kì í fẹ́ kí n ṣe ohun tó wù mí?

Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà làwọn òbí ẹ kì í jẹ́ kó o ṣe ohun tó wù ẹ́, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé wọn ò fẹ́ kó o gbádùn ara ẹ.

Bó ṣe rí lára ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Marie nìyẹn nígbà tó kọ́kọ́ ra fóònù. Ó sọ pé: “Oríṣiríṣi òfin ni dádì mi ṣe. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sọ àwọn nǹkan tí mo lè gbà sórí ẹ̀, àwọn tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti ìgbà tí mo lè bá wọn sọ̀rọ̀ dà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ọ̀rẹ́ mi lè ṣe ohun tó bá wù wọ́n.”

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé dádì Marie ò fẹ́ kó gbádùn ara ẹ̀ lóòótọ́? Kí làwọn ohun tó ṣeé ṣe kó máa rò?

Ọkọ̀ kan ń lọ lójú títì. Àmì kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì náà tó ń sọ ìwọ̀n eré tí awakọ̀ kan lè sá, wọ́n kọ “50” sí i lára. Àwòrán tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ̀ náà jẹ́ ká rí i pé ọkọ̀ náà ò sá kọjá 50.

Àmì ìwọ̀n eré téèyàn lè sá tí wọ́n ń gbé ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà máa ń dáàbò bo àwọn awakọ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í jẹ́ kí wọ́n sáré bí wọ́n ṣe fẹ́, bí òfin táwọn òbí ń fáwọn ọmọ wọn náà ṣe rí nìyẹn

Gbìyànjú èyí wò: Ká sọ pé òbí ni ẹ́, ọmọ ẹ sì ṣẹ̀ṣẹ̀ ra fóònù. Kí làwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó o máa rò? Àwọn òfin wo lo máa ṣe kó o lè dáàbò bo ọmọ ẹ? Kí lo máa ṣe tí ọmọ ẹ bá sọ pé o ò fẹ́ kóun gbádùn ara òun?

“Dádì mi máa ń sọ pé, ‘Ìwọ náà máa di òbí lọ́jọ́ kan.’ Ìyẹn máa ń jẹ́ kí n rí i pé òótọ́ ọ̀rọ̀ ni wọ́n ń bá mi sọ, ó sì máa ń jẹ́ kí n rídìí tí wọ́n fi ní kí n máa ṣe àwọn nǹkan kan. Ká lémi náà ti bímọ ni, ohun tí dádì mi fẹ́ kí n ṣe lèmi náà á fẹ́ káwọn ọmọ mi máa ṣe.”—Tanya.

Kí ni mo lè ṣe káwọn òbí mi lè gbà kí n ṣe ohun tó wù mí?

Ọmọkùnrin kan lejú, ó káwọ́ gbera, èéfín sì ń yọ lẹ́tí ẹ̀.

Ohun tí kò yẹ kó o ṣe: Má bínú, má ṣàròyé, má sì báwọn òbí ẹ jiyàn.

Ọmọkùnrin kan lejú, ó káwọ́ gbera, èéfín sì ń yọ lẹ́tí ẹ̀.

“Tó o bá tiẹ̀ kígbe látòní dọ̀la, ìyẹn ò ní kí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yanjú, ṣe ni wàá tiẹ̀ tún kó àárẹ̀ bá ara ẹ àtàwọn òbí ẹ. Tó o bá ń bá àwọn òbí ẹ jiyàn, wọ́n á gbà pé o ò tíì gbọ́n, àti pé àwọn ṣì gbọ́dọ̀ máa mójú tó ẹ.”—Richard.

Gbìyànjú èyí wò: Má fún àwọn òbí ẹ lésì lójú ẹsẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ronú nípa ohun tó mú kí wọ́n sọ ohun tí wọ́n sọ. Bi ara ẹ pé: “Ṣé àwọn òbí mi ò fọkàn tán mi ni àbí ọkàn wọn ò balẹ̀ nípa ibi tí mo fẹ́ lọ àti àwọn tá a jọ máa wà níbẹ̀?” Á dáa kó o fara balẹ̀, kó o sì bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ẹ kó o lè mọ ohun tó jẹ́ kí wọ́n sọ ohun tí wọ́n sọ.

Iná kan tàn.

Ohun tó o lè ṣe: Kó o tó bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀, rí i dájú pé àlàyé tó mọ́gbọ́n dání lo máa ṣe fún wọn, á sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Táwọn òbí ẹ ò bá tiẹ̀ fara mọ́ ohun tó o sọ, ọ̀rọ̀ ẹ á yé wọn, tiwọn náà á sì yé ẹ.

“Tèmi làwọn òbí mi ń rò tí wọ́n bá ní kí n má ṣe nǹkan kan. Kì í ṣe pé àwọn òbí mi ò fẹ́ kí n gbádùn ara mi; wọn ò kàn fẹ́ kí n ṣe ohun táá kó mi síṣòro ni.”—Ivy

Ìlànà Bíbélì: “Gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára òmùgọ̀ ló máa ń sọ jáde, àmọ́ ọlọ́gbọ́n máa ń mú sùúrù.”—Òwe 29:11.

Ọmọbìnrin kan ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí ìkànnì àjọlò nígbà tílẹ̀ ti ṣú.

Ohun tí kò yẹ kó o ṣe: Má yọ́ nǹkan ṣe lẹ́yìn àwọn òbí ẹ.

Ọmọbìnrin kan ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí ìkànnì àjọlò nígbà tílẹ̀ ti ṣú.

“Mo máa ń dọ́gbọ́n ṣe àwọn nǹkan tí dádì mi ní kí n má ṣe lórí fóònù mi. Bí àpẹẹrẹ, mo lè máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sáwọn ọ̀rẹ́ mi lálẹ́ àbí kí n máa dé àwọn ibi tí wọ́n ní kí n má dé lórí fóònù. Tí dádì mi bá wá mọ̀, ṣe ni wọ́n á fún mi lófin tó ju ti tẹ́lẹ̀ lọ torí mi ò ṣe ohun táá jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán mi. Kò dáa rárá kéèyàn máa ṣe ohun tí wọ́n bá ní kó má ṣe.”—Marie.

Gbìyànjú èyí wò: Máa ṣe ohun táá jẹ́ káwọn òbí ẹ rí i pé onígbọràn ọmọ ni ẹ́ àti pé àwọn lè fọkàn tán ẹ.

Iná kan tàn.

Ohun tó o lè ṣe: Táwọn òbí ẹ bá bi ẹ́ pé (“Àwọn wo ló máa wà níbi ìkórajọ náà?” “Ìgbà wo lo máa dé?”), jẹ́ kí ìdáhùn ẹ ṣe pàtó kó o sì rí i pé òótọ́ lo sọ. Ìdáhùn tó ṣe pàtó á jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán ẹ!

“Ṣe sùúrù. Ó lè ṣe díẹ̀ káwọn òbí ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbà ẹ́ láyè láti ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ní kó o má ṣe tẹ́lẹ̀, àmọ́ tí wọ́n bá rí i pé ò ń ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ní kó o ṣe, wọ́n lè gbà ẹ́ láyè láti ṣe ohun tó o bá fẹ́.”—Melinda.

Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu nínú ohun gbogbo.”—Kólósè 3:20.

Ọmọkùnrin kan ń bẹ̀bẹ̀. Àwòrán tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ jẹ́ ká rí àwọn ọ̀dọ́ mẹ́ta míì.

Ohun tí kò yẹ kó o ṣe: Má fi dandan lé e pé káwọn òbí ẹ ṣe ohun tó o fẹ́ torí pé àwọn ọ̀rẹ́ ẹ ń ṣe bẹ́ẹ̀.

Ọmọkùnrin kan ń bẹ̀bẹ̀. Àwòrán tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ jẹ́ ká rí àwọn ọ̀dọ́ mẹ́ta míì.

“Má rò pé tó o bá ń tẹnu mọ́rọ̀ ìyẹn á jẹ́ kó o rí nǹkan tó ò ń fẹ́.”—Natalie.

Gbìyànjú èyí wò: Lo ìwé “Ronú Lórí Òfin Táwọn Òbí Ẹ Ṣe” kó o lè mọ bí wàá ṣe bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀.

Iná kan tàn.

Ohun tó o lè ṣe: Ìgbà táwọn òbí ẹ máa lè fara balẹ̀ gbọ́ ẹ ni kó o bá wọn sọ̀rọ̀, kì í ṣe ìgbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ibi iṣẹ́ tàbí tí ọwọ́ wọn dí.

“Àwọn òbí máa ń fẹ́ rí i pé ọmọ àwọn mọ nǹkan tó ń ṣe. Torí náà, tí mo bá ń bá àwọn òbí mi sọ̀rọ̀, mo máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé mo ti ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa, dípò kí n máa sọ bó ṣe rí lára mi. Tí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ mi máa ń tà létí wọn.”—Joseph.

Ìlànà Bíbélì: “Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ.”—Éfésù 6:2.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

  • Isabella.

    “Mo ti rí i pé òfin gbọ́dọ̀ wà nínú ìdílé kí nǹkan lè máa lọ dáadáa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé òfin là ń pè é, àǹfààní wa ló wà fún. Tó bá jọ pé òfin kan ti le jù, á jẹ́ pé àwọn nǹkan kan ń ṣẹlẹ̀ tó mú káwọn òbí wa ṣe òfin náà.”—Isabella.

  • Michael.

    “Mo gbà pé àwọn ọmọ táwọn òbí fún lófin nígbà tí wọ́n wà ní kékeré máa ń ṣe dáadáa tí wọ́n bá dàgbà. A ò lè máa ṣe bó ṣe wù wá tá a bá fẹ́ gbádùn ayé wa. Tá ò bá ṣe àwọn nǹkan tí kò yẹ ká ṣe, ìyẹn á fi hàn pé a ṣeé fọkàn tán, á sì tún jẹ́ ká yẹra fún ewu èyíkéyìí.”—Michael.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́