ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/11 ojú ìwé 18-20
  • Kí Nìdí Táwọn Òbí Mi Kì Í Jẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Táwọn Òbí Mi Kì Í Jẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Lè Mú Kí Àwọn Òbí Rẹ Sọ Pé Kí O Má Ṣe Lọ
  • Àwọn Nǹkan Tó O Lè Ṣe Tó O Bá Fẹ́ Kí Wọ́n Máa Fún Ẹ Láyè
  • Kí Nìdí Táwọn Òbí Mi Kì Í Fi Í Jẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Kí Ló Dé Táwọn Òbí Mi Ò Fẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Òfin Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù!
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀?
    Jí!—2010
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 4/11 ojú ìwé 18-20

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Kí Nìdí Táwọn Òbí Mi Kì Í Jẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?

Ọ̀dọ́bìnrin kan láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Allisona sọ pé, wàhálà tó máa ń bá mi níléèwé láàárọ̀ ọjọ́ Monday máa ń pọ̀ jù fún mi, gbogbo ìgbà ló sì máa ń ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀.

Ó sọ pé: “Gbogbo èèyàn ló máa ń sọ ohun tí wọ́n ṣe ní òpin ọ̀sẹ̀, àwọn nǹkan tí wọ́n sọ sì máa ń dùn mọ́ mi, wọ́n lè sọ iye ibi àríyá tí wọ́n lọ, iye àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n fẹnu kò lẹ́nu, kódà wọ́n máa ń sọ bí wọ́n ṣe sá mọ́ àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́. . . Ó máa ń já mi láyà, àmọ́ ó máa ń mú mi lórí yá. Nǹkan bí aago márùn-ún ìdájí ni wọ́n máa ń pa dà wọlé, àwọn òbí wọn kò sì ní bá wọn wí. Kódà, èmi ti gbọ́dọ̀ wà lórí ibùsùn mi lásìkò tí àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń jáde lọ!

“Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ kíláàsì mi bá ti sọ ohun tí wọ́n ṣe lópin ọ̀sẹ̀, wọ́n á wá béèrè ohun tí èmi náà ṣe. Kí sì ni mo ṣe? Mo lọ sí ìpàdé. Mo sì tún lọ sóde ẹ̀rí. Ó máa ń ṣe mi bíi pé, mò ń pàdánù àkókò tó yẹ kí n fi gbádùn ara mi. Ohun tí mo sábà máa ń sọ fún wọn ni pé mi ò ṣe nǹkan kan. Wọ́n á wá béèrè pé kí ló dé tí mi ò kúkú fi bá àwọn jáde.

“Bí ọjọ́ Monday bá ti kọjá, èrò mi ni pé ẹjọ́ ti tán nìyẹn, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ o. Tó bá fi máa di ọjọ́ Tuesday, gbogbo wọn tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí wọ́n máa ṣe ní òpin ọ̀sẹ̀! Ńṣe ni mo kàn máa ń jókòó tí màá máa wo ẹnu wọn. Ó máa ń ṣe mí bíi pé tèmi nìkan ló dá yàtọ̀.”

ṢÉ OHUN kan náà ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ ní gbogbo ọjọ́ Monday nílé ìwé? Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ìgbádùn wà níta, àmọ́ àwọn òbí ẹ kì í jẹ́ kó o gbádùn ara rẹ. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi ìgbà tó o wà níbi ìgbafẹ́ kan, àmọ́ wọn ò fún ẹ láǹfààní láti fi àwọn nǹkan tó wà níbẹ̀ ṣeré. Kì í kúkú ṣe pé gbogbo nǹkan táwọn ojúgbà rẹ ń ṣe nìwọ náà ń fẹ́ ṣe, ó kàn jẹ́ pé ó wù ẹ́ láti máa gbádùn ara rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, kí ni wàá fẹ́ ṣe láti gbádùn ara rẹ lópin ọ̀sẹ̀ yìí?

◯ ijó

◯ agbo ijó àti orin

◯ fíìmù

◯ àríyá

◯ nǹkan míì ․․․․․

Ó yẹ kó o máa ṣe eré ìtura. (Oníwàásù 3:1, 4) Kódà Ẹlẹ́dàá rẹ fẹ́ kó o gbádùn ìgbà ọ̀dọ́ rẹ. (Oníwàásù 11:9) Àwọn òbí rẹ náà fẹ́ kó o gbádùn ara rẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì o lè máa wò ó pé wọn ò fẹ́ kó o gbádùn ara ẹ. Àmọ́, ohun méjì kan wà tó ṣeé ṣe kó máa jẹ àwọn òbí rẹ lọ́kàn: àkọ́kọ́ ohun tó o máa ṣe àti èkejì àwọn tẹ́ ẹ jọ máa lọ.

Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé àwọn kan ní kó o jẹ́ kẹ́ ẹ jọ jáde, àmọ́ tí o kò mọ ohun tí àwọn òbí rẹ máa sọ ńkọ́? Tí ìpinnu kan bá wà tó o fẹ́ ṣe, Bíbélì gbà ẹ́ níyànjú pé kó o gbé àwọn àbá tó o ní yẹ̀ wò, èyí tó dáa àti èyí tí kò dáa, kó o sì ronú nípa ohun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ. (Diutarónómì 32:29; Òwe 7:6-23) Kí lo lè ṣe nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá sọ pé kẹ́ ẹ jọ jáde?

OHUN ÀKỌ́KỌ́: MÁ SỌ FÚN ẸNIKẸ́NI, ṢÁÀ KÀN LỌ NÍ TÌẸ.

Ìdí tó o fi lè gbé èyí yẹ̀ wò: O fẹ́ wú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lórí kó o lè fi hàn wọ́n pé o ní òmìnira. Ó fi hàn pé o mọ̀ ju àwọn òbí rẹ lọ, tàbí pé o ò ka èrò wọn sí pàtàkì.—Òwe 15:5.

Ohun tó lè tẹ̀yìn ẹ̀ yọ: Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ á rí i pé, o lè tan àwọn náà jẹ. Ohun tó mú kó o lè tan àwọn òbí rẹ jẹ, á jẹ́ pé o lè tan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ jẹ náà nìyẹn. Tí àwọn òbí rẹ bá wá mọ̀, ó máa dùn wọ́n gan-an, wọ́n á sì gbà pé o ti já àwọn kulẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n má ṣe máa fún ẹ láyè bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Ìwà òpònú ló máa jẹ́ tó o bá ṣàìgbọràn sáwọn òbí ẹ, tó o sì ń jáde bó ṣe wù ẹ́ láì dágbére fún wọn.—Òwe 12:15.

OHUN KEJÌ: O Ò SỌ FÚN ẸNIKẸ́NI—O Ò SÌ LỌ.

Ìdí tó o fi lè gbé èyí yẹ̀ wò: O ronú nípa ìkésíni náà, o sì pinnu pé ohun tí wọ́n máa ṣe níbẹ̀ kò bá ìlànà tó ò ń tẹ̀ lé mu, tàbí pé àwọn kan lára àwọn tó máa wà níbẹ̀ lè jẹ́ ẹgbẹ́ búburú. (1 Kọ́ríńtì 15:33; Fílípì 4:8) Lọ́wọ́ kejì, ó lè wù ẹ́ láti lọ, àmọ́ ẹ̀rù ń bà ẹ́ láti sọ fún àwọn òbí ẹ.

Ohun tó lè tẹ̀yìn ẹ̀ yọ: Tí o kò bá lọ torí o mọ̀ pé kò tọ́ láti lọ, wàá lè fi ìgboyà sọ ìdí tí o kò fi wá fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Àmọ́ tó bá jẹ́ torí pé ẹ̀rù ń bà ẹ́ láti sọ fún àwọn òbí ẹ ni kò jẹ́ kó o lọ, ó lè jẹ́ pé ńṣe lo kàn máa kárí sọ sílé, tí wàá máa ronú pé ìwọ nìkan lo kì í gbádùn ara ẹ.

OHUN KẸTA: SỌ FÚN ÀWỌN ÒBÍ Ẹ, KÓ O SÌ GBỌ́ OHUN TÍ WỌ́N MÁA SỌ.

Ìdí tó o fi lè gbé èyí yẹ̀ wò: O gbà pé àwọn òbí ẹ láṣẹ lórí ẹ, o sì máa ń fojú tó tọ́ wo èrò wọn. (Kólósè 3:20) O nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí ẹ, o ò sì fẹ́ ṣe ohun tó máa dùn wọ́n nípa yíyọ́ jáde láìsọ fún wọn. (Òwe 10:1) O tún láǹfààní láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún wọn.

Ohun tó lè tẹ̀yìn ẹ̀ yọ: Àwọn òbí rẹ á mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn, o sì bọ̀wọ̀ fún àwọn. Tí wọ́n bá sì rí i pé ohun tó mọ́gbọ́n dání lo béèrè fún, wọ́n lè jẹ́ kó o lọ.

Ohun Tó Lè Mú Kí Àwọn Òbí Rẹ Sọ Pé Kí O Má Ṣe Lọ

Bí àwọn òbí rẹ kò bá wá jẹ́ kó o lọ ńkọ́? Ìyẹn lè dùn ẹ́ gan-an. Àmọ́, tó o bá mọ ìdí tí wọ́n fi ní kí o má ṣe lọ, kò ní jẹ́ kí ohun tí wọ́n sọ dùn ẹ́ kọjá bó ṣe yẹ. Bí àpẹẹrẹ, wọn lè sọ pé kó o má lọ nítorí ọkàn lára àwọn ìdí tá a kọ síbí yìí, tàbí kó ju ẹyọ kan lọ.

Wọ́n ní ìmọ̀ àti ìrírí jù ẹ́ lọ. Ká sọ pé o fẹ́ lọ lúwẹ̀ẹ́ ní odò kan, ó dájú pé odò tí wọ́n ti ní àwọn òmùwẹ̀ tó máa ń yọ ẹni tó bá rì sínú omi ni wàá fẹ́ lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé tó o bá wà nínú omi tó o sì ń ṣeré, o lè má mọ̀ nígbà tí ewu bá ń bọ̀. Àmọ́, ńṣe làwọn òmùwẹ̀ tó máa ń yọ àwọn tó bá rì sómi máa wà lórí òkè téńté kan, níbi tí wọ́n ti lè tètè rí i tí jàǹbá bá fẹ́ ṣẹlẹ̀.

Bákan náà lọ̀rọ̀ àwọn òbí rẹ ṣe rí, torí pé ìmọ̀ àti ìrírí tí àwọn òbí rẹ ní ju tìẹ lọ, wọ́n lè rí àwọn ewu kan tí ìwọ kò rí. Bíi ti àwọn òmùwẹ̀ tó wà ní odò yẹn, kì í ṣe pé àwọn òbí rẹ kò fẹ́ kó o gbádùn ara rẹ. Wọn ò kàn fẹ́ kó o kó sí wàhálà tó lè mú kó o má ṣe gbádùn ìgbésí ayé rẹ ni.

Wọ́n fẹ́ràn ẹ. Ó wu àwọn òbí ẹ gan-an pé kí wọ́n dáàbò bò ẹ́. Ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ẹ́ ló máa ń jẹ́ kí wọ́n gbà ẹ́ láyè láti ṣe àwọn nǹkan kan, ìfẹ́ yìí kan náà sì ló mú kí wọ́n má ṣe gbà ẹ́ láyè láti ṣe àwọn míì. Tó o bá sọ fún wọn pé o fẹ́ ṣe nǹkan kan, wọ́n máa ń bi ara wọn pé, táwọn bá gbà pé kó o ṣe nǹkan náà, ṣé àwọn lè fàyà rán ohun tó bá tẹ̀yìn ẹ̀ yọ? Ẹ̀yìn ìgbà tí wọ́n bá rò ó dáadáa tí wọ́n sì rí i pé jàǹbá kankan ò ní ṣẹlẹ̀ sí ẹ ni ọkàn wọn á tó balẹ̀ láti sọ pé kó o ṣe nǹkan náà.

Bí ọ̀rọ̀ rẹ kò bá yé wọn. Àwọn òbí tó fẹ́ràn ọmọ máa ń fẹ́ kíyè sára gidigidi. Bí ohun tó o béèrè lọ́wọ́ wọn kò bá yé wọn, tàbí tí wọ́n rí i pé àwọn nǹkan pàtàkì ṣì wà tí o kò sọ fún wọn, wọ́n lè má gbà ẹ́ láyè láti lọ.

Àwọn Nǹkan Tó O Lè Ṣe Tó O Bá Fẹ́ Kí Wọ́n Máa Fún Ẹ Láyè

Àwọn nǹkan mẹ́rin kan wà tó o lè ṣe.

Máa sọ òótọ́: Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó yẹ kó o bá ara ẹ sòótọ́ ọ̀rọ̀. Bi ara rẹ pé: ‘Kí nìdí tí mo fi fẹ́ lọ gan-an? Ṣé ohun tí mo máa ń gbádùn ni wọ́n fẹ́ ṣe níbẹ̀ àbí torí káwọn ọ̀rẹ́ mi lè gba tèmi ni mo ṣe fẹ́ lọ? Ṣé torí pé ẹnì kan tí mo gba tiẹ̀ máa wà níbẹ̀ ni mo ṣe fẹ́ lọ?’ Lẹ́yìn náà, máa sọ òótọ́ fún àwọn òbí rẹ. Àwọn náà ti ṣe ọmọdé rí, wọ́n sì mọ̀ ẹ́ dáadáa. Torí náà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n mọ ohun tó o fẹ́ ṣe gan-an. Inú wọn á dùn sí ẹ tó o bá sọ òótọ́ fún wọn, ìwọ náà á sì jàǹfààní látinú ọgbọ́n wọn. (Òwe 7:1, 2) Àmọ́, tó o bá ń parọ́ fún wọn, wọ́n ò ní fọkàn tán ẹ mọ́, kò sì dájú pé wọ́n á fún ẹ láyè.

Mọ ìgbà tó yẹ kó o lọ tọrọ àyè: Má ṣe máa lọ yọ àwọn òbí rẹ lẹ́nu pé kí wọ́n fún ẹ láyè nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ibiṣẹ́ dé tàbí nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó àwọn ọ̀ràn kan. Ìgbà tí ara wọn bá balẹ̀ ni kó o lọ bá wọn. Àmọ́ ṣá o, má ṣe dúró dìgbà tí ohun tó o fẹ́ ṣe bá ti sún mọ́ tán tí wàá sì máa wá yọ wọ́n lẹ́nu pé kí wọ́n tètè dá ẹ lóhùn. Àwọn òbí ẹ kò ní fẹ́ ṣe ìpinnu pàjáwìrì. Àwọn òbí rẹ máa mọrírì ẹ gan-an tí o kò bá jẹ́ kó pẹ́ jù kó o tó tọrọ àyè.

Mọ ohun tó o fẹ́ sọ: Má ṣe fọ̀rọ̀ pa mọ́ fún wọn. Sọ ohun tó o fẹ́ ṣe gan-an fún wọn. Àwọn òbí kì í fẹ́ gbọ́ káwọn ọmọ wọn sọ pé, “Mi ò mọ̀,” nígbà tí wọ́n bá bi ọmọ láwọn ìbéèrè bíi: “Àwọn wo lẹ jọ ń lọ?” “Ṣé àgbàlagbà kan máa wà níbẹ̀?” tàbí “Ìgbà wo lẹ máa ṣe tán?”

Ìwà rẹ: Má ṣe sọ àwọn òbí rẹ di ọ̀tá. Máa wò wọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀. Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tá a sì ti sọ yìí, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ lẹ jọ jẹ́ lóòótọ́. Tó o bá wo àwọn òbí ẹ gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀, o ò ní máa ta kò wọ́n, àwọn náà á sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ. Bí wọ́n kò bá gbà ẹ́ láyé, ńṣe ni kó o fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ìdí tí wọ́n fi ní kó o má ṣe lọ. Bí àpẹẹrẹ, bí wọ́n bá ní kó o má lọ ságbo orin àti ijó kan, ńṣe ni kó o gbìyànjú láti mọ ìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀. Ṣé wọn ò gba ti olórin yẹn ni? ṣé wọn ò gba ti ibi tí wọ́n ti fẹ́ ṣeré yẹn ni? ṣé wọn ò gba táwọn tẹ́ ẹ jọ fẹ́ wà níbẹ̀ ni? àbí wọ́n wò ó pé owó ìwọlé yẹn ti pọ̀ jù? Má ṣe máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ bíi, “Ẹ ò fọkàn tán mi,” “Gbogbo èèyàn ló ń lọ,” tàbí “àwọn òbí àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń jẹ́ kí wọ́n lọ!” Jẹ́ kí àwọn òbí ẹ mọ̀ pé o ti dàgbà tó láti fara mọ́ ìpinnu àwọn àti pé o ò fojú yẹpẹrẹ wo ìpinnu náà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa fọ̀wọ̀ rẹ wọ̀ ẹ́. Tó bá di ìgbà míì, wọ́n á wá bí wọ́n á ṣe jẹ́ kó o lọ síbi tó o bá fẹ́ lọ.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ náà pa dà.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

“Àwọn òbí mi fọkàn tán mi, torí pé mo máa ń sọ ibi tí mo lọ fún wọn. Mi ò kì í fi àwọn ọ̀rẹ́ mi pa mọ́ fún wọn. Ẹ̀rù kì í sì í bà mí láti kúrò níbi àpèjẹ kan tí mo bá kíyè sí i pé ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ kò bá mi lára mu.”

[Àwòrán]

Kimberly

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]

O Ò ṢE BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÒBÍ RẸ?

Ṣé o fẹ́ mọ èrò àwọn òbí rẹ nípa àwọn ohun tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí? Ọ̀nà kan ṣoṣo tó o lè gbà mọ èrò wọn ni pé kó o béèrè lọ́wọ́ wọn! Ní àkókò tó tọ́, béèrè lọ́wọ́ wọn ohun tí wọ́n rò nípa jíjẹ́ kó o gbádùn ara rẹ. Ronú nípa àwọn ìbéèrè tó o máa fẹ́ béèrè lọ́wọ́ wọn, kó o sì kọ ọ́ síbí.

․․․․․

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Bíi ti àwọn òmùwẹ̀ tó máa ń yọ ẹni tó bá rì sínú omi, àwọn òbí rẹ wà ní ipò tí wọ́n ti lè rí ewu kí wọ́n sì kìlọ̀ fún ẹ nípa rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́