ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 10/15 ojú ìwé 3-4
  • Ìbẹ̀rù—Ọ̀rẹ́ Ni Tàbí Ọ̀tá?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbẹ̀rù—Ọ̀rẹ́ Ni Tàbí Ọ̀tá?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Jèhófà Wà Ní Ọkàn Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Kíkọ́ Láti Rí Ìgbádùn Nínú Ìbẹ̀rù Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Bẹ̀rù Jèhófà, Kí o Sì Pa Àwọn Àṣẹ Rẹ̀ Mọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ẹ Bẹru Jehofa Ki Ẹ Sì Fi Ogo Fun Orukọ Mímọ́ rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 10/15 ojú ìwé 3-4

Ìbẹ̀rù—Ọ̀rẹ́ Ni Tàbí Ọ̀tá?

“Mo ronú nípa bí mo ṣe fẹ́ láti kú. Èmi kò fẹ́ kí a yìnbọn pa mí, ṣùgbọ́n bí yóò bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, mo fẹ́ kí a yìnbọn fún mi ní orí, níbí yìí gan-an, kí n baà lè kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”

AKỌ̀RÒYÌN kan fún ìwé ìròyìn Los Angeles Times gbọ́ èyí láti ẹnú ọmọbìnrin ọlọ́dún 14 kan. Ó ń fọ̀rọ̀ wá àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lẹ́nu wo nípa ìpànìyàn àìpẹ́ yìí—àwọn ọ̀dọ́ tí ń pa àwọn àgbàlagbà àti àwọn ọ̀dọ́ mìíràn. Àkọlé ìròyìn náà ni: “Ayé Ìbẹ̀rù.”

Ó dájú pé o mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ń gbé nínú ayé ìbẹ̀rù. Ìbẹ̀rù kí ni? Yóò ṣòro láti tọ́ka sí ìbẹ̀rù kan ní pàtó. Wo inú àpótí tí ó wà ní òdì kejì, bóyá o lè rí àwọn ohun tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàbí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ládùúgbò rẹ ń bẹ̀rù. Àpótí náà wá láti inú ìwé ìròyìn Newsweek ti November 22, 1993, ó sì fi èsì ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ti a ṣe fún “758 àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ láti ọdún 10 sí 17, papọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí wọn hàn.”

Bí a bá fọ̀rọ̀ wá àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí lẹ́nu wò nísinsìnyí, wọ́n lè sọ àwọn àfikún ìdí fún ìbẹ̀rù, irú bí ìmìtìtì ilẹ̀. Lẹ́yìn ìjábá ìmìtìtì ilẹ̀ ti Los Angeles ní January 1994, ìwé ìròyìn Time ròyìn pé: “Lára àwọn àmì àrùn ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ lẹ́yìn ìdààmú mánigbàgbé ni àwọn ìrántí òjijì tí a kò lè ṣàkóso, àlá adẹ́rùbani, wíwà lójúfò lọ́nà tí ó ré kọjá àlà, àti ìbínú pé ẹnì kan kò lágbára lórí ìwàláàyè ti ara rẹ̀.” Oníṣòwò kan tí ó ti pinnu láti ṣí kúrò ní àgbègbè náà sọ pé: “Kékeré ni ti àdánù náà. Ìbẹ̀rù ni nǹkan. O ń wọ bàtà sùn nísàlẹ̀ ilé. O kò lè sùn. O kan ń jókòó síbẹ̀, tí o sì ń retí rẹ̀ ní gbogbo òru. Ó burú.”

“Ìtòtẹ̀léra Ìjábá Ń Mú Àwọn Ará Japan Gbọ̀n Rìrì” ni àkọlé tí a fún ìròyìn kan láti Tokyo, ní April 11, 1995. Ó sọ pé: “Afẹ́fẹ́ ogun bíburú tí ń kọluni . . . jẹ́ ohun tí ó burú gan tí ó ṣẹlẹ̀ sí èrò inú àwọn ará Japan nítorí ó wá gẹ́gẹ́ bí ìtòtẹ̀léra àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó para pọ̀ fa ìpilẹ̀ àwọn àìdánilójú kan nípa ọjọ́ iwájú. . . . Ọkàn àwọn ènìyàn kò balẹ̀ mọ́ ní àwọn òpópónà tí ó ti fìgbà kan rí lókìkí fún ààbò lọ́sàn-án tàbí lóru.” Kì í sì í ṣe àwọn àgbàlagbà nìkan ni ń bẹ̀rù. “Ọ̀jọ̀gbọ́n Ishikawa [ti Seijo University] sọ pé àníyàn náà . . . wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́, àwọn tí wọn kò fìgbà gbogbo mọ bí ọjọ́ ọ̀la yóò ti rí fún wọn ní kedere.”

Ẹ̀rí fi hàn pé “àpẹẹrẹ ẹ̀rù tí ó boni mọ́lẹ̀ lè da ìṣètò ọpọlọ rú, kí ó sì mú kí àwọn ènìyàn túbọ̀ mọ ìlọsókè omi ìsúnniṣe adrenaline lára, àní ní àwọn ẹ̀wádún lẹ́yìn náà pàápàá.” Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ń gbìyànjú láti mọ bí ọpọlọ ṣe ń lóye ipò bíbani lẹ́rù—bí a ti ń ṣe ìdíyelé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, tí a sì ń hùwà padà pẹ̀lú ìbẹ̀rù. Ọ̀jọ̀gbọ́n Joseph LeDoux kọ̀wé pé: “Nípa ṣíṣàwárí àwọn ipa ọ̀nà ètò ìgbékalẹ̀ iṣan ìmọ̀lára, nípasẹ̀ èyí tí ipò kan ń mú kí ẹ̀dá kan kọ́ láti bẹ̀rù, a nírètí láti ṣàlàyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nípa ìṣiṣẹ́ irú ọ̀nà ìrántí yìí ní gbogbogbòò.”

Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa ni kò nífẹ̀ẹ́ tó bẹ́ẹ̀ sí ìpìlẹ̀ kẹ́míkà tàbí ti ètò ìgbékalẹ̀ iṣan ìmọ̀lára fún ìbẹ̀rù. Ní tòótọ́, a lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè bí, Èé ṣe tí a fi ń bẹ̀rù? Báwo ni ó ṣe yẹ kí a hùwà padà? Ìbẹ̀rù èyíkéyìí ha dára bí?

O ṣeé ṣe kí o gbà pé nígbà mìíràn, ìbẹ̀rù lè ràn ọ́ lọ́wọ́. Fún àpẹẹrẹ, ká ní òkùnkùn ti ṣú, bí o ti ń sún mọ́ ilé rẹ. Ilẹ̀kùn ṣí sílẹ̀ díẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o tì í gbọn-ingbọn-in nígbà tí o ń lọ. Láti ojú fèrèsé, ó dà bí pé o ń rí àwọn òjìji tí ń rìn. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, o bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n rìrì, o ń ronú pé ohun kan ti ṣẹlẹ̀. Bóyá olè tàbí òfinràn kan tí ó yọ ọ̀bẹ lọ́wọ́, ni ó wà nínú ilé.

Ìbẹ̀rù onítẹ̀sí ìwà àdánidá tí o ní fún irú ipò bẹ́ẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti má ṣe kù fìrì wọ inú ipò tí ó léwu. Ìbẹ̀rù lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣọ́ra tàbí wá ìrànlọ́wọ́ ṣáájú kí o tó dojú kọ ipò tí ó ṣeé ṣe kí ó léwu. Irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ pọ̀ jáǹtìrẹrẹ: àmì kan tí ń rán ọ létí pé iná tí ó lè pani wà; ìkéde orí redio kan tí ń sọ nípa ìgbì tí ń yára fẹ́ bọ̀ ní àgbègbè rẹ; ariwo kan tí ń hanni létí nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ bí o ti ń wakọ̀ lọ ní ojú ọ̀nà kan tí ó dí fọ́fọ́.

Dájúdájú, ní àwọn àkókò mìíràn ìmọ̀lára ewu lè ṣe wá láǹfààní. Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti dáàbò bo ara wa tàbí láti hùwà lọ́nà ọlọgbọ́n. Bí ó ti wù kí ó rí, o mọ̀ dáradára pé, ní tòótọ́, ìbẹ̀rù ìgbà gbogbo tàbí èyí tí ó jinlẹ̀ gan-an kì í ṣe ọ̀rẹ́. Ó jẹ́ ọ̀tá. Ó lè mú kí a má lè mí délẹ̀, kí ọkàn wa máa lù kìkì, kí a kúsára, kí a máa gbọ̀n rìrì, kí ẹ̀dọ̀ máa rinni, àti ìmọ̀lára dídi ẹni tí a ṣá tì kúrò ní àdúgbò ẹni.

Ó lè dùn mọ́ ọ nínú púpọ̀ pé Bibeli sọ ní pàtó pé, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bíbanilẹ́rù lórí ilẹ̀ ayé àti ìbẹ̀rù gíga ni a óò fi mọ àkókò wa yàtọ̀. Báwo ni ìyẹn ṣe rí bẹ́ẹ̀, báwo ni ó sì ṣe yẹ kí ó nípa lórí ìgbésí ayé rẹ àti bí o ṣe ń ronú? Bákan náà, èé ṣe ti a fi lè sọ pé lójú ìwòye Bibeli, ìbẹ̀rù ojoojúmọ́ kan wà ní pàtàkì, tí ń ṣèrànwọ́, tí ó sì dára? Jẹ́ kí a wò ó ná.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]

Nígbà tí a bi wọ́n nípa ohun tí ó kan àwọn àti ìdílé wọn jù lọ, àti àgbà àti ọmọdé sọ pé àwọn ń bẹ̀rù:

ÀWỌN ỌMỌ ÀWỌN ÒBÍ

56% Kí ìwà ọ̀daràn oníwà ipá ṣẹlẹ̀ sí mẹ́ḿbà ìdílé 73%

53% Kí àgbàlagbà pàdánù iṣẹ́ 60%

43% Kí agbára wọn máà ká oúnjẹ 47%

51% Kí agbára máà ká àti san owó dókítà 61%

47% Kí agbára wọn máà ká àti san owó ilé 50%

38% Kí mẹ́ḿbà ìdílé ní ìṣòro oògùn 57%

38% Kí ìdílé wọn máà lè wà papọ̀ 33%

Orísun ìròyìn: Newsweek, November 22, 1993

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́