Dídé Ọ̀dọ̀ Onírúurú Ènìyàn ní Ateni Òde Òní
NÍGBÀ tí aposteli Paulu ṣèbẹ̀wò sí Ateni ní nǹkan bíi 50 C.E., ìlú ńlá náà ṣì jẹ́ ojúkò pàtàkì fún káràkátà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò gbádùn ògo rẹ̀ àtijọ́ tí ó kàmàmà mọ́. Ìtàn iṣẹ́ ọnà kan sọ pé: “[Ateni] ń bá a lọ láti máa jẹ́ olú ìlú fún ilẹ̀ Griki nípa tẹ̀mí àti ti ọgbọ́n ọnà, bákan náà sì ni ó jẹ́ ibi tí àwọn ọ̀mọ̀wé àti àwọn alágbára ènìyàn ní sànmánì náà ń nífẹ̀ẹ́ ọkàn sí láti bẹ̀ wò.”
Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Paulu ti ní àǹfààní láti wàásù fún àwọn Júù, àwọn abọ̀rìṣà ará Ateni, àti àwọn ènìyàn láti oríṣiríṣi ibi. Ní ti pé ó jẹ́ akíkanjú olùkọ́, tí ó sì já fáfá, ó sọ nínú ìjíròrò kan pé Ọlọrun fún “gbogbo ènìyàn ní ìyè ati èémí,” pé “lati ara ọkùnrin kan ni ó . . . ti ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè awọn ènìyàn,” àti pé “kí gbogbo wọn níbi gbogbo ronúpìwàdà” nítorí pé Òun yóò ṣèdájọ́ “ilẹ̀-ayé tí à ń gbé.”—Ìṣe 17:25-31.
Àgbègbè Ìpínlẹ̀ Yíyàtọ̀ Síra
Ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí, Ateni tún ti di ìlú ńlá kan tí ń fa àwọn ènìyàn láti ibi gbogbo mọ́ra. Àwọn aṣojú orílẹ̀-èdè àti lọ́gàálọ́gàá nínú iṣẹ́ ológun ti dé gẹ́gẹ́ bí apá kan àwọn tí a rán wá láti ilẹ̀ òkèèrè. Àwọn ọ̀dọ́ láti Africa àti Middle East ń gbé níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì. Àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ṣí wá láti Africa, Asia, àti àwọn orílẹ̀-èdè Eastern Europe ti rọ́ wọlé. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Philippines àti àwọn mìíràn láti Gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn Asia, tí wọ́n wá láti ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ wà níbẹ̀. Ìrọ́wọlé àwọn olùwá-ibi-ìsádi nígbà gbogbo láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i ká àti àwọn ibi tí wàhálà tí ń ṣẹlẹ̀ ní àgbáyé wà pẹ̀lú.
Ipò yìí mú ìpèníjà wá fún àwọn oníwàásù ìhìn rere Ìjọba ní àdúgbò. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àtìpó ní ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, ṣùgbọ́n àwọn kan ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn nìkan. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń ṣojú fún ìpò àtilẹ̀wá ti àṣà ìbílẹ̀ àti ìsìn yíyàtọ̀ síra. Lára àwọn àlejò náà, o lè rí àwọn Kristian aláfẹnujẹ́, àwọn Musulumi, onísìn Hindu, Buddha, onímọlẹ̀, àwọn onígbàgbọ́ Ọlọrun kò ṣeé mọ̀, àti àwọn aláìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní láti kọ́ láti mú kí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn bá onírúurú ipò àtilẹ̀wá àwọn ènìyàn wọ̀nyí mu.
Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹni tuntun wọ̀nyí ti la àwọn àkókò tí ó ṣòro kọjá, wọ́n sábà máa ń ní ìbéèrè nípa ìtumọ̀ ìgbésí ayé àti ìfojúsọ́nà fún ọjọ́ ọ̀la. Àwọn kan gbé Bibeli lárugẹ gan-an, kò sì ṣòro fún wọn láti tẹ́wọ́ gba ohun tí ó sọ. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tí wọ́n wà ní àgbègbè yìí jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ọlọ́kàn tútù, ebi tẹ̀mí sì ń pa wọ́n. Ó rọrùn fún wọn láti wá òtítọ́ kiri nítorí pé wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn sí àwọn ìdílé àti àyíká ilé wọn.
A dá ìjọ àkọ́kọ́ tí ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì sílẹ̀ ní Ateni ní 1986 láti máa kárí àgbègbè ìpínlẹ̀ yìí. Ìbísí náà pinmirin. Láàárín ọdún márùn-ún tí ó kọjá, nǹkan bí 80 àwọn ẹni tuntun ni a ti batisí. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé a ti da ìjọ tí ń sọ èdè Lárúbáwá, ìjọ tí ń sọ èdè Polish, àti àwùjọ tí ń sọ èdè French sílẹ̀, fún sáà kan ní Ateni. Àwọn kan láti ìjọ tí ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ṣí lọ láti ran irú àwọn ìjọ àti àwùjọ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ ní àríwá Tessalonika, ní Heraklion, Krete, àti ní Piraeus, ní etíkun Ateni. Ìwọ yóò ha fẹ́ láti rí àwọn kan lára àwọn àjèjì tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní Ateni bí?
Àwọn Ohun Fífani Lọ́kàn Mọ́ra ti Orílẹ̀-Èdè Ń Jáde Wá
A bí Thomas ní Asmara, Eritrea, ó sì dàgbà di onífọkànsìn onísìn Katoliki. Nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún 15, ó lọ sí ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé. Ó béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn olórí ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìsìn pé: “Báwo ni ó ti ṣeé ṣe pé kí Ọlọrun kan jẹ́ Ọlọrun mẹ́ta?” Olórí ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìsìn náà dáhùn pé: “Nítorí pé a ń tẹ́wọ́ gba ohun tí póòpù sọ nípa àwọn ohun tẹ̀mí. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àdììtú ni èyí, o sì ti kéré jù láti lóye rẹ̀.” Lẹ́yìn tí ó lo ọdún márùn-ún ní ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé, Thomas kúrò níbẹ̀, pẹ̀lú ìwà àti ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì tí ó ti mú un rẹ̀wẹ̀sì, tí ó sì já a kulẹ̀. Síbẹ̀, kò tí ì jáwọ́ nínú wíwá Ọlọrun tòótọ́ kiri.
Ní ọjọ́ kan, kété lẹ́yìn tí ó ṣí lọ sí Ateni, ó rí ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà kan ní ẹnu ọ̀nà rẹ̀, tí àkọlé ẹ̀yìn ìwé náà wí pé “Ìlera àti Ayọ̀ Lè Jẹ́ Tìrẹ.” Ó kà á ní àkàtúnkà. Nínú ìwé ìròyìn kan náà, ó rí i kà pé a ní láti wá Ìjọba Ọlọrun àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́ ná. (Matteu 6:33) Thomas kúnlẹ̀ ó sì bẹ Ọlọrun pé kí ó fi bí òun yóò ti ṣe èyí hàn òun, ó sì ṣèlérí pé: “Bí o bá fi bí èmi yóò ti wá Ìjọba rẹ hàn mí, èmi yóò ya oṣù mẹ́fà nínú ìgbésí ayé mi sọ́tọ̀ láti kọ́ láti sìn ọ́.” Ọ̀sẹ̀ mẹ́rin lẹ́yìn náà, àwọn Ẹlẹ́rìí méjì kan ilẹ̀kùn rẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Thomas tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ó sì ṣe batisí ní oṣù mẹ́wàá lẹ́yìn náà. Ó sọ pé: “Jehofa dáhùn ìbéèrè mi ní ti gidi, ó sì fún mi ní àǹfààní láti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀. Nísinsìnyí ìfẹ́ rẹ̀ ń sún mi láti wá Ìjọba rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé mi.”
Nígbà tí wọ́n ń wàásù láti ilé dé ilé, àwọn Ẹlẹ́rìí méjì mìíràn rí orúkọ kan tí ó ṣàjèjì ní ẹ̀gbẹ́ aago ẹnu ọ̀nà kan.
Ohùn obìnrin kan ń dáhùn lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ láti inú ilé wá pé: “Kí ni ẹ ń wá?”
Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà wí pé àwọn ń gbìyànjú láti wá àwọn tí wọ́n ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí Bibeli.
Obìnrin náà béèrè pé: “Ìsìn wo ni tiyín?”
“Ẹlẹ́rìí Jehofa ni wá.”
“Kò burú! Ẹ gun òkè pátápátá wá.”
Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, bí ẹ̀rọ agbéniròkè sì ti ṣí, ọkùnrin kan tí ó sín gbọnlẹ̀, tí ó sì ní ìṣarasíhùwà tí kò bára dé dúró níbẹ̀. Ṣùgbọ́n obìnrin náà sọ̀rọ̀ láti inú ilé wá.
“Jẹ́ kí wọ́n wọlé. Mo fẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀.”
Obìnrin náà sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí náà pé, òun ń bá ẹgbẹ́ eléré ìdárayá ọkọ òun rìnrìn àjò yíká ayé, àti pé lánàá òde yìí, ni òun ṣì ń gbàdúrà láti bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pàdé. Nítorí náà, a bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lójú ẹsẹ̀. Níwọ̀n bí ọjọ́ tí wọn yóò lò ní ilẹ̀ Griki kò ti tó nǹkan, wọ́n ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta láàárín ọ̀sẹ̀, wọ́n sì parí ìwé Walaaye láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá péré.
Sáà eré ìdárayá mìíràn gbé wọn wá sí ilẹ̀ Griki. Ìyàwó náà tún bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ó sì tẹ̀ síwájú dáradára. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, ó dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí nínú iṣẹ́ wíwàásù gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tí ì batisí, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀ àkọ́kọ́. Pẹ̀lú ta ni? Pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, ẹni tí àwọn Ẹlẹ́rìí náà àti ìyípadà tí ó rí nínú ìyàwó rẹ̀ wú lórí.
Allan, tí ó jẹ́ ọmọ pásítọ̀ Protestanti kan, dàgbà ní South Africa. Láti kékeré, ó ní ìdánilójú pé Bibeli jẹ́ ìṣípayá tí Ọlọrun mí sí. Nítorí pé ìsìn rẹ̀ kò tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó yíjú sí ọgbọ́n èrò orí àti ìṣèlú, ṣùgbọ́n èyí mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ jẹ́ aláìnítumọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Lẹ́yìn tí ó ṣí lọ sí Greece, ìgbésí ayé aláìnítumọ̀ rẹ̀ túbọ̀ ń burú sí i. Ó nímọ̀lára pé ìgbésí ayé òun kò ní ète, pé òun wà ní ojú ọ̀nà tí kò forílé ibikíbi.
Ní alẹ́ ọjọ́ kan, ohun kan ṣẹlẹ̀. Allan ròyìn pé: “Mo kúnlẹ̀, mo sì ṣí ọkàn mi payá fún Ọlọrun. Pẹ̀lú omijé ìbànújẹ́ nítorí ipa ọ̀nà ìgbésí ayé mi, mo bẹ Ọlọrun láti darí mi sọ́dọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́. Mo ṣèlérí pé èmi yóò rìn nínú ìmọ́lẹ̀ ìtọ́sọ́nà rẹ̀.” Láàárín ọ̀sẹ̀ náà, ó lọ sí ilé ìtajà kan, ó sì kó wọnú ìjíròrò pẹ̀lú obìnrin tí ó ni ilé ìtajà náà, ẹni tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Ìjíròrò náà jẹ́ ohun tí ó yí ìgbésí ayé Allan padà ní ti gidi. “Ní àwọn ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, mo rí i pé èrò ìgbàgbọ́ mi tí mo fọkàn ṣìkẹ́ pòórá: Mẹ́talọ́kan, iná ọ̀run àpáàdì, àìleèkú ọkàn—ó hàn kedere pé gbogbo wọn kì í ṣe ẹ̀kọ́ Bibeli.” Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan yọ̀ọ̀da láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ̀. Ó fara mọ́ ọn, ó sì tẹ̀ síwájú kíákíá. Allan rántí pé: “Òtítọ́ mú mi sunkún ayọ̀, ó sì tú mi sílẹ̀ lómìnira.” A batisí rẹ̀ ní ọdún kan lẹ́yìn náà. Lónìí, ó láyọ̀ láti máa ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ọ̀kan nínú ìjọ àdúgbò.
Elizabeth wá láti Nigeria, níbi tí ó ti wá Ọlọrun kiri ní onírúurú ṣọ́ọ̀ṣì, ṣùgbọ́n tí kò tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ohun tí ó bà á lẹ́rù jù lọ ni ẹ̀kọ́ nípa ìdálóró ayérayé nínú iná ọ̀run àpáàdì. Nígbà tí ó dé sí Ateni pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí méjì wá sí ilé rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Elizabeth láyọ̀ láti mọ̀ pé Ọlọrun kì í dá ènìyàn lóró, ṣùgbọ́n pé ó pèsè ìrètí fún ìyè ayérayé nínú paradise orí ilẹ̀ ayé. Ó lóyún ọmọ rẹ̀ kẹrin, tí ó fẹ́ láti ṣẹ́. Lẹ́yìn náà ni ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ojú ìwòye Jehofa lórí ìjẹ́mímọ́ ìwàláàyè láti inú Bibeli. Nísinsìnyí ó ní ọmọbìnrin rirẹwà kan. Elizabeth tẹ̀ síwájú kíákíá, ó sì ṣe batisí láìpẹ́. Bí ó tilẹ̀ ní ọmọ mẹ́rin, tí ó sì ní iṣẹ́ alákòókò kíkún, ó ṣeé ṣe fún un láti máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní oṣooṣù. A ti bù kún un ní ti pé ọkọ rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ó sọ pé: “Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, mo rí Ọlọrun tòótọ́ àti ìjọsìn tòótọ́, ọpẹ́ ni fún Jehofa àti ètò ajọ rẹ̀ onífẹ̀ẹ́.”
Ọ̀pọ̀ lára àwọn ènìyàn ní àgbègbè ìpínlẹ̀ yíyàtọ̀ síra yìí ni a ń bá pàdé nínú iṣẹ́ ìwàásù òpópónà, ṣùgbọ́n ó ń béèrè ìforítì láti lè mú ọkàn-ìfẹ́ wọn dàgbà. Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní ti ọ̀dọ́bìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sallay, láti Sierra Leone. Ẹlẹ́rìí kan fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú kan, ó gba àdírẹ́sì rẹ̀, ó sì ṣètò láti padà lọ bẹ̀ ẹ́ wò. Sallay ní ọkàn-ìfẹ́ sí i, ó sì tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ṣùgbọ́n nítorí ìkìmọ́lẹ̀ iṣẹ́ àti àwọn ìṣòro mìíràn, wọn kò ṣe é déédéé. Lẹ́yìn náà, ó kó kúrò níbẹ̀ lójijì láìfi àdírẹ́sì rẹ̀ tuntun sílẹ̀. Ẹlẹ́rìí náà forí tì í ní lílọ sí àdírẹ́sì rẹ̀ àtijọ́, àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Sallay ránṣẹ́ sí Ẹlẹ́rìí náà láti wá sí ilé rẹ̀ tuntun.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ náà wá túbọ̀ ń lọ déédéé sí i, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sallay ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bímọ. Lẹ́yìn tí ó bímọ tán, Sallay di akéde tí kò tí ì batisí. Ó lè dà bí pé gbogbo èyí rọrùn, ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ní agogo 6:30 òwúrọ̀, ó ti ní láti ṣe tán fún ìrìn àjò ọlọ́gbọ̀n ìṣẹ́jú nínú bọ́ọ̀sì láti mú ọmọ rẹ̀ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ jẹ́lé-ó-sinmi, lẹ́yìn náà ni yóò rìnrìn àjò fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú mìíràn nínú bọ́ọ̀sì lọ sí ibi iṣẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ṣíṣe iṣẹ́ tí ó gbà, ti mímú nǹkan wà ní tónítóní, yóò tún rìnrìn àjò padà lọ sí ilé rẹ̀. Ní àwọn ìrọ̀lẹ́ tí ìpàdé bá wà, tàbí nígbà tí ó bá lọ fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ó máa ń rìnrìn àjò oníwákàtí kan mìíràn ní àlọ àti àbọ̀, láìka àtakò ọkọ rẹ̀ sí. Bí ó ti ń fi ìfẹ́ àti sùúrù hàn sí i, ó tẹ̀ síwájú dé orí ìyàsímímọ́ àti batisí. Ọkọ rẹ̀ ń kọ́? Ó wá sí ibi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi ó sì tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.
A Bù Kún Wọn Pẹ̀lú Ìyọrísí Àtàtà
Fún ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí, gbígbé ní Ateni jẹ́ fún ìgbà díẹ̀. Ọ̀pọ̀ padà sí orílẹ̀-èdè wọn láti lọ ṣàjọpín ìhìn rere pẹ̀lú àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́. Àwọn mìíràn ṣí lọ sí àwọn oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé, wọ́n sì ń bá a lọ láti máa ṣiṣẹ́ sin Jehofa. Àwọn wọnnì tí wọ́n dúró sí Griki gbádùn ìyọrísí rere ti wíwàásù fún àwọn ará abúlé wọn, tí àwọn pẹ̀lú ṣí wá sí ibẹ̀. Ní àwọn ìgbà mìíràn, èso òtítọ́ náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn kìkì lẹ́yìn tí àwọn àlejò náà bá ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, tí wọ́n sì bá àwọn Ẹlẹ́rìí pàdé.
Gbogbo èyí fi hàn pé Jehofa kì í ṣe ojúsàájú. Ó ń tẹ́wọ́ gba àwọn ènìyàn tí wọ́n bá bẹ̀rù rẹ̀, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ òdodo, láti inú onírúurú orílẹ̀-èdè. (Ìṣe 10:34‚ 35) Fún irú àwọn ẹni bí àgùntàn bẹ́ẹ̀, ṣíṣí tí wọ́n ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn nítorí àǹfààní ti ara ti yọrí sí àwọn ìbùkún gíga ju ohun tí wọ́n retí lọ—ìmọ̀ nípa Ọlọrun òtítọ́ náà, Jehofa, àti ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun òdodo. Bẹ́ẹ̀ ni, Jehofa ti bù kún ìsapá láti dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ń sọ èdè àjèjì ní Ateni ode òní ní ti gidi ní jìngbìnnì!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ń gbọ́ ìhìn rere náà ní Ateni