Ìwọ́ Ha Rántí Bí?
Ìwọ́ ha ti fara balẹ̀ ronú nípa àwọn ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti lọ́ọ́lọ́ọ́ bí? O lè rí i pé ó runi lọ́kàn sókè láti rántí àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:
◻ Báwo ni ẹnì kan ṣe ‘ń wá sọ́dọ̀ Jesu’ ní ìbámu pẹ̀lú ìkésíni rẹ̀ nínú Matteu 11:28?
Jesu sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀ kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Matteu 16:24) Nígbà náà, láti wá sọ́dọ̀ Jesu túmọ̀ sí jíjuwọ́ sílẹ̀ kí ìfẹ́ inú ẹni bá ìfẹ́ inú Ọlọrun àti Kristi mu, títẹ́wọ́gba àwọn ẹrù iṣẹ́ kan àti bíbá a lọ ní ṣíṣe wọ́n.—8/15, ojú ìwé 17.
◻ Èé ṣe tí ó fi jẹ́ “díẹ̀” ní ń rí ‘ojú ọ̀nà híhá tí ó lọ sí ìyè’ tí Jesu mẹ́nu kàn nínú Matteu 7:13, 14?
Àwọn òfin àti ìlànà Ọlọrun ń pààlà sí ojú ọ̀nà tóóró náà. Nítorí náà, kìkì ẹni tí ó bá fi tọkàntọkàn ní ìfẹ́ ọkàn láti mú ìgbésí ayé rẹ̀ bá àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọrun mu ni yóò wù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó dà bí ohun tí ó káni lọ́wọ́ kò, ‘ojú ọ̀nà híhá’ náà ń tú ẹnì kan sílẹ̀ lómìnira nínú gbogbo ohun ṣíṣe pàtàkì. “Òfin pípé naa tí í ṣe ti òmìnira” ni a fi pààlà rẹ̀. (Jakọbu 1:25)—9/1, ojú ìwé 5.
◻ Báwo ni a ṣe lè mú ìfòyemọ̀ dàgbà?
Ìfòyemọ̀ kì í déédéé wá tàbí kí ó wá lọ́nà àdánidá. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú sùúrù, àdúrà, ìsapá aláápọn, ìkẹ́gbẹ́pọ̀ ọlọgbọ́n, ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò lórí Bibeli, àti ìgbáralé ẹ̀mí mímọ́ Jehofa, a lè mú ìfòyemọ̀ dàgbà.—9/1, ojú ìwé 21.
◻ Báwo ni owú ẹ̀dá ènìyàn ṣe lè mú ohun dídára jáde?
Ó lè sún ẹnì kan láti dáàbò bo ẹnì kan tí ó fẹ́ràn kúrò lọ́wọ́ ipa ìdarí búburú. Ní àfikún sí i, àwọn ẹ̀dá ènìyàn lè fi owú tí ó tọ́ hàn fún Jehofa àti ìjọsìn rẹ̀. (1 Awọn Ọba 19:10)—9/15, ojú ìwé 8, 9.
◻ Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Genesisi 50:23 (NW) nípa àwọn ọmọ-ọmọ Josefu pé: “A bí wọn lórí eékún Josefu”?
Èyí lè wulẹ̀ túmọ̀ sí pé Josefu tẹ́wọ́ gba àwọn ọmọ náà gẹ́gẹ́ bí ìrandíran rẹ̀. Ó tún lè tọ́ka sí pé ó bá àwọn ọmọ náà ṣeré pẹ̀lú ìfẹ́ni, tí ó ń gbé wọn jó lórí eékún rẹ̀. Àwọn bàbá lónìí yóò ṣe dáradára, bí wọ́n bá fi irú ìfẹ́ni kan náà hàn sí àwọn ọmọ wọn.—9/15, ojú ìwé 20, 21.
◻ Kí ni ó ṣe pàtàkì gidigidi fún àṣeyọrí ìgbéyàwó àti ìgbésí ayé ìdílé?
Láti lè rí àbájáde tí ó dára bẹ́ẹ̀, tọkọtaya gbọ́dọ̀ fi Ọlọrun ṣáájú nígbà gbogbo. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, tọkọtaya ń gbìyànjú láti wà pa pọ̀, kí wọ́n sì yanjú àwọn ìṣòro wọn nípa fífi ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílò. Wọ́n tipa báyìí yẹra fún gbogbo ìrora ọkàn tí ó máa ń jẹyọ nígbà tí a bá pa ìfẹ́ inú Ọlọrun tì. (Orin Dafidi 19:7-11)—10/1, ojú ìwé 11.
◻ Báwo ni òye ìjẹ́kánjúkánjú oníwà-bí-Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó lónìí?
Òye ìjẹ́kánjúkánjú oníwà-bí-Ọlọ́run jẹ́ apá kan pàtàkì iṣẹ́ ìsìn wa tọkàntọkàn sí Jehofa. Ó ń bi àwọn ìgbìdánwò Èṣù láti mú kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ‘ṣàárẹ̀, kí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn wọn’ wó, ó sì ń ké àwọn ìgbìdánwò Èṣù nígbèrí. (Heberu 12:3) Ó ń dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ kíkówọnú àjọṣepọ̀ tí kò nídìí pẹ̀lú ayé àti ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì rẹ̀, tí ó sì ń mú kí wọ́n pọkàn pọ̀ sí àwọn ohun ti òkè—“ìyè tòótọ́.” (1 Timoteu 6:19)—10/1, ojú ìwé 28.
◻ Nínú òwe àkàwé àgùtàn àti ewúrẹ́, nígbà wo ni Jesu jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, èé sì ti ṣe? (Matteu 25:31-33)
Òwe àkàwé náà kò fi í hàn pé ó ń jókòó ní ọ̀nà ti dídi Ọba. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jókòó gẹ́gẹ́ bí Adájọ́. Ìdájọ́ náà kì í ṣe ohun tí yóò wà fún sáà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Dípò bẹ́ẹ̀, àkàwé náà tọ́ka sí ọjọ́ iwájú nígbà tí Jesu yóò kéde, tí yóò sì múdàájọ́ ṣẹ lórí àwọn orílẹ̀ èdè ní àkókò kúkúrú.—10/15, ojú ìwé 22, 23.
◻ Kí ni “ìran” tí Jesu tọ́ka sí léraléra?
Jesu lo ọ̀rọ̀ náà “ìran yìí” fún àwọn gbáàtúù alájọgbáyé pẹ̀lú àwọn “afọ́jú afinimọ̀nà” wọn, tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ orílẹ̀ èdè Júù. (Matteu 11:16; 15:14; 24:34)—11/1, ojú ìwé 14.
◻ Nínú ìmúṣẹ ìkẹyìn ti àsọtẹ́lẹ̀ Jesu nínú Matteu 24:34-39, kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìran yìí” tọ́ka sí?
Ó dájú pé Jesu ń tọ́ka sí àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n rí àmì wíwàníhìn-ín Kristi, ṣùgbọ́n tí wọ́n kùnà láti yí àwọn ọ̀nà wọn padà.—11/1, ojú ìwé 19, 31.
◻ Báwo ni ètò àwọn ìlú ààbò àti àwọn ìkálọ́wọ́kò wọn ṣe ṣàǹfààní fún àwọn ènìyàn Israeli ìgbàanì?
Ó tẹ̀ ẹ́ mọ́ àwọn ọmọ Israeli lọ́kàn pé wọn kò ní láti ṣàìbìkítà, tàbí dágunlá nípa ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn. Ó tún tẹnu mọ́ ọn pé a ní láti fi àánú hàn nígbà tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ bá pọn dandan. (Jakọbu 2:13)—11/15, ojú ìwé 14.
◻ Kí ni ìlú ààbò ìṣàpẹẹrẹ náà?
Èyí ni ìpèsè Ọlọrun fún dídáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ikú fún títàpá sí àṣẹ rẹ̀ nípa ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀. (Genesisi 9:6)—11/15, ojú ìwé 17.
◻ Báwo ni ìfẹ́ ẹgbẹ́ ará Kristian ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ‘tún agbára ṣe’? (Isaiah 40:31)
Láàárín àwọn Kristian arákùnrin àti arábìnrin wa, àwọn kan wà tí wọ́n lè máa dojú kọ ìkìmọ́lẹ̀ àti ìdánwò tí ó fara jọ tiwa, tí wọ́n sì lè máa nírìírí ìmọ̀lára bí i tiwa gẹ́lẹ́. (1 Peteru 5:9) Ó ń fọkàn balẹ̀, ó sì ń fún ìgbàgbọ́ lókun láti mọ̀ pé ohun tí a ń dojú kọ kò ṣàjèjì, àti pé ìmọ̀lára wa kì í ṣe ohun tí ojú kò rí rí.—12/1, ojú ìwé 15, 16.