Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Inú wá dùn láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àkàwé Jésù nípa àgùntàn àti ewúrẹ́. Pẹ̀lú ìlàlóye tuntun tí a gbé kalẹ̀ nínú “Ilé-Ìṣọ́nà” October 15, 1995, ǹjẹ́ a ṣì lè sọ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ lónìí bí?
Bẹ́ẹ̀ ni. Gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, ọ̀pọ̀ ti ronú nípa èyí nítorí Mátíù 25:31, 32 sọ pé: “Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà ni òun yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a óò sì kó jọ níwájú rẹ̀, òun yóò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́.” Ilé-Ìṣọ́nà ti October 15, 1995, fi ìdí tí ó fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀ ni àwọn ẹsẹ wọ̀nyí yóò ní ìmúṣẹ hàn. Jésù yóò dé nínú ògo rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀, yóò sì jókòó sórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀. Nígbà náà, yóò ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀. Lọ́nà wo? Òun yóò gbé ìdájọ́ rẹ̀ karí ohun tí àwọn ènìyàn ṣe tàbí tí wọ́n kùnà láti ṣe ṣáájú àkókò yẹn.
A lè fi èyí wé àwọn sáà ìgbẹ́jọ́, tí ń ṣamọ̀nà sí ìdájọ́ nílé ẹjọ́. Ẹ̀rí yóò gbára jọ fún sáà gígùn kan, kí ilé ẹjọ́ tó ṣèdájọ́, kí ó sì tó sọ ìyà tí a óò fi jẹni. Ẹ̀rí bóyá àwọn ènìyàn tí ó wà láàyè nísinsìnyí yóò di àgùntàn tàbí ewúrẹ́ ti ń gbára jọ fún àkókò pípẹ́. Àwọn ẹ̀rí mìíràn ṣì ń wọlé wá. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù bá jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, ẹjọ́ náà yóò parí. Òun yóò ti ṣe tán láti ṣèdájọ́. A óò ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ yálà fún ìkékúrò àìnípẹ̀kun tàbí fún ìyè àìnípẹ̀kun.
Ṣùgbọ́n, òtítọ́ náà pé ìyàsọ́tọ̀ àwọn ènìyàn sí ìyè tàbí sí ikú, tí a mẹ́nu kàn nínú Mátíù 25:32, ṣì jẹ́ ní ọjọ́ iwájú kò túmọ̀ sí pé, iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ tàbí ìpínyà kankan kò ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn. Bíbélì, nínú Mátíù orí 13, mẹ́nu kan iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ kan tí ó ṣẹlẹ̀ ṣáájú. Ó dùn mọ́ni nínú pé ìwé Isopọṣọkan ninu Ijọsin Ọlọrun Tootọ Kanṣoṣo Naa ṣàlàyé èyí ní ojú ìwé 179 sí 180, lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Iyasọtọ Awọn Eniyan”.a Ìwé náà sọ pé: “Àwọn iṣẹlẹ pataki miiran tún wà tí Jesu sopọ ní kedere mọ́ ipari-opin eto-igbekalẹ awọn nkan. Ọ̀kan lara iwọnyi ni iyasọtọ awọn ‘ọmọ ijọba’ kuro lara ‘awọn ọmọ ẹni buburu nì.’ Jesu sọrọ nipa eyi ninu òwe-àkàwé rẹ̀ nipa pápá-oko alikama kan tí ọ̀tá kan dà èpò sinu rẹ̀.”
Ìwé yẹn ń tọ́ka sí àkàwé Jésù tí a kọ sínú Mátíù 13:24-30, tí a sì ṣàlàyé ní ẹsẹ 36-43. Kíyè si ní ẹsẹ 38 pé, èso àtàtà ti àlìkámà dúró fún àwọn ọmọ Ìjọba náà, ṣùgbọ́n èpò náà dúró fún àwọn ọmọ ẹni búburú náà. Ẹsẹ 39 àti 40 fi hàn pé, ní ‘ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan’—ní àkókò tí a ń gbé nísinsìnyí—a kó àwọn èpò jọ. A yà wọ́n sọ́tọ̀, a sì finá sun wọ́n, a sì jó wọn run ráúráú nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
Àkàwé náà ní í ṣe pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró (àwọn tí a pè ní arákùnrin Jésù nínú àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́). Síbẹ̀, kókó náà ṣe kedere pé, ìyàsọ́tọ̀ pàtàkì kan ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wa, ní yíya àwọn ẹni àmì òróró sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tí wọ́n sọ pé Kristẹni ni àwọn, ṣùgbọ́n tí wọ́n fẹ̀rí hàn pé “ọmọ ẹni búburú náà” ni àwọn ń ṣe.
Jésù pèsè àwọn àpẹẹrẹ mìíràn nípa àwọn ènìyàn tí a pín níyà, tàbí yà sọ́tọ̀. Rántí pé, ó sọ nípa ojú ọ̀nà gbígbòòrò tí ó lọ sí ìparun pé: ‘Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ẹni tí ń gbà á wọlé.’ (Mátíù 7:13) Ìyẹn kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa àbájáde ìkẹyìn lásán. Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ohun kan tí ń lọ lọ́wọ́, bí ó ti jẹ́ òtítọ́ nísinsìnyí nípa ìwọ̀nba àwọn díẹ̀ tí ń rí ojú ọ̀nà híhá tí ó lọ sínú ìyè. Rántí pẹ̀lú pé, nígbà tí ó ń rán àwọn àpọ́sítélì jáde, Jésù sọ pé wọn yóò rí àwọn kan tí yóò jẹ́ ẹni yíyẹ. Àwọn mìíràn kì yóò jẹ́ ẹni yíyẹ, àwọn àpọ́sítélì sì ní láti gbọn ekuru ẹsẹ̀ wọn dà nù “fún ẹ̀rí lòdì sí” irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 9:5) Kì í ha ń ṣe òtítọ́ pé ohun kan náà ń ṣẹlẹ̀ bí àwọn Kristẹni ṣe ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìtagbangba wọn lọ lónìí bí? Àwọn kan ń dáhùn pa dà lọ́nà rere, nígbà tí àwọn mìíràn ń kọ ìhìn iṣẹ́ àtọ̀runwá tí a ń mú wá fún wọn.
Àwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé-Ìṣọ́nà tí ó sọ nípa àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ sọ pé: “Bí ìdájọ́ náà tí a ṣàpèjúwe nínú òwe àkàwé tilẹ̀ ṣì wà ní ọjọ́ ọ̀la tí kò jìnnà mọ́, àní nísinsìnyí pàápàá, ohun pàtàkì kan ń ṣẹlẹ̀. Àwa Kristẹni ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà kan ti pípolongo ìhìn iṣẹ́ kan tí ń fa ìyapa láàárín àwọn ènìyàn. (Mátíù 10:32-39).” Nínú àyọkà yẹn nínú Mátíù orí 10, a kà pé Jésù sọ pé, títẹ̀ lé òun yóò fa ìyapa—bàbá sí ọmọkùnrin rẹ̀, ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀.
Lákòótán, àwọn arákùnrin Kristi tí a fi ẹ̀mí yàn ti ṣe agbátẹrù wíwàásù ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kárí ayé. Bí àwọn ènìyàn ṣe ń gbọ́ ọ, tí wọ́n sì ń dáhùn pa dà, yálà lọ́nà tí ó dára tàbí lọ́nà tí kò dára, wọ́n ń fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ hàn. Àwa ènìyàn kò lè sọ pé, ‘Àgùntàn ni lágbájá; ewúrẹ́ ni làkáṣègbè,’ lọ́nà tí Mátíù orí 25 gbà lò ó, a kò sì gbọ́dọ̀ sọ bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, sísọ ìhìn rere fún àwọn ènìyàn ń fún wọn láǹfààní láti fi ibi tí wọ́n dúró sí hàn—irú ènìyàn tí wọ́n jẹ́ àti bí wọ́n ṣe ń hùwà sí àwọn arákùnrin Jésù. Nítorí náà, ìyàsọ́tọ̀ àwọn tí wọ́n ti àwọn arákùnrin Jésù lẹ́yìn àti àwọn tí ó kọ̀ láti tì wọ́n lẹ́yìn ń di ohun tí ń ṣe kedere síwájú àti síwájú sí i, bí ẹ̀rí tí ń gbára jọ fún ìdájọ́ nílé ẹjọ́. (Málákì 3:18) Gẹ́gẹ́ bí Ilé-Ìṣọ́nà ti fi hàn, láìpẹ́, Jésù yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, yóò sì ṣèdájọ́, lọ́nà àṣekágbá, a óò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ sí ìyè tàbí sí ìkékúrò.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde ní 1987.