Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Àwọn Ọ̀tá Tẹ́lẹ̀ Rí Pa Pọ̀ Ṣọ̀kan Ninu Ṣíṣiṣẹ́ Sin Jehofa
BRANKO ṣàlàyé pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ tí n óò gbọ́ ohunkóhun nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ nígbà tí mo ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun ẹ̀ṣọ́ ní Bosnia.”a
Branko wà lẹ́nu iṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ní ilé ìwòsàn ti a tí ń tọ́jú àwọn tí wọ́n fara pa. Ọ̀kan lára àwọn dókítà náà ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí, ní ìgbà kan tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ alẹ́, ó ṣàlàyé púpọ̀ lára ohun tí ó ti kọ́ nípa Bibeli fún Branko.
Ohun tí Branko gbọ́ ní alẹ́ ọjọ́ náà nípa lórí rẹ̀ débi pé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni o fi àwọn ohun ìjà rẹ̀ sílẹ̀. Ó kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí, ó fẹ́ láti mọ̀ sí i. Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn ṣíṣí lọ sí orílẹ̀-èdè míràn ni Europe, Branko wá Gbọ̀ngàn Ìjọba rí, ó sì pàdé pọ̀ pẹ̀lú ìjọ Yugoslavia ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Níbẹ̀ ni Branko ti pàdé Slobodan.
Slobodan pẹ̀lú wá láti Bosnia, ó sì ti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí olùyọ̀ọ̀da ara ẹni nínú ogun kan náà gẹ́gẹ́ bí Branko ti ṣe—ṣùgbọ́n ní ìhà kejì. Slobodan jà fún àwọn Serb lòdì sí àwọn Croat. Nígbà tí àwọn méjèèjì pàdé, Slobodan ti di Ẹlẹ́rìí tí a batisí fún Jehofa. Ó fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ Branko, ọ̀tá rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ti ń tẹ̀ síwájú, Branko mọ̀ sí i nípa Jehofa, ìfẹ́ rẹ̀ fún Ọlọrun sì dàgbà sí i. Èyí sún Branko láti ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Ẹlẹ́dàá. Ní October 1993, ó fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi.
Báwo ni Slobodan ṣe di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa? Ó ti fi ojú ogun ní Bosnia sílẹ̀ ṣáájú. Ó ti ka àwọn ìtẹ̀jáde kan láti ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí, ṣùgbọ́n ìgbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí méjì bẹ̀ ẹ́ wò ní ilé rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1992 ni ìfẹ́ rẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣẹ̀ṣẹ̀ dàgbà. Ta ni ẹni tí ó bẹ Slobodan wo, tí ó fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ̀ ọ́? Mujo ni, tí òun pẹ̀lú wá láti Bosnia, ṣùgbọ́n a tọ́ ọ dàgbà gẹ́gẹ́ bí Mùsùlùmí. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ti ń tẹ̀ síwájú, Mujo àti Slobodan, tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá tẹ́lẹ̀ rí, lo àkókò díẹ̀ pa pọ̀ lójoojúmọ́ láti fún ìgbàgbọ́ ara wọn lẹ́nì kíní kejì lókun.
Ogun tí ó wà ní Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí, ti gba ẹ̀mí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n Branko, Slobodan, àti Mujo ń ṣiṣẹ́ sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí alákòókò kíkún oníwàásù ìhìn rere ní ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan náà. Wọ́n ti borí gbọ́nmi-si-i-omi-ò-tó-o ti ẹ̀yà àti ti ẹ̀yà ìran, wọ́n sì ń wá àlàáfíà nísinsìnyí bí wọ́n ti ń juwọ́ sílẹ̀ fún Ẹlẹ́dàá náà, Jehofa.
Ṣùgbọ́n kí ni ó mú irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ wá? Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jehofa, ọ̀wọ̀ tí wọ́n ní fún Bibeli, àti ìháragàgà wọn láti fi òtítọ́ Bibeli sílò nínú ìgbésí-ayé wọn ni. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ, “ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè ó sì ń sa agbára . . . ó sì lè fi òye mọ ìrònú ati awọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.”—Heberu 4:12.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A lo arúmọlójú orúkọ.