Ìròyìn Ìjọba No. 35
Gbogbo Ènìyàn Yóò Ha Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn Láé Bí?
Ìfẹ́ Fún Aládùúgbò Ti Di Tútù
ÀRÀÁDỌ́TA ọ̀kẹ́ jẹ́ aláì-lólùrànlọ́wọ́ àti aláìláyọ̀, tí wọn kò sì rí ibi yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́. Obìnrin oníṣòwò kan tí ó ti fẹ́yìn tì sọ pé: ‘Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, obìnrin opó kan tí ń gbé ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ kan náà pẹ̀lú mi kanlẹ̀kùn mi, ó sì sọ pé òun kò rẹ́ni bá ṣeré. Mo sọ fún un tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó ṣe tààràtà pé ọwọ́ mi dí. Ó tọrọ àforíjì fún yíyọ mí lẹ́nu, ó sì kúrò lọ́dọ̀ mi.’
Lọ́nà tí ó bani nínú jẹ́, ní alẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an, obìnrin opó náà pa ara rẹ̀. Lẹ́yìnwá èyí, obìnrin oníṣòwò náà sọ pé òun ti kọ́ “ẹ̀kọ́ ńlá gbáà.”
Ṣíṣàìní ìfẹ́ aládùúgbò sábà máa ń yọrí sí ìbànújẹ́. Nígbà ìforígbárí ẹ̀yà ìran ní Bosnia àti Herzegovina, tí ó fìgbà kan rí jẹ́ apá kan Yugoslavia, ó lé ní mílíọ̀nù kan ènìyàn tí a fipá lé kúrò nílé wọn, a sì pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá mẹ́wàá ènìyàn. Láti ọwọ́ àwọn wo? Ọmọdébìnrin kan tí a ti lé kúrò ní abúlé rẹ̀ kérora pé: “Àwọn aládùúgbò wa ni. A kúkú mọ̀ wọ́n.”
Ní Rwanda, a pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn nípakúpa, lọ́pọ̀ ìgbà láti ọwọ́ àwọn aládùúgbò wọn. “Àwọn Hutu àti Tutsi [ń gbé] pa pọ̀, wọ́n ń gbé ara wọn níyàwó, láìbìkítà tàbí láìmọ̀ pé ẹnì kan jẹ́ Hutu tàbí pé ẹnì kan jẹ́ Tutsi pàápàá,” ni ìwé agbéròyìnjáde náà, The New York Times, ròyìn. ‘Lẹ́yìn náà, nǹkankan ṣàdédé ṣẹlẹ̀, tí ìpànìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀.’
Bákan náà, Àwọn Júù àti Arab ní Ísírẹ́lì ń gbé níbì kan náà, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ kórìíra ara wọn. Bákan náà ni ọ̀ràn rí pẹ̀lú ọ̀pọ̀ Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì ní Ireland àti iye àwọn ènìyàn tí ń pọ̀ sí i ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn. Kò tí ì sí ìgbà kankan rí ṣáájú nínú ìtàn tí ayé tí ì ṣàìní ìfẹ́ tó èyí rí.
Èé Ṣe Tí Ìfẹ́ Aládùúgbò Fi Di Tútù?
Ẹlẹ́dàá wa pèsè ìdáhùn náà. Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, pe àkókò tí a ń gbé inú rẹ̀ ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Èyí ni àkókò kan tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wí pé, àwọn ènìyàn yóò jẹ́ “aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” Nípa “àwọn àkókò líle koko tí ó nira lati bá lò” wọ̀nyí, tí a tún pè ní “ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan” nínú Ìwé Mímọ́, Jésù Kristi sọ tẹ́lẹ̀ pé “ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.”—Tímótì Kejì 3:1-5; Mátíù 24:3, 12.
Nítorí náà, àìnífẹ̀ẹ́ tí ń bẹ lónìí jẹ́ apá kan ẹ̀rí pé a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé yìí. Lọ́nà tí ń múni láyọ̀, ó tún túmọ̀ sí pé ayé ti àwọn ènìyàn aláìwà-bí-Ọlọ́run yìí ni a óò fi ayé tuntun òdodo kan tí ìfẹ́ ń ṣàkóso rọ́pò láìpẹ́.—Mátíù 24:3-14; Pétérù Kejì 2:5; 3:7, 13.
Ṣùgbọ́n, a ha ní ìdí ní ti gidi láti gbà gbọ́ pé irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe—pé gbogbo ènìyàn lè kẹ́kọ̀ọ́ láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì máa gbé pa pọ̀ ní àlàáfíà pẹ̀lú ara wọn bí?
Ìfẹ́ Fún Aládùúgbò—Òtítọ́ Gidi
Agbẹjọ́rò kan ní ọ̀rúndún kìíní béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?” Ó dájú pé òun retí pé kí Jésù sọ pé, ‘Àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ rẹ ni.’ Ṣùgbọ́n nínú ìtàn kan nípa aládùúgbò ará Samáríà kan, Jésù fi hàn pé àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ti orílẹ̀-èdè míràn pẹ̀lú jẹ́ aládùúgbò wa.—Lúùkù 10:29-37; Jòhánù 4:7-9.
Jésù tẹnu mọ́ ọn pé, lẹ́yìn ìfẹ́ fún Ọlọ́run, ìfẹ́ fún aládùúgbò ni ó gbọ́dọ̀ ṣàkóso ìgbésí ayé wa. (Mátíù 22:34-40) Ṣùgbọ́n àwùjọ ènìyàn èyíkéyìí ha ti nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wọn rí ní tòótọ́ bí? Àwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe bẹ́ẹ̀! A mọ̀ wọ́n fún ìfẹ́ tí wọ́n ní sí àwọn ẹlòmíràn.—Jòhánù 13:34, 35.
Òde ìwòyí ńkọ́? Ẹnikẹ́ni ha ń fi ìfẹ́ bíi ti Kristi ṣèwàhù bí? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopedia Canadiana, sọ pé: “Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ mímú Ìsìn Kristẹni ìjímìjí tí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe . . . sọ jí, kí wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i . . . Ará ni gbogbo wọn.”
Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò jẹ́ kí ohunkóhun—ì báà jẹ́ ìran, orílẹ̀-èdè, tàbí ipò àtilẹ̀wá ní ti ẹ̀yà ìran—mú wọn kórìíra aládùúgbò wọn. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì yóò pa ẹnikẹ́ni nítorí pé lọ́nà ìṣàpẹ̀ẹrẹ, wọ́n ti fi idà wọn rọ abẹ ohun èlò ìtúlẹ̀, wọ́n sì ti fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. (Aísáyà 2:4, NW) Ní tòótọ́, a mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí fún lílo àtinúdá láti ran àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́.—Gálátíà 6:10.
Abájọ tí ọ̀rọ̀ olótùú kan nínú ìwé agbéròyìnjáde ti California náà, Sacramento Union, fi sọ pé: “Ó tó kí a sọ pé bí gbogbo ayé bá ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìkórìíra yóò dópin, ìfẹ́ yóò sì jọba.” Òǹkọ̀wé kan nínú ìwé ìròyìn Ring, ti Hungary sọ pé: “Mo ti dé ìparí èrò náà pé bí ó bá jẹ́ pé kìkì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, ogun kì yóò wáyé mọ́, dídarí ọkọ̀ àti fífúnni ní ìwé ìrìnnà sì ni kìkì iṣẹ́ tí àwọn ọlọ́pàá ì bá máa ṣe.”
Bí ó ti wù kí ó rí, a gbà pé a óò nílò ìyípadà ńláǹlà kárí ayé bí gbogbo ènìyàn yóò bá fẹ́ràn ara wọn. Báwo ní ìyípadà yẹn yóò ṣe ṣẹlẹ̀? (Jọ̀wọ́ wo ojú ewé tí ó wà lẹ́yìn.)
Ìgbà Tí Gbogbo Ènìyàn Yóò Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn
Àdúrà tí Jésù Kristi fi kọ́ni fi hàn pé ìyípadà amúnijígìrì kan ti sún mọ́lé. Nínú Ìwàásù rẹ̀ olókìkí Lórí Òkè, Jésù kọ́ wa láti gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé; Ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe, bíi ti ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.”—Mátíù 6:10, King James Version.
Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Ó jẹ́ ìjọba gidi kan, ọ̀kan tí ń ṣàkóso láti ọ̀run. Ìdí nìyẹn tí a fi pè é ní “ìjọba àwọn ọ̀run.” Jésù, “Ọmọ Aládé Àlàáfíà,” ni Bàbá rẹ̀ ti yàn sípò láti jẹ́ alákòóso rẹ̀.—Mátíù 10:7; Aísáyà 9:6, 7; Orin Dáfídì 72:1-8.
Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ayé tí ó kún fún ìkórìíra yìí? “Ìjọba náà” yóò “fọ́” gbogbo ìjọba oníwà ìbàjẹ́ ti ayé yìí “túútúú, yóò sì fi òpin sí” wọn. (Dáníẹ́lì 2:44, NW) Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ayé ń kọjá lọ . . . ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—Jòhánù Kíní 2:17.
Ní ti ayé tuntun ti Ọlọ́run, Bíbélì wí pé: “Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.” (Orin Dáfídì 37:9-11, 29; Òwe 2:21, 22) Ẹ wo àkókò ológo tí ìyẹn yóò jẹ́! “Ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:4) Àní àwọn ẹni tí ó ti kú pàápàá yóò tún wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i, a óò sì sọ ilẹ̀ ayé lápapọ̀ di párádísè kan ní ti gidi.—Aísáyà 11:6-9; 35:1, 2; Lúùkù 23:43; Ìṣe 24:15.
Láti gbé nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wa, àní bí Ọlọ́run ti kọ́ wa láti ṣe pàápàá. (Tẹsalóníkà Kíní 4:9) Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí ó jẹ́ ará Ìlà Oòrùn sọ pé: “Mo ń wọ̀nà fún àkókò náà nígbà tí, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti ṣèlérí, gbogbo ènìyàn yóò ti kẹ́kọ̀ọ́ láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kíní kejì.” A sì lè ní ìdánilójú pé Ọlọ́run yóò pa ìlérí rẹ̀ mọ́! Ó wí pé: “Èmi ti sọ ọ́, èmi óò sì mú un ṣẹ.”—Aísáyà 46:11.
Ṣùgbọ́n láti gbádùn àwọn ìbùkún lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ gba ìmọ̀ Bíbélì sínú gẹ́gẹ́ bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn aláìlábòsí ọkàn ti ń ṣe kárí ayé. (Jòhánù 17:3) Ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. Gba ẹ̀dà kan nípa kíkọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù tí ó wà ní ojú ewé tí ó ṣáájú, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ilé rẹ jù lọ.
□ Èmi yóò fẹ́ láti gba ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
□ Ẹ jọ̀wọ́ kàn sí mi ní ti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Alúgọtaniníbọn àti ààtò ìsìnkú ní Bosnia: Reuters/Corbis-Bettmann