Kí Ló Ṣẹlẹ̀ sí Ìfẹ́ Aládùúgbò?
ÀRÀÁDỌ́TA ọ̀kẹ́ ènìyàn ni kò lólùrànlọ́wọ́, tí ẹ̀rù ń bà, àní tí wọn kò láyọ̀ páàpáà, tí wọn kò sì rí ibi yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́. Obìnrin kan dárò pé: “Ńṣe ni mo máa ń dá jẹun, tí mo máa ń dá rìn, tí mo máa ń dá sùn, tí mo sì máa ń dá sọ̀rọ̀.” Àwọn díẹ̀ ló ṣe tán láti ṣèrànwọ́, kí wọ́n sì fi ìfẹ́ hàn fún àwọn tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́.
Obìnrin oníṣòwò kan tí ó ti fẹ̀yìn tì sọ pé: ‘Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, obìnrin opó kan tí ń gbé ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ kan náà pẹ̀lú mi kanlẹ̀kùn mi, ó sì sọ pé òun kò rẹ́ni bá ṣeré. Mo sọ fún un tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó ṣe tààràtà, pé ọwọ́ mi dí. Ó tọrọ àforíjì fún yíyọ mí lẹ́nu, ó sì kúrò lọ́dọ̀ mi.’
Obìnrin náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: ‘Inú mi dùn pé n kò jẹ́ kí irú ẹni tí ń fi nǹkan súni bẹ́ẹ̀ dá mi lọ́wọ́ kọ́. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kejì, ọ̀rẹ́ mi kan tẹ̀ mí láago, ó sì béèrè bóyá mo mọ obìnrin tí a jọ ń gbé ilé kan náà tí ó pa ara rẹ̀ ní alẹ́ àná. Bí ẹ kò bá tíì ronú ẹni tó jẹ́, obìnrin tó wá kanlẹ̀kùn mi yẹn ni.’ Lẹ́yìn náà, obìnrin oníṣòwò náà sọ pé òun ti kọ́ “ẹ̀kọ́ ńlá gbáà.”
A mọ̀ dáadáa pé àwọn ọmọ tí a bá fi ìfẹ́ dù lè kú. Àwọn àgbàlagbà pẹ̀lú lè kú bí a kò bá fi ìfẹ́ hàn sí wọn. Arẹwà ọmọbìnrin ọlọ́dún 15 kan, tí ó pa ara rẹ̀, kọ lẹ́tà kan sílẹ̀ pé: “Àìdáwà lorúkọ tí ìfẹ́ ń jẹ́.
Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ Òde Òní
Nígbà tí ìwé ìròyìn Newsweek ń sọ nípa ìkórìíra ìran lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, ó wí pé: “Ó jọ pé ‘kórìíra aládùúgbò rẹ’ ni àkọmọ̀nà ọdún yìí.” Lákòókò tí rògbòdìyàn ń ṣẹlẹ̀ ní Bosnia àti Herzegovina, tí ó wà lára Yugoslavia tẹ́lẹ̀, ó lé ní mílíọ̀nù kan ènìyàn tí a fipá lé kúrò ní ilé wọn, tí a sì pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn. Àwọn wo ló ṣe é? Ọmọdébìnrin kan, tí a lé kúrò ní abúlé rẹ̀, kédàárò pé, “àwọn aládùúgbò wa ni. A mọ̀ wọ́n.”
Obìnrin kan sọ nípa 3,000 Hutu àti Tutsi tí wọ́n ń gbé abúlé Ruganda pé: “A ti máa ń gbé papọ̀ ní àlàáfíà.” Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Ìtàn abúlé yìí ni ìtàn Rwanda: àwọn Hutu àti Tutsi ń gbé papọ̀, wọ́n ń fẹ́ ara wọn, láìfẹ́ mọ̀ tàbí láìmọ ẹni tí ó jẹ́ Hutu àti ẹni tí ó jẹ́ Tutsi. Ohun kan wá ṣẹlẹ̀ lójijì,” lẹ́yìn náà, “ìpànìyàn náà bẹ̀rẹ̀.”
Bákan náà, àwọn Júù àti àwọn Lárúbáwá tí wọ́n wà ní Ísírẹ́lì múlé gbe ara wọn, àmọ́, púpọ̀ wọn ló kórìíra ara wọn. Jálẹ̀ ọ̀rúndún ogún yìí, irú ìṣòro kan náà ń ṣẹlẹ̀ ní Àríwá Ireland, ní Íńdíà àti Pakistan, ní Malaysia àti Indonesia, àti láàárín onírúurú ẹ̀yà tó wà ní United States—bẹ́ẹ̀ ló rí, ó ń ṣẹlẹ̀ jákèjádò ayé tí a ń gbé inú rẹ̀.
A lè máa mẹ́nu kan àpẹẹrẹ oríṣiríṣi ìkórìíra ìran àti ìsìn láìdánu dúró. Ọ̀rọ̀ àìsí ìfẹ́ láyé kò tíì ṣẹlẹ̀ tó báyìí rí nínú ìtàn.
Ta Ló Lẹ̀bi Rẹ̀?
A ń fi ìkórìíra kọ́ni bí ìfẹ́. Orin kan tí ó gbajúmọ̀ sọ pé àwọn ọmọdé ń “gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ kó tó pẹ́ jù/Kí o tó pé ọmọ ọdún mẹ́fà tàbí méje tàbí mẹ́jọ/Láti kórìíra gbogbo ènìyàn tí àwọn ẹbí rẹ kórìíra.” Ní pàtàkì, wọ́n ń fi ìkórìíra kọ́ni lónìí. Pàápàá jù lọ, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ti kùnà láti kọ́ àwọn ọmọ ìjọ láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn.
Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Faransé náà, Le Monde, béèrè pé: “Báwo ni ẹnì kan ṣe lè yẹra fún ríronú pé àwọn míṣọ́nnárì Kristẹni kan náà ni wọ́n kọ́ àwọn Tutsi àti Hutu tí wọ́n ń jagun ní Burundi àti Rwanda lẹ́kọ̀ọ́ àti pé ṣọ́ọ̀ṣì kan náà ni wọ́n ń lọ?” Ní gidi, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn National Catholic Reporter ṣe sọ, Rwanda jẹ́ “orílẹ̀-èdè tí ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún ti jẹ́ Kátólíìkì.”
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, àwọn orílẹ̀-èdè ìhà Ìlà Oòrùn Yúróòpù yíjú sí ètò ìjọba Kọ́múníìsì aláìgbà-pọ́lọ́run-wà. Èé ṣe? Ní 1960, àlùfáà ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìsìn kan ní Prague, Czechoslovakia, sọ pé: “Àwa, àwa Kristẹni nìkan, ni a fa ètò ìjọba Kọ́múníìsì. . . . Rántí pé Kristẹni ni àwọn Kọ́múníìsì nígbà kan. Bí wọn kò bá gbà gbọ́ pé Ọlọ́run olódodo kan wà, ta ló lẹ̀bi?”
Gbé ohun tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ṣe nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní yẹ̀ wò. Ọ̀gágun tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Britain náà, Frank Crozier sọ nípa ogun yẹn pé: “Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni ni aṣáájú lára àwọn agbátẹrù ìtàjẹ̀sílẹ̀ tó wà, a sì ti lò wọ́n fàlàlà.” Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Nígbà kan rí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìgbà gbogbo ni àwọn aláṣẹ Kátólíìkì àdúgbò ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ogun orílẹ̀-èdè wọn, wọ́n ń súre fún àwọn ọmọ ogun, wọ́n sì ń gbàdúrà fún ìṣẹ́gun, nígbà tí ẹgbẹ́ àwọn bíṣọ́ọ̀bù mìíràn, tí wọ́n wà lápá kejì, ń gbàdúrà ní gbangba pé kí ìdà kejì rẹ̀ ṣẹlẹ̀.”
Síbẹ̀, Jésù Kristi fi ìfẹ́ hàn nínú gbogbo ohun tí ó ṣe, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì kọ̀wé pé: “Ọlọ́run ti kọ́ ẹ̀yin fúnra yín láti nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Tẹsalóníkà 4:9) Akọ̀ròyìn kan tí ń ṣiṣẹ́ fún ìwé ìròyìn Sun ti Vancouver sọ pé: “Àwọn Kristẹni tòótọ́ jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin nínú Jésù Kristi. Wọn kò jẹ́ dìídì pa ara wọn lára láé.”
Ó ṣe kedere pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ló lẹ̀bi àìsí ìfẹ́ lóde òní. Àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn India Today sọ pé: “Orúkọ ìsìn ni a fi ń hu ìwà ọ̀daràn bíbanilẹ́rù tí ó pọ̀ jù lọ.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ohun pàtàkì kan ló ń mú kí irú ìwà àìfinipè bíburú jáì bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ nínú ìran wa.
Ìdí Tí Ìfẹ́ Fi Di Tútù
Ẹlẹ́dàá wa dáhùn ìbéèrè náà. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, Bíbélì, pe àkókò tí a ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sọ pé àkókò yìí ni àwọn ènìyàn yóò jẹ́ “aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” Jésù Kristi sọ tẹ́lẹ̀ nípa “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí, tí Ìwé Mímọ́ tún pè ní “ìparí ètò àwọn nǹkan,” pé, “ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.”—2 Tímótì 3:1-5; Mátíù 24:3, 12.
Nítorí náà, àìsí ìfẹ́ tí ó wà lóde òní wà lára ẹ̀rí pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé yìí ni a ń gbé. Ó dùn mọ́ni pé ó tún túmọ̀ sí pé a óò fi ayé tuntun òdodo kan tí ìfẹ́ ti gbilẹ̀ rọ́pò ayé àwọn ènìyàn búburú yìí láìpẹ́.—Mátíù 24:3-14; 2 Pétérù 3:7, 13.
Ṣùgbọ́n, ìdí gidi ha wà fún wa láti gbà gbọ́ pé irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe—pé a óò lè gbé ayé kan nínú èyí tí gbogbo ènìyàn yóò nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọn óò sì máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà bí?