Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ ní Rwanda—Ẹ̀bi Ta Ni?
Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report wí pé: “Ní ìṣẹ́jú díẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tó ṣá agbárí atọ́kọ̀ṣe ẹni ọdún 23 náà gbẹgẹdẹ, ọ̀kan lára àwọn akọluni náà sọ fún Hitiyise pé: ‘O níláti kú nítorí pé o jẹ́ Tutsi.’”
ẸWO bí irú ìran yẹn ṣe ń wáyé léraléra tó ní Rwanda orílẹ̀-èdè kékeré ti Central Africa láàárín àwọn oṣù April àti May! Ní àkókò náà àwọn ìjọ 15 ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni o wà nínú àti ní agbègbè Kigali, olú-ìlú Rwanda. Tutsi ni Ntabana Eugène, alábòójútó ìlú-ńlá náà. Òun, aya rẹ̀, ọmọkùnrin rẹ̀, àti ọmọbìnrin rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́sàn-án, Shami, wà lára àwọn tí a kọ́kọ́ dúḿbú nígbà tí rúkèrúdò ìwà-ipá náà bẹ́ sílẹ̀.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ara Rwanda ni a ń pa lójoojúmọ́—lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ìwé ìròyìn tí a tọ́kasí lókè yìí ròyìn láàárín oṣù May pé: “Ní ọ̀sẹ̀ mẹ́fà tí ó ti kọjá iye àwọn ènìyàn tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 250,000 ti kú nínú ìgbétáásì ìparun-ẹ̀yà àti ìgbẹ̀san tí ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìléjáde onítàjẹ̀sílẹ̀ ti Khmer Rouge tí ó wáyé ní Cambodia ní àárín àwọn ọdún 1970.”
Ìwé ìròyìn Time wí pé: “Nínú ìran kan tí ó farajọ ti Nazi Germany, a ṣa àwọn ọmọdé jáde láti inú àwùjọ bíi 500 kìkì nítorí pé wọ́n jọ Tutsi. . . . Butare olórí ìlú tí ó wà níhà gúúsù, ẹni tí ó fẹ́ Tutsi kan láya, ni àwọn àgbẹ̀ alárojẹ tí wọ́n jẹ́ Hutu fún ní yíyàn kan [tí ó mú ìrora lọ́wọ́]: òun lè gba aya àti àwọn ọmọ rẹ̀ là bí ó bá lè yọ̀ọ̀da ìdílé aya rẹ̀—àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì àti àbúrò rẹ̀ obìnrin—fún pípa. Ó gbà pẹ̀lú wọn.”
Àwọn ènìyàn mẹ́fà ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní Ọ́fíìsì Ìtúmọ̀-Èdè ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Kigali, mẹ́rin lára wọn jẹ́ Hutu méjì sì jẹ́ Tutsi. Ananie Mbanda àti Mukagisagara Denise ni Tutsi tí ń bẹ láàárín wọn. Nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun papọ̀ pẹ̀lú àwọn afipá-gba-dúkìá de inú ilé náà, inú bí wọn láti rí i bí àwọn Hutu àti Tutsi ṣe ń gbé papọ̀. Wọ́n fẹ́ pa Mbanda àti Denise.
Emmanuel Ngirente, ọ̀kan lára àwọn arákùnrin tí ó jẹ́ Hutu wí pé: “Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ irin pẹlẹbẹ kúrò lẹ́nu bọ́m̀bù aláfọwọ́jù wọn, ní híhalẹ̀ pé àwọn yóò pa wá níwọ̀n bí a ti ní àwọn ọ̀tá wọn láàárín wa. . . . Wọ́n ń fẹ́ owó púpọ̀ rẹpẹtẹ. A fún wọn ní gbogbo owó tí a ní lọ́wọ́, síbẹ̀síbẹ̀ kò tẹ́ wọn lọ́rùn. Wọ́n pinnu láti gba gbogbo ohun tí wọ́n bá lè lò lọ́wọ́ wa gẹ́gẹ́ bí ìsanpadà, èyí tí ó ní nínú kọ̀m̀pútà kékeré kan tí a ń lò nínú iṣẹ́ ìtumọ̀ wa, ẹ̀rọ̀ fọtokópíà, àwọn rédíò wa, àwọn bàtà wa, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lójijì wọ́n lọ láìpa ẹnì kankan lára wa, ṣùgbọ́n wọ́n wí pé àwọn yóò padà wa láìpẹ́.”
Ní àwọn ọjọ́ tí ó tẹ̀lé e, àwọn afipá-gba-dúkìá náà bẹ̀rẹ̀ síi pààrà, ní gbogbo ìgbà náà sì ni àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ Hutu máa ń bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀mí àwọn ọ̀rẹ́ wọn tí wọ́n jẹ́ Tutsi. Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, nígbà tí ó wá léwu gidigidi fún Mbanda àti Denise láti máa wà níbẹ̀ nìṣó, a ṣètò fún wọn láti bá àwọn Tutsi mìíràn tí wọ́n jẹ́ olùwá-ibi-ìsádi lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ kan tí ó wà nítòsí. Nígbà tí wọn kọlu ilé-ẹ̀kọ́ náà, ó ṣeé ṣe fún Mbanda àti Denise láti sá. Wọ́n kẹ́sẹjárí nínú kíkọjá ní ọ̀pọ̀ ibi ìṣàyẹ̀wò ọkọ̀, ṣùgbọ́n, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ wọ́n kó gbogbo àwọn Tutsi sí ẹ̀gbẹ́ kan, wọ́n sì pa Mbanda àti Denise.
Nígbà tí àwọn ṣọ́jà náà padà lọ sí Ọ́fíìsì Ìtúmọ̀-Èdè tí wọ́n sì rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ Tutsi náà ti lọ, àwọn ṣọ́jà náà lu àwọn arákùnrin tí wọ́n jẹ́ Hutu náà ní àlùbolẹ̀. Lẹ́yìn náà ni ìbọn dún nítòsí, àwọn arákùnrin náà sì gbìyànjú láti sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.
Bí ìpànìyàn náà ti ń bá a lọ jákèjádò orílẹ̀-èdè náà, iye àwọn tí ó kú fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì million. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, nǹkan bíi million méjì sí mẹ́ta, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, lára àwọn million mẹ́jọ olùgbé Rwanda ni wọ́n fi ilé wọn sílẹ̀. Púpọ̀ lára wọn wá ààbò lọ sí Zaire àti Tanzania tí ó wà nítòsí. Ọgọ́rùn-ún mélòókan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a pa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ mìíràn sì wà lára àwọn wọnnì tí wọ́n sálọ sí àwọn ibùdó lẹ́yìn odi orílẹ̀-èdè náà.
Kí ni ó tanná ran irú ìpakúpa àti ìkójáde tí kò ṣẹlẹ̀ rí bẹ́ẹ̀? Wọ́n ha ti lè dènà rẹ̀ bí? Báwo ni ipò nǹkan ti rí ṣáájú kí rògbòdìyàn náà tó wáyé?
Àwọn Hutu àti Tutsi
Àwọn Hutu tí wọ́n sábà máa ń jẹ́ ènìyàn kúkúrú, tí a mọ̀ sí àwọn Bantu kíkipọ́pọ́, àti àwọn Tutsi, tí wọ́n jẹ́ ènìyàn gíga tí wọ́n sì mọ́ láwọ̀ tí a tún mọ̀ sí Watusi ni wọ́n ń gbé ní Rwanda àti orílẹ̀-èdè Burundi tí ó múlé gbè é. Ní àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì àwọn Hutu kó ìpín 85 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn olùgbé ìlú náà àwọn Tutsi sì kó ìpín 14 nínú ọgọ́rùn-ún. Ìkọlura tí ó wà láàárín àwọn àwùjọ ẹ̀yà yìí ti wà tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn láti nǹkan bí ọ̀rúndún kẹẹ̀dógún. Síbẹ̀, fún apá tí ó pọ̀ jùlọ, wọ́n ti gbé papọ̀ ní àlàáfíà.
Obìnrin kan ẹni ọdún 29 sọ nípa 3,000 àwọn Hutu àti Tutsi tí wọ́n ń gbé ní abúlé Ruganda, tí ó wà ní ibùsọ̀ díẹ̀ ní ìhà ìlà-oòrùn Zaire, pé: “A ti máa ń gbé papọ̀ ní àlàáfíà.” Ṣùgbọ́n, ní April àwọn àjọ-ìpàǹpá onísùnmọ̀mí Hutu fẹ́rẹ̀ẹ́ pa gbogbo àwọn Tutsi tí ń bẹ ní abúlé náà run tan. Ìwé ìròyìn The New York Times ṣàlàyé pé:
“Ìtàn abúlé yìí ni ìtàn Rwanda: àwọn Hutu àti Tutsi tí wọ́n ń gbé papọ̀, ń fẹ́ ara wọn, láìfẹ́ mọ̀ tàbí láì mọ ẹni tí ó jẹ́ Hutu àti ẹni tí ó jẹ́ Tutsi.
“Ohun kan wá ṣẹlẹ̀ lójijì. Ní April, àwọn àwùjọ ènìyànkénìyàn Hutu jákèjádò orílẹ̀-èdè náà dá rúkèrúdò sílẹ̀, ní pípa àwọn Tutsi níbikíbi tí wọ́n bá ti lè rí wọn. Nígbà tí ìpànìyàn náà bẹ̀rẹ̀, àwọn Tutsi sá lọ sí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì fún ààbò. Àwọn àwùjọ ènìyànkénìyàn náà gbá tẹ̀lé wọn, ní sísọ àwọn ibi mímọ́ di itẹ́-òkú tí a fi ẹ̀jẹ̀ bá bálabàla.”
Kí ni ó tanná ran ìpànìyàn yìí? Ikú àwọn ààrẹ Rwanda àti Burundi, nínú jàm̀bá ọkọ òfúúrufú ní Kigali ní April 6, ni ó fà á, Hutu ni àwọn méjèèjì. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lọ́nà kan ṣáá ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìpakúpa kì í ṣe ti àwọn Tutsi nìkan ṣùgbọ́n ti àwọn Hutu èyíkéyìí tí a bá ronú pé wọ́n bá wọn kẹ́dùn pẹ̀lú.
Ní àkókò kan náà, ìjà gbóná síi láàárín àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀—R.P.F. (Rwandan Patriotic Front) tí ó kún fún àwọn Tutsi—àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti Ìjọba ti ó kún fún àwọn Hutu. Nígbà tí ó fi máa di July àwọn R.P.F. ti ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun ti Ìjọba wọ́n sì ti gba àkóso lórí Kigali àti àwọn apá yòókù tí ó pọ̀ jùlọ ní Rwanda. Ní bíbẹ̀rù ìforóyáró, ní ìbẹ̀rẹ̀ July, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Hutu ti sá kúrò ní orílẹ̀-èdè náà.
Ẹ̀bi Ta Ni?
Nígbà tí a béèrè pé kí ó ṣàlàyé ìdí tí rúkèrúdò náà fi wáyé lójijì ní April, àgbẹ̀ kan tí ó jẹ́ Tutsi wí pé: “Àwọn aṣáájú búburú ni wọ́n fà á.”
Níti tòótọ́, la àwọn ọ̀rúndún já, àwọn aṣáájú òṣèlú ti tan irọ́ kálẹ̀ nípa àwọn ọ̀tá wọn. Lábẹ́ ìdarí “olùṣàkóso ayé yii,” Satani Eṣu, àwọn olóṣèlú ayé ti fọgbọ́n darí àwọn ènìyàn wọn láti bá àwọn ẹ̀yà-ìran, ẹ̀yà-èdè, tàbí orílẹ̀-èdè mìíràn jà. (Johannu 12:31, NW; 2 Korinti 4:4; 1 Johannu 5:19) Ipò ọ̀ràn náà kò yàtọ̀ ní Rwanda. Ìwé ìròyìn The New York Times wí pé: “Àwọn olóṣèlú ti gbìyànjú léraléra láti mú ìdúróṣinṣin sí ẹ̀yà-èdè àti ìbẹ̀rù ẹ̀yà-èdè dàgbà—nínú ọ̀ràn ti àwọn Hutu, láti lè máa darí Ìjọba nìṣó; nínú ọ̀ràn ti àwọn Tutsi, láti gbá ìtìlẹ́yìn jọ fún ẹgbẹ́ ọmọ-ogun ọlọ̀tẹ̀.”
Níwọ̀n bí àwọn ará Rwanda ti jọra ní àwọn ọ̀nà púpọ̀, ẹnì kan kò ní retí pé kí wọ́n kórìíra kí wọ́n sì máa pa araawọn. Raymond Bonner tí ó jẹ́ oníròyìn kọ̀wé pé: “Èdè kan náà ni àwọn Hutu àti àwọn Tutsi ń sọ wọ́n sì ní àṣà kan náà ní gbogbogbòò. Lẹ́yìn tí ìran púpọ̀ ti gbé ara wọn níyàwó, àwọn ìyàtọ̀ ti ara-ìyára náà—pé àwọn Tutsi ga tí wọ́n sì tín-ín-rín, àti pé àwọn Hutu kúrú tí wọ́n sì tóbi—ti pòórá títí dé ìwọ̀n tí ó fi jẹ́ pé kò dá àwọn ará Rwanda lójú mọ́ bóyá ẹnì kan jẹ́ Hutu tàbí Tutsi.”
Síbẹ̀, òpòòrò àwọn ìgbékèéyíde ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ti ní ipa ìdarí ti kò ṣeé gbàgbọ́. Ní ṣíṣàpèjúwe ọ̀ràn náà, Alex de Waal, olùṣekòkáárí ẹgbẹ́ African Rights, wí pé: “Ó ya àwọn àgbẹ̀ alárojẹ tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè tí àwọn R.P.F. ti gbà lẹ́nu pé àwọn ṣọ́jà Tutsi kò ní ìwo, ìrù àti ojú tí ń tàn yinrin nínú òkùnkùn—irú ìròyìn tí wọ́n ń gbọ́ lórí rédíò nìyẹn.”
Kì í wulẹ̀ ṣe pé àwọn aṣáájú òṣèlú ń darí ìrònú àwọn ènìyàn nìkan ni ṣùgbọ́n ìsìn ń ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Àwọn ìsìn wo ní pàtàkì ni àwọn ara Rwanda ń ṣe? Wọ́n ha ti jẹ̀bi ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ náà bí?
Ipa Tí Ìsìn Kó
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia (1994) sọ nípa Rwanda pé: “Èyí tí ó pọ̀ jùlọ lára àwọn ènìyàn náà jẹ́ Roman Katoliki. . . . Àwọn Roman Katoliki àti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristian mìíràn ni wọ́n ń darí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ilé-ẹ̀kọ́ gíga.” Níti tòótọ́, ìwé ìròyìn National Catholic Reporter, pe àwọn ará Rwanda ní “orílẹ̀-èdè tí ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún ti jẹ́ Katoliki.”
Ìwé ìròyìn The Observer, ti Great Britain, sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ipò ọ̀ràn ìsìn ní Rwanda, ní ṣíṣàlàyé pé: “Láàárín àwọn ọdún 1930, nígbà tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń jà fún ìdarí ètò-ìgbékalẹ̀ ẹ̀kọ́-ìwé, àwọn Katoliki kọ́wọ́ti ìjọba ọ̀tọ̀kùlú onípò-ọlá ti àwọn Tutsi lẹ́yìn nígbà tí àwọn Protẹstanti lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn Hutu tí a tẹ̀lóríba. Ní 1959 àwọn Hutu gba agbára wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn ìtìlẹ́yìn àwọn Katoliki àti àwọn Protẹstanti lọ́nà tí ó yára kánkán. Ìtìlẹ́yìn àwọn Protẹstanti fún ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn Hutu jẹ́ èyí tí ó túbọ̀ lágbára síi.”
Fún àpẹẹrẹ, àwọn aṣáájú ìsìn Protẹstanti ha ti dẹ́bi fún ìpakúpa náà bí? Ìwé ìròyìn The Observer dáhùn pé: “A béèrè lọ́wọ́ àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì [Anglikan] méjì bóyá wọ́n dẹ́bi fún ìpakúpa àwọn ọmọdé tí a gé lórí tí a sì kó wọn dà sí gbàgede ṣọ́ọ̀ṣì Rwanda.
“Wọ́n kọ̀ láti dáhùn. Wọ́n yẹ àwọn ìbéèrè sílẹ̀, inú bí wọn, ohùn wọn sì ga sókè gan-an, a sì túdìí gbongbo jíjinlẹ̀ ti yánpọnyánrin Rwanda—àwọn mẹ́ḿbà tí wọ́n wà ní ipò gíga nínú ṣọ́ọ̀ṣì Anglikan ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ońṣẹ́ fún àwọn ọ̀gá òṣèlú tí wọ́n ti wàásù ìpànìyàn tí wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ kún inú odò.”
Níti tòótọ́, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm ní Rwanda kò yàtọ̀ sí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ibòmíràn. Fún àpẹẹrẹ, Ọ̀gágun Oníràwọ̀-Kan Frank P. Crozier ọmọ ilẹ̀ Britain sọ nípa ìtìlẹ́yìn wọn fún àwọn aṣáájú òṣèlú nínú Ogun Àgbáyé I pé: “A ní àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Kristian gẹ́gẹ́ bí aṣíwájú lára àwọn tí ó ní ọkàn-ìfẹ́ nínú ìtàjẹ̀sílẹ̀ a sì ti lò wọ́n fàlàlà fún ire ti araawa.”
Bẹ́ẹ̀ni, àwọn aṣáájú ìsìn ni wọ́n jẹ̀bi jùlọ fún ohun tí ó ṣẹlẹ̀! Ìwé ìròyìn The National Catholic Reporter ti June 3, 1994, ròyìn pé: “Ìjà náà ní orílẹ̀-èdè Africa wémọ́ ‘ìpakúpa-ẹ̀yà tí ó jẹ́ gidi àti èyí tí ó jẹ́ òtítọ́, tí ó sì ṣeni láàánú pé, àwọn Katoliki pàápàá ni wọ́n jẹ̀bi rẹ̀,’ ni póòpù wí.’”
Ní kedere, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ti kùnà láti kọ́ni ní ìlànà Kristian tòótọ́, tí a gbékarí àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ bíi Isaiah 2:4 àti Matteu 26:52. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn French náà Le Monde ti wí, àlùfáà kan kédàárò pé: “Wọ́n ń dúḿbú ara wọn, ní gbogbo ìgbà yìí wọ́n gbàgbé pé ará ni wọ́n jẹ́.” Àlùfáà mìíràn tí ó jẹ́ ará Rwanda jẹ́wọ́ pé: “Àwọn Kristian ti pa Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn, lẹ́yìn ìwàásù lórí ìfẹ́ àti ìdáríjì fún ọgọ́rùn-ún ọdún. Ó ti kùnà.” Ìwé ìròyìn Le Monde béèrè pé: “Báwo ni ẹnì kan ṣe lè yẹra fún ríronú pé àwọn míṣọ́nnárì Kristian kan náà ni wọ́n kọ́ àwọn Tutsi àti Hutu tí wọ́n ń jagun ní Burundi àti Rwanda lẹ́kọ̀ọ́ àti pé ṣọ́ọ̀ṣì kan náà ni wọ́n ń lọ?”
Àwọn Kristian Tòótọ́ Yàtọ̀
Àwọn ọmọlẹ́yìn tòótọ́ ti Jesu Kristi ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ láti ‘nífẹ̀ẹ́ ara wọn ẹnìkínní kejì.’ (Johannu 13:34, NW) Ìwọ ha rò pé Jesu tàbí ọ̀kan lára àwọn aposteli rẹ̀ yóò mú àdá tí yóò sì ṣa ẹnì kan pa? Irú ìpànìyàn lọ́nà àìlófin bẹ́ẹ̀ ń fi àwọn ènìyàn hàn gẹ́gẹ́ bí “awọn ọmọ Èṣù.”—1 Johannu 3:10-12, NW.
Lọ́nà èyíkéyìí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò lọ́wọ́ nínú ogun, ìdìtẹ̀, tàbí ìforígbárí mìíràn tí àwọn òṣèlú ayé tí wọ́n wà lábẹ́ ìdarí Satani Eṣu, ṣe agbátẹrù fún. (Johannu 17:14, 16; 18:36; Ìṣípayá 12:9) Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí araawọn ẹnìkínní kejì. Nípa báyìí, nígbà tí ìpakúpa náà ń lọ lọ́wọ́, àwọn Hutu tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí fi tinú-tinú fi ìwàláàyè wọn wéwu nínú ìsapá wọn láti dáàbòbo àwọn ará wọn tí wọ́n jẹ́ Tutsi.
Síbẹ̀, irú ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ bẹ́ẹ̀ kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jesu nípa “ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan,” ó sọtẹ́lẹ̀ pé: “Awọn ènìyàn . . . yoo sì pa yín.” (Matteu 24:3, 9, NW) Ó dùnmọ́ni pé, Jesu ṣèlérí pé a óò rántí àwọn olóòótọ́ nígbà àjíǹde àwọn òkú.—Johannu 5:28, 29.
Títí di ìsinsìnyí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Rwanda àti ní ibi gbogbo ti pinnu láti máa bá a nìṣó ní fífi arawọn hàn ní ọmọ-ẹ̀yìn Kristi nípa nínífẹ̀ẹ́ araawọn ẹnìkínní kejì. (Johannu 13:35) Ìfẹ́ wọn ń jẹ́rìí àní láàárín àwọn ipò ìnira tí ń lọ lọ́wọ́ wọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí ó tẹ̀lé e “Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Àwọn Ibùdó Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi” ti fihàn. Gbogbo wa níláti rántí ohun tí Jesu sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ pé: “Ẹni tí ó bá faradà á dé òpin ni ẹni tí a óò gbàlà.”—Matteu 24:13, NW.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ NÍ ÀWỌN IBÙDÓ ÀWỌN OLÙWÁ-IBI-ÌSÁDI
Títí di July ọdún yìí, nǹkan bíi 4,700 àwọn Ẹlẹ́rìí àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn wà ní àwọn ibùdó àwọn olùwá-ibi-ìsádi. Ní Zaire, 2,376 wà ní Goma, 454 ní Bukavu, àti 1,592 ní Uvira. Ní àfikún síi, nǹkan bíi 230 wà ní Benaco ní abúlé Tanzania.
Àtidé ibùdó àwọn olùwá-ibi-ìsádi náà kò rọrùn. Ìjọ kan tí ó ní 60 Ẹlẹ́rìí gbìyànjú láti rékọjá afárá Rusumo, ọ̀nà àbáyọ kanṣoṣo sí àwọn ibùdó olùwá-ibi-ìsádi ní Tanzania. Nígbà tí a kò gbà wọ́n láyè láti kọjá, wọ́n ń rìn káàkiri bèbè odò náà fún ọ̀sẹ̀ kan. Lẹ́yìn náà wọn pinnu láti gbìyànjú títu araawọn kọjá nínú ọkọ̀ ọlọ́pọ́n. Wọ́n kẹ́sẹjárí, lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, wọ́n dé ibùdó náà ní Tanzania ní àìséwu.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ṣètò àwọn ìsapá ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà. Àwọn Ẹlẹ́rìí ní France kó ohun tí ó ju ọgọ́rùn-ún tọ́ọ̀nù àwọn aṣọ àti tọ́ọ̀nù mẹ́sàn-án bàtà, wọ́n sì kó irú àwọn ohun-èlò bẹ́ẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú àwọn oúnjẹ amẹ́mìídè àti egbòogi, ránṣẹ́ sí àwọn agbègbè tí wọ́n ti nílò wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun àkọ́kọ́ tí àwọn ará ní àwọn ibùdó àwọn olùwá-ibi-ìsádi máa ń kọ́kọ́ béèrè fún lọ́pọ̀ ìgbà ni Bibeli tàbí ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà tàbí Jí!
Ìfẹ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí fihàn ní Zaire àti Tanzania wú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùṣàkíyèsí, tí wọ́n ṣèbẹ̀wò tí wọ́n sì ran àwọn ará wọn tí a ti lè kúrò nílé lọ́wọ́ lórí. Àwọn olùwá-ibi-ìsádi náà sọ pé: “Àwọn ènìyàn láti inú ìsìn yín ti wá bẹ̀ yín wò, ṣùgbọ́n àlùfáà kan láti inú ìsìn tiwa kò tí ì bẹ̀ wá wò.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí wá di ẹni tí a mọ̀-bí-ẹni-mowó nínú ibùdó náà, ní pàtàkì nítorí ìṣọ̀kan, ìwàlétòlétò, àti ìṣarasíhùwà onífẹ̀ẹ́ tí ń bẹ láàárín wọn. (Johannu 13:35) Ó dùnmọ́ni láti kíyèsíi pé ní Benaco, Tanzania, ìṣẹ́jú 15 péré ni ó gba àwọn Ẹlẹ́rìí láti wa àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wọn rí láàárín àwọn ènìyàn bíi 250,000 tí ń bẹ ní ibùdó náà.