ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 12/15 ojú ìwé 30
  • Ìwọ Ha Rántí Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Ha Rántí Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Ní Ìyọ́nú Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Jẹ́ Adúróṣinṣin Kó O sì Máa Dárí Jini Bíi Ti Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Kí Lo Lè Ṣe Láti Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Jóòbù Gbé Orúkọ Jèhófà Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 12/15 ojú ìwé 30

Ìwọ Ha Rántí Bí?

Ìwọ ha ti rí i pé àwọn ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti ẹnu àìpẹ́ yìí ti jẹ́ èyí tí ó wúlò lọ́nà gbígbéṣẹ́ fún ọ bí? Nígbà náà èéṣe tí o kò fi dán agbára ìrántí rẹ wò pẹ̀lú àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀lé e wọ̀nyí:

▫ Èéṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ń bá a nìṣó láti máa ṣèbẹ̀wò lemọ́lemọ́ sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò wọn?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fúnraawọn ń fẹ́ ìbùkún Ọlọrun nípasẹ̀ Ìjọba tí a ṣèlérí náà, àti nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wọn, wọ́n fẹ́ ìbùkún kan náà fún wọn. Ní títipa báyìí tẹ̀lé àpẹẹrẹ Jesu, ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan sún wọ́n láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò wọn. (Matteu 6:9, 10; 22:37-⁠39)​—⁠8/15, ojú-ìwé 8, 9.

▫ Èéṣe tí èrò-ìgbàgbọ́ nínú ẹfolúṣọ̀n fi jẹ ọ̀ràn ìgbàgbọ́?

Àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ kò tí ì ri kí ìyípadà òjijì nínú apilẹ̀ àbùdá​—⁠àní ìwọ̀nyí tí ó ṣàǹfààní pàápàá⁠—​kí ó mú ohun alààyè titun jáde rí, síbẹ̀ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfoluṣọn jẹ́wọ́ pé bí irú ọ̀wọ́ àwọn ohun titun ṣe ń wáyé nìyẹn. Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n kò tí ì fojúrí wíwáyé àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí láti inú ẹ̀dá aláìlẹ́mìí rí, síbẹ̀ wọn tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.​—⁠9/1, ojú-ìwé 5.

▫ Ọ̀nà dídára jùlọ wo ni a lè gbà borí ìrẹ̀wẹ̀sì tí ó lè wá láti inú ìkálọ́wọ́kò inú ìgbésí-ayé?

Ohun yòówù kí ipò wa jẹ́ nínú ìgbésí-ayé, bí a bá pọkànpọ̀ sórí ohun tí a lè ṣe dípò kí a máa dààmú nípa ohun tí a kò lè ṣe, ìgbésí-ayé yóò mú ìtẹ́lọ́rùn tí ó túbọ̀ pọ̀ sí i wá, àwa yóò sì rí ayọ̀ nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun. (Orin Dafidi 126:​5, 6)​—⁠9/1, ojú-ìwé 28.

▫ Kí ni àwọn àǹfààní dídáríjini?

Dídáríji àwọn ẹlòmíràn ń mú ipò-ìbátan sunwọ̀n síi (Efesu 4:32); kì í ṣe àlàáfíà pẹ̀lú ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa nìkan ni ó ń mú wá ṣùgbọ́n àlàáfíà inú lọ́hùn-⁠ún pẹ̀lú (Romu 14:19; Kolosse 3:​13-⁠15); dídáríji àwọn ẹlòmíràn ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún dídárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá (Matteu 6:14); bákan náà, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti rántí pé àwa fúnraawa nílò ìdáríjì. (Romu 3:23)​—⁠9/15, ojú-ìwé 7.

▫ Báwo ni àpẹẹrẹ wòlíì Amosi ṣe ràn wá lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò ìwàásù wa?

Gẹ́gẹ́ bí Amosi, àwa kì í yí ìhìn-iṣẹ́ Ọlọrun padà tàbí kí a bomi là á. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ń fi pẹ̀lú ìgbọràn polongo rẹ̀ láìka ìhùwàpadà àwọn tí ń gbọ́ wa sí.​—⁠9/15, ojú-ìwé 17.

▫ Àwọn àmì ànímọ́ Ọlọrun wo ni a níláti ṣàfarawé?

Àwọn méjì tí ò ṣe pàtàkì ni agbára ìṣe Jehofa láti ṣètòjọ àti ayọ̀ rẹ̀. (1 Korinti 14:33; 1 Timoteu 1:11) Àwọn ànímọ́ Ọlọrun wọ̀nyí wàdéédéé, kí ó lè jẹ́ pé ọ̀kan kò tayọ lọ́nà tí ó ṣèpalára fún èkejì.​—⁠10/1, ojú-ìwé 10.

▫ Àwọn ìgbésẹ̀ onífojúsọ́nà-fún-rere wo ni àwọn òbí ti gbé láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́sin Jehofa?

Kọ́kọ́rọ́ kan tí ó ṣe kókó ni láti tètè bẹ̀rẹ̀. Àwọn èrò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn tí wọ́n rí gbà àti àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ nígbà tí ọkàn-àyà wọn sì ṣeé tẹ̀síhìn-⁠ín sọ́hùn-⁠ún yóò wà jálẹ̀ gbogbo àkókò ìgbésí-ayé wọn. (Owe 22:6) Ó ṣe pàtàkì lati kọ́ wọn ní ìgbọràn àti ọ̀wọ̀ fún Jehofa àti ìjọsìn rẹ̀ ní gbogbo àwọn ìpàdé. Àwọn òbí tí wọ́n ti ṣàṣeyọrí kọ́ láti mọ àwọn ìsúnniṣe tí ó burú, wọ́n sì ń ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe wọn. (Owe 22:15) Lákòótán, tètè bẹ̀rẹ̀ láti gbé àwọn góńgó ti ìṣàkóso Ọlọrun tí ọwọ́ ọmọ rẹ lè tètè tẹ̀ kalẹ̀ fún un.​—⁠10/1, ojú-ìwé 27 sí 28.

▫ Apá ẹ̀ka títayọ wo níti ìdáríjì Jehofa ni a níláti gbìyànjú láti ṣe àmúlò rẹ̀?

Jehofa máa ń dáríjì ó sì máa ń gbàgbé rẹ̀. (Jeremiah 31:34) Èyí nira fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn láti ṣe. Ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ni Jesu tẹnumọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní Matteu 6:​14, 15.​—⁠10/15, ojú-ìwé 25 sí 26.

▫ Àwọn ohun ìdínà mẹ́ta wo ni ó wà fún wa láti di oníyọ̀ọ́nú?

Nítorí ipò ẹ̀ṣẹ̀ wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn, ìmọ̀lára ìlara lè fìdímúlẹ̀. Bí a ba ń ṣe ìlara ẹnì kan, báwo ni a ṣe lè fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ bá a lò? Ìdínà mìíràn ni mímú araawa wá sábẹ́ ìdarí ìwà-ipá tí ó ṣeé yẹ̀sílẹ̀. Èyí máa ń sọ ìmọ̀lára ìbánikẹ́dùn wa nítorí ìjìyà àwọn ẹlòmíràn dòkú. Síwájú síi, ẹnì kan tí ó jẹ́ anìkànjọpọ́n ṣeéṣe kí ó ṣàìní ìyọ́nú. (1 Johannu 3:17)​—⁠11/1, ojú-ìwé 19, 20.

▫ Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ láti inú àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ nípa Jobu?

Àkọsílẹ̀ Jobu mú kí a túbọ̀ wà lójúfò sí àwọn ìhùmọ̀ Satani ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti rí bí ipò ọba-aláṣẹ àgbáyé ti Jehofa ṣe tan mọ́ ìwàtítọ́ ẹ̀dá ènìyàn. Bíi ti Jobu, gbogbo àwọn tí wọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun ni a gbọ́dọ̀ dánwò. Àwa pẹ̀lú lè lo ìfaradà bí Jobu ti ṣe, kí a mú Satani ní òpùrọ́, kí a sì gbádùn àwọn ìbùkún Ìjọba Ọlọrun.​—⁠11/15, ojú-ìwé 20.

▫ Báwo ni alága ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ṣe lè fi ìkanisí tí ó yẹ hàn sí alàgbà kọ̀ọ̀kan?

Nígbàkugbà tí ó bá ṣeéṣe alága náà níláti pèsè ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ọ̀rọ̀-àjọrò tipẹ́ ṣáájú àkókò kí ó lè fàyè sílẹ̀ fún àwọn alàgbà yòókù láti gbé àwọn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tí a tò lẹ́ṣẹẹsẹ yẹ̀wò dáradára àti tàdúrà-tàdúrà. Nínú ìpàdé àwọn alàgbà, òun kò ní gbìyànjú láti darí èrò àwọn alàgbà ṣùgbọ́n yóò fún wọn níṣìírí láti lo “òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ” lórí àwọn ọ̀ràn tí wọ́n ń gbéyẹ̀wò. (1 Timoteu 3:13, NW)​—⁠12/1, ojú-ìwé 30.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́