ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bhs orí 12 ojú ìwé 124-134
  • Kí Lo Lè Ṣe Láti Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Lo Lè Ṣe Láti Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?
  • Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Ká à ní Bíbélì Fi Kọ́ni
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • JÈHÓFÀ MÁA Ń DÁÀBÒ BO ÀWỌN Ọ̀RẸ́ RẸ̀
  • Ẹ̀SÙN LÁTỌ̀DỌ̀ SÁTÁNÌ
  • SÁTÁNÌ KỌ LU JÓÒBÙ
  • BÍ Ẹ̀SÙN SÁTÁNÌ ṢE KÀN Ẹ́
  • MÁA GBỌ́RÀN SÍ ÀṢẸ JÈHÓFÀ
  • BÓ O ṢE LÈ NÍFẸ̀Ẹ́ OHUN TÍ ỌLỌ́RUN NÍFẸ̀Ẹ́
  • Jóòbù Gbé Orúkọ Jèhófà Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Bí A Ṣe Lè Mú Inú Ọlọ́run Dùn
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • “Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Jobu Lo Ìfaradà—Àwa Pẹ̀lú Lè Ṣe Bẹ́ẹ̀!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
bhs orí 12 ojú ìwé 124-134

ORÍ KEJÌLÁ

Kí Lo Lè Ṣe Láti Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

1, 2. Dárúkọ àwọn kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà.

IRÚ ẹni wo lo fẹ́ kó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ? Ó dájú pé ẹni tó o fẹ́ràn, tí ìwà yín bára mu, tó sì níwà ọmọlúwàbí lo máa fẹ́ kó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ.

2 Jèhófà Ọlọ́run yan àwọn èèyàn kan láti jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà. (Àìsáyà 41:8; Jémíìsì 2:23) Jèhófà tún fẹ́ràn Dáfídì. Ó sọ pé Dáfídì jẹ́ ‘ẹni tí ọkàn òun fẹ́.’ (Ìṣe 13:22) Bákan náà, Bíbélì sọ pé wòlíì Dáníẹ́lì “ṣeyebíye gan-an” lójú Jèhófà.​—Dáníẹ́lì 9:23.

3. Kí ló mú kí Ábúráhámù, Dáfídì àti Dáníẹ́lì jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà?

3 Báwo ni Ábúráhámù, Dáfídì àti Dáníẹ́lì ṣe di ọ̀rẹ́ Jèhófà? Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé: “O fetí sí ohùn mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Ìyẹn fi hàn pé, àwọn tó bá ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì jẹ́ onígbọràn ló lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Kódà, odindi orílẹ̀-èdè kan lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Jèhófà sọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Ẹ gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, màá sì di Ọlọ́run yín, ẹ ó sì di èèyàn mi.” (Jeremáyà 7:23) Torí náà, tó o bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Jèhófà, ìwọ náà gbọ́dọ̀ máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu.

JÈHÓFÀ MÁA Ń DÁÀBÒ BO ÀWỌN Ọ̀RẸ́ RẸ̀

4, 5. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dáàbò bo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀?

4 Bíbélì sọ pé Jèhófà ń wá ọ̀nà “láti fi agbára rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.” (2 Kíróníkà 16:9) Ní Sáàmù 32:8, Jèhófà ṣèlérí fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé: “Màá fún ọ ní ìjìnlẹ̀ òye, màá sì kọ́ ọ ní ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn. Màá fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.”

5 Ọ̀tá alágbára kan ò fẹ́ ká di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́ Jèhófà máa ń dáàbò bò wá. (Ka Sáàmù 55:22.) À ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, torí pé a jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. Kódà, a máa ń jẹ́ adúróṣinṣin sí i nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro tó le gan-an. Ọkàn wa balẹ̀ bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Torí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, mìmì kan ò ní mì mí.” (Sáàmù 16:8; 63:8) Kí ni Sátánì máa ń ṣe ká bàa lè di ọ̀tá Ọlọ́run?

Ẹ̀SÙN LÁTỌ̀DỌ̀ SÁTÁNÌ

6. Kí ni Sátánì sọ nípa àwa èèyàn?

6 Ní Orí 11, a kẹ́kọ̀ọ́ pé Sátánì fẹ̀sùn kan Jèhófà pé òpùrọ́ ni àti pé ìwà ìkà ló hù bí kò ṣe jẹ́ kí Ádámù àti Éfà pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ fúnra wọn. Nínú Bíbélì, ìwé Jóòbù kọ́ wa pé Sátánì máa ń fẹ̀sùn kan àwọn tó bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Sátánì sọ pé kì í ṣe torí pé àwa èèyàn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run la ṣe ń sìn ín, àmọ́ nítorí ohun tá a máa rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ni. Kódà, o tún fi kún un pé, òun lè mú kí ẹnikẹ́ni kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a rí kọ́ lára Jóòbù àti bí Jèhófà ṣe dáàbò bò ó.

7, 8. (a) Ojú wo ni Jèhófà fi wo Jóòbù? (b) Kí ni Sátánì sọ nípa Jóòbù?

7 Ta ni Jóòbù? Ọkùnrin olódodo kan tó gbé ayé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (3,600) ọdún sẹ́yìn ni. Jèhófà sọ pé kò sí ẹni kankan nígbà yẹn tó dà bí rẹ̀ ní gbogbo ayé. Jóòbù ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run, ó sì kórìíra ohun tó burú. (Jóòbù 1:8) Ẹ ò rí i pé ọ̀rẹ́ àtàtà ni Jóòbù jẹ́ sí Jèhófà lóòótọ́.

8 Sátánì sọ pé torí àwọn ohun tí Jóòbù ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ló ṣe ń sìn ín. Sátánì sọ fún Jèhófà pé: “Ṣebí o ti ṣe ọgbà [tàbí ògiri] yí i ká láti dáàbò bo òun, ilé rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní? O ti bù kún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sì ti pọ̀ gan-an ní ilẹ̀ náà. Àmọ́, kí nǹkan lè yí pa dà, na ọwọ́ rẹ, kí o sì kọ lu gbogbo ohun tó ní, ó dájú pé ó máa bú ọ níṣojú rẹ gan-an.”​—Jóòbù 1:10, 11.

9. Kí ni Jèhófà gba Sátánì láyè láti ṣe?

9 Sátánì sọ pé torí ohun tí Jóòbù máa rí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà ló ṣe ń sìn ín. Sátánì tún sọ pé, òun lè ṣe é kí Jóobù má sin Jèhófà mọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ò fara mọ́ ohun tí Sátánì sọ, síbẹ̀ ó gba Sátánì láyè láti dán Jóòbù wò, kó lè mọ̀ bóyá ìfẹ́ tí Jóòbù ní sí Jèhófà ló jẹ́ kó máa sìn ín.

SÁTÁNÌ KỌ LU JÓÒBÙ

10. Báwo ni Sátánì ṣe kọ lu Jóòbù, kí sì ni Jóòbù ṣe?

10 Ohun àkọ́kọ́ tí Sátánì ṣe ni pé, ó jẹ́ kí wọ́n jí gbogbo ẹran ọ̀sìn Jóòbù. Lẹ́yìn náà, Sátánì pa èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìránṣẹ́ Jóòbù. Gbogbo nǹkan tí Jóòbù ní pátá ló pàdánù. Kò tán síbẹ̀ o, Sátánì tún fi ìjì líle kan pa àwọn ọmọ mẹ́wàá tí Jóòbù bí. Síbẹ̀, Jóòbù ṣì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. “Nínú gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, Jóòbù ò dẹ́ṣẹ̀, kò sì fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé ó ṣe ohun tí kò dáa.”​—Jóòbù 1:12-19, 22.

Inú Jóòbù àti ìyàwó rẹ̀ ń dùn, pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn mẹ́wàá

Jèhófà san Jóòbù lérè torí pé ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tòótọ́

11. (a) Kí ni Sátánì tún ṣe fún Jóòbù? (b) Kí ni Jóòbù ṣe?

11 Sátánì ò jáwọ́ o. Sátánì tún sọ fún Ọlọ́run pe: “Kọ lu egungun àti ara rẹ̀, ó dájú pé ó máa bú ọ níṣojú rẹ gan-an.” Bí Sátánì ṣe fi àrùn burúkú kan tó ń roni lára kọ lu Jóòbù nìyẹn o. (Jóòbù 2:5, 7) Síbẹ̀, Jóòbù ṣì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ó sọ pé: “Títí màá fi kú, mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!”​—Jóòbù 27:5.

12. Báwo ni Jóòbù ṣe fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì?

12 Jóòbù ò mọ nǹkan kan nípa ìdí tóun fi ń jìyà àti ẹ̀sùn tí Sátánì fi kàn án. Ó rò pé Jèhófà ló fa àwọn ìṣòro tó dé bá òun. (Jóòbù 6:4; 16:11-14) Síbẹ̀, Jóòbù ò fi Jèhófà sílẹ̀. Ó wá ṣe kedere pé, Jóòbù kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan. Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ló ṣe di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Irọ́ ni gbogbo ẹ̀sùn Sátánì!

13. Kí ni Jóòbù rí gbà torí pé ó jẹ́ olóòótọ́?

13 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run, síbẹ̀ ó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, ó sì fi hàn pé ẹni ibi ni Sátánì. Jèhófà san Jóòbù lérè torí pé ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́.​—Jóòbù 42:12-17.

BÍ Ẹ̀SÙN SÁTÁNÌ ṢE KÀN Ẹ́

14, 15. Ẹ̀sùn wo ni Sátánì fi kan gbogbo èèyàn?

14 A lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù. Lónìí, Sátánì ń fẹ̀sùn kàn wá pé torí ohun tá a máa rí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà la ṣe ń sìn ín. Ní Jóòbù 2:4, Sátánì sọ pé: “Gbogbo ohun tí èèyàn bá ní ló máa fi dípò ẹ̀mí rẹ̀.” Ìyẹn fi hàn pé, kì í ṣe Jóòbù nìkan ni Sátánì fẹ̀sùn kàn, gbogbo èèyàn ló ń fẹ̀sùn kàn pé wọ́n jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Jóòbù kú, Sátánì ṣì ń fẹ̀sùn kan Jèhófà àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Òwe 27:11 sọ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tó ń pẹ̀gàn mi [tàbí, tó ń bú mi] lésì.”

15 Tó o bá yàn láti ṣègbọràn sí Jèhófà tó o sì jẹ́ olóòótọ́ nígbà ìṣòro, ńṣe lò ń fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Kódà, tó bá gba pé kó o ṣe àwọn àyípadà ńlá nínú ìgbésí ayé rẹ kó o lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ! Ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù lọ ni. Sátánì sọ pé tí ìṣòro bá dé bá ẹ, o máa kẹ̀yìn sí Jèhófà. Ńṣe ló máa ń wá bó ṣe máa tàn wá jẹ, ká lè di aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run. Báwo ló ṣe ń ṣe é?

16. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Sátánì ń lò láti mú káwọn èèyàn má sin Jèhófà mọ́? (b) Báwo ni Èṣù ṣe lè mú kí ìwọ náà má sin Jèhófà mọ́?

16 Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Sátánì máa ń lò láti mú ká má ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run mọ́. Ó máa ń gbéjà kò wá ‘bíi kìnnìún tó ń ké ramúramù, tó ń wá bó ṣe máa pani jẹ.’ (1 Pétérù 5:8) Má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu táwọn ọ̀rẹ́, ẹbí tàbí àwọn míì bá ń sọ pé kó o má ṣe kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́ tàbí pé kó o ṣe ohun tí kò tọ́. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ńṣe ni wọ́n ń gbógun tì ẹ́.a (Jòhánù 15:19, 20) Sátánì tún máa ń ṣe bíi pé “áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀ ni òun.” Torí náà, ó lè lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti mú ká ṣàìgbọràn sí Jèhófà. (2 Kọ́ríńtì 11:14) Ọ̀nà míì tí Sátánì máa ń gbà láti mú ká má sin Jèhófà mọ́ ni pé ó máa ń jẹ́ ká rò pé a ò dáa tó láti sin Ọlọ́run.​—Òwe 24:10.

MÁA GBỌ́RÀN SÍ ÀṢẸ JÈHÓFÀ

17. Kí nìdí tá a fi ń ṣègbọràn sí Jèhófà?

17 Tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà, ńṣe là ń fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onígbọràn? Bíbélì sọ pé: “Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo okun rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Diutarónómì 6:5) Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà ló ń jẹ́ ká máa ṣègbọràn sí i. Bí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ṣe ń pọ̀ sí i, á mú ká máa ṣe gbogbo ohun tó bá ní ká ṣe. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Torí ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí nìyí, pé ká pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kò nira.”​—1 Jòhánù 5:3.

18, 19. (a) Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà sọ pé kò dáa? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà kì í sọ pé ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ?

18 Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà sọ pé kò dáa? Àwọn kan lára wọn wà nínú àpótí náà, “Kórìíra Àwọn Ohun Tí Jèhófà Kórìíra.” Tó o bá kọ́kọ́ wò ó, o lè rò pé àwọn kan lára wọn ò fi bẹ́ẹ̀ burú. Àmọ́ tó o bá ka àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn, tó o sì fara balẹ̀ ronú nípa wọn, wàá rí i pé ó bọ́gbọ́n mu pé ká máa ṣègbọràn sí àwọn òfin Jèhófà. O tún lè rí i pé ó yẹ kó o ṣe àwọn àyípadà kan nínú ìgbésí ayé rẹ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè má rọrùn nígbà míì láti ṣe àwọn àyípadà yẹn, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn á sì jẹ́ kó o ní àlàáfíà àti ayọ̀. (Àìsáyà 48:17, 18) Kí nìdí tá a fi gbà pé àwọn àyípadà náà ò kọjá ohun tá a lè ṣe?

19 Jèhófà kì í sọ pé ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ. (Diutarónómì 30:11-14) Torí pé ó jẹ́ Ọ̀rẹ́ tòótọ́, ó mọ̀ wá dáadáa ju bá a ṣe mọ ara wa lọ. Ó mọ ibi tá a dáa sí àti ibi tá a kù sí. (Sáàmù 103:14) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́, kò ní jẹ́ kí a dán yín wò kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n nínú àdánwò náà, yóò ṣe ọ̀nà àbáyọ kí ẹ lè fara dà á.” (1 Kọ́ríńtì 10:13) Ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà máa fún wa lókun nígbà gbogbo láti ṣe ohun tó tọ́. Ó máa fún ẹ ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá” kó o lè fara da àwọn ìṣòro tó le gan-an. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Lẹ́yìn tí Jèhófà ti ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ nígbà tó wà nínú ìṣòro tó le gan-an, ó sọ pé: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.”​—Fílípì 4:13.

BÓ O ṢE LÈ NÍFẸ̀Ẹ́ OHUN TÍ ỌLỌ́RUN NÍFẸ̀Ẹ́

20. Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ ká ní, kí sì nìdí?

20 Tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ohun tí Jèhófà sọ pé kò dáa, àmọ́ kì í ṣè ìyẹn nìkan. (Róòmù 12:9) Ó tún pọn dandan kí àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ohun tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́. A sọ àwọn ìwà tó yẹ kí wọ́n máa hù nínú Sáàmù 15:1-5. (Kà á.) Àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà máa ń gbé àwọn ànímọ́ rẹ̀ yọ, wọ́n sì máa ń ní “ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.”​—Gálátíà 5:22, 23.

21. Kí lo lè ṣe láti ní àwọn ànímọ́ tí inú Ọlọ́run dùn sí?

21 Kí lo lè ṣe láti ní àwọn ànímọ́ rere yẹn? Tó o bá ń ka Bíbélì déédéé tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, wàá mọ àwọn ohun tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́. (Àìsáyà 30:20, 21) Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà á jinlẹ̀, ìyẹn á sì mú kó o máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu.

22. Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ṣègbọràn sí Jèhófà?

22 Tó o bá fẹ́ ṣe àwọn àyípadà kan, ńṣe ló dà bí ìgbà tó o bọ́ aṣọ tó ti gbó, tó o sì wọ tuntun. Bíbélì sọ pé ó yẹ kó o “bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀” kó sì fi “ìwà tuntun” wọ ara rẹ láṣọ. (Kólósè 3:9, 10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má rọrùn, àmọ́ tá a bá ṣe àwọn àyípadà yìí, tá a sì ń ṣègbọràn sí Jèhófà, ó ṣèlérí pé òun máa fún wa ní “èrè ńlá.” (Sáàmù 19:11) Tórí náà, máa ṣègbọràn sí Jèhófà kó o lè fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Máa sin Jèhófà torí ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn tó o ní sí i, kì í ṣe torí kó o lè gba èrè ọjọ́ iwájú. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run lóòótọ́!

a Èyí ò túmọ̀ sí pé Sátánì ló ń darí àwọn tó ń sọ pé kó o má ṣe kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́. Àmọ́ Sátánì ni “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” àti pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára [rẹ̀].” Torí náà, kò yani lẹ́nu táwọn kan ò bá fẹ́ ká sin Jèhófà.​—2 Kọ́ríńtì 4:4; 1 Jòhánù 5:19.

KÓRÌÍRA ÀWỌN OHUN TÍ JÈHÓFÀ KÓRÌÍRA

  • Ìpànìyàn

    Ẹ́kísódù 20:13; 21:22, 23

  • Ìṣekúṣe

    Léfítíkù 20:10, 13, 15, 16; Róòmù 1:24, 26, 27, 32; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10

  • Ìbẹ́mìílò

    Diutarónómì 18:9-13; 1 Kọ́ríńtì 10:21, 22; Gálátíà 5:20, 21

  • Ìbọ̀rìṣà

    1 Kọ́ríńtì 10:14

  • Ìmutípara

    1 Kọ́ríńtì 5:11

  • Olè jíjà

    Léfítíkù 6:2, 4; Éfésù 4:28

  • Irọ́ pípa

    Òwe 6:16, 19; Kólósè 3:9; Ìfihàn 22:15

  • Ojúkòkòrò

    1 Kọ́ríńtì 5:11

  • Ìwà ipá

    Sáàmù 11:5; Òwe 22:24, 25; Málákì 2:16; Gálátíà 5:20, 21

  • Ìsọkúsọ àti òfófó

    Léfítíkù 19:16; Éfésù 5:4; Kólósè 3:8

  • Lílo ẹ̀jẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́

    Jẹ́nẹ́sísì 9:4; Ìṣe 15:20, 28, 29

  • Kéèyàn kọ̀ láti pèsè fún ìdílé rẹ̀

    1 Tímótì 5:8

  • Lílọ́wọ́ sí ogun tàbí ìṣèlú

    Àìsáyà 2:4; Jòhánù 6:15; 17:16

  • Mímu sìgá àti lílo oògùn nílòkulò

    Máàkù 15:23; 2 Kọ́ríńtì 7:1

KÓKÓ PÀTÀKÌ

ÒTÍTỌ́ 1: ÀWỌN Ọ̀RẸ́ JÈHÓFÀ MÁA Ń GBỌ́RÀN SÍ I LẸ́NU

“Ẹ gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, màá sì di Ọlọ́run yín, ẹ ó sì di èèyàn mi.”​—Jeremáyà 7:23

Ṣé èèyàn lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

  • Jẹ́nẹ́sísì 22:18; Jémíìsì 2:23

    Ábúráhámù di ọ̀rẹ́ Jèhófà nítorí pé ó fetí sí ohùn Ọlọ́run, ó sì gbà á gbọ́.

  • 2 Kíróníkà 16:9

    Jèhófà máa ń ran àwọn onígbọràn lọ́wọ́.

  • Sáàmù 25:14; 32:8

    Jèhófà máa ń fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye.

  • Sáàmù 55:22

    Jèhófà máa ń dúró ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.

ÒTÍTỌ́ 2: JÓÒBÙ JẸ́ Ọ̀RẸ́ ỌLỌ́RUN, Ó SÌ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́

“Nínú gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, Jóòbù ò dẹ́ṣẹ̀, kò sì fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé ó ṣe ohun tí kò dáa.”​—Jóòbù 1:22

Báwo ni Sátánì ṣe kọ lu Jóòbù, kí sì ni Jóòbù ṣe?

  • Jóòbù 1:10, 11

    Sátánì sọ pé Jóòbù jẹ́ onímọtara-ẹni nìkan, kò sì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.

  • Jóòbù 1:12-19; 2:7

    Jèhófà gba Sátánì láyè láti gba gbogbo ohun tí Jóòbù ní, Sátánì tiẹ̀ tún fi àìsàn burúkú kọ lu Jóòbù.

  • Jóòbù 27:5

    Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù ò mọ ìdí tóun fi ń jìyà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ ó jẹ́ olóòótọ́.

ÒTÍTỌ́ 3: SÁTÁNÌ FẸ́ KÓ O FI JÈHÓFÀ SÍLẸ̀

“Gbogbo ohun tí èèyàn bá ní ló máa fi dípò ẹ̀mí rẹ̀.”​—Jóòbù 2:4

Báwo la ṣe mọ̀ pé Sátánì fẹ́ ba ọ̀rẹ́ àwa àti Jèhófà jẹ́?

  • 2 Kọ́ríńtì 11:14

    Sátánì máa ń sapá láti fọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mú wa ṣàìgbọràn sí Jèhófà.

  • Òwe 24:10

    Ó máa ń sapá láti mú ká rò pé a ò dáa tó láti sin Jèhófà.

  • 1 Pétérù 5:8

    Sátánì máa ń ṣe inúnibíni sí wa.

  • Òwe 27:11

    Máa gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu, kó o sì jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tòótọ́. Èyí á fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì.

ÒTÍTỌ́ 4: À Ń GBỌ́RÀN SÍ JÈHÓFÀ LẸ́NU TORÍ PÉ A NÍFẸ̀Ẹ́ RẸ̀

“Ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí nìyí, pé ká pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.”​—1 Jòhánù 5:3

Kí lo lè ṣe láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà?

  • Diutarónómì 6:5

    Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Èyí á jẹ́ kó o lè máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu.

  • Àìsáyà 48:17, 18

    Máa gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu. Ìyẹn máa ṣe ẹ́ láǹfààní.

  • Diutarónómì 30:11-14

    Fọkàn balẹ̀, Jèhófà ò ní sọ pé kó o ṣe ohun tó ju agbára ẹ lọ.

  • Fílípì 4:13

    Máa ṣe ohun tó tọ́, Jèhófà máa fún ẹ lókun.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́