ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 4/15 ojú ìwé 8-10
  • Ìgbétásì Ìjẹ́rìí Tí Ó Kẹ́sẹ Járí ní Ilẹ̀ Gíríìkì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbétásì Ìjẹ́rìí Tí Ó Kẹ́sẹ Járí ní Ilẹ̀ Gíríìkì
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àwọn Òṣìṣẹ́ Ìjọba Dáhùn Padà
  • Àwọn Agbẹjọ́rò fún Àwọn Ará Ìlú Dáhùn Padà
  • Àwọn Olùtọ́jú Ibi Àkójọ Ìwé Kíkà Dáhùn Padà
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 4/15 ojú ìwé 8-10

Ìgbétásì Ìjẹ́rìí Tí Ó Kẹ́sẹ Járí ní Ilẹ̀ Gíríìkì

ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA ti dojú kọ àtakò ní ilẹ̀ Gíríìkì fún ìgbà pípẹ́. Àwọn ọlọ́pàá, ilé ẹjọ́, àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan ti ṣe inúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí, ó sì sábà máa ń jẹ́ nítorí ìfipámúni láti ọ̀dọ̀ àwùjọ àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Gíríìkì. Nígbà míràn, àwáwí náà ni òfin ìgbógunti ìsọnidaláwọ̀ṣe tí ilẹ̀ Gíríìkì gbé kalẹ̀, nígbà míràn, ó máa ń jẹ́ nítorí kíkọ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí kọ̀, ní ìbámu pẹ̀lu Bibeli, láti lọ sí ojú ogun tàbí láti gba ẹ̀jẹ̀ sára.—Isaiah 2:2-5; Ìṣe 15:28, 29.

Nínú ìsapá láti túbọ̀ jẹ́ kí àwọn aláṣẹ tí wọ́n jẹ́ aláìlábòsí ọkàn ní ilẹ̀ Gíríìkì lóye wọn sí i, nǹkan bí 200 Ẹlẹ́rìí tí ìjọba ilẹ̀ Gíríìkì fún láṣẹ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ìsìn, àti àwọn kan tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà òṣìṣẹ́ òfin, lọ́wọ́ nínú ìgbétásì kan tí a ṣe káàkiri orílẹ̀-èdè náà láìpẹ́ yìí. Wọ́n fi ìwé pẹlẹbẹ kan tí a ṣe lákànṣe lọni, tí a pè ní Jehovah’s Witnesses in Greece, àti ìwé náà, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom. Wọ́n tún pèsè ìdìpọ̀ àwọn ìwé tí ó fi hàn pé kò sí ìdí kankan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin fún inúnibíni tí a ń ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ọ̀gá ọlọ́pàá, àwọn olórí ìlú, àwọn agbẹjọ́rò fún àwọn ará ìlú, àti àwọn lọ́gàá-lọ́gàá mìíràn.

Kí ni ìdáhùn padà wọn? Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìrírí tí ó múni lọ́kàn yọ̀. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Olùdarí àgọ́ ọlọ́pàá kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Macedonia gba àwọn arákùnrin wa tọwọ́tẹsẹ̀, ó sì wí pé: “Mo ti mọ ẹ̀yin ènìyàn yìí tipẹ́tipẹ́, . . . ìwàlétòlétò yín sì jọ mí lójú. . . . N kò fara mọ́ òfin ìsọnidaláwọ̀ṣe, tí ó bá sì jẹ́ pé mo ní agbára láti ṣe é ni, n óò fagi lé e.”

Àwọn olùdarí onírúurú àgọ́ ọlọ́pàá ní ọ̀pọ̀ ìlú ńlá sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ bíi: “Mo gbóṣùbà fún yín fún iṣẹ́ afẹ́nifẹ́re tí ẹ ń ṣe.” “Àwùjọ yín kì í dá wàhálà sílẹ̀ fún àwọn ọlọ́pàá; iṣẹ́ afẹ́nifẹ́re bàǹtàbanta ni ẹ ti ṣe yọrí.” “A kò ní ìṣòro kankan pẹ̀lú yín. A bọ̀wọ̀ fún yín, a sì mọrírì yín.”

Ní Piraeus, ọ̀gá kan nínú iṣẹ́ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ sọ fún àwọn arákùnrin, pẹ̀lú omi lójú, pé òún mọ̀ bí a ṣe ń gbàdúrà sí Jehofa Ọlọrun nípasẹ̀ orúkọ Jesu Kristi. Ó túbọ̀ ya àwọn Ẹlẹ́rìí náà lẹ́nu nígbà tí ó tún sọ síwájú sí i pé òún mọ̀ pé wọ́n ń retí inúnibíni díẹ̀ ṣáájú Armageddoni, ó sì retí pé Ọlọrun yóò lo òun láti ràn wọ́n lọ́wọ́ ní àkókò yẹn! Ó tẹ́wọ́ gba ìkésíni àwọn arákùnrin náà láti túbọ̀ jíròrò síwájú sí i.

Àwọn Òṣìṣẹ́ Ìjọba Dáhùn Padà

Ọ̀gá ìlú kan ní Thessaly sọ nípa ìwé Proclaimers pé: “Ó yẹ kí a wa àyè kan fún un ní ibi àkójọ ìwé kíkà ti ìlú—ibì kan tí ó ta yọ!” Ó tìtorí bẹ́ẹ̀ palẹ̀ àwọn ìwé mọ́ kúrò lórí pẹpẹ, ó sì fi ìwé Proclaimers síbẹ̀, kí a baà lè rí ẹ̀yìn rẹ̀.

Ní àríwá ilẹ̀ Gíríìkì, olórí ìlú kan fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà kí àwọn arákùnrin káàbọ̀, ó sì wí pé: “Ẹ̀yin ni ènìyàn tí ó dára jù lọ tí mo fẹ́ láti ní nínú ìlú mi.” Onínúure olórí ìlú kan ní àríwá Euboea sọ fún àwọn arákùnrin pé: “Ọ̀gá sójà ni mí tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin—mo mọrírì yín gidigidi.” Ó fi tìtaratìtara gba àwọn kókó tí àwọn Ẹlẹ́rìí náà sọ. Nígbà tí wọ́n fi ọ̀wọ́ àwọn ìwé tí Watch Tower Society ti tẹ̀ jáde hàn án, ó wí pé: “Bí mo bá ṣèlérí láti ka gbogbo wọn, ẹ̀yin yóò ha fún mi bí?” Wọ́n dáhùn pé: “Dájúdájú—ìwọ ni o ni wọ́n!” Inú rẹ̀ dùn, kò sì fẹ́ kí àwọn arákùnrin náà lọ mọ́.

Ní ìgbèríko kan ní Attica, olórí ìlú kan fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn arákùnrin náà fi lọ̀ ọ́, ó sì ní kí wọ́n máa mú àwọn ìtẹ̀jáde Society wá fún òun. Bí wọ́n ṣe fẹ́ máa lọ, ó sọ fún wọn pé: “Àwọn òṣèlú ti já àwọn ènìyàn kulẹ̀ gidigidi, wọ́n sì wá òtítọ́ náà gan-an lọ sí ibòmíràn. Ó dá mi lójú pé láti ìsinsìnyí lọ, ọwọ́ yín yóò dí gidigidi nítorí pé òtítọ́ náà wà lọ́wọ́ yín.”

Àwọn Agbẹjọ́rò fún Àwọn Ará Ìlú Dáhùn Padà

Àwọn arákùnrin tí wọ́n ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ igbá kejì agbẹjọ́rò fún àwọn ará ìlú ní àríwá ilẹ̀ Gíríìkì rántí pé: “Àwọn ìtẹ̀jáde wa, ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wa, àti àwọn ìsapá wa láti rí i dájú pé àwọn ènìyàn wa kò wà láìní ìrànlọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá dojú kọ ọ̀ràn ìfàjẹ̀sínilára tí ó lágbára, wú u lórí. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ wa, ó sì gbóríyìn fún wa fún lílo ìdánúṣe náà láti bẹ òun wò, tí a sì fi ìsọfúnni náà tó òun létí. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, a gbọ́ pé, ní ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, ó ti pe àwọn ọlọ́pàá, tí ó sì pàṣẹ fún wọn láti fàṣẹ ọba mú àwọn arákùnrin méjì tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá.”

Ẹnu ya àwọn agbẹjọ́rò méjì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí, tí wọ́n ṣèbẹ̀wò sí ọ́fíìsì agbẹjọ́rò fún àwọn ará ìlú ní Ateni láti rí agbẹjọ́rò fún àwọn ará ìlú kan tí ó lọ́jọ́ lórí, tí a mọ̀ bí-ẹni-mowó, tí a sì bọ̀wọ̀ fún níbi gbogbo, tí ó tọ̀ wọ́n wá. Ó pè wọ́n síkọ̀kọ̀, ó sì wí fún wọn pé òfin tí ó lòdì sí ìsọnidaláwọ̀ṣe kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ rárá, ó sì ń fa ìdàrúdàpọ̀ nínú ètò ìdájọ́ ilẹ̀ Gíríìkì. Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, ó sì bọ̀ wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ọ̀yàyà.

Ní àríwá ilẹ̀ Gíríìkì, agbẹjọ́rò fun àwọn ará ìlú kan jẹ́ ẹni tí ó yá mọ́ni, ó sì tẹ́wọ́ gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Bí ó ti ń ṣí ojú ewé ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, ẹnú yà á láti rí onírúurú àkòrí tí ó wà nínú kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé náà. Ó sọ pé: “N kò tí ì rí ohun tí ìwé yìí kárí rẹ̀ nínú ìwé Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kankan.”

Agbẹjọ́rò fún àwọn ará ìlú kan ní Boeotia gbà pé, ní àtijọ́, òun ti pàṣẹ fún fífa ẹ̀jẹ̀ sára àwọn Ẹlẹ́rìí ní ìlòdìsí ohun tí wọ́n fẹ́. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí àwọn arákùnrin náà ti bá a sọ̀rọ̀ lórí ọ̀ràn náà, ó polongo pé: “Èmi kì yóò pa irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ mọ́ láé ní ọjọ́ ọ̀la!” Ó pinnu pé kí a kàn sí Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó wà ládùúgbò, kí a baà lè lo gbogbo ọ̀nà àfidípò míràn fún ẹ̀jẹ̀. Ó fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè.

Àwọn Olùtọ́jú Ibi Àkójọ Ìwé Kíkà Dáhùn Padà

A gbé ọ̀rọ̀ náà kalẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ibi àkójọ ìwé kíkà. Ní ibi àkójọ ìwé kíkà kan ní Ateni, olùtọ́jú ibi àkójọ ìwé kíkà kan tí ó jẹ́ ọmọlúwàbí tẹ́wọ́ gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ó sì sọ pé: “Ó dára tí ẹ mú ìwé yín wá fún wa nítorí pé èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìwé tí a ní ní ibi àkójọ ìwé kíkà wa lòdì sí yín. . . . Inú bí àlùfáà kan láti rí àwọn ìwé yín ní ibi àkójọ ìwé kíkà náà. . . . Ìyẹn kò já mọ́ nǹkan kan. Ó yẹ kí a jẹ́ kí olúkúlùkù sọ tẹnu rẹ̀.”

Ọ̀gá kan ní ibi àkójọ ìwé kíkà ìlú ńlá ní Krete, ẹni tí ó mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ibùdó àwọn ológun, sọ fún àwọn arákùnrin pé, kíkọ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí kọ̀ láti kópa nínú ogun wú òun lórí. Ó ti ń bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Èé ṣe tí àwọn ènìyàn yìí fi ní láti máa jìyà?’ Ó tẹ́wọ́ gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ àwọn arákùnrin, ó sì sọ nípa ìgbétásì tí ń lọ lọ́wọ́ pé: “Ẹ ti ṣe iṣẹ́ tí ó dára púpọ̀, ẹ̀ bá sì ti ṣe èyí ní àwọn ọdún tí ó ti kọjá. . . . Ní ilẹ̀ Gíríìkì ọ̀pọ̀ ẹ̀tanú ń bẹ.” Ó ní kí àwọn arákùnrin tún bẹ òun wò láìpẹ́.

Ní àkókò àkànṣe ìgbétásì yìí, àwọn arákùnrin fi iye tí ó lé ní 1,000 ìwé Proclaimers, 1,600 ìwé pẹlẹbẹ náà, Jehovah’s Witnesses in Greece, àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìwé àti ìwé ìròyìn síta. Lọ́nà tí ó túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i, wọ́n bá ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn lọ́gàá-lọ́gàá ilẹ̀ Gíríìkì sọ̀rọ̀ lójúkorojú. Wàyí o, ìrètí àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jehofa ní ilẹ̀ Gíríìkì àti káàkiri àgbáyé ni pé, àwọn aláṣẹ aláìlábòsí ọkàn ní ilẹ̀ Gíríìkì yóò túbọ̀ ní ojú ìwòye aláìṣègbè nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́