ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 4/15 ojú ìwé 22-27
  • Ìmúgbòòrò Tí Ó ní Ìbùkún Jehofa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìmúgbòòrò Tí Ó ní Ìbùkún Jehofa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Amọ́kànyọ̀
  • Àwọn Ilé Tí A Yà Sí Mímọ́
  • Èé Ṣe Tí A Fi Nílò Ilé Púpọ̀ Sí I
  • Ìtàn Tí Ó Tan Mọ́ Ilé Tí Ó Wà Ní 90 Òpópónà Sands
  • Ìbùkún Jehofa Fara Hàn
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 4/15 ojú ìwé 22-27

Ìmúgbòòrò Tí Ó ní Ìbùkún Jehofa

ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ ìyàsímímọ́ tí ó wáyé ní ìrọ̀lẹ́ September 18, 1995, tẹnu mọ́ ọn pé, ní tòótọ́, Jehofa Ọlọrun ti bù kún ìmúgbòòrò àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀, ní ọ̀gangan olú ilé iṣẹ́ wọn lágbàáyé ní Brooklyn, New York.

Àwọn tí ó tẹ́tí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìyàsímímọ́ náà lé ní 6,000. Wọ́n pé jọ ní Brooklyn, níbi tí a ti pilẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, àti ní àwọn ọ̀gangan mìíràn, títí kan ilé lílò àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nítòsí Patterson àti Wallkill, New York, àti ní ẹ̀ka wọn nítòsí Toronto, Canada. Àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀gangan ibòmíràn yàtọ̀ sí Brooklyn gbọ́ bí nǹkan ṣe ń lọ sí lórí wáyà tẹlifóònù.

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Amọ́kànyọ̀

Àwọn òṣìṣẹ́ Beteli, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń pe àwọn òṣìṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni náà, tí wọ́n tẹ́tí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, wọ́n jẹ́ apá tí ó pọ̀ jù lọ nínú àwọn mẹ́ḿbà ìdílé àgbáyé ti Beteli tí mẹ́ḿbà rẹ̀ lé ní 16,400. Irú àwọn mẹ́ḿbà bẹ́ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ sìn ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún orílẹ̀-èdè, níbi tí wọ́n ti ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìrànwọ́ fún ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó lé ní 78,600 káàkiri àgbáyé.

Ìfojúsọ́nà ga nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìyàsímímọ́ náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orin ní agogo 6:30 ìrọ̀lẹ́, tí àdúrà láti ẹnu Karl Klein sì tẹ̀ lé e. Alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, Lloyd Barry, fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà kí gbogbo ènìyàn káàbọ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìlóhùnsí ṣókí lórí ìjẹ́pàtàkì àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Albert Schroeder ṣàtúnyẹ̀wò ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà ti ọ̀sẹ̀ náà, lẹ́yìn náà ni Daniel Sydlik sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́ Ọlọ́wọ̀ Wa ní Beteli.” Gbogbo àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí pátá jẹ́ mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.

Apá ìtòlẹ́sẹẹsẹ méjì tí ó tẹ̀ lé e—“Kíkojú Àìní Wa Tí Ń Gbòòrò Sí I Ní Ti Ilé Gbígbé, 1974 sí 1995,” àti “Àwọn Kókó Pàtàkì Nípa Títún Beteli Ṣe àti Ilé Kíkọ́ ní Brooklyn”—gbé àwọn kókó pàtàkì jáde nípa kíkọ́ àwọn ilé tí a yà sí mímọ́ náà àti rírà wọ́n pẹ̀lú títún wọn ṣe. Àwọn ọ̀rọ̀ náà darí àfiyèsí sórí ilé gbígbé tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ parí láìpẹ́ yìí, tí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan òṣìṣẹ́ Beteli ń gbé nísinsìnyí. Ilé tí ó ga ní 115 mítà yìí ní 90 Òpópónà Sands wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé ìtẹ̀wé.

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà fi ọ̀rọ̀ ìyàsímímọ́ tí Milton Henschel, ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society, sọ hàn. Ó tẹnu mọ́ àwọn àpẹẹrẹ ìṣáájú nínú Ìwé Mímọ́, fún yíya àwọn ilé tí a óò lò fún iṣẹ́ ìsìn Jehofa sí mímọ́. Lẹ́yìn orin kan, a mú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà wá sí òpin pẹ̀lú àdúrà láti ẹnu Carey Barber, tí òun pẹ̀lú jẹ́ mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Ṣùgbọ́n kí ni díẹ̀ lára àwọn kókó ìtẹnumọ́ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà?

Àwọn Ilé Tí A Yà Sí Mímọ́

Alábòójútó Ilé Beteli, George Couch, ṣàlàyé pé a ti fi ilé gbígbé 17 kún àwọn tí a ní tẹ́lẹ̀, láti ìgbà ìyàsímímọ́ ilé gbígbé Beteli ní Brooklyn ní May 2, 1969.a Àwọn wọ̀nyí jẹ́ yálà ilé tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ tàbí ilé tí a rà, tí a sì tún ṣe. Ìyàsímímọ́ yìí ní ti gidi jẹ́ ti ilé gbígbé 17 wọ̀nyí, ilé kékeré méjì—tí a rà ní àwọn ọdún 1940, ṣùgbọ́n tí a sọ di ilé gbígbé Beteli—àti ilé iṣẹ́ àti ilé ọ́fíìsì tí a kọ́ tàbí tí a rà láti ìgbà ìyàsímímọ́ olú ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní March 15, 1982.b

Èyí tí ó tóbi jù lọ nínú àwọn ilé tí a yà sí mímọ́ náà ni èyí tí ó wà ní 360 Òpópónà Furman. Ọdún 1928 gan-an ni a kọ́ ọ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa rà á ní March 15, 1983, wọ́n sì tún un ṣe látòkèdélẹ̀. Ilẹ̀ rẹ̀ jẹ́ 93,000 mítà níbùú lóòró, tàbí kí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó hẹ́kítà mẹ́sàn-án. Àwọn ilé mìíràn tí a tún yà sí mímọ́ ní ilé iṣẹ́ tí ó wà ní 175 Òpópónà Pearl àti ibi ìtọ́kọ̀ṣe ńlá tí a kọ́ ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí.

Èé Ṣe Tí A Fi Nílò Ilé Púpọ̀ Sí I

Ní 1969, nígbà tí a ṣe ìyàsímímọ́ ilé gbígbé tí a kọ́ kẹ́yìn ní Beteli Brooklyn, 1,336,112 ni iye àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun káàkiri àgbáyé. Ṣùgbọ́n ní 1995, 5,199,895 ní ń ṣe bẹ́ẹ̀, iye tí ó ti ju ìlọ́po mẹ́ta àti ààbọ̀ ti tẹ́lẹ̀ lọ gan-an! Nípa báyìí, láti lè pèsè àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli púpọ̀ sí i tí a ń béèrè fún, ìdílé Beteli ti Brooklyn lọ sókè láti 1,042 àwọn tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà gan-an ní 1969 sí iye tí ó lé ní 3,360, tí ń gbé ní ilé gbígbé 22 nísinsìnyí!

George Couch jíròrò bí a ṣe kojú àìní fún àfikún ilé ní 1974 sí 1995. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, ọ̀pọ̀ àjà inú Hòtẹ́ẹ̀lì Towers tí ó wà nítòsí ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa háyà kí ìdílé Beteli tí ń ga sókè lè ríbi gbé. Ní December 1973, Nathan Knorr, ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, kọ̀wé sí Ọ́fíìsì Beteli àti àwọn olùṣekòkáárí Towers, ní sísọ pé Society ń wéwèé láti ‘ṣí kúrò ní Hòtẹ́ẹ̀lì Towers ní October 1, 1974.’

Arákùnrin Couch sọ pé ẹnu ya òun, nítorí pé, kò sí ibi tí a óò kó àwọn òṣìṣẹ́ Beteli tí ń gbé ní Towers sí. Ẹnu ya àwọn olùṣekòkáárí Towers pẹ̀lú, níwọ̀n bí wọ́n ti gbára lé owó ilé tí Society ń san láti máa fi gbọ́ bùkátà wọn. Àbájáde rẹ̀ ni pé àwọn olùṣekòkáárí Towers rọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láti ra hòtẹ́ẹ̀lì náà. Wọ́n wí pé: “Láti ìgbà tí a ti jọ jẹ́ aládùúgbò ni ẹ ti ń gbòòrò sí i, ẹ sì nílò ilé náà.”

Àwọn aṣojú Society fèsì pé: “Àwọn ayálégbé kún ibẹ̀. Bí a bá rà á, àwa yóò fẹ́ láti fi àwọn ènìyàn tiwa sínú rẹ̀.”

Àwọn olùṣekòkáárí Towers ṣèlérí pé: “A óò kó àwọn ayálégbé náà lọ sí ibòmíràn nítorí yín.” Kí a má fa ọ̀rọ̀ gùn, kété lẹ́yìn náà àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ra ilé Towers ní iye tí ó yẹ wẹ́kú. Couch béèrè lọ́wọ́ àwùjọ tí a ti ru ìfẹ́-ọkàn wọn sókè pé: “Èé ṣe tí Arákùnrin Knorr fi kọ lẹ́tà yẹn? Bóyá ni òun fúnra rẹ̀ fi mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ohun tí ó fa títa Hòtẹ́ẹ̀lì Towers fun Watch Tower Society nìyẹn.”

Olùbánisọ̀rọ̀ náà tún ṣàpèjúwe bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe ra 97 Columbia Heights, ibi tí Hòtẹ́ẹ̀lì Margaret lílókìkí nì wà tẹ́lẹ̀, gẹ́rẹ́ ní òdì kejì òpópónà tí ó wá láti Ilé Beteli gan-an. Ọ̀gangan náà dára púpọ̀, níwọ̀n bí a ti lè so ó pọ̀ mọ́ ilé Beteli nípasẹ̀ ojú ọ̀nà abẹ́lẹ̀. Ní February 1980, nígbà tí wọ́n ń tún ilé náà ṣe lọ́wọ́, ó jóná ráúráú. Lẹ́yìn náà, nítorí pé onílé náà ní ìṣòro kíkọ́ ilé tuntun sórí ilẹ̀ náà, ó tà á fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.

Arákùnrin Couch sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ilé wọ̀nyí ni wọ́n ní ìtàn fífani lọ́kàn mọ́ra tí yóò tọ́ka sí ohun kan—pé Jehofa Ọlọrun ni ẹni náà tí ń darí ètò àjọ rẹ̀ tí a lè fojú rí, láti lè rí ilé yẹn gan-an.”

Ìtàn Tí Ó Tan Mọ́ Ilé Tí Ó Wà Ní 90 Òpópónà Sands

Ilé gbígbé tuntun, tí ó sì tóbi jù lọ ni ti 90 Òpópónà Sands. Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ra ilé náà ní December 1986, wọ́n kọ́ ilé iṣẹ́ ńlá kan tí ó wà ní 160 Òpópónà Jay sínú rẹ̀.c A wó ilé iṣẹ́ náà palẹ̀, nígbà tí ó sì di August 30, 1990, a fi tó ìdílé Beteli létí pé, a ti gba àṣẹ láti kọ́ ilé gbígbé alájà 30 sí orí ilẹ̀ náà.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, Theodore Jaracz darí, alábòójútó ilé iṣẹ́ Society ní Brooklyn, Max Larson, ṣàpèjúwe bí a ṣe gba ìyọ̀ọ̀da láti kọ́ ilé gbígbé tí ó wà ní 90 Òpópónà Sands. Arákùnrin Larson ṣàlàyé pé, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní 1965 kò rọrùn.

Nígbà yẹn, Society fẹ́ kọ́ ilé iṣẹ́ alájà mẹ́wàá sórí ilẹ̀ kan tí ó wà nítòsí àwọn ilé iṣẹ́ rẹ̀ míràn, ṣùgbọ́n ìṣètò ilé kíkọ́ agbègbè náà fàyè gba kìkì ilé alájà méjì. Olùyàwòrán ilé kan ṣe tán láti yàwòrán ilé fun ilé iṣẹ́ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbèrò láti kọ́ náà, ṣùgbọ́n ó wí pé: “Èmi kì yóò dójú ti ara mi nípa gbígbé e kalẹ̀ fún àjọ náà.” Ó dá a lójú pé, Àjọ Ìdíwọ̀n Ilé Kíkọ́ àti Ìpẹjọ́ Kọ̀tẹ́milọ́rùn kì yóò yí òfin wọn lórí ìṣètò ilé kíkọ́ ní àdúgbò náà padà láé. Nígbà tí wọ́n fọwọ́ sí àwòrán ilé náà, ó sọ pé: “Báwo gan-an ni ẹ ṣe rí ìyẹn gbà!”

Larson ń bá a nìṣó pé, ìdí náà ni pé, nígbà tí a gbé ètò míràn kalẹ̀ fún ilé kíkọ́ ní àdúgbò yẹn nítorí ilé iṣẹ́ wa alájà mẹ́wàá, a gbé ètò míràn kalẹ̀ fún àwọn ilé tí ó wà nítòsí pẹ̀lú, títí kan èyí tí ó wà ní 160 Òpópónà Jay. Ó yani lẹ́nu pé, ètò àtúnṣe náà fàyè gba hòtẹ́ẹ̀lì kan. Ṣùgbọ́n, Larson sọ pé, ó jẹ́ ohun kan tí kò sí ẹnikẹ́ni tí ó kíyè sí i—ó kéré tán títí di ọdún 25 lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí a bẹ̀rẹ̀ sí í wá ilẹ̀ míràn láti kọ́ ilé Beteli tuntun. Ìgbà náà ni a ṣẹ̀ṣẹ̀ tún rí òfin tuntun fún ètò ilé kíkọ́ náà!

Arákùnrin Larson ṣàlàyé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ pé: “Nígbà tí a ya àwòrán ilé gbígbé wa alájà 30, tí a sì mú un lọ sí ẹ̀ka ìkọ́lé, a sọ fún wa pé: ‘Ẹ kò lè kọ́ ilé gbígbé sí ibẹ̀ yẹn. Ilé iṣẹ́ ní ibẹ̀ yẹ́n wà fún, wọn kò sì lè yí ètò ilé kíkọ́ rẹ̀ padà nítorí yín.’

A sọ fún àwọn ọ̀gá náà pé: “‘Wọ́n kò ní láti yí i padà. Wọ́n ti pín in fún hòtẹ́ẹ̀lì tẹ́lẹ̀.’ Nígbà tí wọ́n yẹ àkọsílẹ̀ náà wò, ó yà wọ́n lẹ́nu!” Larson parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Tóò, bí a ṣe parí ọ̀rọ̀ lórí ilé wa alájà 30 nìyẹn o.”

Ìbùkún Jehofa Fara Hàn

Onipsalmu kan nínú Bibeli kọ̀wé pé: “Bí kò ṣe pé Oluwa bá kọ́ ilé náà, àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán.” (Orin Dafidi 127:1) Ní kedere, ìbùkún Jehofa ti wà lórí ìgbòkègbodò ìkọ́lé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láti túbọ̀ mú kí iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni káàkiri àgbáyé tí Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣe rọrùn sí i.—Matteu 24:14; 28:19, 20.

Àwọn tí wọ́n ní àǹfààní láti gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní September 18, 1995, ni a ru sókè nígbà tí wọ́n rí irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ lórí ìmúgbòòrò ní olú ilé iṣẹ́ àgbáyé ti àwọn ìránṣẹ́ Jehofa. Àwọn ènìyàn Jehofa lè ní ìgbọ́kànlé pé, ìbùkún rẹ̀ yóò máa wà lórí wọn, bí wọ́n ṣe ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó pàṣẹ.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ilé-Ìṣọ́nà, June 15, 1969 (Gẹ̀ẹ́sì), ojú ìwé 379 sí 382.

b Ilé-Ìṣọ́nà, December 1, 1982, ojú ìwé 23 sí 31.

c Jí!, June 22, 1988, ojú ìwé 16 sí 18.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

90 Òpópónà Sands • 1995

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Díẹ̀ lára àwọn àfikún ilé gbígbé tí a yà sí mímọ́

97 Columbia Hts. • 1986

Hòtẹ́ẹ̀lì Bossert, 98 Òpópónà Montague • 1983

34 Òpópónà Orange • 1945

Hòtẹ́ẹ̀li̇̀ Standish, 169 Columbia Hts. • 1981

67 Òpópónà Livingston • 1989

108 Òpópónà Joralemon • 1988

Hòtẹ́ẹ̀li̇̀ Towers, 79-99 Òpópónà Willow • 1975

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

175 Òpópónà Pearl • 1983

69 Òpópónà Adams • 1991

360 Òpópónà Furman • 1983

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́