ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 8/15 ojú ìwé 22-26
  • “Òkìtì Ẹ̀rí” ní Ilẹ̀ “Òkè Ọlọ́run”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Òkìtì Ẹ̀rí” ní Ilẹ̀ “Òkè Ọlọ́run”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Ṣe Nípasẹ̀ Ọkọ̀ Òbèlè, Bọ́ọ̀sì Kékeré, Tàbí Kẹ̀kẹ́ Ológeere?
  • Nínú Lọ́hùn-únlọ́hùn-ún
  • Jìnnà Réré Níhà Àríwá
  • Jíjẹ́rìí ní Àwọn Ìlú Ńlá
  • Wíwéwèé Ìbẹ̀wò Kan Kẹ̀?
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 8/15 ojú ìwé 22-26

“Òkìtì Ẹ̀rí” ní Ilẹ̀ “Òkè Ọlọ́run”

LÓRÍ àwòrán ilẹ̀ ti kọ́ńtínẹ́ǹtì, bí o bá tọ ìlà bèbè etíkun Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, tí o sì forí lé ìlà oòrùn ní ojú ọ̀nà síbi Ìyawọlẹ̀ Omi Guinea, ní ọ̀gangan ibi tí etíkun náà ti ṣẹ́rí sí gúúsù, ìwọ yóò rí Cameroon. Bí o bá ń tọ etíkun lọ sí ìsàlẹ̀ níhà gúúsù, ìwọ yóò dé etíkun oníyanrìn dúdú tí ó lọ salalu. Yanrìn dúdú náà jẹ́ iṣẹ́ ìbújáde Òkè Cameroon.

Orí òkè ńlá onímítà 4,070, onírìísí òkòtó yìí gba agbègbè náà kan. Nígbà tí oòrùn ọjọ́rọ̀ bá tan ìmọ́lẹ̀ sára gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Cameroon, ó máa ń ní àwọn àwọ̀ àrímáleèlọ títàn yòò—àwọ̀ èsè àlùkò, àwọ̀ òrom̀bó, àwọ̀ wúrà, àti àwọ̀ pípọ́n roro. Òkun àti àwọn irà tí ó wà nítòsí ṣàgbéyọ gbogbo àwọn àwọ̀ wọ̀nyí bíi ti dígí, ní mímú kí ó dà bíi pé òfuurufú àti ilẹ̀ ayé fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́. Ó rọrùn láti lóye ìdí tí àwọn ẹ̀yà ìbílẹ̀ tí ń bọ imọlẹ̀ ní ẹkùn náà fi sọ òkè náà ní Mongo Ma Loba, tí ó túmọ̀ sí “Kẹ̀kẹ́ ẹṣin àwọn ọlọ́run,” tàbí lọ́nà tí ó túbọ̀ wọ́pọ̀, “Òkè Ọlọ́run.”

Jìnnà réré níhà gúúsù, ọ̀pọ̀ ibùsọ̀ etíkun oníyanrìn funfun, tí a gbin igi àgbọn sí lọ rẹrẹ níbẹ̀. Yàtọ̀ sí ìlà bèbè etíkun tí ń fani mọ́ra, orílẹ̀-èdè náà kún fún igbó ẹgàn dídí fọ́fọ́ ti ìlà agbede méjì ìbú ayé, tí ó lọ títí dé ààlà Kóńgò àti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Àárín Gbùngbùn Áfíríkà àti àríwá dé Nàìjíríà àti ìhà gúúsù Áfíríkà ti Sàhárà ní Ṣáàdì. Ìhà ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè náà jẹ́ olókè, ní rírán arìnrìn àjò létí nípa àwọn apá ibì kan ní Europe. Ṣùgbọ́n, ipò ojú ọjọ́ tí ó móoru, kì yóò jẹ́ kí o gbàgbé pé ìwọ kò jìnnà sí ìlà agbede méjì ìbú ayé. Bí àwọn agbègbè àrọko rẹ̀ ṣe yàtọ̀ síra mú kí ọ̀pọ̀ olùmúni rìnrìn àjò ṣàpèjúwe Cameroon gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kékeré kan nípa ìrísí Áfíríkà. Àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ ẹ̀yà ìran ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti èyí tí ó ju 220 èdè gbogbogbòò àti èdè àdúgbò tí ó wà nínú àkọsílẹ̀ túbọ̀ fún èrò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn yìí lágbára.

Bí o bá ní láti ṣe ìbẹ̀wò sí Cameroon, o lè wọ̀ sí ọ̀kan nínú àwọn hòtẹ́ẹ̀lì ńláńlá tí ó wà ní èbúté òkun ní Douala, tàbí ní olú ìlú orílẹ̀-èdè náà, Yaoundé. Ṣùgbọ́n o lè pàdánù àǹfààní mímọ ohun kan nípa ìgbésí ayé àwọn ènìyàn náà, ní pàtàkì, nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó ju 24,000, tí ọwọ́ wọ́n di lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú kíkọ́ “òkìtì ẹ̀rí” jákèjádò ilẹ̀ “Òkè Ọlọ́run”a yìí. Èé ṣe tí o kò fi rìnrìn àjò la inú orílẹ̀-èdè náà kọjá láti fojú gán-án-ní díẹ̀ lára wọn? Dájúdájú, a óò san èrè jìngbìnnì fún àwárí rẹ nípa ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà yìí.

Ṣe Nípasẹ̀ Ọkọ̀ Òbèlè, Bọ́ọ̀sì Kékeré, Tàbí Kẹ̀kẹ́ Ológeere?

Sanaga, odò tí ó gùn jù lọ ní Cameroon, pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ níbi tí ó gbà wọnú òkun. Láti dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí ń gbé ẹkùn gbígbòòrò yìí, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní láti rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ òbèlè. Èyí ni ohun tí àwọn akéde Ìjọba mẹ́sàn-án tí ń bẹ̀ nínú àwùjọ kékeré ní Mbiako ṣe. Méjì lára wọn ń gbé ní abúlé Yoyo, tí ó jìnnà tó kìlómítà 25. Kí wọ́n baà lè dé Mbiako, ó ń béèrè pé kí wọ́n tukọ̀ àtùlamilójú, síbẹ̀, wọ́n máa ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni nígbà gbogbo. Nígbà tí alábòójútó arìnrìn àjò kan ń bẹ àwùjọ yìí wò, ó dábàá fífi fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name hàn. Ṣùgbọ́n, ẹnú dùn-ún ròfọ́ lọ̀rọ̀ náà. Ní abúlé tí ó jìnnà réré bẹ́ẹ̀, níbo ni yóò ti rí ẹ̀rọ fídíò, tẹlifíṣọ̀n, àti iná mànàmáná tí yóò mú wọn ṣiṣẹ́?

Láàárín ọ̀sẹ̀ ìbẹ̀wò náà, àwọn akéde díẹ̀ kàn sí pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò. Sí ìyàlẹ́nu wọn, pásítọ̀ náà gbà wọ́n tọ̀yàyàtọ̀yàyà, wọ́n sì ní ìjíròrò Bíbélì tí ń wúni lórí pẹ̀lú rẹ̀. Ní kíkíyè sí i pé kì í ṣe kìkì pé pásítọ̀ náà ní ẹ̀rọ fídíò nìkan ni, ṣùgbọ́n, ó tún ní ẹ̀rọ iná mànàmáná, àwọn arákùnrin náà lo ìgboyà láti béèrè bí wọ́n bá lè yá ohun èlò rẹ̀. Níwọ̀n bí ó ti gbádùn ìjíròrò Bíbélì ṣáájú, pásítọ̀ náà gbà láti ṣèrànwọ́. Ní ìrọ̀lẹ́ Saturday, ènìyàn 102 títí kan pásítọ̀ náà àti ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ wá sí ibi tí a ti fi fídíò hàn náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì náà láti Yoyo fi ọkọ̀ òbèlè méjì kó àwọn olùfìfẹ́hàn mélòó kan wá. Ìṣòro àtitukọ̀ ní ìdojúkọ ìṣàn ìrugùdù omi tí ń tètè ga sókè náà kò jọ wọ́n lójú rárá. Lẹ́yìn tí wọ́n ti wo fídíò náà tán, a ru wọ́n sókè, a sì fún wọn níṣìírí, wọ́n sì láyọ̀ láti jẹ́ apá kan ètò àjọ ńlá bẹ́ẹ̀ tí ète rẹ̀ jẹ́ láti bọlá fún Jèhófà.

Láti lọ síbi tí ọkọ̀ òbèlè kò lè dé, ó ṣeé ṣe láti lo bọ́ọ̀sì kékeré. Àwọn ènìyàn máa ń rọ́ wìtìwìtì ní agbègbè tí àwọn bọ́ọ̀sì wọ̀nyí ti máa ń dúró de àwọn èrò ọkọ̀. Ó rọrùn kí ènìyàn máà mọ èwo-ni-ṣíṣe láàárín àwọn tí ń ta omi tútù, àwọn tí ń ta ọ̀gẹ̀dẹ̀, àti àwọn agbèrò. Iṣẹ́ àwọn agbèrò ni láti wá àwọn èrò ọkọ̀ sínú àwọn bọ́ọ̀sì tí ń dúró náà, tí ó jẹ́ pé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti máa ń sọ, gbogbo wọ́n “ti ṣe tán láti ṣí.” Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán ni “ti ṣe tán” jẹ́. Àwọn arìnrìn àjò máa ń dúró fún ọ̀pọ̀ wákàtí, àní ọ̀pọ̀ ọjọ́ nígbà míràn. Gbàrà tí a bá ti to àwọn èrò sínú ọkọ̀ lọ́nà híhá gádígádí, tí awakọ̀ sì ti to àwọn ẹrù, àwọn àpò oúnjẹ, àti nígbà míràn, àwọn ààyè adìyẹ àti ewúrẹ́ pàápàá sórí irin orí ọkọ̀, bọ́ọ̀sì kékeré náà yóò bọ́ sọ́nà gbágungbàgun, eléruku.

Nígbà tí irú ọ̀nà ìrìn àjò yìí sú òjíṣẹ́ arìnrìn àjò kan, ó gbòmìnira fún ara rẹ̀. Wàyí o, kẹ̀kẹ́ ológeere ni ó fi ń rin gbogbo ìrìn àjò rẹ̀. Ó sọ pé: “Láti ìgbà tí mo ti pinnu láti máa lo kẹ̀kẹ́ ológeere láti rìnrìn àjò láti ìjọ dé ìjọ, mo máa ń débẹ̀ lákòókò fún ìbẹ̀wò náà. Ní tòótọ́, ìrìn àjò náà lè gba ọ̀pọ̀ wákàtí, ṣùgbọ́n, ó ṣe kò ṣe, n kò ní láti lo ọjọ́ kan tàbí méjì ní dídúró fún bọ́ọ̀sì kékeré. Nígbà òjò, àwọn ojú ọ̀nà kan máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ bàjẹ́ tán pátápátá nítorí ọ̀gbàrá. O ní láti bọ́ bàtà rẹ kí o tó lè kọjá nínú ẹrẹ̀ àti omi wọ̀nyí. Lọ́jọ́ kan, ọ̀kan nínú bàtà mí já sínú odò, n kò sì rí i títí di ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ lẹ́yìn náà, nígbà tí ọmọbìnrin ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí ṣèèṣì rí i nígbà tí ó ń pẹja! Mo láyọ̀ pé mo tún lè wọ bàtà yìí lẹ́ẹ̀kan sí i, lẹ́yìn tí ọ̀kan lára rẹ̀ ti lọ lo àsìkò díẹ̀ lọ́dọ̀ ẹja. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo máa ń lọ sí àwọn agbègbè tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò tí ì wàásù rí. Àwọn ará abúlé sábà máa ń bi mí pé kí ni mo mú wá. Nítorí náà, mo máa ń kó ìwé ìròyìn àti ìwé pẹlẹbẹ dání. Nígbà kọ̀ọ̀kan tí mo bá ti dúró, mo máa ń fi àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì wọ̀nyí lọni, mo sì ń jẹ́rìí ní ṣókí. Mo gbà gbọ́ pé Jèhófà yóò mú kí àwọn èso òtítọ́ wọ̀nyí dàgbà.”

Nínú Lọ́hùn-únlọ́hùn-ún

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sakun láti ṣàjọpín ìhìn rere Ìjọba náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, àní nínú lọ́hùn-ún láàárín Cameroon, nínú àwọn abúlé tí wọ́n fara sin nínú igbó ẹgàn jíjìnnà réré. Èyí ń béèrè fún ìsapá púpọ̀ gan-an, ṣùgbọ́n àbájáde rẹ̀ ń múni lọ́kàn yọ̀.

Marie, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan, bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ọmọdébìnrin kan tí ń jẹ́ Arlette. Ní òpin ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́, Marie béèrè lọ́wọ́ Arlette bí yóò bá sin òun dé ẹnu ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn ní apá Áfíríkà yìí. Ṣùgbọ́n, ọmọdébìnrin náà ṣàlàyé pé agbára káká ni òún fi ń rìn nítorí ẹsẹ̀ tí ń dun òun. Kòkòrò kan tí abo rẹ̀ máa ń wọnú ẹran ara, tí yóò sì mú kí ibẹ̀ ní ọyún, ti wọ Arlette lẹ́sẹ̀. Marie fi ìgboyà yọ àwọn kòkòrò náà kúrò lọ́kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, ó tún wá mọ̀ pé àwọn ẹ̀mí èṣù máa ń da ọmọdébìnrin yìí láàmú lóru. Marie fi sùúrù ṣàlàyé bí ẹnì kan ṣe lè fi ìgbọ́kànlé rẹ̀ sínú Jèhófà, ní pàtàkì, nípa pípe orúkọ rẹ̀ sókè nínú àdúrà.—Òwe 18:10.

Arlette, tẹ̀ síwájú lọ́nà yíyára kánkán. Lákọ̀ọ́kọ́, ìdílé rẹ̀ kò rí ohun tí ó burú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nítorí ìtẹ̀síwájú tí ń gbàfiyèsí tí ó ń ní nípa ti ìrísí ara àti ní ti ọgbọ́n orí. Ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n mọ̀ pé ó fẹ́ di ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n kà á léèwọ̀ fún un láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ nìṣó. Ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn náà, nígbà tí ìyá Arlette rí bí ọmọbìnrin rẹ̀ ti sorí kọ́ tó, ó kàn sí Marie, ó sì sọ fún un láti padà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.

Nígbà tí àkókò tó láti lọ sí àpéjọ àyíká, Marie sanwó fún awakọ̀ kan láti gbé Arlette lọ ní ọjọ́ méjèèjì. Ṣùgbọ́n, awakọ̀ náà kọ̀ láti wakọ̀ délé Arlette níwọ̀n bí ó ti mọ̀ dájú pé ọ̀nà tí ó lọ síbẹ̀ kò ṣeé gbà. Nítorí náà, Marie dọ́gbọ́n gbé ọmọbìnrin náà wá sí ojú ọ̀nà. Dájúdájú, Jèhófà bù kún ìsapá yìí. Lónìí, Arlette ń lọ sí gbogbo ìpàdé ìjọ. Láti ràn án lọ́wọ́ láti ṣe èyí, Marie kò káàárẹ̀ láti máa wá mú un. Wọ́n jọ máa ń rin ìrìn ìṣẹ́jú 75 ní àlọ tàbí ní àbọ̀. Níwọ̀n bí ìpàdé Sunday ti máa ń bẹ̀rẹ̀ ní agogo 8:30 òwúrọ̀, Marie ní láti kúrò nílé ní agogo 6:30; síbẹ̀ wọ́n ń gbìyànjú láti dé lákòókò. Arlette ń fojú sọ́nà láìpẹ́ láti fi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ rẹ̀ hàn nípasẹ̀ batisí nínú omi. Marie sọ pé: “Ẹni tí kò bá rí i nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ kò lè ronú wòye bí ó ti ṣe yí padà tó. Mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà fún ọ̀nà tí ó ti gbà bù kú un.” Dájúdájú, Marie jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà ti ìfẹ́ onífara-ẹni-rúbọ.

Jìnnà Réré Níhà Àríwá

Àríwá Cameroon kún fún ìyàtọ̀ àti ìyàlẹ́nu. Nígbà òjò, ó máa ń di ọgbà ńlá, tí ó tutù yọ̀yọ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn tí ń mú ganrínganrín bá bẹ̀rẹ̀, àwọn koríko náà máa ń rọ dànù. Ní ọ̀sán, nígbà tí oòrùn bá kan àtàrí, tí ó sì ṣòro láti rí ìbòji, àwọn àgùntàn máa ń fún ara wọn mọ ará ògiri ilé aláfọwọ́mọ. Láàárín yanrìn àti koríko gbígbẹ, kìkì ohun aláwọ̀ ewéko tí ojú lè rí ni àwọn ewé igi oṣè mélòó kan. Àní bí ìwọ̀nyí kò tilẹ̀ tóbi bí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn ní igbó ẹgàn ìlà agbede méjì ìbú ayé, wọ́n jọ lágbára bákan náà ni. Agbára wọn láti fara da àyíká ipò líle koko ṣàkàwé ìtara àti ìgboyà ìwọ̀nba àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ti lọ láti gbé ni ẹkùn yìí dáradára kí wọ́n baà lè jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ máa tàn.

Díẹ̀ nínú àwọn ìjọ ní agbègbè yìí jìnnà síra ní kìlómítà 500 sí 800, wọ́n sì ń nímọ̀lára ìdánìkanwà ní ti gidi. Ṣùgbọ́n, ọkàn-ìfẹ́ púpọ̀ wà. Àwọn Ẹlẹ́rìí láti àwọn agbègbè míràn wá síhìn-ín láti ṣèrànwọ́. Láti gbéṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, wọ́n ní láti kọ́ èdè Foufouldé, èdè àdúgbò kan.

Ẹlẹ́rìí kan láti Garoua pinnu láti lo ọjọ́ díẹ̀ ní wíwàásù ní abúlé ìbílẹ̀ rẹ̀, tí ó jìnnà tó nǹkan bíi 160 kìlómítà. Ó rí ọkàn-ìfẹ́ díẹ̀, ṣùgbọ́n owó ọkọ̀ tí ó ga kò jẹ́ kí ó lè máa padà lọ déédéé. Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà, Ẹlẹ́rìí náà gba lẹ́tà kan láti ọ̀dọ̀ ọ̀kan nínú àwọn olùfìfẹ́hàn náà tí ń bẹ̀ ẹ́ láti wá kí ó sì ṣèbẹ̀wò lẹ́ẹ̀kan sí i. Bí kò ti ní owó ọkọ̀ síbẹ̀, kò ṣeé ṣe fún un láti lọ. Ẹ wo bí ẹnú ti ya Ẹlẹ́rìí náà tó nígbà ti ẹni náà ṣèbẹ̀wò sí ilé rẹ̀ ní Garoua láti sọ fún un pé ènìyàn mẹ́wàá ní abúlé náà ń wọ̀nà fún ìbẹ̀wò rẹ̀!

Ní abúlé mìíràn, nítòsí ààlà ẹnubodè Ṣáàdì, àwùjọ kan tí ó ní 50 olùfìfẹ́hàn nínú ti ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tiwọn. Wọ́n ṣètò fún mẹ́ta nínú wọn láti lọ sí àwọn ìpàdé ní ìjọ tí ó wà nítòsí ní Ṣáàdì. Nígbà tí wọ́n bá padà dé, àwọn wọ̀nyí yóò wá darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú gbogbo àwùjọ náà. Ní tòótọ́, ọ̀rọ̀ Jésù ṣeé fi sílò dáradára níhìn-ín pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ̀nba díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.”—Mátíù 9:37, 38.

Jíjẹ́rìí ní Àwọn Ìlú Ńlá

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún àìtó ìwé ìròyìn, ní nǹkan bí ọdún méjì sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ti wá pọ̀ yanturu ní Cameroon. Ìtara ọkàn àti ọkàn-ìfẹ́ ti wá pọ̀ gan-an fún ìwé ìròyìn wọ̀nyí bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti ń kà wọ́n fún ìgbà àkọ́kọ́. Tọkọtaya ọ̀dọ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kan tí a yàn sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ńlá náà fi ìwé ìròyìn 86 sóde ní ọjọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ wàásù ní òwúrọ̀ ní ìpínlẹ̀ wọn tuntun. Àwọn akéde kan fi àwọn ìwé ìròyìn tí ó tó 250 sóde nínú oṣù kan ṣoṣo! Kí ni àṣírí àṣeyọrí wọn? Fi ìwé ìròyìn lọ ẹni gbogbo.

Ẹlẹ́rìí kan tí ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì kan tí gbogbogbòò máa ń ṣèbẹ̀wò sí sábà máa ń kó ìwé ìròyìn síbi tí gbogbo ènìyàn ti lè rí i. Obìnrin kan wo àwọn ìwé ìròyìn náà ṣùgbọ́n kò mú èyíkéyìí nínú wọn. Ẹlẹ́rìí náà fi òye mọ ọkàn-ìfẹ́ rẹ̀, ó sì fi ẹ̀dà kan lọ̀ ọ́, èyí tí òún tẹ́wọ́ gbà. Ó yà á lẹ́nu láti rí i pé ó padà wá ní ọjọ́ kejì. Kì í ṣe kìkì pé ó fẹ́ ṣètọrẹ fún ìwé ìròyìn tí ó ti gbà nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún béèrè fún òmíràn sí i. Èé ṣe? Níwọ̀n bí a ti fipá bá a lòpọ̀ rí, ó yan ìwé ìròyìn tí ó sọ̀rọ̀ nípa kókó ẹ̀kọ́ yẹn. Ó ti lo gbogbo òru fún ṣíṣe àkàtúnkà ìmọ̀ràn tí a fúnni. Níwọ̀n bí ara ti tù ú lọ́pọ̀lọpọ̀, ó ń fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àwọn ọmọ kékeré pàápàá lè ṣàjọpín nínú títan ìhìn iṣẹ́ Bíbélì tí ń fúnni ní ìrètí kálẹ̀. Nígbà tí olùkọ́ tí ń kọ́ Ẹlẹ́rìí kan, ọmọdébìnrin ọlọ́dún mẹ́fà, sọ pé kí ó kọ orin ìsìn Kátólíìkì kan, ó kọ̀ jálẹ̀, ní sísọ pé òún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà náà, olùkọ́ náà sọ fún un pé kí ó kọ ọ̀kan nínú àwọn orin ìsìn tirẹ̀, kí òún baà lè lò ó láti fún un ní máàkì. Ó yan orin tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ileri Ọlọrun fun Paradise,” ó sì kọ ọ́ láìgbéwèé lọ́wọ́. Olùkọ́ náà bi í léèrè pé: “O mẹ́nu kan párádísè kan nínú orin rẹ. Níbo ni párádísè yìí wà?” Ọmọdébìnrin náà ṣàlàyé ète Ọlọ́run láti fìdí Párádísè múlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé láìpẹ́. Nítorí tí ìdáhùn rẹ̀ yà á lẹ́nu, ó béèrè ìwé tí ọmọdébìnrin náà fi ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀. Ó fẹ́ lo èyí láti fún un ní máàkì dípò ohun tí ó ti kọ́ nígbà ẹ̀kọ́ nípa ìsìn. Àwọn òbí rẹ̀ sọ fún olùkọ́ náà pé bí ó bá fẹ̀ láti fún un ní máàkì tí ó tọ́, ó yẹ kí òun fúnra rẹ̀ kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan pẹ̀lú rẹ̀.

Wíwéwèé Ìbẹ̀wò Kan Kẹ̀?

Ní ọ̀pọ̀ ibi nínú ayé lónìí, àwọn ènìyàn máa ń dágunlá sí ìhìn rere Ìjọba náà. Wọn kò ní ọkàn-ìfẹ́ sí Ọlọ́run tàbí sí Bíbélì. Ìbẹ̀rù ti kó jìnnìjìnnì bá àwọn ẹlòmíràn, wọn a sì wulẹ̀ kọ̀ láti dáhùn padà sí àjèjì èyíkéyìí tí ó bá wá sí ẹnu ọ̀nà wọn. Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ ìpèníjà gidi fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Ṣùgbọ́n, ẹ wo bí èyí ṣe yàtọ̀ tó ní Cameroon!

Ìdùnnú ni wíwàásù láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà jẹ́ níhìn-ín. Dípò kíkan ilẹ̀kùn, ó jẹ́ àṣà láti sọ pé, “Kong, kong, kong.” Lẹ́yìn náà, ohùn kan láti inú ilé yóò sọ pé, “Ìwọ ta nì yẹn?” lẹ́yìn èyí tí a óò sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òbí yóò sọ pé kí àwọn ọmọ wọ́n gbé àga wá, wọn yóò sì gbé wọn sábẹ́ ìbòji igi kan, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ lábẹ́ igi máńgòrò. Lẹ́yìn náà, a óò lo àkókò lílárinrin ní ṣíṣàlàyé ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àti ohun tí yóò ṣe láti tú aráyé sílẹ̀ kúrò nínú ipò ègbé.

Kété lẹ́yìn irú ìjíròrò kan bẹ́ẹ̀, obìnrin kan sọ ti inú rẹ̀ jáde, ní sísọ pé: “Ó dùn mí láti rí i pé a kò lè rí òtítọ́ tí mo ti ń wá kiri nínú ìsìn tí a bí mi sí, tí mo sì dàgbà sí. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ó ti fi òtítọ́ hàn mí. Mo jẹ́ díákónì ní ṣọ́ọ̀ṣì mi. Ère Màríà Wúńdíá máa ń lo ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní ilé díákónì kọ̀ọ̀kan, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan baà lè tọrọ nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀. Ní tèmi, ìgbà gbogbo ni mo máa ń sọ fún Màríà pé kí ó ràn mí lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́. Wàyí o, Ọlọ́run ti fi hàn mí pé òtítọ́ náà kò sí lọ́dọ̀ rẹ̀. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà.”

Nítorí náà, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ní ọjọ́ kan, o nímọ̀lára àìní náà láti nírìírí ayọ̀ tí ènìyàn lè ní ní wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, èé ṣe tí o kò fi ṣèbẹ̀wò sí apá ibí yìí ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà? Yàtọ̀ sí ṣíṣàwárí “Áfíríkà níwọ̀nba,” bóyá nípasẹ̀ ọkọ̀ òbèlè, bọ́ọ̀sì kékeré, tàbí kẹ̀kẹ́ ológeere, ìwọ yóò tún máa fi kún “òkìtì ẹ̀rí” tí a ti ń kọ́ ní ilẹ̀ “Òkè Ọlọ́run.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Òkìtì Ẹ̀rí” ni ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù náà tí a túmọ̀ sí “Gílíádì.” Láti 1943, ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ti ń rán àwọn míṣọ́nnárì jáde láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù náà kárí ayé, títí kan Cameroon.

[Credit Line tó wà ní ojú ìwé 22]

Àwòrán ilẹ̀: Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́