Ojú Ìwòye Títọ́ Nípa Òmìnira
NÍWỌ̀N bí ó ti jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run ni Olódùmarè, Ọba Aláṣẹ Olùṣàkóso àgbáyé, àti Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, òun nìkan ṣoṣo ni ó ní òmìnira pátápátá, tí kò ní ààlà. (Jẹ́nẹ́sísì 17:1; Jeremáyà 10:7, 10; Dáníẹ́lì 4:34, 35; Ìṣípayá 4:11) Ohun gbogbo yòó kù gbọ́dọ̀ rìn, kí wọ́n sì gbégbèésẹ̀ láàárín ìwọ̀n agbára tí a fi fún wọn, kí wọ́n sì mú ara wọn wá sábẹ́ àwọn òfin àgbáyé rẹ̀. (Aísáyà 45:9; Róòmù 9:20, 21) Fún àpẹẹrẹ, gbé òòfà ilẹ̀, àti àwọn òfin tí ń darí àwọn ìyípadà oníkẹ́míkà, tí ń nípa lórí oòrùn, àti ìdàgbàsókè; àwọn òfin ìwà híhù; ẹ̀tọ́ àti ìgbésẹ̀ àwọn ẹlòmíràn, tí ń nípa lórí òmìnira ẹnì kan yẹ̀ wò. Nítorí náà, òmìnira gbogbo ìṣẹ̀dá Ọlọ́run jẹ́ òmìnira tí ó ní ààlà.
Ìyàtọ̀ wà láàárín òmìnira tí ó ní ààlà àti ìsìnrú. Òmìnira tí ó wà nínú àwọn ààlà tí Ọlọ́run là sílẹ̀ ń mú ayọ̀ wá; ìsìnrú fún àwọn ìṣẹ̀dá, fún àìpé, fún àìlera, tàbí fún àwọn èrò òdì, ń mú ìnilára àti ìbànújẹ́ wá. Ó tún yẹ kí a fi ìyàtọ̀ hàn láàárín òmìnira àti ìṣetinúẹni, ìyẹn ni pé, fífojútín-ínrín àwọn òfin Ọlọ́run, kí ènìyàn sì fúnra rẹ̀ pinnu ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Irú rẹ̀ ń ṣamọ̀nà sí rírakaka lé ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíràn, ó sì máa ń fa wàhálà, gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú àbájáde ẹ̀mí òmìnira, aṣetinúẹni tí Ejò náà fi lọ Ádámù àti Éfà nínú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́nẹ́sísì 3:4, 6, 11-19) Òfin ni ó ń darí òmìnira tòótọ́, òfin Ọlọ́run, tí ó yọ̀ǹda fún ẹnì kan láti lo òmìnira rẹ̀ lọ́nà tí ó yẹ, tí ó gbéni ró, tí ó sì ṣàǹfààní, tí ó sì bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíràn, ní fífikún ayọ̀ gbogbogbòò.—Orin Dáfídì 144:15; Lúùkù 11:28; Jákọ́bù 1:25.
Ọlọ́run Òmìnira
Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run òmìnira. Ó dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀ lómìnira kúrò nínú ìsìnrú ní Íjíbítì. Ó sọ fún wọn pé, níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ti ń ṣe ìgbọ́ràn sí àwọn òfin òun, wọn kì yóò ṣaláìní. (Diutarónómì 15:4, 5) Dáfídì sọ̀rọ̀ nípa “òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìdààmú” láàárín àwọn ilé ìṣọ́ ibùgbé Jerúsálẹ́mù. (Orin Dáfídì 122:6, 7, NW) Bí ó ti wù kí ó rí, Òfin yọ̀ǹda pé, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan di òtòṣì, ó lè ta ara rẹ̀ sínú oko ẹrú, kí ó baà lè pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. Ṣùgbọ́n Òfin náà dá Hébérù yí sílẹ̀ lómìnira ní ọdún keje ìsìnrú rẹ̀. (Ẹ́kísódù 21:2) Nígbà Júbílì (tí ń wáyé ní gbogbo àràádọ́ta ọdún), a máa ń pòkìkí òmìnira ní ilẹ̀ náà fún gbogbo olùgbé rẹ̀. A máa ń dá gbogbo ẹrú tí ó jẹ́ Hébérù sílẹ̀ lómìnira, olúkúlùkù yóò sì pa dà sí ilẹ̀ tí ó ti jogún.—Léfítíkù 25:10-19.
Òmìnira Tí Ó Wá Nípasẹ̀ Kristi
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ìjẹ́pàtàkì dídá ìran ènìyàn sílẹ̀ lómìnira kúrò nínú “ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́.” (Róòmù 8:21) Jésù Kristi sọ fún àwọn Júù tí ó gbà á gbọ́ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ óò sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” Fún àwọn tí wọ́n rò pé àwọn ní òmìnira nítorí pé wọ́n jẹ́ irú ọmọ Ábúráhámù nípa ti ara, ó fi yé wọn kedere pé, wọ́n jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ó sì sọ pé: “Nítorí náà bí Ọmọkùnrin bá dá yín sílẹ̀ lómìnira, ẹ óò di òmìnira ní ti gàsíkíá.”—Jòhánù 8:31-36; fi wé Róòmù 6:18, 22.
Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a ti sọ di òmìnira. Pọ́ọ̀lù fi hàn pé, wọn “kì í ṣe ọmọ ìránṣẹ́bìnrin, bí kò ṣe ti òmìnira obìnrin,” ẹni tí ó tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bíi “Jerúsálẹ́mù ti òkè.” (Gálátíà 4:26, 31) Lẹ́yìn náà, ó gbani níyànjú pé: “Fún irúfẹ́ òmìnira bẹ́ẹ̀ [tàbí, “Pẹ̀lú òmìnira rẹ̀,” àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé] ni Kristi dá wa sílẹ̀ lómìnira. Nítorí náà ẹ dúró ṣinṣin, ẹ má sì jẹ́ kí a tún há yín mọ́ inú àjàgà ìsìnrú.” (Gálátíà 5:1) Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn ènìyàn kan báyìí, tí wọ́n ń fi èké pe ara wọn ní Kristẹni, ti da ara wọn pọ̀ mọ́ àwọn ìjọ tí ó wà ní Gálátíà. Wọ́n ń sapá láti mú kí àwọn Kristẹni ní Gálátíà pàdánù òmìnira wọn nínú Kristi, nípa gbígbìyànjú láti jèrè òdodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ Òfin, dípò nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé, wọn yóò tipa bẹ́ẹ̀ yẹsẹ̀ kúrò nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Kristi.—Gálátíà 5:2-6; 6:12, 13.
Òmìnira tí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbádùn lọ́wọ́ ìsìnrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú àti lọ́wọ́ ìbẹ̀rù (“Nítorí tí Ọlọ́run kò fún wa ní ẹ̀mí ojo, bí kò ṣe ti agbára àti ti ìfẹ́ àti ti ìyèkooro èrò inú”) ni ó fara hàn kedere nínú àìfọ̀rọ̀bọpobọyọ̀ àti òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ti àwọn àpọ́sítélì nínú pípolongo ìhìn rere. (2 Tímótì 1:7; Ìṣe 4:13; Fílípì 1:18-20) Wọ́n ka òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ nípa Kristi yìí sí ohun ìní ṣíṣeyebíye, ọ̀kan tí a gbọ́dọ̀ mú dàgbà, dáàbò bò, kí a sì pa mọ́, kí a baà lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run. Ó tún jẹ́ kókó kan tí ó yẹ láti gbàdúrà lé lórí.—Tímótì Kíní 3:13; Hébérù 3:6; Éfésù 6:18-20.
Lílo Òmìnira Kristẹni Lọ́nà Yíyẹ
Àwọn Kristẹni òǹkọ̀wé tí a mí sí, ní mímọrírì ète Ọlọ́run ní nínawọ́ inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí jáde nípasẹ̀ Kristi (“Dájúdájú, òmìnira ni a pè yín fún, ẹ̀yin ará”), fún àwọn Kristẹni nímọ̀ràn lemọ́lemọ́ láti dáàbò bo òmìnira wọn, kí wọ́n má sì ṣi òmìnira yẹn lò, tàbí lò ó nílòkulò gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti lọ́wọ́ sí àwọn iṣẹ́ ti ara tàbí gẹ́gẹ́ bí ìbòjú fún ìwà búburú. (Gálátíà 5:13; Pétérù Kíní 2:16) Jákọ́bù sọ̀rọ̀ nípa ‘wíwo inú òfin pípé náà tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín’ ó sì fi yéni pé, ẹni tí kò di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, ṣùgbọ́n tí ó tẹpẹlẹ mọ́ ọn gẹ́gẹ́ bí olùṣe, ni yóò láyọ̀.—Jákọ́bù 1:25.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbádùn òmìnira tí ó jèrè nípasẹ̀ Kristi, ṣùgbọ́n, ó yẹra fún lílo òmìnira rẹ̀ láti tẹ́ ìfẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn tàbí fún lílò ó láti ṣèpalára fún àwọn ẹlòmíràn. Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí ìjọ tí ó wà ní Kọ́ríńtì, ó fi hàn pé, òun kì yóò pa ẹ̀rí ọkàn ẹlòmíràn lára nípa ṣíṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ fún un lómìnira láti ṣe, ṣùgbọ́n tí ẹnì kan tí ìmọ̀ rẹ̀ kò pọ̀ tó, tí ìwà Pọ́ọ̀lù lè ṣàkóbá fún ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, lè gbé ìbéèrè dìde sí. Ó fi jíjẹ ẹran tí a ti fi rúbọ níwájú òrìṣà ṣáájú kí a tó gbé e lọ sọ́jà láti tà, ṣe àpẹẹrẹ. Jíjẹ irú ẹran bẹ́ẹ̀ lè mú kí ẹni tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò lera ṣe lámèyítọ́ òmìnira ìgbésẹ̀ yíyẹ tí Pọ́ọ̀lù gbé, kí ó sì tipa báyìí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ Pọ́ọ̀lù, tí kì yóò sì tọ̀nà rárá. Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èé ṣe tí ó fi ní láti jẹ́ pé ẹ̀rí ọkàn ẹlòmíràn ní ń ṣèdájọ́ òmìnira mi? Bí mo bá ń fi ọpẹ́ ṣalábàápín, èé ṣe tí a óò fi máa sọ̀rọ̀ mi tèébútèébú lórí èyíinì tí mo ti dúpẹ́ fún?” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àpọ́sítélì náà pinnu láti lo òmìnira rẹ̀ ní ọ̀nà tí ń gbéni ró, kì í ṣe ni ọ̀nà tí ń ṣàkóbá fúnni.—Kọ́ríńtì Kíní 10:23-33.
Ìjàkadì Kristẹni àti Ìrètí Aráyé
Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ewu ń bẹ fún òmìnira Kristẹni, ní ti pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé “òfin ẹ̀mí yẹn èyí tí ń fúnni ní ìyè ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù ti dá ọ sílẹ̀ lómìnira kúrò nínú òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ti ikú,” òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ti ikú, tí ń ṣiṣẹ́ nínú ẹran ara Kristẹni, ń jìjàkadì láti mú ènìyàn wá sábẹ́ ìsìnrú lẹ́ẹ̀kan sí i. (Róòmù 8:1, 2) Nítorí náà, Kristẹni kan gbọ́dọ̀ pa ọkàn rẹ̀ pọ̀ sórí àwọn ohun tẹ̀mí, láti baà lè ṣẹ́gun.—Róòmù 7:21-25; 8:5-8.
Lẹ́yìn títo ìjàkadì Kristẹni lẹ́sẹẹsẹ, Pọ́ọ̀lù ń bá a lọ láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi gẹ́gẹ́ bí “àwọn ọmọ Ọlọ́run.” Lẹ́yìn náà, ó tọ́ka sí àwọn aráyé yòó kù gẹ́gẹ́ bí “ìṣẹ̀dá,” ó sì gbé ète àgbàyanu Ọlọ́run kalẹ̀ “pé a óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ lómìnira kúrò nínú ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́ yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:12-21.
Lílò Ó Lọ́nà Àpèjúwe
Nígbà tí Jóòbù, nínú ìpọ́njú rẹ̀, dàníyàn láti rí ìtúsílẹ̀ nínú ikú, ó fi ikú wé òmìnira fún àwọn tí a ń pọ́n lójú. Ní kedere, ó fọgbọ́n tọ́ka sí ìgbésí ayé líle koko tí àwọn ẹrú ń gbé, ní sísọ pé: “[Nínú ikú] ẹrú sì di òmìnira kúrò lọ́wọ́ olówó rẹ̀.”—Jóòbù 3:19; fi wé ẹsẹ 21 àti 22.