ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 3/15 ojú ìwé 11
  • “Bíbélì Oníka Kan”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Bíbélì Oníka Kan”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé Fáwọn Tó Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ọ̀kẹ́ Àìmọye Èèyàn Mọyì Rẹ̀ Kárí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Jèhófà Máa Ń Bá Àwa Èèyàn Sọ̀rọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Bíbélì Tí Wọ́n Túmọ̀ Lọ́nà Tó Dára?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 3/15 ojú ìwé 11

“Bíbélì Oníka Kan”

JOSEPH Schereschewsky rọ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ lẹ́yìn tí àìsàn kọ lù ú, kò lè fọwọ́ rẹ̀ kọ̀wé mọ́ àfi kí ó lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, nípa lílo ìka kan ṣoṣo. Síbẹ̀ ó lé góńgó rẹ̀ bá—láti tú Bíbélì sí èdè Chinese, ọ̀kan nínú àwọn èdè tí ó díjú jù lọ fún àjèjì láti mọ̀.

Ojúlówó Júù ni Schereschewsky, gẹ́gẹ́ bí àgbà kan, ó ṣèwádìí nípa ẹ̀sìn Kristẹni, ó sì tẹ́wọ́ gbà á. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó di míṣọ́nnárì ní China. Níbẹ̀, ó lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìtumọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ láti nǹkan bí ọdún 1866, ó sì ṣe é títí di àwọn ọdún àkọ́kọ́ nínú ọ̀rúndún ogún. Nítorí tí ó jẹ́ Júù, Schereschewsky ní òye èdè Hébérù dáadáa ju àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ lọ. Nípa báyìí, a fa títú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù látòkè délẹ̀ lé e lọ́wọ́. Nígbà tí iṣẹ́ onígbà pípẹ́ rẹ̀ ń parí lọ, ó tún mú ìtumọ̀ odindi Bíbélì tí ó ní atọ́ka jáde ní èdè Chinese.

Gẹ́gẹ́ bí olùtumọ̀ Bíbélì, Joseph Schereschewsky jẹ́ onítara alágbàwí fún níní onírúurú ẹ̀dà ìtumọ̀ ní àwọn èdè gbáàtúù. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ rẹ̀ kò rọrùn. Ìwé náà, The Book of a Thousand Tongues, sọ pé ipa tí ó kó nínú èdè Chinese jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ “nítorí pé ó gbòòrò gan-an, tí a sì parí rẹ̀ lábẹ́ ọ̀pọ̀ ìṣòro.”

Lẹ́yìn tí ọwọ́ Schereschewsky rọ, ó ṣì ń bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ. Títẹ̀wé béèrè ìsapá gidigidi, níwọ̀n bí ọwọ́ rẹ̀ kò ti ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́. Nítorí náà, ó pe ìtumọ̀ yìí ní Bíbélì oníka kan. Schereschewsky forí tì í fún ọdún 25, láti lè mú un jáde láìfi àìlera rẹ̀ pè. Nítorí tí kò káàárẹ̀, ó lọ́wọ́ nínú mímú kí a lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní èdè Chinese—èdè tí àwọn ènìyàn tí ń sọ ọ́ pọ̀ ju àwọn tí ń sọ èdè èyíkéyìí mìíràn lọ.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 11]

Àwòrán méjèèjì: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínuure ti American Bible Society Archives

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́