Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé Ní Ilẹ̀ Faransé
“A KÒ FẸ́ ÌLÚ JÈHÓFÀ!” ni àkọlé tí ó wà lára àwọn ìwé tí àwọn èèyàn ń gbé káàkiri jákèjádò ìlú. Ẹgbẹ́ alátakò kan gbani níyànjú pé: “Ẹ Jẹ́ Kí Gbogbo Wa Tako Iṣẹ́ Jèhófà.” Ní ti gidi, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àpilẹ̀kọ nínú ìwé ìròyìn gbé ọ̀ràn náà síta fáyé gbọ́. Àwọn èèyàn fọwọ́ sí àwọn ìwé ìfẹ̀sùnkanni, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwé pélébé tí ó lé ní ìlàjì mílíọ̀nù, tí ń mẹ́nu kan iṣẹ́ ìdáwọ́lé náà sì kún inú àwọn àpótí ìfìwéránṣẹ́. Iṣẹ́ ìdáwọ́lé wo ni ó kó másùnmáwo bá ìlú píparọ́rọ́ ti Louviers, ní ìwọ̀ oòrùn àríwá ilẹ̀ Faransé? Iṣẹ́ ìdáwọ́lé ti kíkọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun àti ilé gbígbé ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mà ni o.
Jèhófà Ń Mú Kí Ó Dàgbà
Ìgbòkègbodò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Faransé ti wà tipẹ́tipẹ́, láti òpin ọ̀rúndún kọkàndínlógún. A ṣí ibi ìkẹ́rùsí àkọ́kọ́ fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ọdún 1905, ní Beauvène, gúúsù ilẹ̀ Faransé, nígbà tí ó sì fi máa di ọdún 1919, ọ́fíìsì kékeré kan ní Paris ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. A ṣí ẹ̀ka ọ́fíìsì kan ní ìlú náà ní ọdún 1930, ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, àwọn òṣìṣẹ́ ọ́fíìsì náà bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní ilé Bẹ́tẹ́lì ní Enghien-les-Bains, ní àríwá Paris. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ìdílé Bẹ́tẹ́lì ṣí padà wá sí Paris, nígbà tí ó sì fi máa di ọdún 1959, a gbé ẹ̀ka náà lọ sí ilé alájà mẹ́rin kan tí ń bẹ ní Boulogne-Billancourt, lẹ́yìn òde ìwọ̀ oòrùn olú ìlú náà.
Nítorí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà tí ń gbòòrò sí i, ní ọdún 1973, a kó ilé ìtẹ̀wé àti ẹ̀ka ìfẹrùránṣẹ́ lọ sí Louviers, 100 kìlómítà ní ìwọ̀ oòrùn Paris, àmọ́ ọ́fíìsì ṣì wà ní Boulogne-Billancourt. Ṣùgbọ́n, láìka àfikún tí a ṣe ní ọdún 1978 àti 1985 sí, ìbísí nínú iye àwọn akéde ní ilẹ̀ Faransé kò jẹ́ kí ilé tí ó wà ní Louviers tóó lò mọ́. Nítorí náà, a pinnu láti mú un gbòòrò sí i, kí a sì mú kí gbogbo ìdílé Bẹ́tẹ́lì wà papọ̀ lójú kan. Kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìdáwọ́lé yìí, gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nu kàn án ní ìbẹ̀rẹ̀. Láìfi irú àtakò bẹ́ẹ̀ pè, a rí ilẹ̀ kan ní nǹkan bí kìlómítà kan ààbọ̀ sí ibi tí ilé ìtẹ̀wé wà. Iṣẹ́ àṣekára fún ọdún mẹ́fà bẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn ọdún 23 tí ìdílé Bẹ́tẹ́lì lódindi fi wà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a mú wọn wà papọ̀ ní Louviers ní August 1996.
Pẹ̀lú ìdùnnú kíkọyọyọ ni 1,187 ògìdìgbó aláyọ̀, títí kan 300 mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti ilẹ̀ Faransé, àti àwọn 329 àyànṣaṣojú láti ẹ̀ka 42 mìíràn, fi péjọ lọ́jọ́ Saturday, November 15, 1997, láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyàsímímọ́ tí Arákùnrin Lloyd Barry, mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, sọ. Àmọ́ ṣá o, níwọ̀n bí ìyàsímímọ́ yìí ti ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò kan tí ẹ̀tanú àti ìbàlórúkọjẹ́ tí kò dáwọ́ dúró láti ọ̀dọ̀ ilé iṣẹ́ ìròyìn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Faransé ń lọ lọ́wọ́, a lérò pé ó yẹ kí gbogbo Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó wà ní ilẹ̀ Faransé lè nípìn-ín nínú ṣíṣayẹyẹ ìjagunmólú yìí. Àbájáde rẹ̀ ni pé, lọ́jọ́ Sunday, November 16, a ṣètò ìpàdé àkànṣe kan tí ó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Dúró Nínú Ìfẹ́ Kristi,” ní Ibi Ìpàtẹ Ọjà ti Villepinte, ní àríwá Paris. A fìwé pe gbogbo Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà ní ilẹ̀ Faransé pátá àti Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń sọ èdè Faransé ní Belgium àti Switzerland, àti àwọn ìjọ ní Britain, Germany, Luxembourg, àti Netherlands.
Àpéjọ Pípẹtẹrí
Nígbà tí ó ti ku oṣù mẹ́fà ni kùrùkẹrẹ àpéjọ náà ti bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọ̀sẹ̀ méjì péré ṣáájú ìyàsímímọ́ náà, àwọn awakọ̀ ilẹ̀ Faransé daṣẹ́ sílẹ̀, wọ́n dí gbogbo ojú ọ̀nà pàtàkì-pàtàkì, wọn kò sì jẹ́ kí ọkọ rí epo rà. Àga àti àwọn ohun èlò mìíràn yóò ha tètè dé ibi ìpàdé náà bí? Ọ̀nà tí a ti dí yóò ha ṣèdíwọ́ fún àwọn ará láti wá bí? Láàárín ọ̀sẹ̀ kan ìdaṣẹ́sílẹ̀ náà parí, wọ́n sì padà sí ojú ọ̀nà, ọkàn olúkúlùkù wá balẹ̀. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Friday tí ó ṣáájú òpin ọ̀sẹ̀ ìyàsímímọ́ náà, ọkọ̀ ẹrù 38 ni ó kó 84,000 àga wá sí gbọ̀ngàn ńlá méjì tí a ti háyà fún ayẹyẹ náà. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ó lé ní 800 ṣiṣẹ́ kára ní gbogbo òru títí di agogo mẹ́sàn-án àbọ̀ òwúrọ̀ Saturday láti to ìjókòó, láti ṣètò pèpéle, àti àwọn ohun èlò ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, àti tẹlifíṣọ̀n ràgàjì mẹ́sàn-án.
Ní agogo 6:00 òwúrọ̀ ọjọ́ Sunday, a ti ṣí gbogbo ilẹ̀kùn sílẹ̀, èrò sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ wọlé. Lápapọ̀, ọkọ̀ ojú irin 17 tí a háyà lákànṣe ni ó kó Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó lé ní 13,000 wá sí olú ìlú náà. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin àdúgbò tí ó lé ní igba ti wà ní sẹpẹ́ ní ibùdókọ̀ ojú irin láti máa kí àwọn arìnrìn àjò káàbọ̀ àti láti mú wọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí lọ sí ibi àpéjọpọ̀ náà. Arábìnrin kan wí pé ìṣètò onífẹ̀ẹ́ yìí fún wọn ní “ìmọ̀lára ààbò àti ìdùnnú.”
Ọkọ̀ òfuurufú ni àwọn mìíràn wọ̀ wá sí Paris, nígbà tí àwọn kan sì wọ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wá. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ jù lọ bá 953 bọ́ọ̀sì wá, nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó wá láti àgbègbè Paris sì bá ọkọ̀ èrò lọ sí Ibi Ìpàtẹ Ọjà náà. Ọ̀pọ̀ ti fi gbogbo òru rìnrìn àjò, àwọn mìíràn ti fi ilé wọn sílẹ̀ ní ìdájí, ṣùgbọ́n wọn kò lè pa ìdùnnú wọn láti wà níbi ìpàdé yìí mọ́ra rárá. Ariwo ayọ̀ àti fífi ìfẹ́ dì mọ́ra gbàgì-gbàgì tún jẹ́ ohun tí a fi dá àwọn ọ̀rẹ́ tí wọn kò tí ì fojú kanra wọn fún ọ̀pọ̀ ọdún mọ̀. Ìmúra tí ó jojú ní gbèsè ti onírúurú ilẹ̀ mú kí àwùjọ náà jọ ti ẹgbẹ́ tí ó wá láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. Kò sí àní-àní pé, ohun àrà ọ̀tọ̀ fẹ́ẹ́ ṣẹlẹ̀.
Nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò fi bẹ̀rẹ̀, ní agogo 10:00 òwúrọ̀, kò sí àyè ìjókòó mọ́, síbẹ̀ ìṣẹ́jú kọ̀ọ̀kan ni ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ń ya wọlé. Ibi yòówù tí èèyàn bá yíjú sí, ọ̀pọ̀ ojú tí ń rẹ́rìn-ín músẹ́ ni yóò rí. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún wà lórí ìdúró, àwọn kan sì jókòó sórí kọnkéré. Ní fífi ẹ̀mí àpéjọ náà hàn, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ fi ìfẹ́ dìde dúró kí àwọn àgbàlagbà lè rí ibi jókòó sí. Tọkọtaya kan kọ̀wé pé: “Ẹ wo bí a ti láyọ̀ tó láti fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tí a kò mọ̀ rí, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa, ní ìjókòó wa!” Ọ̀pọ̀ fi ẹ̀mí rere ti ìfara-ẹni-rúbọ hàn: “A wà lórí ìdúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn àga tí a ti ṣèrànwọ́ láti fi gbogbo òru ọjọ́ Friday tò, títí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà fi parí. Ṣùgbọ́n pé a tilẹ̀ wà níbẹ̀, mú kí a kún fún ọpẹ́ sí Jèhófà.”
Láìfi àárẹ̀ àti ipò tí kò fara rọ náà pè, àwọn tí ó wá, tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí àwọn ìròyìn láti orílẹ̀-èdè mìíràn àti àwọn àsọyé tí Lloyd Barry àti Daniel Sydlik, tí àwọn pẹ̀lú jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, sọ. Arákùnrin Barry sọ̀rọ̀ lórí kókó ọ̀rọ̀ náà, “Jèhófà Ń Mú Kí Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Agbára Ńlá Pọ̀ Gidigidi,” ó sì ṣàpèjúwe lọ́nà tí ó wúni lórí, bí Jèhófà ṣe fi ìbísí bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀ láìfi onírúurú àdánwò pè. Ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé Arákùnrin Sydlik ni, “Aláyọ̀ Ni Àwọn Ènìyàn Tí Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Wọn!” Àwọn àsọyé méjèèjì ní pàtàkì bọ́ sákòókò lójú ìwòye àtakò tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dojú kọ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ilẹ̀ Faransé. Arákùnrin Sydlik fi hàn pé ayọ̀ tòótọ́ kò sinmi lórí àwọn nǹkan tòde ara ṣùgbọ́n lórí ipò ìbátan wa pẹ̀lú Jèhófà àti ìṣarasíhùwà wa sí ìgbésí ayé. Ó béèrè lọ́wọ́ àwùjọ pé, “Ṣé inú yín dùn?” àtẹ́wọ́ wàá-wàá-wàá ni wọ́n fi fèsì.
Arábìnrin kan tí ó ti “pàdánù ayọ̀ rẹ̀” kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Lójijì mo rí i pé ayọ̀ kò jìnnà sí mi. Mo ti ń darí ìsapá mi sí ọ̀nà òdì, àmọ́ nípasẹ̀ àsọyé yìí, Jèhófà fi hàn mí bí mo ti nílò ìyípadà tó.” Arákùnrin mìíràn polongo pé: “Wàyí o, mo fẹ́ jìjàkadì láti mú inú Jèhófà dùn. N kò fẹ́ kí ohunkóhun mú ayọ̀ tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní nínú mi lọ́hùn-ún kúrò.”
Bí ìpàdé náà ti ń parí lọ, pẹ̀lú ìtara ńláǹlà ni alága fi kéde iye àwọn tí ó pésẹ̀: 95,888—àpéjọ títóbi jù lọ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ì ṣe rí ní ilẹ̀ Faransé!
Lẹ́yìn orin àkọparí, tí ọ̀pọ̀ kọ pẹ̀lú omijé ayọ̀ lójú wọn, àti àdúrà ìparí, àwọn ará bẹ̀rẹ̀ sí í rin ìrìn àjò padà sí ilé wọn pẹ̀lú onírúurú ìmọ̀lára. Ìfẹ́ àti ọ̀yàyà tí ó wà ní àpéjọ náà kò pa mọ́ rárá. Àwọn awakọ̀ sọ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ amóríwú nípa àwọn tí ó wá síbẹ̀. Ètò tí a ṣe, ti ó mú kí bọ́ọ̀sì 953 lè kúrò ní Ibi Ìpàtẹ Ọjà náà láàárín wákàtí méjì láìsí àkọlùkọgbà ọkọ̀ rárá wú wọn lórí gidigidi! Ìwà àwọn tí ó wá pẹ̀lú wú àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin àti ọkọ̀ èrò lórí gidigidi. Ọ̀pọ̀ ìjíròrò tí ó mọ́yán lórí tẹ̀ lé e, a sì jẹ́rìí tí ó jíire.
“Ipadò Nínú Aṣálẹ̀”
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ . . . jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, . . . kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Hébérù 10:24, 25) Ó dájú pé, ìpàdé àkànṣe yìí jẹ́ orísun ìṣírí ńláǹlà fún gbogbo ènìyàn, “ipadò nínú aṣálẹ̀” gẹ́gẹ́ bí arábìnrin kan ti ṣàpèjúwe rẹ̀. Àwọn arákùnrin tí ó wá láti ẹ̀ka Tógò sọ pé: “A padà sílé pẹ̀lú ìmúlọ́kànle, ìṣírí, okun, a sì túbọ̀ pinnu láti máa yọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.” Alábòójútó àyíká kan wí pé: “Àwọn tí wọ́n sorí kọ́ fi ayọ̀ padà sílé.” Ẹlòmíràn sọ pé: “A ru àwọn ará sókè, a sì fún wọn lókun.” Ó mú kí tọkọtaya kan kọ̀wé pé: “A kò tí ì nímọ̀lára sísúnmọ́ ètò àjọ Jèhófà pẹ́kípẹ́kí tó bẹ́ẹ̀ rí.”
Onísáàmù náà polongo pé: “Dájúdájú, ẹsẹ̀ mi yóò dúró lórí ibi títẹ́jú pẹrẹsẹ; inú àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn ni èmi yóò ti máa fi ìbùkún fún Jèhófà.” (Sáàmù 26:12) Irú àpéjọ Kristẹni bẹ́ẹ̀ ń ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti padà fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nípa tẹ̀mí láìfi àwọn ìṣòro pè. Arábìnrin kan mú un dáni lójú pé: “Ohun yòówù kí ìpọ́njú náà jẹ́, àwọn àkókò àrà ọ̀tọ̀ yìí ti wọ inú ọkàn wa ṣinṣin, yóò sì máa tù wá nínú títí láé.” Lọ́nà kan náà, alábòójútó arìnrìn àjò kan kọ̀wé pé: “Nígbà tí àkókò ìnira bá dé, ìrántí ìtọ́wò Párádísè yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kojú wọn.”
Sáàmù 96:7 gbà wá níyànjú pé: “Ẹ gbé e fún Jèhófà, ẹ̀yin ìdílé àwọn ènìyàn, ẹ gbé ògo àti okun fún Jèhófà.” Kò sí iyèméjì pé, ìyàsímímọ́ ẹ̀ka tuntun ní ilẹ̀ Faransé jẹ́ ìjagunmólú pípabanbarì fún Jèhófà. Òun nìkan ṣoṣo ni ó ti lè mú kí iṣẹ́ ìdáwọ́lé náà kẹ́sẹ járí láìka àtakò gbígbóná janjan tí ó sì tàn kálẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ sí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Faransé ti túbọ̀ kún fún ìpinnu ju ti ìgbàkígbà rí lọ láti ‘dúró nínú ìfẹ́ Kristi’ àti láti jẹ́ ‘kí ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn.’ (Jòhánù 15:9; Mátíù 5:16) Gbogbo àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìyàsímímọ́ náà ṣàjọpín ìmọ̀lára onísáàmù náà láìkù síbì kan pé: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èyí ti wá; ó jẹ́ àgbàyanu ní ojú wa.”—Sáàmù 118:23.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Lloyd Barry
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Daniel Sydlik
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
95,888 ni ó wá síbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ àkànṣe ní Ibi Ìpàtẹ Ọjà ti Villepinte
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó wá jókòó sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀, àwọn mìíràn sì wà lórí ìdúró láti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ń lọ lọ́wọ́