Ìṣẹ̀lẹ̀ Tẹ̀mí Tí Kò Ṣeé Gbàgbé! Ìmújáde Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Lédè Yorùbá
NÍ OCTOBER 11, 1997, ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí kò ṣeé gbàgbé wáyé: A mú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé tuntun jáde lédè Yorùbá.
Wàyí o, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun pẹ̀lú ti wá wà lárọ̀ọ́wọ́tó bíi ti àwọn Bíbélì yòókù tí àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run ti ń lò ní ilẹ̀ Nàìjíríà láti ìgbà pípẹ́. Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí a fi nílò ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn? Ta ní ń bẹ lẹ́yìn rẹ̀? Báwo sì ni ó ṣe lè dá ọ lójú pé Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣeé gbára lé?
Èé Ṣe Tí Ìtumọ̀ Bíbélì Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a ti tẹ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìtumọ̀ Bíbélì tuntun jáde. Àwọn ìtumọ̀ tuntun kan ti mú kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àwọn èdè kan fún ìgbà àkọ́kọ́. Ṣùgbọ́n, àwọn Bíbélì tuntun tún ń jáde ní àwọn èdè tí ó ti ní àwọn ìtumọ̀ tí a mọ̀ dáradára tẹ́lẹ̀. Èé ṣe? Ìwé tí Sakae Kubo àti Walter Specht pawọ́ pọ̀ ṣe, So Many Versions?, ṣàlàyé pé: “Kò sí ìtumọ̀ Bíbélì kan tí a lè kà sí àṣekágbá. Ìtumọ̀ gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ síwájú bí ìmọ̀ Bíbélì àti ìyípadà nínú èdè bá ṣe ń tẹ̀ síwájú.”
Ọ̀rúndún yìí ti rí ìdàgbàsókè gígalọ́lá nínú òye èdè Hébérù, Árámáìkì, àti Gíríìkì—àwọn èdè tí a fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lú, a ti ṣàwárí àwọn ìwé Bíbélì tí a fọwọ́ kọ, tí ó ti wà ṣáájú èyí tí àwọn olùtumọ̀ Bíbélì ní àwọn ìran ìṣáájú lò, tí ó sì tún péye jù wọ́n lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, a lè tú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà pípéye lónìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ!
Ní dídọ́gbọ́n sọ̀rọ̀ bá àwọn ilé iṣẹ́ okòwò, ìwé ìròyìn The Atlantic Monthly sọ pé: “Títẹ Bíbélì jáde jẹ́ òwò ńlá—òwò rẹpẹtẹ.” Nígbà mìíràn, ìfẹ́ ọkàn láti mú èyí tí yóò tà jù lọ jáde máa ń borí ìdàníyàn fún mímú èyí tí ó péye jáde. Bíbélì tuntun kan dìídì yọ àwọn ẹsẹ tí àwọn tí ó tẹ̀ ẹ́ jáde rò pé ó lè tètè “súni” kúrò. Bíbélì mìíràn yí ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn tí ó lè bí àwọn òǹkàwé òde òní nínú padà. Fún àpẹẹrẹ, ó gbìyànjú láti fa àwọn olójú ìwòye ọkùnrin kò lọ́lá ju obìnrin lọ mọ́ra nípa pípe Ọlọ́run ni “Baba-òun-Ìyá.”
Mímú Kí Orúkọ Ọlọ́run Fara Sin
Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ìtẹ̀sí tí ó kó ìdààmú báni jù lọ ní í ṣe pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́run gan-an—Jèhófà. (Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan pè é ní “Yahweh.”) Nínú àwọn ẹ̀dà Bíbélì ìjímìjí, kọ́ńsónáǹtì mẹ́rin ti èdè Hébérù tí a lè pa lẹ́tà rẹ̀ dà sí YHWH tàbí JHVH ni ó dúró fún orúkọ àtọ̀runwá náà. Orúkọ yíyàtọ̀ gédégbé yìí fara hàn ní ìgbà tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 7,000 nínú apá tí a ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé nìkan ṣoṣo. (Ẹ́kísódù 3:15; Sáàmù 83:18) Nígbà náà, ó ṣe kedere pé, Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ kí àwọn olùjọsìn òun mọ orúkọ yẹn, kí wọ́n sì lò ó!
Ṣùgbọ́n, ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, ìbẹ̀rù ìgbàgbọ́ nínú ohun asán mú kí àwọn Júù dẹ́kun pípe orúkọ àtọ̀runwá náà. Nígbà tí ó yá, irú ojú ìwòye onígbàgbọ́ nínú ohun asán bẹ́ẹ̀ ran ẹ̀sìn Kristẹni. (Fi wé Ìṣe 20:29, 30; 1 Tímótì 4:1.) Ó wá di àṣà tí ó wọ́pọ̀ pé kí àwọn olùtumọ̀ Bíbélì máa fi orúkọ oyè náà, “Olúwa,” rọ́pò orúkọ àtọ̀runwá náà. Lónìí, ọ̀pọ̀ jù lọ Bíbélì yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò pátápátá. Àwọn Bíbélì òde òní kan lédè Gẹ̀ẹ́sì tilẹ̀ fo ìtọ́ka tí a ṣe sí ọ̀rọ̀ náà, “orúkọ,” tí a lò nínú Jòhánù 17:6, níbi tí Jésù ti sọ pé: “Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere.” Bí Bíbélì Today’s English Version ṣe tú ẹsẹ náà nìyí: “Mo ti fi ọ́ hàn.”
Èé ṣe tí wọ́n fi kórìíra orúkọ Ọlọ́run tó bẹ́ẹ̀? Gbé ọ̀rọ̀ tí a sọ nínú ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà náà, Practical Papers for the Bible Translator, yẹ̀ wò. (Ìdìpọ̀ 43, nọnba 4, ti ọdún 1992) Ìparapọ̀ Àwọn Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì (UBS), tí ó ń ṣe kòkáárí ọ̀pọ̀ nínú akitiyan títúmọ̀ Bíbélì kárí ayé, ni ó tẹ̀ ẹ́ jáde. Àpilẹ̀kọ kan nínú rẹ̀ sọ pé: “Níwọ̀n bí kò ti sí iyèméjì pé YHWH jẹ́ orúkọ gidi, gẹ́gẹ́ bí ìlànà, ìpalẹ́tàdà ni yóò jẹ́ ọ̀nà tí ó bọ́gbọ́n mu jù lọ láti gbà túmọ̀ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n àpilẹ̀kọ náà kìlọ̀ pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn kókó pàtàkì kan wà ti a ní láti gbé yẹ̀ wò.”
Báwo ni “àwọn kókó pàtàkì” bẹ́ẹ̀ ti bá ìlànà mu tó? Gẹ́gẹ́ bi ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà yìí ti sọ, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ronú pé: “Bí a bá fi orúkọ bí Yahweh kọ́ [àwọn tí kì í ṣe Kristẹni], ó lè gbé èrò tí ó lòdì yọ . . . ní fífihàn pé ‘Yahweh’ jẹ́ Ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè, tàbí Ọlọ́run tuntun tàbí tí wọn kò mọ̀, ti ó yàtọ̀ sí Ọlọ́run tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀.” Ṣùgbọ́n, Bíbélì kọ́ni léraléra pé Jèhófà Ọlọ́run yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ọlọ́run tí àwọn tí kì í ṣe Kristẹni ń jọ́sìn!—Aísáyà 43:10-12; 44:8, 9.
Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ni àwọn wulẹ̀ ń tẹ̀ lé nígbà tí àwọn fi orúkọ oyè náà, “OLÚWA,” rọ́pò orúkọ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n Jésù bẹnu àtẹ́ lu títẹ̀lé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí ó tàbùkù Ọlọ́run. (Mátíù 15:6) Yàtọ̀ sí ìyẹn, gbogbo èrò fífi orúkọ oyè rọ́pò orúkọ gidi kò ní ìpìlẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. Jésù Kristi ní ọ̀pọ̀ orúkọ oyè, irú bí “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” àti “Ọba àwọn ọba.” (Ìṣípayá 19:11-16) Ó ha yẹ kí a fi ọ̀kan nínú àwọn orúkọ oyè wọ̀nyí rọ́pò orúkọ náà, Jésù bí?
Àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà tí a mẹ́nu kàn yìí sọ pé: “Ó yẹ kí a yẹ ọ̀nà ìgbàpe orúkọ náà, ‘Jèhófà’ sílẹ̀.” Èé ṣe? “Ní gbogbogbòò, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ gbà pé ‘Yahweh’ ni ó dún lọ́nà tí wọ́n gbà ń pe orúkọ náà ní ìpilẹ̀ṣẹ̀.” Síbẹ̀síbẹ̀, a kọ àwọn orúkọ tí ó wọ́pọ̀ nínú Bíbélì, irú bíi Jeremáyà, Aísáyà, àti Jésù, lọ́nà tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìjọra pẹ̀lú bí a ṣe ń pè wọ́n ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní èdè Hébérù (Yir·meyahʹ, Yeshaʽ·yaʹhu, àti Yehoh·shuʹaʽ). Níwọ̀n bí ọ̀nà ìgbàpe orúkọ náà, “Jèhófà,” ti jẹ́ ọ̀nà tí ó bá ìlànà mu láti pe orúkọ Ọlọ́run—tí ó sì jẹ́ ọ̀kan tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ bí ẹní mowó—títako lílò ó kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá. Ní tòótọ́, ó dà bíi pé a gbé lílọ́ra láti lo orúkọ àtọ̀runwá náà karí ìmọ̀lára àti ẹ̀tanú, a kò gbé e karí ìmọ̀ ẹ̀kọ́.
Ṣùgbọ́n, ọ̀ràn tí ó wà nílẹ̀ yìí kì í ṣe ti ìmọ̀ ẹ̀kọ́ lásán. Fún àpẹẹrẹ, ògbógi nínú ẹgbẹ́ UBS kan ní Íńdíà kọ̀wé nípa àbájáde yíyọ orúkọ àtọ̀runwá náà kúrò nínú àwọn ìtumọ̀ tí ó ti wà tẹ́lẹ̀. Ó sọ pé: “Àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù kò fẹ́ mọ orúkọ oyè Ọlọ́run; orúkọ Ọlọ́run gan-an ni wọ́n fẹ́ mọ̀, bí wọn kò bá sì mọ orúkọ náà, wọn kò lè rí ìbátan tí ó wà láàárín àwọn àti ẹni tí ń jẹ́ orúkọ náà.” Ní tòótọ́, bi ó ṣe yẹ kí ọ̀ràn rí pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ń wá Ọlọ́run nìyí. Mímọ orúkọ Ọlọ́run ṣe pàtàkì láti lè mọ̀ ọ́n, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ipá aláìlẹ́mìí, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan—ẹnì kan tí a lè mọ̀. (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Nípa báyìí, Bíbélì polongo pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a óò gbà là.” (Róòmù 10:13) Dandan ni fún àwọn olùjọsìn láti lo orúkọ rẹ̀!
Ìtumọ̀ Tí Ó Bọlá fún Ọlọ́run
Nítorí náà, ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé ni ó jẹ́ ní ọdún 1950, nígbà tí a kọ́kọ́ mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì. Ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn ìgbà yẹn, a mú àwọn apá kan nínú èyí tí a sábà ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé, tàbí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, jáde ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Ní ọdún 1961, a mú odindi Bíbélì náà jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì ní ìdìpọ̀ kan ṣoṣo. Lọ́nà tí ó ṣe pàtàkì, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lo orúkọ àtọ̀runwá náà, Jèhófà, ní gbogbo ibi tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 7,000, tí ó ti fara hàn nínú “Májẹ̀mú Láéláé.” Ohun tí ó tún mú kí ó tayọ lọ́lá ní pàtàkì ni mímú tí ó mú orúkọ àtọ̀runwá náà padà bọ̀ sípò nígbà 237 nínú “Májẹ̀mú Tuntun,” tàbí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.
Kì í ṣe kìkì pé ìmúpadàbọ̀sípò náà bọlá fún Ọlọ́run nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún òye tuntun gbígbòòrò. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ tú Mátíù 22:44 lọ́nà yìí: “Olúwa wí fún Olúwa mi pé.” Ṣùgbọ́n ta ni ń bá ta ni sọ̀rọ̀? Ìtumọ̀ Ayé Tuntun túmọ̀ ẹsẹ yìí báyìí, “Jèhófà wí fún Olúwa mi pé,” ó tipa báyìí ṣàyọlò Sáàmù 110:1 lọ́nà tí ó tọ́. Nípa báyìí, àwọn òǹkàwé lè rí ìyàtọ̀ ṣíṣe kókó gan-an, láàárín Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀.
Ta Ní Ń Bẹ Lẹ́yìn Rẹ̀?
Watch Tower Bible and Tract Society, ẹgbẹ́ tí a gbé kalẹ̀ lábẹ́ òfin, tí ń ṣojú fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ni ó mú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde. Fún ohun tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún, Society yìí ti tẹ Bíbélì jáde, ó sì ti pín in kiri jákèjádò ayé. Àwùjọ Kristẹni kan, tí a mọ̀ sí Ìgbìmọ̀ Atúmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun, ni ó fi ìtumọ̀ yìí lédè Gẹ̀ẹ́sì fún Society. Láìfẹ́ pòkìkí ara wọn rárá, àwọn mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ náà sọ pé kí a máà dárúkọ àwọn, àní lẹ́yìn tí àwọn bá kú pàápàá.—Fi wé 1 Kọ́ríńtì 10:31.
Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí a fi ń pe iṣẹ́ yìí ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun? Èyí fi ìgbàgbọ́ dídájú náà hàn pé aráyé wà “ní bèbè ayé tuntun” tí a ṣèlérí nínú 2 Pétérù 3:13. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ìgbìmọ̀ náà fúnra rẹ̀ kọ, ní “àkókò tí ayé ògbólógbòó ń tán lọ” yìí, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì jẹ́ kí “òtítọ́ mímọ́ gaara Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” mọ́lẹ̀.—Wo Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú ìtẹ̀jáde ti ọdún 1950 (èdè Gẹ̀ẹ́sì).
Ìtumọ̀ Pípéye
Nípa báyìí, a fún ìpéye ní àfiyèsí gíga jù lọ. Àwọn olùtumọ̀ ti èdè Gẹ̀ẹ́sì tú u tààràtà láti inú èdè Hébérù, Árámáìkì, àti Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀, ní lílo àwọn ìwé ìpilẹ̀ṣẹ̀ dídára jù lọ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó.a Wọ́n tún kíyè sára gidigidi láti rí i pé a tú ìwé ìjímìjí náà ni ṣangiliti bí ó ti ṣeé ṣe tó—ṣùgbọ́n ní èdè tí àwọn òǹkàwé òde òní yóò lè tètè lóye.
Kò yani lẹ́nu pé, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ti gbóṣùbà fún Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì fún àìlábùlà àti ìpéye rẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Benjamin Kedar, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ní Ísírẹ́lì, tí ó jẹ́ Hébérù, sọ ní ọdún 1989 pé: “Nínú ìwádìí mi nínú ìmọ̀ èdè tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Bíbélì Hébérù àti àwọn ìtumọ̀ rẹ̀, mo sábà máa ń wo ìtẹ̀jáde èdè Gẹ̀ẹ́sì tí a mọ̀ sí New World Translation. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, mo rí i léraléra pé òtítọ́ ni ìmọ̀lára mi pé iṣẹ́ yìí fi ìsapá aláìlábòsí láti rí i pé a lóye ìwé tí ó péye bí ó ti ṣe lè ṣeé ṣe tó hàn.”
Mímú Kí Àwọn Ìtẹ̀jáde Mìíràn Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó
Nígbà náà, ó jẹ́ ohun yíyẹ pé Watch Tower Society ti mú kí Ìtumọ̀ Ayé Tuntun wà ní àwọn èdè mìíràn yàtọ̀ sí Gẹ̀ẹ́sì. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́ a ti tẹ̀ ẹ́ jáde lódindi, tàbí lápá kan, ní 30 èdè. Láti mú kí ìdáwọ́lé yìí túbọ̀ rọrùn, Society ṣe ọ̀nà ìtumọ̀ Bíbélì kan tí ó pa ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì pọ̀ mọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà. Society tún dá Ẹ̀ka Aṣekòkáárí Iṣẹ́ ìtumọ̀, tí ó wà ní Patterson, New York, nísinsìnyí sílẹ̀, láti ran àwọn olùtumọ̀ lọ́wọ́. Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà darí iṣẹ́ títúmọ̀ Bíbélì nípasẹ̀ Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé rẹ̀. Ṣùgbọ́n báwo ni a tilẹ̀ ṣe ṣiṣẹ́ yìí?
Lákọ̀ọ́kọ́, a yan àwùjọ àwọn Kristẹni tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́ láti sìn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ olùṣètumọ̀. Ìrírí ti fi hàn pé nígbà tí àwọn olùtumọ̀ bá ṣiṣẹ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan dípò kí ẹnì kọ̀ọ̀kan dá tirẹ̀ ṣe, wọ́n ń mú ìtumọ̀ tí ó dára, tí ó sì túbọ̀ mọ́yán lórí jáde. (Fi wé Òwe 11:14.) Ní gbogbogbòò, ọ̀kọ̀ọ̀kan mẹ́ńbà ẹgbẹ́ náà ti nírìírí tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùtumọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde Society. Lẹ́yìn èyí, ẹgbẹ́ náà gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ó múná dóko lórí àwọn lájorí ìlànà títúmọ̀ Bíbélì àti nínú lílo àwọn ohun àmúṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà tí a pilẹ̀ ṣe.
A fún ẹgbẹ́ olùtumọ̀ náà nítọ̀ọ́ni láti mú Bíbélì kan tí ó (1) péye, (2) tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bára mu délẹ̀, (3) tí ó wà ní ṣangiliti bí èdè náà bá ti yọ̀ǹda tó, síbẹ̀ tí ó (4) jẹ́ èyí tí ó lè rọrùn fún àwọn gbáàtúù láti lóye, jáde. Báwo ni a ṣe ń ṣe èyí? Gbé Bíbélì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde náà yẹ̀ wò. Ẹgbẹ́ olùtumọ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nípa yíyan àwọn ọ̀rọ̀ èdè Yorùbá tí ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú gbogbo ọ̀rọ̀ Bíbélì tí a lò nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì. A ti ṣètò kọ̀ǹpútà láti gbé àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tí ó tan mọ́ra, tí ìtumọ̀ wọn sì bára mu jáde. Ó tún ń fi àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tàbí Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ láti inú èyí tí a ti mú ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì jáde hàn, kí olùtumọ̀ lè mọ bí a ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tàbí Hébérù wọ̀nyẹn ní ibòmíràn tí wọ́n ti fara hàn. Gbogbo èyí jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńlá láti lè yan àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá tí ó bá a mu wẹ́kú. Gbàrà tí ẹgbẹ́ náà ti fohùn ṣọ̀kan lórí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, ni títúmọ̀ Bíbélì ti bẹ̀rẹ̀ ni rẹbutu, ní lílo kọ̀ǹpútà láti fi àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá tí ó bá a mu wẹ́kú hàn, bí wọ́n ti ń tú ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.
Ṣùgbọ́n, títúmọ̀ wé mọ́ ohun púpọ̀ ju wíwulẹ̀ fi ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ kan rọ́pò òmíràn. Ó ń béèrè iṣẹ́ takuntakun láti rí i dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá tí a yàn gbé èrò inú Ìwé Mímọ́ tí ó wà ní àyíká ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan yọ. Wọ́n tún ní láti ṣọ́ra láti rí i dájú pé gírámà àti àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ dùn ún gbọ́ létí, a sì gbé e kalẹ̀ lọ́nà tí a gbà ń sọ ọ́ ní èdè wa. Iṣẹ́ bàǹtàbanta tí a ṣe nínú ìdáwọ́lé yìí ti jẹ́rìí gbé ara rẹ̀. Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Yorùbá gbé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kalẹ̀ lọ́nà tí ó rọrùn láti kà, tí ó ṣe kedere, tí ó sì yéni, ó sì rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ Ìwé Mímọ́ ìgbàanì.
A rọ̀ ọ́ pé kí ìwọ fúnra rẹ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. O lè rí i gbà lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe ìwé ìròyìn yìí jáde tàbí láti inú ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà ládùúgbò rẹ. O lè kà á pẹ̀lú ìdánilójú pé ó gbé àsọjáde Ọlọ́run gan-an kalẹ̀ láìlábùlà ní èdè rẹ. Kò sí iyè méjì pé láìpẹ́ ìwọ yóò gbà pé ìmújáde rẹ̀ àìpẹ́ yìí jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tẹ̀mí tí kò ṣeé gbàgbé ní tòótọ́!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bíbélì The New Testament in the Original Greek, láti ọwọ́ Westcott àti Hort, ni olú ìwé èdè Gíríìkì tí wọ́n lò. Bíbélì Biblia Hebraica láti ọwọ́ R. Kittel, sì ni olú ìwé tí wọ́n lò fún Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 32]
Díẹ̀ Nínú Apá Fífanimọ́ra ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Lẹ́tà Rekete, Tí Ó Sì Ṣeé Kà
A Tò Wọ́n sí Ìpínrọ̀-Ìpínrọ̀: Dípò mímú kí ẹsẹ kan jẹ́ ìpínrọ̀ kan gédégbé, a to àwọn ẹsẹ sí ìpínrọ̀-ìpínrọ̀. Èyí ń ran òǹkàwé lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé èrò tí àwọn tí ó kọ Bíbélì ń mú jáde.
Àkọlé Orí Ìwé: Wọ́n fara hàn ní òkè ọ̀pọ̀ jù lọ ojú ìwé, wọ́n jẹ́ àrànṣe ti ó lè jẹ́ kí a tètè wá àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì.
Ìtọ́kasí Àárín Ìwé: Ojú ìwé kọ̀ọ̀kan ní àwọn atọ́ka tí ń darí rẹ sí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí ó tan mọ́ ọn.
Atọ́ka: Apá kan lẹ́yìn ìwé náà tí a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Atọ́ka Àṣàyàn Ọ̀rọ̀ Bíbélì.” A to àwọn àṣàyàn ọ̀rọ̀ àti ibi tí a ti lè rí wọn nínú Bíbélì lẹ́sẹẹsẹ, lọ́pọ̀ ìgbà ó ní àyọkà ṣókí tí ń fi àyíká ọ̀rọ̀ náà hàn.
Àsomọ́: Ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ ṣókí lórí àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ inú Bíbélì àti àwọn ọ̀ràn mìíràn tí ó tan mọ́ ọn.