Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Ẹ Má Ṣe Fà Sẹ́yìn Kúrò Nínú Kíkéde Ìhìn Rere Náà
NÍGBÀ tí àwọn olùṣàwárí ará Yúróòpù kọ́kọ́ ṣèbẹ̀wò sí Ibi Ìyawọlẹ̀ Omi Venezuela àti Adágún Maracaibo, àwọn abà ṣókótóṣókótó tí wọ́n kọ́ sórí òpó lórí omi tí kò jìn ló kún etíkun náà. Ìran náà ń ránni létí Venice ní Ítálì, níbi tí àwọn ènìyàn ti ń kọ́ ilé wọn sí etí omi. Ìdí nìyẹn tí àwọn olùṣàwárí tí ń sọ èdè Spanish fi sọ ibẹ̀ ní Venezuela, tí ó túmọ̀ sí “Venice Kékeré.”
Ní báyìí, oríṣi ètò ìtẹ̀lúdó mìíràn ń lọ ní orílẹ̀-èdè rírẹwà yìí, ìyẹn jẹ́ tẹ̀mí. Níbẹ̀, ọwọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dí nínú gbígbin èso Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo àkókò tí ó bá yẹ. Irè tẹ̀mí tí a ń kó níbẹ̀ ń mú ìyìn púpọ̀ wá fún “Ọ̀gá ìkórè” náà, Jèhófà Ọlọ́run.—Mátíù 9:37, 38.
Nígbà tí alábòójútó arìnrìn-àjò kan lọ bẹ ìjọ kan wò ní ìpínlẹ̀ Zulia ní ìhà àríwá ìwọ̀ oòrùn Venezuela, Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n wà níbẹ̀ ṣètò kí òun àti ìyàwó rẹ̀ yọjú sí erékùṣù kan tí ń jẹ́ Toas nítòsí ibẹ̀. Nígbà tí wọ́n tò síbi tí wọ́n óò ti wọ ọkọ̀ ojú omi tí ń lọ sí erékùṣù náà ní fẹ̀ẹ̀rẹ̀, ìyàwó alábòójútó arìnrìn-àjò náà, Mery, dábàá pé kí arábìnrin aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún tí ó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ kí àwọn bá díẹ̀ lára àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ sọ̀rọ̀. Arábìnrin aṣáájú ọ̀nà náà gbà.
Wọ́n lọ sọ́dọ̀ atọ́kọ̀ṣe kan, Mery sì fi ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun lọ̀ ọ́. Ó fi orí náà, “Gbígbé Ìdílé kan Tí Ó Bọlá fún Ọlọ́run Ró” hàn án, ó sì jọ pé ọkùnrin náà nífẹ̀ẹ́ sí i. Mery wá ṣàlàyé pé ó lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé yìí nínú ilé rẹ̀. Ó gba ìwé náà, wọ́n sì ṣètò kí ẹnì kan lọ máa bẹ̀ ẹ́ wò ní ilé rẹ̀.
Láìpẹ́ sí àkókò yẹn, wọ́n ṣe ìpàdé àkànṣe ọlọ́jọ́ kan ní àgbègbè náà. Ẹ wo bí ó ti ya Mery lẹ́nu tó nígbà tí ó rí atọ́kọ̀ṣe náà, Senor Nava, ìyàwó rẹ̀, àti àwọn ọmọbìnrin wọn kéékèèké méjì níbẹ̀! Mery béèrè ohun tí ìyàwó ọkùnrin náà rò nípa ẹ̀kọ́ tí ìdílé wọn ń kọ́ nínú Bíbélì. Ìdáhùn rẹ̀ yani lẹ́nu gan-an.
Ó wí pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé a ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.” Ó wá ṣàlàyé pé: “Kò tíì pẹ́ tí ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí gbé obìnrin mìíràn kiri ni ẹ bá a sọ̀rọ̀. Ó tún máa ń mutí gan-an nígbà yẹn. Nígbà mìíràn tí ó bá ti yó kẹ́ri, ṣeni yóò máa da àdúgbò rú, ìyẹn kì í sì í dùn mọ́ àwọn ènìyàn kéréje tí wọ́n wà ní erékùṣù náà nínú. Ó tún máa ń bá ẹ̀mí lò. Àmọ́, ìmọ̀ Bíbélì tí ó jèrè láti inú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ti ràn án lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà ńláǹlà nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ó ti jáwọ́ nínú gbogbo ìwàkiwà tó ń hù tẹ́lẹ̀. Ìyípadà wọ̀nyí wú àwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ìjọ Kátólíìkì lórí gan-an. Inú wọn ń dùn pé ó ti wá di ọkọ àti bàbá tí ó ṣeé fọkàn tẹ̀ báyìí.”
Senor Nava ṣèrìbọmi ní 1996, ó sì ń sìn bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nísinsìnyí. Ìyàwó rẹ̀, Jenny, ṣèrìbọmi ní 1997. Àwọn ìyípadà tí atọ́kọ̀ṣe yìí ṣe wú baálẹ̀ ìlú náà lórí gan-an tí òun pẹ̀lú fi ní kí wọ́n máa wá kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ wo bí inú àwọn arábìnrin wọ̀nyí ti dùn tó pé àwọn kò fà sẹ́yìn kúrò nínú kíkéde ìhìn rere náà nígbà tí àwọn tò síbi tí àwọn óò ti wọ ọkọ̀ ojú omi lówùúrọ̀ ọjọ́ yẹn!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ṣíṣàjọpín ìhìn rere náà pẹ̀lú atọ́kọ̀ṣe kan yọrí sí ohun ayọ̀