Nígbà Tí Àwọn Ọkàn Yíyigbì Bá Yí Padà
NÍ 1989, ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ NÍ POLAND di àwùjọ tí ìjọba tẹ́wọ́ gbà gẹ́gẹ́ bí ìsìn kan lábẹ́ òfin. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tú Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ti jù sẹ́wọ̀n nítorí àìdásí-tọ̀túntòsì wọn bí Kristẹni sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀, wọ́n sì fi àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n fẹ́ mọ̀ sí i nípa Bíbélì sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Ìròyìn tí a kọ yìí jẹ́ bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe sapá láti ran àwọn tí ọkàn wọn yigbì tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣàmúlò agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ọ̀kan lára irú ọgbà ẹ̀wọ̀n bẹ́ẹ̀.
NÍ WOŁÓW, ìlú kan tí iye ènìyàn ibẹ̀ jẹ́ 12,000, ní ìhà gúúsù ìwọ̀ oòrùn Poland, wọ́n ní ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tí ó ti pé 200 ọdún, tí wọ́n máa ń fi díẹ̀ lára àwọn ọ̀daràn paraku ní Poland sí. Láti ìgbà tí òfin ti fàyè gba iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n ti ń sapá láti mú ìhìn rere Ìjọba náà lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ibẹ̀, wọ́n sì ń ṣe é pẹ̀lú ìtara púpọ̀.
Lẹ́tà kan tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ kọ sí gbogbo àwọn alábòójútó ọgbà ẹ̀wọ̀n Poland ní February 1990 ló mú kí èyí rọrùn. Lẹ́tà náà sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ “ṣèdíwọ́ kankan” fún ẹlẹ́wọ̀nkẹ́lẹ́wọ̀n tó bá fẹ́ gba àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower tàbí tí ó fẹ́ máa jíròrò pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn Ẹlẹ́rìí, tí díẹ̀ lára wọn ti ṣẹ̀wọ̀n ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Wołów fún ọ̀pọ̀ ọdún, mọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n paraku púpọ̀ tí wọ́n wà níbẹ̀. Àmọ́, Jèhófà ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé láti bù kún ìsapá wọn kí òtítọ́ Bíbélì lè yí ọkàn yíyigbì àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn padà.
Bíbẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Náà
Arákùnrin Czesław láti ìlú ńlá Wrocław, tí ó tó 40 kìlómítà síbẹ̀, tí wọ́n gbà láyè láti bẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n ti Wołów wò, sọ pé: “Àtibẹ̀rẹ̀ ètò náà kò rọrùn. Ẹnu fẹ́rẹ̀ẹ́ bó sídìí ọ̀rọ̀ sísọ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n kí wọ́n tó gbà pé ‘ìpàdé ìsìn’ wa yóò ṣe àwọn ẹlẹ́wọ̀n láǹfààní.”
Pawel tí ó ṣìkejì Czesław rántí pé, ohun kan tó mú kí ọ̀ràn túbọ̀ lọ́jú pọ̀ ni ti “ọ̀gá àgbà kan tí ó ranrí pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà wulẹ̀ ń fi àwọn ìpàdé ìsìn náà bojú kí wọ́n lè máa rí nǹkan gbà ni.” Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ ọ̀daràn paraku tẹ́lẹ̀ rí ní àwọn fẹ́ ṣèrìbọmi ní 1991, àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà yí èrò wọn padà, wọ́n sì túbọ̀ fọwọ́ sówọ́ pọ̀ pẹ̀lú wa.
Czesław ṣàlàyé pé: “A kọ́kọ́ wàásù fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà, àwọn ẹbí wọ́n tí wọ́n wá wò wọ́n lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àti àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n. Lẹ́yìn náà, wọ́n jẹ́ kí a wàásù ìhìn rere náà ní àwọn ilé inú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, ohun tí kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀. Níkẹyìn, nígbà tí a rí àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ fìfẹ́ hàn, wọ́n fún wa láyè láti máa lo gbọ̀ngàn kékeré kan láti máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí a sì máa ṣe ìpàdé Kristẹni níbẹ̀.” Dájúdájú, Jèhófà ṣí ọ̀nà àtidé inú ọkàn yíyigbì àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà sílẹ̀.
Ètò Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Tí Ó Gbéṣẹ́
Láìpẹ́, gbọ̀ngàn kékeré yẹn kò gbà wọ́n mọ́. Níwọ̀n bí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n ti ṣe batisí àti àwọn ará tí wọ́n ń wá láti ìta ti ń jùmọ̀ ṣe iṣẹ́ ìwàásù, nǹkan bí 50 ẹlẹ́wọ̀n ló bẹ̀rẹ̀ sí wá sí ìpàdé. Ọ̀kan lára àwọn alàgbà àdúgbò náà ṣàlàyé pé: “Ó lé ní ọdún mẹ́ta tí a ti ń ṣe gbogbo ìpàdé níbẹ̀, àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì ń wá sí àwọn ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ déédéé.” Nígbà tí ó sì di May 1995, wọ́n gbà wọ́n láyè láti máa lo gbọ̀ngàn tí ó tóbi ju ìyẹn lọ.
Báwo ni àwọn arákùnrin tí a fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ ṣe ń pinnu irú ẹni tí ó lè wá sí àwọn ìpàdé tí wọ́n ń ṣe ní ọgbà ẹ̀wọ̀n náà? Arákùnrin Czesław àti Zdzisław ṣàlàyé pé: “A ní orúkọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn fìfẹ́ hàn sí òtítọ́ lọ́wọ́. Bí ẹlẹ́wọ̀n kan kò bá ṣe dáadáa tàbí tí ó bá ń pa ìpàdé jẹ láìsí ìdí gúnmọ́, tí èyí sì ń fi hàn pé kò mọrírì irú ìpèsè bẹ́ẹ̀, a óò fagi lé orúkọ rẹ̀, a óò sì sọ fún alábòójútó ọgbà ẹ̀wọ̀n náà.”
Lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn arákùnrin náà tún máa ń kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà bí wọ́n ṣe lè múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa àti bí wọ́n ṣe lè lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́nà tó gbéṣẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n bá wá sí ìpàdé, wọ́n ti máa ń wà ní ìmúrasílẹ̀ dáadáa, wọ́n sì ń kópa fàlàlà. Àwọn ìlóhùnsí wọn máa ń gbéni ró, wọ́n máa ń lo Bíbélì wọn lọ́nà jíjáfáfá, wọ́n sì ń lo àwọn ìtọ́ni inú rẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà wọ́n máa ń fi àwọn àkíyèsí bí èyí tí ó tẹ̀ lé e yìí kún ìlóhùnsí wọn pé, ‘Ó wá yé mi pé mo gbọ́dọ̀ ṣe báyìí-báyìí.’
Akọ̀wé ìjọ náà sọ pé: “Lápapọ̀, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì 20 ní a ń darí ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Wołów. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ akéde ló ń darí mẹ́jọ lára wọn.” Ìwàásù wọn ní àwọn ilé inú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, àti lákòókò tí wọ́n bá ń rìn kiri nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ti yọrí sí rere. Fún àpẹẹrẹ, láàárín oṣù mẹ́wàá, láti September 1993 sí June 1994, wọ́n fi ìwé ńlá 235, nǹkan bí 300 ìwé pẹlẹbẹ, àti 1,700 ìwé ìròyìn sóde. Láìpẹ́ yìí, méjì lára àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Àwọn Ìpàdé Àkànṣe Ń Mú Ayọ̀ Wá
Bí àkókò ti ń lọ, a fi apá mìíràn kún ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ń lọ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn, ìyẹn ni, àwọn ìpàdé àkànṣe. Àwọn alábòójútó àyíká àti àwọn arákùnrin mìíràn tí wọ́n tóótun yóò sọ àwọn ọ̀rọ̀ ṣíṣekókó lára ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé àyíká àti ìpàdé àkànṣe ọlọ́jọ́ kan ní ibi ìṣeré ìdárayá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Wọ́n ṣe ìpàdé àkànṣe àkọ́kọ́ ní October 1993. Ìwé ìròyìn Słowo Polskie sọ pé, àwọn ẹlẹ́wọ̀n 15 ló wà nípàdé náà, “odindi ìdílé, títí kan àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wẹẹrẹ, wá láti Wrocław,” àròpọ̀ gbogbo àwọn tó wá sípàdé náà sì jẹ́ 139. Wọ́n lo àkókò ìsinmi ní ìpàdé náà láti gbádùn oúnjẹ tí àwọn arábìnrin sè, wọ́n sì rí àyè láti ní ìfararora gbígbámúṣé gẹ́gẹ́ bí Kristẹni.
Wọ́n ti ṣe ìpàdé àkànṣe méje mìíràn lẹ́yìn ìyẹn, kì í sì í ṣe àwọn tí wọ́n wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà nìkan ni wọ́n ti jàǹfààní rẹ̀, àwọn tí wọ́n wà níta pẹ̀lú ti jẹ níbẹ̀. Nígbà tí arábìnrin kan tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan tó ti ṣẹ̀wọ̀n ní Wołów rí, ṣùgbọ́n tó ti ń gbé ìlú báyìí, kò fẹ́ gbà wọ́n láyè lákọ̀ọ́kọ́. Àmọ́ nígbà tí wọ́n sọ fún ọkùnrin náà pé ẹlẹ́wọ̀n kan báyìí ti di Ẹlẹ́rìí, ó sọ̀rọ̀ tìyanutìyanu pé: “Apààyàn yẹn ti di Ẹlẹ́rìí kẹ̀?” Ní àbájáde rẹ̀, ọkùnrin náà tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Àbájáde Ìyípadà Àgbàyanu
Ǹjẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ńlá yìí ti mú ọkàn yíyigbì àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà rọ̀ ní ti gidi? Ẹ jẹ́ kí àwọn fúnra wọn ṣàlàyé.
Zdzisław, tí ó jẹ́ ẹ̀dá onílàákàyè, jẹ́wọ́ pé: “N kò mọ àwọn òbí mi rárá nítorí pé wọ́n gbé mi jù sílẹ̀ nígbà tí mo wà lọ́mọdé, ìyà tí ó sì jẹ́ mí jù lọ ni pé n kò nímọ̀lára pé a nífẹ̀ẹ́ mi rí. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé mi ni mo ti ń dáràn kiri, tí mo sì pànìyàn níkẹyìn. Ìmọ̀lára ẹ̀bi sún mi ronú pípa ara mi, mo sì ń fi ìgbékútà wá ìrètí gidi kiri. Nígbà tí ó sì di 1987, mo rí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ níbì kan. Mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrètí àjíǹde àti ìyè ayérayé nínú rẹ̀. Nígbà tí mo mọ̀ pé ìrètí ṣì wà, mo gbàgbé èrò ti pípa ara mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nísinsìnyí, Jèhófà àti àwọn ará ti kọ́ mi ní ohun tí ìfẹ́ túmọ̀ sí.” Láti 1993 ni apànìyàn nígbà kan rí yìí ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, tí ó sì ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ó sì di aṣáájú ọ̀nà déédéé ní ọdún tó kọjá.
Ní ti Tomasz, ó tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láìjanpata. Ó jẹ́wọ́ pé: “Àmọ́, ìgbésẹ̀ yẹn kò wá láti ọkàn mi. Mo wulẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nítorí pé mo fẹ́ láti máa yangàn tí mo bá ń ṣàlàyé ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ fún àwọn ẹlòmíràn ni. Ṣùgbọ́n n kò ṣe nǹkan gúnmọ́ kan nípa òtítọ́ Bíbélì. Lọ́jọ́ kan, mo pinnu lọ́kàn mi, mo sì lọ sí ìpàdé Kristẹni. Ẹlẹ́wọ̀n tó ti ṣe batisí náà kí mi káàbọ̀ tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Mo wá mọ̀ pé dípò kí n máa gbìyànjú láti fi ìmọ̀ yangàn, mo ní láti yí ọkàn mi tí ó yigbì padà, kí n sì yí èrò inú mi padà.” Tomasz bẹ̀rẹ̀ sí gbé àkópọ̀ ìwà tuntun ti Kristẹni wọ̀. (Éfésù 4:22-24) Lónìí, ó ti di Ẹlẹ́rìí tí ó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, tí ó sì ti ṣe batisí, ó sì ń rí ìdùnnú nínú wíwàásù ní àwọn ilé inú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà.
Àwọn Ọ̀rẹ́ Àtijọ́ Ń Fìtínà Wọn
Àwọn ọ̀rẹ́ àtijọ́ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n àti àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n bẹ̀rẹ̀ sí fìtínà àwọn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì ní ọgbà ẹ̀wọ̀n gan-an. Ọ̀kan lára wọn rántí pé: “Ìgbà gbogbo ni wọ́n ń yọ ṣùtì sí mi, wọ́n sì ń fi mí ṣẹ̀sín. Àmọ́ mo fi ìṣírí tí àwọn ará ń fún mi sọ́kàn. Wọ́n ní kí ń ‘máa gbàdúrà sí Jèhófà. Kí n máa ka Bíbélì mi, n óò sì ní àlàáfíà ọkàn.’ Ìyẹn ràn mí lọ́wọ́ gan-an.”
Ryszard, arákùnrin kan tí ó lómi lára, tí ó sì ti ṣe batisí, sọ pé: “Àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ mi kì í fi ọ̀rọ̀ rò mí wò, kí wọ́n tó sọ̀rọ̀ burúkú sí mi. Wọ́n máa ń kìlọ̀ fún mi pé: ‘O lè máa lọ sí ìpàdé yín, àmọ́ má ṣe bí ènìyàn gidi kan, máà díbọ́n bí pé o sàn jù, ṣé o gbọ́?’ Ìgbàkigbà tí mo bá ṣe àwọn ìyípadà kan nínú ìgbésí ayé mi nítorí fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, wọ́n máa ń fìyà rẹ̀ jẹ mí. Wọ́n dojú bẹ́ẹ̀dì mi délẹ̀, wọ́n fọ́n àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi káàkiri ilẹ̀, wọ́n sì ba apá ibi tí mo ń lò sí nínú iyàrá ẹ̀wọ̀n jẹ́. Mo gbàdúrà sí Jèhófà fún okun láti kó ara mi níjàánu, mo sì rọra tún àwọn ẹrù mi tò padà. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, wọ́n jáwọ́ ìgbóguntì náà.”
Àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn tí wọ́n ti ṣe batisí sọ pé: “Ìgbàkigbà tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ wa bá rí i pé a ti ṣèpinnu tí kò lè yẹ̀ láti sin Jèhófà, wọn óò tún gba ọ̀nà mìíràn láti fìtínà wa. Wọ́n lè sọ pé, ‘Rántí pé kò yẹ kí ó máa mutí, kò yẹ kí o máa mu sìgá, kò sì yẹ kí o máa purọ́ mọ́.’ Irú ìfìtínà yẹn ń ran àwa alára lọ́wọ́ láti kó ara wa níjàánu, láti tètè tọwọ́ ìwà abèṣe tàbí sísọ nǹkan di bárakú èyíkéyìí bọlẹ̀. Ó tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti mú àwọn èso tẹ̀mí dàgbà.”—Gálátíà 5:22, 23.
Dídi Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Tí Ó Ṣèyàsímímọ́
Lábẹ́ àṣẹ àwọn alábòójútó ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, a ṣe batisí àkọ́kọ́ nínú gbọ̀ngàn eré ìdárayá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ní ìgbà ìrúwé ọdún 1991. Zdzisław ló ṣe batisí pẹ̀lú ìdùnnú nígbà náà. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n 12 ló wá sí ìpàdé náà, àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wá fún ìpàdé náà láti ìta jẹ́ 21. Ìpàdé náà ní ipa tí ń fúnni níṣìírí lórí àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà. Àwọn bí mélòó kan tẹ̀ síwájú lọ́nà tí ó kàmàmà débi pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n méjì mìíràn ṣe batisí ní apá ìparí ọdún yẹn. Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, ní 1993, ẹ̀ẹ̀mejì ni wọ́n ṣe batisí, àwọn ẹlẹ́wọ̀n méje mìíràn sì fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn sí Jèhófà hàn!
Ìwé ìròyìn àdúgbò náà, Wieczór Wrocławia, sọ nípa batisí tí a ṣe ní December pé: “Àwọn ènìyàn kàn ń rọ́ wá sí gbọ̀ngàn eré ìdárayá náà ni, wọ́n ń kí ara wọn, wọ́n sì ń bọ ara wọn lọ́wọ́. Kò sí ẹni tó ṣàjèjì ara wọn níbẹ̀. Wọ́n jẹ́ ìdílé ńlá kan, wọ́n sì ṣọ̀kan ní ìrònú, ní ọ̀nà ìgbésí ayé, àti nínú sísin Ọlọ́run kan, Jèhófà.” Àwọn 135 ni wọ́n jẹ́ “ìdílé ńlá kan” yẹn, tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n 50 sì wà lára wọn nígbà yẹn. Ẹ jẹ́ kí a bá díẹ̀ lára wọn sọ̀rọ̀.
Jerzy, tí ó ṣe batisí ní June, sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti gbọ́ nípa òtítọ́ Bíbélì lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, ọkàn mi yigbì gan-an nígbà yẹn. Mo ń lu jìbìtì, mo kọ ìyàwó àárọ̀ mi sílẹ̀, mo ń bá Krystyna ṣèṣekúṣe, mo bímọ kan síta, mo máa ń ṣẹ̀wọ̀n léraléra—irú ìgbésí ayé tí mo ń gbé nígbà kan nìyẹn.” Nígbà tí ó rí i tí àwọn ọ̀daràn paraku mìíràn di Ẹlẹ́rìí nígbà tí wọ́n wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Ṣé èmi náà ò lè yí padà ni?’ Ó béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wá sí ìpàdé. Àmọ́, àkókò ìyípadà ńlá gidi náà dé nígbà tí agbẹjọ́rò ìjọba sọ fún un pé Krystyna ti di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ìdunta. Jerzy sọ pé: “Ẹnu yà mi gan-an! Mo rò nínú ara mi pé, ‘Èmi náà ń kọ́? Èwo ni mo ń ṣe?’ Mo mọ̀ pé kí Jèhófà tó lè tẹ́wọ́ gbà mí, mo ní láti tún ayé mi ṣe.” Ní àbáyọrí rẹ̀, òun àti Krystyna àti Marzena, ọmọbìnrin wọn ọlọ́dún 11, tún padà ṣọ̀kan nígbà tí ó ṣì wà lẹ́wọ̀n. Láìpẹ́ láìjìnnà, wọ́n ṣègbéyàwó lábẹ́ òfin. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, tí ìṣòro rẹ̀ kò sì tí ì tán, láìpẹ́ yìí, Jerzy kọ́ ara rẹ̀ ní èdè àwọn adití, ó sì ṣeé ṣe fún un láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n jẹ́ adití.
Ìgbà tí Mirosław ti wà ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ló ti ń dáràn kiri. Ó nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń ṣe gan-an, kò sì pẹ́ tí òun náà bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí tiwọn. Ó ti ja ọ̀pọ̀ ènìyàn lólè, ó sì ti lu ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ó wá bá ara rẹ̀ lẹ́wọ̀n. Mirosław jẹ́wọ́ pé: “Nígbà tí mo bá ara mi lẹ́wọ̀n, mo tọ àlùfáà lọ pé kí ó ràn mí lọ́wọ́. Àmọ́, ìjákulẹ̀ tí mo rí kò ṣeé fẹnu sọ. Ìdí nìyẹn tí mo ṣe pinnu pé n óò gbé májèlé jẹ.” Ní ọjọ́ náà gan-an tí ó wéwèé pé òun yóò pa ara òun, wọ́n gbé e lọ sí ilé mìíràn lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà. Ó rí ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ kan níbẹ̀ tí ó sọ nípa ète ìgbésí ayé. Ó sọ síwájú pé: “Àlàyé rẹ̀ rírọrùn, tí ó sì ṣe kedere ni mo nílò gan-an. Ní báyìí n kò fẹ́ kú mọ́! Ìdí nìyẹn tí mo fi gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì ní kí Àwọn Ẹlẹ́rìí máa wá bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ó yára tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀, ó sì ṣe batisí ní 1991. Ní báyìí, ó ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, ó sì láǹfààní láti máa wàásù ní àwọn ilé inú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà.
Títí di báyìí, àwọn ẹlẹ́wọ̀n 15 ni wọ́n ti ṣe batisí. Àpapọ̀ iye ọdún tí a bù fún wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 260. Wọ́n dá àwọn kan sílẹ̀ kí wọ́n tó parí ọdún tí a bù fún wọn. Wọ́n bu ọdún 10 kúrò lára ọdún 25 tí wọ́n bù fún ẹlẹ́wọ̀n kan. Àwọn mélòó kan tí wọ́n fi ìfẹ́ hàn nígbà tí wọ́n wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n sì di Ẹlẹ́rìí tí a batisí lẹ́yìn tí wọ́n tú wọn sílẹ̀. Ní àfikún sí i, àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́rin ń múra sílẹ̀ fún ìrìbọmi.
Ohun Tí Àwọn Aláṣẹ Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Sọ
Ìròyìn kan láti ọgbà ẹ̀wọ̀n náà sọ pé: “Ìyípadà tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ń ṣe hàn gan-an. Ọ̀pọ̀ lára wọn ni kì í mu sìgá mọ́, wọ́n sì ń tún ibi tí wọ́n ń gbé nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ṣe. Ọ̀pọ̀ ẹlẹ́wọ̀n ni irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ hàn nínú ìhùwà wọn.”
Ìwé ìròyìn Życie Warszawy sọ pé ẹgbẹ́ àwọn alákòóso ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Wołów sọ pé, “àwọn tí wọ́n di onígbàgbọ́ náà ti wá di ọmọlúwàbí; wọn kì í fún àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà níṣòro rárá.” Àpilẹ̀kọ náà sọ síwájú sí i pé, àwọn tí wọ́n dá sílẹ̀ kí wọ́n tó parí ọdún tí a bù fún wọn ti mú ìwà wọn bá ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mu gan-an, wọn kò sì padà sídìí ìwà ọ̀daràn mọ́.
Kí wá ni èrò alábòójútó ọgbà ẹ̀wọ̀n náà? Ó wí pé: “Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n yìí ni ó wuni jù lọ, òun ni ó sì ṣèrànwọ́ jù lọ.” Alábòójútó náà sọ gbangba pé, “lákòókò tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì [lọ́dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí], ìwà àti ọ̀pá ìdiwọ̀n wọn ti yí padà, èyí sì ń fún wọn ní ìtọ́sọ́nà tuntun nínú ìgbésí ayé wọn. Ìwà wọn mọ́gbọ́n dání, ó sì jẹ́ ti ọmọlúwàbí. Wọn kì í fiṣẹ́ ṣeré, wọn kì í sì í fa wàhálà.” Ní gidi, irú àwọn ọ̀rọ̀ dáradára bẹ́ẹ̀ tí àwọn aláṣẹ ń sọ ń dùn mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Wołów nínú.
Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń bẹ ibẹ̀ wò mọrírì ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Mo . . . mọ àwọn àgùntàn mi, àwọn [àgùntàn] mi sì mọ̀ mí. . . . wọn yóò . . . fetí sí ohùn mi, wọn yóò sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.” (Jòhánù 10:14, 16) Àwọn ògiri ọgbà ẹ̀wọ̀n pàápàá kò lè dí Olùṣọ́ Àgùntàn Rere náà, Jésù Kristi, lọ́wọ́ kíkó àwọn ẹni bí àgùntàn jọ. Inú Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Wołów dùn pé àwọn ní àǹfààní nínípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn aláyọ̀ yìí. Wọ́n sì ń wojú Jèhófà fún ìbùkún rẹ̀ tí kò dáwọ́ dúró nínú ríran ọkàn yíyigbì púpọ̀ sí i lọ́wọ́ láti gbọ́ ìhìn rere náà kí òpin tó dé.—Mátíù 24:14.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
Ìṣòro “Àgbàlagbà Tí Ń Ṣe Bí Ọmọdé”
Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń ṣiṣẹ́ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Wołów sọ pé: “Lẹ́yìn wíwà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ìgbà díẹ̀, ẹlẹ́wọ̀n kan kì í sábà mọ ohun tí ó túmọ̀ sí láti wà láìgbára lé ẹnikẹ́ni, tàbí láti máa dá gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Ìṣòro tí a sábà máa ń ní ni ìṣòro ‘àgbàlagbà tí ń ṣe bí ọmọdé,’ ẹni tí kò mọ bí yóò ṣe máa gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ lẹ́yìn tí a bá tú u sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Ìdí nìyẹn tí ipa tí ìjọ ń kó fi ré kọjá kìkì kíkọ́ ọ ní òtítọ́ Bíbélì. A ní láti múra rẹ̀ sílẹ̀ fún dídi apá kan àwùjọ, kí a kìlọ̀ fún un nípa àwọn ewu tuntun àti ìtànjẹ tí ó lè kojú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní láti ṣọ́ra fún ríràdọ̀ bò ó jù, a gbọ́dọ̀ ràn án lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé lákọ̀tun.”