ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 12/15 ojú ìwé 29
  • Àwọn Ọ̀mọ̀wé Sọ Déètì Mìíràn Tí A Kọ Bíbélì Àfọwọ́kọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọ̀mọ̀wé Sọ Déètì Mìíràn Tí A Kọ Bíbélì Àfọwọ́kọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 12/15 ojú ìwé 29

Àwọn Ọ̀mọ̀wé Sọ Déètì Mìíràn Tí A Kọ Bíbélì Àfọwọ́kọ

Gẹ́gẹ́ bí Carstem Peter Thiede, ọmọ ilẹ̀ Germany, tó jẹ́ ògbógi nínú ìwádìí lórí àwọn òrépèté tí a kọ ọ̀rọ̀ kún ti sọ, ẹ̀rí tó dájú hán-ún hán-ún wà pé, ọ̀rúndún kìíní ni a kọ àwọn àjákù òrépèté mẹ́ta ti ìwé Ìhìn Rere ti Mátíù (tí a mọ̀ sí Òrépèté ti Magdalen).

Lẹ́yìn tí Thiede fi àwọn àjákù (tó ní apá kan Mátíù orí 26 nínú) wéra pẹ̀lú lẹ́tà okòwò láéláé kan tí a rí ní Íjíbítì, ó ṣàkíyèsí pé, lẹ́tà ará Íjíbítì náà pẹ̀lú “Òrépèté ti Magdalen jọra wọn gan-an—ní ti bí wọ́n ṣe rí, bí wọ́n ṣe fẹ̀ tó àti bí a ṣe kọ ọ̀rọ̀ kún wọn, wọ́n mà jọra o.” Thiede àti ajùmọ̀ṣèwé náà, Matthew D’Ancona parí èrò nínú ìwé wọn Eyewitness to Jesus—Amazing New Manuscript Evidence About the Origin of the Gospels pé ìjọra tó wà láàárín àwọn àkọsílẹ̀ méjèèjì fi hàn pé, àfàìmọ̀ ni kò fi ní jẹ́ pé àkókò kan náà la kọ wọ́n. Ìgbà wo wá nìyẹn? Déètì tó wà lórí lẹ́tà náà ni “‘Ní ọdún kejìlá ti Olúayé Nero, Epeiph 30’—lórí kàlẹ́ńdà tiwa, ó jẹ́ July 24, ọdún 66 [Sànmánì Tiwa.]”

Ọ̀jọ̀gbọ́n Philip W. Comfort sọ nínú àpilẹ̀kọ kan tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé Tyndale Bulletin, pé: “Bó bá jẹ́ pé déètì yìí tọ̀nà lóòótọ́, a jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì gan-an, nítorí pé ó fi ìwé àfọwọ́kọ ti Ìhìn Rere Mátíù sí ọ̀rúndún náà gan-an tí a kọ ọ́.” Yóò sì tún jẹ́ kí Òrépèté ti Magdalen jẹ́ àjákù òrépèté ti ìwé Ìhìn Rere tó lọ́jọ́ lórí jù lọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda President and Fellows of Magdalen College, Oxford

[Credit Line]

Òrépèté ti Magdalen, bó ṣe fẹ̀ tó

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́