Ìpinnu Tó Gbé Ẹ̀tọ́ Yíyàn Lárugẹ
KÒ TÚN sí ẹlòmíràn tó lè fọwọ́ sí ẹ̀tọ́ yíyàn bí kò ṣe Ọ̀ga Ògo jù lọ ní gbogbo àgbáyé. Òun ni Ẹlẹ́dàá wa. Nítorí, ó mọ gbogbo ohun tí ènìyàn nílò, ó fún wá nítọ̀ọ́ni, ìkìlọ̀, àti ìtọ́sọ́nà tí ó pọ̀ tó nípa ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu láti tọ̀. Síbẹ̀, kò ṣàìnáání agbára ìmọnúúrò tí ó fi jíǹkí àwọn ẹ̀dá onílàákàyè tí ó dá. Mósè, wòlíì Ọlọ́run, sọ ojú ìwòye Ọlọ́run pé: “Èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ìfiré; kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ.”—Diutarónómì 30:19.
Ìlànà yìí ṣeé lò nínú ìmọ̀ ìṣègùn. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, èròǹgbà ẹ̀tọ́ yíyàn, tàbí ìjọ́hẹn fun ìtọ́jú ìṣègùn, ń di ohun tí a tẹ́wọ́ gbà ní ilẹ̀ Japan àti ní àwọn ilẹ̀ mìíràn tí kò gbajúmọ̀ tẹ́lẹ̀. Bí Dókítà Michitaro Nakamura ṣe ṣàlàyé ìjọ́hẹn fún ìtọ́jú ìṣègùn nìyí: “Èròǹgbà náà ni pé, dókítà yóò ṣàlàyé àwọn nǹkan wọ̀nyí fún aláìsàn tó wá gbàtọ́jú lọ́nà tó lè tètè lóye, irú àìsàn tó ń ṣe é, bí ara rẹ̀ yóò ṣe mókun, ọ̀nà tí wọn óò gbà tọ́jú rẹ̀ àti ewu tó lè tibẹ̀ jáde, yóò sì bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ tí aláìsàn náà ní láti fúnra rẹ̀ pinnu irú ìtọ́jú tí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn.”—Japan Medical Journal.
Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn dókítà ní Japan ti ṣàlàyé onírúurú ìdí tí wọn kò fi fara mọ́ lílo ìlànà yìí láti tọ́jú àwọn aláìsàn, ó sì dà bí pé àwọn ilé ẹjọ́ fẹ́ tẹ́wọ́ gba àṣà àwọn onímọ̀ ìṣègùn yìí. Nípa báyìí, ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé ló jẹ́ nígbà tí Adájọ́ Àgbà ti Ilé Ẹjọ́ Gíga ní Tokyo, Takeo Inaba, gbé ìpinnu kan kalẹ̀ ní February 9, 1998 tó gbé ẹ̀tọ́ yíyàn lárugẹ. Kí ni ìpinnu ọ̀hún, kí ló sì mú kí wọ́n gbé ọ̀ràn náà lọ sí ilé ẹjọ́?
Ní July 1992 mà ni o, Misae Takeda, ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta, tó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lọ sí Ilé Ìwòsàn Ẹ̀ka Ìmọ̀ Ìṣègùn, ti Yunifásítì Tokyo. Àyẹ̀wò ìṣègùn ti fi hàn pé kókó ọlọ́yún wà nínú ẹ̀dọ̀ màmá yìí, kò sì sí lọ-ká-bọ̀, wọ́n ní láti ṣe iṣẹ́ abẹ fún un ni. Nítorí pé ó fẹ́ gidigidi láti ṣègbọràn sí àṣẹ Bíbélì tó lòdì sí àṣìlò ẹ̀jẹ̀, ó sọ fún àwọn oníṣègùn náà pé, ìtọ́jú ìṣègùn tí kò ní la lílo ẹ̀jẹ̀ lọ ní òun ń fẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4; Ìṣe 15:29) Àwọn oníṣègùn náà sọ pé kó tọwọ́ bọ̀wé pé, bí ọ̀ràn náà bá yíwọ́, kò gbún àwọn, èyí yóò yọ àwọn àti ilé ìwòsàn náà kúrò nínú wàhálà, bí ìpinnu tó ṣe bá lọ jẹ́ kí ọ̀ràn náà di nǹkan mì-í-ì. Wọ́n fọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé ohun tó fẹ́ gan-an làwọn óò ṣe.
Àmọ́, nígbà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ náà tán, tí oògùn oorun tí wọ́n lò fún Misae kò sì tí ì ṣiṣẹ́ tán, wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára—ohun tó sọ gbọnmọgbọnmọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe. Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà tó fi ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ tí a fà sí màmá yìí lára tó oníròyìn kan létí ló jẹ́ kí gbogbo akitiyan láti bo ọ̀ràn náà mọ́lẹ̀ já sí pàbó. Gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, ọkàn Kristẹni obìnrin olóòótọ́ yìí gbọgbẹ́ nígbà tó gbọ́ pé wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sí òun lára láìgba àṣẹ. Àwọn èèyàn tó ṣeé fọkàn tán ló pe àwọn òṣìṣẹ́ ìṣègùn wọ̀nyí, ó gbà gbọ́ pé wọn kò ní sọ ohun kan kí wọ́n lọ ṣe ohun mìíràn lẹ́yìn, ó gbà pé wọ́n á bọ̀wọ̀ fún ìgbàgbọ́ òun. Nítorí làásìgbò tí yíyẹ àdéhùn tó wà láàárín òun àti àwọn dókítà náà mú bá a, àti nítorí pé ó fẹ́ fi àpẹẹrẹ kan lélẹ̀ tí kò ní jẹ́ kí wọ́n tún hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ sí àwọn ẹlòmíràn lẹ́yìnwá ọ̀la, ó gbé ọ̀ràn náà lọ sí ilé ẹjọ́.
Ìwàlétòlétò Ará Ìlú àti Ìwà Híhù
Adájọ́ mẹ́ta ti Kóòtù Àgbègbè Tokyo ló gbọ́ ẹjọ́ náà, wọ́n sì dá àwọn oníṣègùn náà láre, nípa báyìí, ẹ̀tọ́ ìjọ́hẹn fún ìtọ́jú ìṣègùn kò rọ́wọ́ mú. Nínú ìpinnu wọn tí wọ́n gbé kalẹ̀ ní March 12, 1997, wọ́n sọ pé, ìgbìyànjú èyíkéyìí láti wọnú àdéhùn àìní-lo-ẹ̀jẹ̀ rárá nínú ìtọ́jú ìṣègùn kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ohun tí wọ́n dì mú ni pé, ó lòdì sí kojo ryozoku,a tàbí ìlànà àwùjọ, pé kí oníṣègùn kan wọnú àdéhùn àkànṣe kan láti má ṣe lo ẹ̀jẹ̀ kódà nígbà tí ipò bá mú kó pọndandan. Èrò wọn ni pé, ojúṣe dókítà ni láti lo gbogbo ọ̀nà tó bá lè lò láti gba ẹ̀mí là, nítorí náà, láìka ohun tí aláìsàn náà gbà gbọ́ sí, àdéhùn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni wọ́n ka irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ sí. Wọ́n sọ pé, ní àbárèbábọ̀, èrò oníṣègùn kan nípa iṣẹ́ rẹ̀ ni yóò borí ohun yòówù tí aláìsàn ti lè béèrè fún tẹ́lẹ̀.
Síwájú sí i, àwọn adájọ́ náà sọ pé nítorí ìdí kan náà tí wọ́n ti mẹ́nu bà, nígbà tí a bá retí kí oníṣègùn kan ṣàlàyé àwọn ọ̀nà ìtọ́jú tí yóò lò, ipa tó lè ní, àti àbájáde iṣẹ́ abẹ tó fẹ́ ṣe, ó “lè má sọ ní pàtó pé òun yóò lo ẹ̀jẹ̀ tàbí pé òun kò ní lò ó.” Ìdájọ́ wọn ni pé: “A kò lè sọ pé àwọn dókítà náà, gẹ́gẹ́ bí Olùjẹ́jọ́, ru òfin tàbí pé wọ́n jẹ̀bi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé Olùpẹ̀jọ́ kò fẹ́ gbẹ̀jẹ̀ lábẹ́ ipò èyíkéyìí, tí wọ́n sì ṣe bí ẹni pé àwọn yóò bọ̀wọ̀ fún ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ kí ó lè gbà láti ṣe iṣẹ́ abẹ́ tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí.” Èrò náà ni pé, ká ní àwọn oníṣègùn náà kò ti dọ́gbọ́n bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe kí aláìsàn náà máà jẹ́ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ yìí, kí ó sì forí lé ilé rẹ̀.
Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ yẹn ya àwọn alágbàwí ìjọ́hẹn fún ìtọ́jú ìṣègùn lẹ́nu, ó sì kó gìrìgìrì bá wọn. Nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Takao Yamada, abẹnugan kan nínú òfin ẹ̀tọ́ ẹni, ń sọ̀rọ̀ nípa ìpinnu ilé ẹjọ́ lórí ọ̀ràn Takeda àti ipa tó ní lórí ìjọ́hẹn fún ìtọ́jú ìṣègùn, ó kọ̀wé pé: “Bí a bá gbà kí ìpinnu ilé ẹjọ́ yìí di èyí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ pẹ́nrẹ́n, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni kíkọ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀ àti ìlànà tó bófin mu nípa ìjọ́hẹn fún ìtọ́jú ìṣègùn yóò di ìgbàgbé.” (Ìwé ìròyìn òfin Hogaku Kyoshitsu) Ó bẹnu àtẹ́ lu fífipá fẹ̀jẹ̀ síni lára, ó pè é ní “ìwà ọ̀dàlẹ̀ pátápátá gbáà, tí a tún lè fi wé kíkọluni lójijì.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Yamada fi kún un pé, “a kò gbọ́dọ̀ fàyè gba” irú ìwà ọ̀bàyéjẹ́ bẹ́ẹ̀ rárá.
Nítorí tí Misae jẹ́ onítìjú, ìṣoro ni ó jẹ́ fún un pé kí a gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ wá sí ojútáyé. Àmọ́ nígbà tó wá mọ̀ pé òun lè nípìn-ín nínú jíjà fún orúkọ Jèhófà àti ìlànà òdodo rẹ̀ nípa ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀, ó gbà láti ṣe ipa tirẹ̀. Ó kọ̀wé sí agbẹjọ́rò rẹ̀ pé: “Erùpẹ̀ lásán làsàn ni mí. Bí ó ṣe wá jẹ́ irú mi tí kò já mọ́ nǹkan kan bẹ́ẹ̀ ní a ó lò yà mí lẹ́nu. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí Jèhófà—ẹni tó lè mú kí òkúta fọhùn—wí, yóò kúkú fún mi lágbára.” (Mátíù 10:18; Lúùkù 19:40) Níbi ìdúró-rojọ́ nígbà ìgbẹ́jọ́ náà, ṣe ni ohùn rẹ̀ ń gbọ̀n nígbà tó ń ṣàpèjúwe làásìgbò tí ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí a hù sí i mú bá a. “Ohun tí mo kà á sí ni pé wọ́n ṣèkà sí mi, bí ìgbà tí ẹnì kan bá fipá bá obìnrin lò pọ̀.” Ọ̀pọ̀ tó wà nínú ilé ẹjọ́ lọ́jọ́ táà ń wí yìí ló da omi lójú.
Ọ̀rọ̀ Ìṣírí Tó Yani Lẹ́nu
Nítorí ẹjọ́ tí Kóòtù Àgbègbè dá yìí, kíá ni a pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga. Ìjiyàn àkọ́kọ́ ní ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà bẹ̀rẹ̀ ní July 1997, àga aláìsàn ni a sì fi gbé Misae, tí àwọ̀ rẹ̀ ti ṣì, wá síbẹ̀, àmọ́ ṣá ó, ìpinnu rẹ̀ kò tí ì yí padà. Àrùn jẹjẹrẹ náà tún ti padà mú un, agbára rẹ̀ sì ń dín kù ṣáá. Lọ́nà tó ṣàjèjì, a fún Misae ní ìṣírí gidigidi nígbà tí adájọ́ àgbà náà sọ ohun tí ilé ẹjọ́ fẹ́ ṣe. Ó là á mọ́lẹ̀ pé ilé ẹjọ́ náà kò fara mọ́ ìpinnu ilé ẹjọ́ kékeré—pé, oníṣègùn kan lẹ́tọ̀ọ́ láti fọwọ́ rọ́ ìfẹ́ ọkàn aláìsàn tó wá gbàtọ́jú tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, tí oníṣègùn ọ̀hún wá ṣe bí ẹni pé ó fara mọ́ ọn, àmọ́, tí ó jẹ́ pé lọ́kàn rẹ̀, àrà mìíràn ló fẹ́ dá. Adájọ́ àgbà náà sọ pé, bó bá di ti ọ̀ràn ìmọ̀ ìṣègùn, ilé ẹjọ́ náà kò ní fara mọ́ ìlànà àbáláyé ti “Shirashimu bekarazu, yorashimu beshi,”b tó túmọ̀ sí pé, “Má ṣe finú hàn wọ́n, kí wọ́n má sì lè dá ìpinnu ṣe” nínú ọ̀ràn ìṣègùn. Níkẹyìn, Misae wí pé: “Inú mi dùn jọjọ fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀ tí kò gbè sẹ́yìn ẹnikẹ́ni lẹ́nu adájọ́ náà, èyí tó yàtọ̀ pátápátá sí ìdájọ́ Kóòtù Àgbègbè.” Ó fi kún un pé: “Ohun tí mo ti ń gbàdúrà sí Jèhófà fún tipẹ́tipẹ́ nìyí.”
Àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ tí wọ́n fẹ́ràn rẹ̀ gidigidi àti agbo òṣìṣẹ́ ìṣègùn ti ilé ìwòsàn mìíràn, tí wọ́n lóye ìgbàgbọ́ rẹ̀, tí wọn kò sí kó iyán ọ̀ràn ìgbàgbọ́ rẹ̀ kéré wà lọ́dọ̀ Misae kó tó kú ní oṣù tó tẹ̀ lé e. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú rẹ̀ ba ọmọ rẹ̀, Masami, àti àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ yòókù lọ́kàn jẹ́, wọ́n pinnu láti rí i pé àwọn bá ẹjọ́ náà dé òpin, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn Misae.
Ìpinnu Ilé Ẹjọ́
Níkẹyìn, ní February 9, 1998, àwọn adájọ́ mẹ́ta ti Ilé Ẹjọ́ Gíga gbé ìdájọ́ wọn kalẹ̀, wọ́n yí ìpinnu ilé ẹjọ́ kékeré yẹn padà. Àwọn oníròyìn, àwọn ọ̀mọ̀wé, àti àwọn mìíràn tí wọ́n ti ń fọkàn bá ìgbẹ́jọ́ náà lọ kún kóòtù tí kò tóbi náà fọ́fọ́. Àwọn ìwé ìròyìn pàtàkì pàtàkì àti àwọn ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán gbé ìpinnu náà jáde. Díẹ̀ lára àwọn àkọlé ìròyìn kà pé: “Kóòtù: Aláìsàn Lẹ́tọ̀ọ́ Àtikọ Ìtọ́jú”; “Ilé Ẹjọ́ Gíga: Ìfàjẹ̀sínilára Jẹ́ Fífi Ẹ̀tọ́ Ẹni Duni”; “Dókítà Tó Fipá Fẹ̀jẹ̀ Síni Lára Jẹ̀bi Nílé Ẹjọ́”; àti “Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbowó Gbà-Máà-Bínú fún Fífẹ̀jẹ̀ Sí I Lára.”
Àwọn ìròyìn tí wọ́n kọ nípa ìpinnu yìí péye, ó sì fi hàn pé a dá wa láre lọ́nà kíkọ yọyọ. Ìwé ìròyìn The Daily Yomiuri ròyìn pé: “Adájọ́ Takeo Inaba wí pé, kò bójú mu rárá kí àwọn dókítà ṣe ohun kan tí aláìsàn ti kọ̀.” Ó tún là á mọ́lẹ̀ pé: “Àwọn dókítà tí wọ́n [fẹ̀jẹ̀ sí i lára] fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ tó ní láti yan irú ìtọ́jú tó fẹ́ dù ú.”
Ìwé ìròyìn Asahi Shimbun sọ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú ẹjọ́ yìí, ilé ẹjọ́ náà gbà pé kò sí ẹ̀rí kíkún pé, àdéhùn kan wà láàárín aláìsàn náà àti oníṣègùn, nínú èyí tí àwọn méjèèjì ti fohùn ṣọ̀kan pé kódà bí ẹ̀mí aláìsàn náà bá fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́, wọn kò ní lo ẹ̀jẹ̀, àwọn adájọ́ ta ko sísọ tí ilé ẹjọ́ kékeré náà sọ pé àdéhùn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ní irú àdéhùn bẹ́ẹ̀, wọ́n sọ pé: “Bí àdéhùn kan tí aláìsàn àti àwọn oníṣègùn náà fikùnlukùn lé lórí bá wà láàárín àwọn méjèèjì pé, wọn ò gbọ́dọ̀ fa ẹ̀jẹ̀ sí aláìsàn náà lára lábẹ́ ipò èyíkéyìí, Ilé Ẹjọ́ yìí kò ka èyí sí ohun tó lòdì sí ìwàlétòlétò ará ìlú, tí a lè wá torí rẹ̀ sọ pé kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.” Síwájú sí i, ìwé ìròyìn yìí darí àfiyèsí sí èrò àwọn adájọ́ náà pé “kò sẹ́ni tí kò ní kú, ẹnì kọ̀ọ̀kan ló sì lẹ́tọ̀ọ́ àtipinnu irú ọ̀nà tí òun fẹ́ gbà kú.”
Ká sọ̀rọ̀ síbi ọ̀rọ̀ wà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wádìí ọ̀ràn yìí jinlẹ̀, ó sì dá wọn lójú gbangba pé ọ̀nà ìgbésí ayé tí wọ́n yàn ni èyí tó dára jù lọ. Ìyẹn kan kíkọ jàǹbá táráyé ti mọ̀ nípa gbígba ẹ̀jẹ̀ sára àti títẹ́wọ́gba ọ̀nà ìtọ́jú tí kò la lílo ẹ̀jẹ̀ lọ, èyí tó wọ́pọ̀ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, tí ó sì bá òfin Ọlọ́run mu. (Ìṣe 21:25) Ìlú-mọ̀ọ́ká ọmọ ilẹ̀ Japan kan, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú àgbékalẹ̀ òfin, sọ pé: “Ká sòótọ́, kíkọ [ìfàjẹ̀sínilára] tó fa arukutu yìí, kì í ṣe ọ̀ràn yíyàn ‘láti kú’ bí kò ṣe, yíyàn láti wà láàyè.”
Ìpinnu Ilé Ẹjọ́ Gíga yìí yẹ kó jẹ́ kí àwọn oníṣègùn súnra kì, kí wọ́n mọ̀ pé ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti lo àtinúdá kò tó bí àwọn kan ti rò pé ó tó. Ó sì yẹ kó sún ọ̀pọ̀ ilé ìwòsàn láti gbé àwọn ìlànà iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe kalẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo gbòò ló fara mọ́ ìpinnu ilé ẹjọ́ yìí, tí èyí sì fi ìṣírí fún àwọn aláìsàn, tó jẹ́ pé wọn kò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́nu ọ̀rọ̀ nípa bí a óò ṣe tọ́jú wọn, síbẹ̀ àwọn kan wà tí kò fi bẹ́ẹ̀ fara mọ́ ọn. Ilé ìwòsàn ìjọba àti àwọn oníṣègùn mẹ́ta tọ́ràn yìí kàn ti pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ. Ẹ jẹ́ ká ṣì máa wò ó bóyá ilé ẹjọ́ gíga jù lọ nílẹ̀ Japan yóò gbé ẹ̀tọ́ aláìsàn lárugẹ, bí Ọba Aláṣẹ àgbáyé ti ṣe gbé e lárugẹ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Èròǹgbà tí kò ní ìtumọ̀ nínú òfin, tí a fi sílẹ̀ fún adájọ́ láti túmọ̀ rẹ̀, kí ó sì lò ó.
b Èyí ni ìgbàgbọ́ àwọn ọ̀gá onílẹ̀ ti sáà Tokugawa nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣàkóso àwọn ọmọ abẹ́ wọn.