ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 12/15 ojú ìwé 32
  • Ìwọ Yóò Ha Fetí sí Ìkìlọ̀ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Yóò Ha Fetí sí Ìkìlọ̀ Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 12/15 ojú ìwé 32

Ìwọ Yóò Ha Fetí sí Ìkìlọ̀ Bí?

NÍ May 19, 1997, ìjì ńlá kan jà ní àgbègbè Chittagong, ní Bangladesh. Ni ìlú Cox Bazaar, ọwọ́ tí ẹ̀fúùfù táà ń wí yìí fi fẹ́ le tó àádọ́ta-lénígba kìlómítà láàárín wákàtí kan. Ní àwọn ìgbèríko, gáú ló ṣí gbogbo imọ̀ tí a fi bo ahéré, àwọn ògiri amọ̀ kúúkùùkù nìkan ló kù tí a lè rí ní ibi tí ahéré wà tẹ́lẹ̀. Ó hú igi tegbòtigaga, òpó wáyà ìbánisọ̀rọ̀ wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ; ó dá àwọn mìíràn sí méjì gbáú, bí ẹni dá igi ìṣáná. Àkọlé ìwé ìròyìn Bhorar Kagoj kan sọ pé, èèyàn márùndínláàádọ́fà ló bá ìjì ńlá náà rìn.

Ó ku nǹkan bí wákàtí mẹ́rìndínlógójì kí ìjì ńlá yìí jà ni ilé iṣẹ́ tí ń sọ̀rọ̀ nípa ojú ọjọ́ ti sọ àwọn apá ibi tí yóò jà dé. Kò sí àní-àní pé, fífi tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn lọ forí wọn pamọ́ sínú àwọn ilé oníkọnkéré, tí a kọ́ nítorí ìjì jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí là.

Ó mà ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kéde àjálù kan tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀, tí jàǹbá tí yóò ṣe yóò ju ti ìjì èyíkéyìí. “Ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà” mà ni Bíbélì pè é. (Jóẹ́lì 2:31) Bí a bá fetí sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì, a lè bọ́ lọ́wọ́ ìbínú ọjọ́ náà.—Sefanáyà 2:2, 3.

Ẹ jọ̀ọ́ o, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe alásọtẹ́lẹ̀ ibi. Iṣẹ́ tí ń fúnni nírètí ni wọ́n ń jẹ́. Wọ́n ń fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, tí yóò mú gbogbo àìṣòdodo kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, sọ fún wa pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò . . . sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

WHO/League of Red Cross

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́