Gbogbo Èèyàn Ló Fẹ́ Lómìnira
“A bí èèyàn lómìnira, àmọ́ gbogbo ọ̀nà ló fi wà nígbèkùn,” onímọ̀ ọgbọ́n orí, tó tún jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé, Jean-Jacques Rousseau, ló kọ̀wé bẹ́ẹ̀ lọ́dún 1762. Ká bí èèyàn lómìnira. Ìrònú kíkọyọyọ nìyẹn mà jẹ́ o! Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí Rousseau ti sọ, jálẹ̀ ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ni kò tọ́ òmìnira wò rí. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ti lo ìgbésí ayé wọn “nígbèkùn,” ètò kan ti há wọn mọ́ débi pé ó ti fi ayọ̀ pípẹ́ títí àti ìtẹ́lọ́rùn ìgbésí ayé dù wọ́n.
ÀRÀÁDỌ́TA ọ̀kẹ́ tó wà lónìí ló ṣì rí i pé “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Níbi tí wọ́n ti ń lépa ipò ńláńlá, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ń wá ipò ọlá ń bá a nìṣó láti máà tilẹ̀ bìkítà nípa títẹ òmìnira àwọn ẹlòmíràn ní àtẹ̀rẹ́. Ìròyìn kan tó jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ sọ pé: “Àwọn ẹgbẹ́ panipani pa èèyàn mọ́kànlélógún.” Òmíràn sọ nípa “ìpakúpa,” níbi tí àwọn ọmọ ogun ẹ̀ṣọ́ ‘ti ń pa àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé, àtàwọn àgbàlagbà tí kò lè gbèjà ara wọn, tí wọn kò sì lè janpata, tí wọ́n ń dúńbú wọn, tí wọ́n ń yìnbọn lu àwọn aráàlú tó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n lágbárí, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìlànà bíba ilẹ̀ tí ń pèsè oúnjẹ fún àwọn olódì wọn jẹ́, wọ́n run àwọn abúlé, wọ́n sì ń rọ̀jò ìbọn lé wọn lórí.’
Abájọ táwọn èèyàn fi ń fẹ́ jà fómìnira kúrò lọ́wọ́ ìnira lójú méjèèjì! Àmọ́ ṣá o, òótọ́ tó korò níbẹ̀ ni pé, bẹ́nìkan bá ń jà fómìnira ẹ̀, yóò máa tẹ ẹ̀tọ́ àti òmìnira àwọn ẹlòmíràn lójú. Nígbà tí èyí bá ń lọ lọ́wọ́, àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ ni a sábà máa ń fi ẹ̀mí wọn dí i, a óò wá máa pé ikú tó ń pa wọ́n “ní èyí tó bá ìlànà mu” nípa pípè é ní ohun tó tọ́, tó sì yẹ. Fún àpẹẹrẹ, lọ́dún tó kọjá, ní Ireland, bọ́ǹbù kan tí “àwọn ajàjàgbara” lọ gbé sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan ní abúlé kan ní Omagh pa èèyàn mọ́kàndínlọ́gbọ̀n tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀, tó kàn jẹ́ pé wọ́n wà nítòsí lásán ni, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn mìíràn ló sì fara pa.
A Ṣì Wà “Nígbèkùn” Síbẹ̀síbẹ̀
Nígbà tí ìjà náà bá parí, kí là ń rí gbà nínú ẹ̀? Nígbà tí “àwọn ajàjàgbara” bá ṣẹ́gun, wọ́n lè rí òmìnira díẹ̀ gbà. Àmọ́, ṣé wọ́n wà lómìnira lóòótọ́? Ṣé kì í ṣòótọ́ ni pé ní àwọn àwùjọ kan tí wọ́n ti gbòmìnira, àwọn tí a sábà ń pè ní ayé olómìnira, àwọn èèyàn ṣì wà “nígbèkùn” àwọn ohun tí ń gboni mọ́lẹ̀ bí òṣì, àìpé, àìsàn, àti ikú? Báwo lẹ́nì kan ṣe lè sọ pé òun wà lómìnira lóòótọ́ bí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bá mú un lẹ́rú?
Mósè, tó kọ apá kan Bíbélì nígbàanì ṣàpèjúwe ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láti ìgbà ìwáṣẹ̀, tó sì tún wà títí di òní olónìí. A lè wà láàyè fún àádọ́rin tàbí ọgọ́rin ọdún, ó wí pé, “síbẹ̀, wíwà nìṣó wọn jẹ́ lórí ìdààmú àti àwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́.” (Sáàmù 90:10) Ǹjẹ́ èyí yóò yí padà láé? Ǹjẹ́ ó ha lè ṣeé ṣe fún gbogbo wa láti gbé ìgbésí ayé tí ń tẹ́ni lọ́rùn ní kíkún, ìgbésí ayé tí kò ní ìrora àti ìpayà tí ọ̀pọ̀ ń nírìírí rẹ̀ lónìí?
Bíbélì sọ pé bẹ́ẹ̀ ni! Ó sọ nípa “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò òmìnira yẹn dáadáa, èyí tí a sọ nípa rẹ̀ nípasẹ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nínú lẹ́tà kan tó kọ sí àwọn Kristẹni ní Róòmù. Nínú lẹ́tà yìí, Pọ́ọ̀lù ṣe àlàyé bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè ní “òmìnira ológo” wíwà pẹ́ títí, òmìnira tòótọ́.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Láti inú ìwé náà Beacon Lights of History, Ìdìpọ̀ Kẹtàlá