ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 8/15 ojú ìwé 3-4
  • Ṣé Ìyè Wù Ọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ìyè Wù Ọ́?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Gbogbo Ojúṣe Ènìyàn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìgbésí Ayé Rẹ—Kí Ni Ète Rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Gbé Ìgbé Ayé Rere?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìgbésí Ayé Tó Dára—Nísinsìnyí àti Títí Láé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 8/15 ojú ìwé 3-4

Ṣé Ìyè Wù Ọ́?

“Ẹ JẸ́ kí n rí ìmọ́lẹ̀.” Ọ̀rọ̀ yìí la gbọ́ pé akéwì, tí í ṣe ọmọ ilẹ̀ Ítálì nì, Giacomo Leopardi, sọ fáwọn tó ń tọ́jú rẹ̀, nígbà tó kù díẹ̀ kó kú. Gbólóhùn náà fi hàn pé, Èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ìyè gan-an ni, òun lọ̀gbẹ́ni náà sì fi wé ìmọ́lẹ̀.

Fífẹ́ láti wà láàyè jẹ́ àbùdá ṣíṣeyebíye tí ń mú kí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn máa sá fún ewu tí wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti wà láàyè. Nínú ọ̀ràn yìí o, èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ẹranko, torí pé àwọn ẹranko pàápàá kì í fẹ́ kú rárá.

Ṣùgbọ́n, irú ìgbésí ayé wo gan-an ló yẹ ká fẹ́ gbé, irú ìyè wo ló yẹ kó máa dá wa lọ́rùn? Kò yẹ kó jẹ́ ti pé, ká ṣáà ti mọ̀ pé a wà láàyè—ìyẹn ni pé à ń mí, a sì ń rìn káàkiri. Líláǹfààní láti kó gbogbo ohun tí ọwọ́ bá ṣáà lè tẹ̀ láyé jọ pàápàá kì í fúnni ní ìtẹ́lọ́rùn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìmọ̀ ọgbọ́n orí tí àwọn ọmọlẹ́yìn Epikúréì gbé lárugẹ, èyí tó lọ báyìí pé, “ẹ jẹ́ kí a máa jẹ́, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú,” kò tí ì mú ìtẹ́lọ́rùn wá fún àwọn ènìyàn. (1 Kọ́ríńtì 15:32) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun kan wà tó jẹ́ àìní ènìyàn nípa ti ara, tí wọ́n sì jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì, èèyàn tún ní àwọn nǹkan tó nífẹ̀ẹ́ sí, tó jẹ́ ti àṣà àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ká má tilẹ̀ tí ì mẹ́nu kan àwọn ohun tẹ̀mí tó nílò, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Onípò Àjùlọ. Ó bani nínú jẹ́ pé, ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn, tí kò bá tilẹ̀ ní tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ pàápàá ló jẹ́ pé kò sí ohun tí wọ́n ń gbádùn láwùjọ ju pé wọ̀n ṣáà ń mí, èyí jẹ́ nítorí ipò òṣì tó wà láwùjọ àti bí ipò nǹkan ti rí ní àwọn àgbègbè púpọ̀ lágbàáyé. Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ pé kó ṣáà ti tẹ́ àìní rẹ̀ nípa ti ara lọ́rùn nìkan ló mọ̀—ìyẹn ni pé kó jẹ, kó mu, kó ní dúkìá, tàbí kó tẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ fún ìbálòpọ̀ lọ́rùn—tó sì jẹ́ pé nǹkan wọ̀nyí nìkan ló ń fún un ní ìtẹ́lọ́rùn díẹ̀ tó ń rí, kò sí ohun tí ìgbésí ayé onítọ̀hún fi yàtọ̀ sí ti ẹranko. Ohun táà ń sọ ni pé, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò lo àwọn àǹfààní pàtàkì mìíràn tí ìwàláàyè fúnni láti lo ọgbọ́n àti ìmọ̀lára tí ènìyàn ní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Láfikún sí i, àwọn tó bá jẹ́ pé bí tiwọn nìkan ṣe máa dáa ṣáá ni wọ́n ń wá máa ń ní ìjákulẹ̀ débi pé ọwọ́ wọn kì í sábà tẹ ohun tí wọ́n ń lépa nínú ìgbésí ayé, wọ́n sì tún ń ba àwùjọ tí wọ́n ń gbé jẹ́, wọn kì í sì í gbé ire àwọn ẹlòmíràn lárugẹ.

Nígbà tí adájọ́ kan tó máa ń gbẹ́jọ́ àwọn ọ̀daràn èwe ń jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé “wàhálà nípa ìwà tó tọ́, gbígbé àwọn oníwà burúkú gẹ̀gẹ̀ láwùjọ, àti àṣeyọrí nípa títètè dọlọ́rọ̀” ń jọ pé “ó ń gbé ẹ̀mí ìbáradíje lárugẹ.” Èyí ń yọrí sí àwọn ìwà tó ń ba àwùjọ jẹ́, tó sì ń pa àwọn èwe lára, pàápàá jù lọ nígbà tí wọ́n bá yíjú sí jíjoògùnyó.

Ṣóo mọ̀ pé ohun tí èèyàn lè gbádùn nínú ayé pọ̀—gbígbafẹ́ lọ sí àwọn àgbègbè tó fani mọ́ra, kíkàwé tó dùn tàbí ṣíṣèwádìí tó gbádùn mọ́ni, wíwá láàárín àwọn ọ̀rẹ́ tó yááyì, gbígbọ́ orin tó dùn. Ọ̀pọ̀ ìgbòkègbodò mìíràn tún wà tó ń mú ìtẹ́lọ́rùn wá, ó lè pọ̀, ó sì lè kéré. Àwọn tó yẹ ki ìyè túbọ̀ wù jù lọ ni àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú Ọlọ́run, pàápàá jù lọ nínú Jèhófà, Ọlọ́run Bíbélì. Ìgbàgbọ́ tòótọ́ jẹ́ orísun okun àti ìbàlẹ̀-ọkàn tó lè ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti kojú àwọn àkókò ìṣòro. Àwọn tó gba Ọlọ́run tòótọ́ gbọ́ lè fọwọ́ sọ̀yà pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà.” (Hébérù 13:6) Àwọn ènìyàn tí wọ́n ti mọ̀ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run máa ń mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Wọ́n ń fìmọrírì hàn sí ìfẹ́ rẹ̀, wọ́n ń rí ayọ̀ tó jinlẹ̀ nínú rẹ̀. (1 Jòhánù 4:7, 8, 16) Wọ́n lè gbé ìgbésí ayé tó ń mu ọwọ́ ẹni dí, èyí tó fẹ́dàáfẹ́re, ìgbésí ayé tó ń mú ìtẹ́lọ́rùn wá. Bí Jésù Kristi ti sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

Ó bani nínú jẹ́ pé, ìhà tí ayé ìsinsìnyí tún kọ sí àwọn ẹlòmíràn yàtọ̀ pátápátá. Ìyà, àìṣèdájọ́ òdodo, òṣì, àìsàn, àti ikú wà káàkiri—ká kàn mẹ́nu kan díẹ̀ nínú àwọn apá tó ń fa ìbànújẹ́ tó sábà ń sọ ayé di èyí tí kò fẹ́ ṣeé gbé mọ́. Kò sí ohun tí èèyàn ń fẹ́ láti mú un láyọ̀ tí Sólómọ́nì Ọba ọlọ́gbọ́n, tó lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, tó sì jẹ́ alágbára ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì kò ní. Síbẹ̀, nǹkan kan da ọkàn rẹ̀ láàmú—mímọ̀ pé bíkú bá dé èèyàn yóò fi gbogbo ohun tó ní sílẹ̀ fún ẹlòmíràn, ìyẹn ni ‘gbogbo iṣẹ́ àṣekára,’ tó ti fi ‘ọgbọ́n àti ìmọ̀ àti ìgbóṣáṣá,’ kó jọ fún ara rẹ̀.—Oníwàásù 2:17-21.

Bíi ti Sólómọ́nì, àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ ló mọ̀ pé ìwàláàyè èèyàn kúrú, wọ́n mọ̀ pé ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, gbogbo rẹ̀ ti pin. Ìwé Mímọ́ sọ pé Ọlọ́run ‘ti fi ayérayé sí wa ní èrò inú.’ (Oníwàásù 3:11, Byington) Èrò nípa ayérayé yìí ló ń sún àwọn ènìyàn láti ronú jinlẹ̀ lórí bí ìwàláàyè ṣe kúrú yìí. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, láìrí ìdáhùn sí ohun tí ìwàláàyè àti ikú túmọ̀ sí, ẹnì kan lè wá di ẹni tí àwọn èrò burúkú àti èrò pé asán lórí asán ni gbogbo nǹkan, kò jẹ́ kó gbádùn. Èyí gan-an lè mú kí ayé súni.

Ǹjẹ́ a lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí ń da ènìyàn láàmú wọ̀nyí? Ǹjẹ́ àwọn ipò kan lè wà tí yóò mú kí ìyè túbọ̀ wuni, kó sì jẹ́ èyí tí yóò wà pẹ́ títí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́