Ìgbésí Ayé Rẹ—Kí Ni Ète Rẹ̀?
“Èmi ń fi ọgbọ́n tọ́ àyà mi . . . títí èmi óò fi rí ohun tí ó dára fún ọmọ ènìyàn . . . ní iye ọjọ́ ayé wọn gbogbo.”—ONÍWÀÁSÙ 2:3.
1, 2. Èé ṣe tí kò fi lòdì láti fẹ́ràn ara ẹni lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu?
O FẸ́RÀN ara rẹ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ìyẹn bá ìwà ẹ̀dá mu. Nítorí èyí, a máa ń jẹun lójoojúmọ́, a máa ń sùn nígbà tí ó bá rẹ̀ wá, a sì máa ń fẹ́ láti wà láwùjọ ọ̀rẹ́ àti àwọn olólùfẹ́ wa. Nígbà míràn, a máa ń ṣe eré àṣedárayá, a máa ń lúwẹ̀ẹ́, tàbí kí a ṣe àwọn ohun mìíràn tí ó máa ń gbádùn mọ́ wa, ní fífi hàn pé a fẹ́ràn ara wa lọ́nà tí ó wà déédéé.
2 Irú ìfẹ́ nínú ara ẹni bẹ́ẹ̀ bá ohun tí Ọlọ́run sún Sólómọ́nì láti kọ mu, pé: “Kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ju kí ó jẹ, kí ó sì mu àti kí ó mú ọkàn rẹ̀ jadùn ohun rere nínú làálàá rẹ̀.” Láti inú ìrírí, Sólómọ́nì fi kún un pé: “Èyí ni mo rí pẹ̀lú pé, láti ọwọ́ Ọlọ́run wá ni. Nítorí pé ta ni ó lè jẹun, tàbí ta ni pẹ̀lú tí ó lè mọ adùn jù mí lọ?”—Oníwàásù 2:24, 25.
3. Àwọn ìbéèrè tí ń rúni lójú wo ni ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn kò rí ìdáhùn sí?
3 Síbẹ̀, o mọ̀ pé ìgbésí ayé kì í ṣe kìkì jíjẹ, mímu, sísùn, àti ṣíṣe àwọn ohun rere kan. A ń ní ìrora, ìjákulẹ̀, àti ìdààmú. Ó sì dà bí ẹni pé ọwọ́ wa máa ń dí púpọ̀ láti ronú lórí ète ìgbésí ayé wa. Kì í ha ń ṣe bí ọ̀ràn ti rí nìyẹn pẹ̀lú rẹ bí? Vermont Royster, olóòtú ìwé ìròyìn The Wall Street Journal tẹ́lẹ̀ rí, kọ̀wé, lẹ́yìn tí ó ti kíyè sí ìmọ̀ àti ìjáfáfá wa gbígbòòrò sí i, pé: “Kàyéfì kan nìyí. Nígbà tí a bá ronú nípa ènìyàn fúnra rẹ̀, nípa ẹtì rẹ̀, nípa ipò rẹ̀ nínú àgbáálá ayé yìí, ìwọ̀nba ni ìmọ̀ wa fi pọ̀ ju bí ó ṣe wà lọ láti ọjọ́ táláyé ti dáyé. A kò tí ì mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà nípa ẹni tí a jẹ́ àti ìdí tí a fi wà níhìn-ín àti ibi tí a ń lọ.”
4. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fẹ́ láti lè dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó ní í ṣe pẹ̀lú wa?
4 Báwo ni ìwọ yóò ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè náà: Ta ni wá? Èé ṣe tí a fi wà níhìn-ín? Níbo ni a sì ń lọ? Ọ̀gbẹ́ni Royster kú ní July tí ó kọjá. Ìwọ ha rò pé ó rí ìdáhùn tí ń tẹ́ni lọ́rùn ṣáájú ìgbà yẹn bí? Kí a túbọ̀ sọjú abẹ níkòó, Ọ̀nà kan ha wà tí ìwọ lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Báwo sì ni èyí ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbádùn ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ láyọ̀, tí ó sì túbọ̀ ní ète nínú? Ẹ jẹ́ kí a gbé e yẹ̀ wò.
Olórí Orísun Ìjìnlẹ̀ Òye
5. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a yíjú sí Ọlọ́run nígbà tí a bá ń wá ìjìnlẹ̀ òye sínú àwọn ìbéèrè nípa ète ìgbésí ayé?
5 Bí a bá ń fúnra wa wá ète ìgbésí ayé wa, a lè má ṣàṣeyọrí rárá, tàbí kí àṣeyọrí wa máà tó nǹkan, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú ọ̀ràn ọ̀pọ̀ jù lọ ọkùnrin àti obìnrin, àní àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀ àti ìrírí púpọ̀ pàápàá. Ṣùgbọ́n, a kò fi wá sílẹ̀ ni àwa nìkan. Ẹlẹ́dàá wa ti pèsè ìrànwọ́. Nígbà tí o bá ronú nípa rẹ̀, kì í ha ṣe òun ni olórí Orísun ìjìnlẹ̀ òye àti ọgbọ́n, nítorí tí ó wà “láti ayérayé,” tí ó sì ní ìmọ̀ àgbáyé àti ìtàn látòkèdélẹ̀? (Orin Dáfídì 90:1, 2) Òun ni ó dá ènìyàn, ó sì ti kíyè sí gbogbo ìrírí ẹ̀dá ènìyàn látòkèdélẹ̀, nítorí náà, òun ni Ẹni tí ó yẹ kí a yíjú sí fún ìjìnlẹ̀ òye, kì í ṣe àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, tí ìmọ̀ àti agbára ìlóye wọn kò tó nǹkan.—Orin Dáfídì 14:1-3; Róòmù 3:10-12.
6. (a) Báwo ni Ẹlẹ́dàá ṣe pèsè ìjìnlẹ̀ òye tí a nílò? (b) Báwo ni ó ṣe kan Sólómọ́nì?
6 Bí a kò tilẹ̀ lè retí pé kí Ẹlẹ́dàá sọ ìtúmọ̀ ìgbésí ayé sí wa létí, ó ti pèsè orísun ìjìnlẹ̀ òye kan—Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó mí sí. (Orin Dáfídì 32:8; 111:10) Ìwé Oníwàásù wúlò gidigidi fún èyí. Ọlọ́run mí sí ẹni tí ó kọ ọ́, tí ó fi jẹ́ pé, ‘ọgbọ́n Sólómọ́nì borí ọgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ Ìlà Oòrùn.’ (Àwọn Ọba Kìíní 3:6-12; 4:30-34) “Ọgbọ́n Sólómọ́nì” wú ọbabìnrin kan tí ń ṣèbẹ̀wò lórí débi pé, ó sọ pé, a kò sọ ìdajì rẹ̀ fún òun, àti pé àwọn tí ń fetí sí ọgbọ́n rẹ̀ yóò jẹ́ aláyọ̀ ní tòótọ́.a (Àwọn Ọba Kìíní 10:4-8) Àwa pẹ̀lú lè jèrè ìjìnlẹ̀ òye àti ayọ̀ láti inú ọgbọ́n àtọ̀runwá tí Ẹlẹ́dàá wa pèsè nípasẹ̀ Sólómọ́nì.
7. (a) Kí ni ìparí èrò tí Sólómọ́nì dé lórí ọ̀pọ̀ jù lọ ìgbòkègbodò tí a ń ṣe lábẹ́ ọ̀run? (b) Kí ní ṣàpèjúwe àgbéyẹ̀wò aláìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ tí Sólómọ́nì ṣe?
7 Ìwé Oníwàásù gbé ọgbọ́n tí Ọlọ́run fi fún Sólómọ́nì yọ, tí ó nípa lórí ọkàn àyà àti ọpọlọ rẹ̀. Nítorí tí ó ní àkókò, ohun àmúṣọrọ̀, àti ìjìnlẹ̀ òye láti ṣe bẹ́ẹ̀, Sólómọ́nì ṣàyẹ̀wò “ohun gbogbo tí a ń ṣe lábẹ́ ọ̀run.” Ó rí i pé, èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú rẹ̀ ni ó jẹ́ ‘asán àti ìmúlẹ̀mófo,’ tí ó jẹ́ àgbéyẹ̀wò onímìísí tí ó yẹ kí a ní lọ́kàn nígbà tí a bá ń ronú nípa ète wa nínú ìgbésí ayé. (Oníwàásù 1:13, 14, 16) Sólómọ́nì kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, kò sì fi bọpo bọyọ̀. Fún àpẹẹrẹ, fẹ̀sọ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó wà nínú Oníwàásù 1:15, 18. O mọ̀ pé, jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún, àwọn ènìyàn ti gbìyànjú onírúurú ìjọba, ní fífi òtítọ́ inú gbìdánwò nígbà míràn láti yanjú àwọn ìṣòro, kí wọ́n sì mú kí ìgbésí ayé àwọn ènìyàn sunwọ̀n sí i. Ṣùgbọ́n, ìjọba èyíkéyìí ha ti mú gbogbo ohun ‘wíwọ́’ inú ètò ìgbékalẹ̀ àìpé yìí tọ́ ní ti gidi bí? O sì lè ti rí i pé, bí ìmọ̀ ènìyàn bá ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe mọ̀ dáradára tó pé, nítorí ọjọ́ orí ènìyàn tí ó kúrú, kò ṣeé ṣe láti ṣàtúnṣe àwọn nǹkan tán. Irú òye bẹ́ẹ̀ ń mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìjákulẹ̀, ṣùgbọ́n kò pọn dandan pé kí ó rí bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀ràn tiwa.
8. Àwọn ìpele ìyípo wo ni ó ti wà tipẹ́tipẹ́?
8 Kókó mìíràn tí ó yẹ kí a gbé yẹ̀ wò ni, ìpele ìyípoyípo tí ń nípa lórí wa, irú bíi yíyọ àti wíwọ̀ oòrùn tàbí fífẹ́ lẹlẹ atẹ́gùn àti ṣíṣàn omi. Wọ́n ń bẹ ní ọjọ́ Mósè, Sólómọ́nì, Napoléon, àti àwọn bàbá baba ńlá wa. Wọ́n sì ń bá a lọ. Lọ́nà kan náà, “ìran kan lọ, ìran mìíràn sì bọ̀; ṣùgbọ́n ayé dúró títí láé.” (Oníwàásù 1:4-7) Tí a bá fi ojú ènìyàn wò ó, kò sí ohun tí ó fi bẹ́ẹ̀ yí pa dà. Àwọn ènìyàn àtijọ́ àti ti òde òní ti ní ìgbòkègbodò, ìrètí, ìlépa, àti àṣeyọrí tí ó jọra. Kódà bí ẹnì kan tilẹ̀ ṣe orúkọ fún ara rẹ̀ láwùjọ ènìyàn, tàbí tí ó ní ẹwà tàbí agbára tí ó ga lọ́lá, ẹni náà dà lónìí? Ó ti fi ilẹ̀ bora, ó sì ṣeé ṣe kí a ti gbàgbé rẹ̀. Ojú ìwòye yẹn kì í ṣe láti múni banú jẹ́. Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn kò tilẹ̀ mọ orúkọ bàbá baba ńlá wọn, tàbí ìyá ìyá ńlá wọn, wọn kò sì lè sọ ibi tí a bí wọn sí, tí a sì sin wọ́n sí. O lè rí ìdí tí Sólómọ́nì fi sọ bí nǹkan ti rí ní ti gidi pé, asán ni ìlépa àti ìsapá ẹ̀dá ènìyàn.—Oníwàásù 1:9-11.
9. Báwo ni jíjèrè ìjìnlẹ̀ òye tòótọ́ gan-an nípa ipò ẹ̀dá ènìyàn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
9 Dípò mímú wa ní ìjákulẹ̀, ìjìnlẹ̀ òye àtọ̀runwá yìí nípa ipò ẹ̀dá ènìyàn lè ní ipa dídára lórí wa, ní sísún wa láti yẹra fún síso ìjẹ́pàtàkì tí kò yẹ mọ́ àwọn góńgó tàbí ìlépa tí yóò pòórá láìpẹ́, tí a óò sì gbàgbé. Ó yẹ kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò ohun tí a ń jèrè láti inú ìgbésí ayé, àti ohun tí a ń gbìyànjú láti ṣàṣeparí. Láti ṣàkàwé, dípò jíjẹ́ olùsẹ́ra-ẹni, a lè rí ìdùnnú nínú jíjẹ àti mímu níwọ̀ntúnwọ̀nsì. (Oníwàásù 2:24) Gẹ́gẹ́ bí a óò sì ti rí i, Sólómọ́nì dé ìparí èrò tí ó dára, tí ó sì ń gbéni ró. Ní ṣókí, òun ni pé, kí a ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún ipò ìbátan wa pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa, tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀, àti eléte tí yóò wà títí ayérayé. Sólómọ́nì tẹnu mọ́ ọn pé: “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbogbo ohun tí a ti gbọ́, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́ náà, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo ojúṣe ènìyàn.”—Oníwàásù 12:13, NW.
Ète Wa Lójú Ìwòye Ìpele Ìyípo Ìgbésí Ayé
10. Ọ̀nà wo ni Sólómọ́nì gbà fi ènìyàn wé ẹranko?
10 Ọgbọ́n àtọ̀runwá tí a gbé yọ nínú ìwé Oníwàásù lè ràn wá lọ́wọ́ síwájú sí i ní gbígbé ète wa nínú ìgbésí ayé yẹ̀ wò. Lọ́nà wo? Ní ti pé, láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, Sólómọ́nì darí àfiyèsí sí àwọn òtítọ́ mìíràn tí a kì í sábà ronú lé lórí. Ọ̀kan ní í ṣe pẹ̀lú ìjọra tí ó wà láàárín ènìyàn àti ẹranko. Jésù fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wé àgùntàn, síbẹ̀ inú ọ̀pọ̀ ènìyàn kì í dùn tí a bá fi wọ́n wé ẹranko. (Jòhánù 10:11-16) Síbẹ̀, Sólómọ́nì mú àwọn òtítọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro wá sójútáyé: “Kí Ọlọ́run kí ó lè fi [àwọn ọmọ ènìyàn] hàn, àti kí wọn kí ó lè rí i pé ẹran ni àwọn tìkára wọn fún ara wọn. Nítorí pé ohun tí ń ṣe ọmọ ènìyàn ń ṣe ẹran; àní ohun kan náà ni ó ń ṣe wọ́n: bí èkíní ti ń kú bẹ́ẹ̀ ni èkejì ń kú; . . . bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kò ní ọlá ju ẹran lọ: nítorí pé asán ni gbogbo rẹ̀. . . . Láti inú erùpẹ̀ wá ni gbogbo wọn, gbogbo wọ́n sì tún pa dà di erùpẹ̀.”—Oníwàásù 3:18-20.
11. (a) Báwo ni a ṣe lè ṣàpèjúwe ìpele ìyípo ìgbésí ayé ẹranko kan? (b) Kí ni èrò rẹ nípa irú ìfọ́síwẹ́wẹ́ bẹ́ẹ̀?
11 Ronú nípa ẹranko kan tí o gbádùn láti máa wò, bóyá ehoro tàbí òkété. (Diutarónómì 14:7; Orin Dáfídì 104:18; Òwe 30:26) Tàbí kí o fọkàn yàwòrán ọ̀kẹ́rẹ́; oríṣi tí ó lé ní 300 ni ó wà kárí ayé. Báwo ni ìpele ìyípo ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe rí? Lẹ́yìn tí ó bá ti bí i, ìyá rẹ̀ yóò tọ́jú rẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, yóò ti hu irun, ó sì lè jáde síta. O lè rí i tí ń sáré kiri, tí ń kọ́ bí a ti ń wá oúnjẹ. Ṣùgbọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà, ó jọ bíi pé ó kàn ń ṣeré ni, ó ń gbádùn ìgbà èwe rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti dàgbà tó nǹkan bí ọdún kan, yóò wá akọ tàbí abo rí. Lẹ́yìn náà, ó gbọ́dọ̀ kọ́ ìtẹ́, kí ó sì tọ́jú àwọn ọmọ. Bí ó bá rí èso oníwóóníṣu, èkùrọ́, àti kóró èso tí ó pọ̀ tó, ìdílé ọ̀kẹ́rẹ́ náà lè sanra, kí wọ́n sì rí àyè láti mú ilé wọn gbòòrò sí i. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ẹranko náà á darúgbó, yóò sì tètè máa fara pa, àìsàn kò sì ní pẹ́ ṣe é. Yóò kú nígbà tí yóò bá fi tó ọdún mẹ́wàá. Bí ọ̀kẹ́rẹ́ tilẹ̀ yàtọ̀ síra wọn ní onírúurú, ìpele ìyípo ìgbésí aye rẹ̀ nìyẹn ní gbogbogbòò.
12. (a) Láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, èé ṣe tí ìpele ìyípo ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe dà bíi ti ẹranko? (b) Kí ni a lè ronú nípa rẹ̀ nígbà tí a bá tún rí ẹranko tí a ní lọ́kàn?
12 Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn kò ní lòdì sí irú ìgbésí ayé yẹn fún ẹranko, wọn kò sì retí rárá pé kí ọ̀kẹ́rẹ́ gbé ìgbésí ayé tí ó ní ète nínú. Ṣùgbọ́n, ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ ènìyàn kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ìyẹn, àbí ó yàtọ̀? A bí wọn, a sì ṣètọ́jú wọn gẹ́gẹ́ bí ìkókó. Wọ́n ń jẹun, wọ́n ń dàgbà, wọ́n sì ń ṣeré nígbà tí wọ́n wà ní èwe. Kò pẹ́ kò jìnnà, wọ́n dàgbà, wọ́n wá akọ tàbí abo, wọ́n sì wá ibì kan gbé, àti ọ̀nà láti pèsè oúnjẹ. Bí nǹkan bá ṣẹnuure fún wọn, wọ́n lè sanra, kí wọ́n sì mú ilé (ìtẹ́) wọn, tí wọn yóò ti tọ àwọn ọmọ dàgbà, gbòòrò. Ṣùgbọ́n, àwọn ẹ̀wádún yára kánkán, wọ́n sì darúgbó. Bí wọn kò bá kú ṣáájú kí wọ́n tó pé 70 tàbí 80 ọdún, tí ó kún fún “làálàá òun ìbìnújẹ́,” wọ́n lè kú lẹ́yìn àkókò náà. (Orin Dáfídì 90:9, 10, 12) O lè ronú nípa àwọn òkodoro òtítọ́ tí ń múni ronú jinlẹ̀ wọ̀nyí, nígbà tí o bá tún rí ọ̀kẹ́rẹ́ (tàbí ẹranko mìíràn tí o ní lọ́kàn).
13. Àtúbọ̀tán wo ni ó jẹ́ òtítọ́ nípa ẹranko àti ènìyàn?
13 Ìwọ lè rí ìdí tí Sólómọ́nì ṣe fi ìgbésí ayé ènìyàn wé ti ẹranko. Ó kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù ohun ni àkókò wà fún, . . . ìgbà bíbíni, àti ìgbà kíkú.” Àtúbọ̀tán tí a mẹ́nu kàn kẹ́yìn yẹn, ikú, ń pa ọmọ ènìyàn bí ó ti ń pa ẹranko, “bí èkíní ti ń kú bẹ́ẹ̀ ni èkejì ń kú.” Ó fi kún un pé: “Láti inú erùpẹ̀ wá ni gbogbo wọn, gbogbo wọ́n sì tún pa dà di erùpẹ̀.”—Oníwàásù 3:1, 2, 19, 20.
14. Báwo ni àwọn ènìyàn kan ṣe gbìyànjú láti yí ìpele ìyípo ìgbésí ayé pa dà, ṣùgbọ́n, kí ni ìyọrísí rẹ̀?
14 Kò yẹ kí a ka àgbéyẹ̀wò aláìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ yí sí ìrònú òdì. Òtítọ́ ni pé, àwọn kan gbìyànjú láti yí ipò nǹkan pa dà, bíi nípa ṣíṣiṣẹ́ kára láti mú ipò wọn nípa ti ara sunwọ̀n sí i, ju ti àwọn òbí wọn lọ. Wọ́n lè fi ọ̀pọ̀ ọdún lépa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ láti lè pèsè ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ dẹrùn sí i, bí wọ́n ti ń gbìyànjú láti mú òye wọn nípa ìgbésí ayé gbòòrò sí i. Wọ́n sì lè kó gbogbo àfiyèsí wọn sórí ṣíṣe eré ìmárale tàbí ṣíṣọ́ oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ, láti lè gbádùn ìlera jíjí pépé sí i, kí ọjọ́ ayé wọ́n sì gùn díẹ̀ sí i. Àwọn ìsapá wọ̀nyí sì lè mú àwọn àǹfààní kan wá. Ṣùgbọ́n, ta ní lè fọwọ́ sọ̀yà pé irú àwọn ìsapá bẹ́ẹ̀ yóò kẹ́sẹ járí? Bí wọ́n tilẹ̀ kẹ́sẹ járí, fún ọdún mélòó?
15. Àgbéyẹ̀wò ṣíṣe ṣàkó wo nínú ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ni ó jẹ́ òtítọ́?
15 Sólómọ́nì béèrè pé: “Kíyè sí i, ohun púpọ̀ ni ó wà tí ń mú asán bí sí i, èrè kí ni ènìyàn ní? Nítorí pé ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé yìí, ní iye ọjọ́ asán rẹ̀ tí ń lọ bí òjìji? nítorí pé ta ni ó lè sọ fún ènìyàn ní ohun tí yóò wà lẹ́yìn rẹ̀?” (Oníwàásù 6:11, 12) Níwọ̀n bí ikú ti tètè ń fòpin sí ìsapá ènìyàn, àǹfààní gidi púpọ̀ ha wà nínú lílàkàkà láti jèrè àwọn ohun ìní púpọ̀ sí i tàbí nínú fífi ọ̀pọ̀ ọdún lépa ìmọ̀ ẹ̀kọ́, láti baà lè kó àwọn ohun ìní púpọ̀ jọ bí? Níwọ̀n bí ìgbésí ayé sì ti kúrú púpọ̀, tí ń kọjá lọ bí òjìji, ọ̀pọ̀ ń róye pé, kò sí àyè láti tún darí àfiyèsí sí góńgó mìíràn, nígbà tí wọ́n bá fura pé àwọn ti kùnà nínú lílé góńgó àwọn bá; ènìyàn kò sì lè mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ rẹ̀ “lẹ́yìn rẹ̀.”
Àkókò Láti Ṣe Orúkọ Rere
16. (a) Kí ni ó yẹ kí a ṣe tí ẹranko kò lè ṣe? (b) Òtítọ́ mìíràn wo ni ó yẹ kí ó nípa lórí ìrònú wa?
16 Láìdà bí àwọn ẹranko, àwa ènìyàn ní làákàyè láti sinmẹ̀dọ̀ ronú pé, ‘Kí ni ète ìwàláàyè mi? Ó ha wulẹ̀ jẹ́ ìpele ìyípo tí kò ṣeé yí pa dà, ti ìgbà bíbíni, àti ìgbà kíkú?’ Ní ti èyí, rántí òtítọ́ inú ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì nípa ènìyàn àti ẹranko pé: “Gbogbo wọ́n sì tún pa dà di erùpẹ̀.” Ìyẹn ha túmọ̀ sí pé, ikú fi òpin pátápátá sí ìgbésí ayé ènìyàn bí? Toò, Bíbélì fi hàn pé, ènìyàn kò ní àìlèkú ọkàn, tí ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú. Ènìyàn jẹ́ ọkàn, ọkàn tí ó sì ṣẹ̀ ń kú. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4, 20) Sólómọ́nì ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà pé: “Alààyè mọ̀ pé àwọn óò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní èrè mọ́; nítorí ìrántí wọn ti di ìgbàgbé. Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ rí ní ṣíṣe, fi agbára rẹ ṣe é, nítorí tí kò sí ète, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀, tàbí ọgbọ́n, ní isà òkú níbi tí ìwọ ń rè.”—Oníwàásù 9:5, 10.
17. Kí ni Oníwàásù 7:1, 2 yẹ kí ó mú wa sinmẹ̀dọ̀ ronú lé lórí?
17 Lójú ìwòye òtítọ́ tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ yẹn, gbé ọ̀rọ̀ yí yẹ̀ wò: “Orúkọ rere dára ju òróró ìkunra; àti ọjọ́ ikú ju ọjọ́ ìbí ènìyàn lọ. Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju àtilọ sí ilé àsè: nítorí pé èyí ni òpin gbogbo ènìyàn; alààyè yóò sì pa á mọ́ ní àyà rẹ̀.” (Oníwàásù 7:1, 2) A ní láti gbà pé ikú ti jẹ́ “òpin gbogbo ènìyàn.” Kò tí ì ṣeé ṣe fún ènìyàn kankan láti rí oògùn máàkú mu, láti jẹ àpòpọ̀ fítámìn, láti jẹ́ àwọn oúnjẹ tí a là lẹ́sẹẹsẹ, tàbí láti lọ́wọ́ nínú eré ìmárale èyíkéyìí, tí ó ti yọrí sí ìyè ayérayé. Lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, “ìrántí wọ́n ti di ìgbàgbé” kété lẹ́yìn ikú wọn. Nítorí náà, èé ṣe tí orúkọ rere fi “dára ju òróró ìkunra; àti ọjọ́ ikú ju ọjọ́ ìbí ènìyàn lọ”?
18. Èé ṣe tí a fi lè ní ìdánilójú pé Sólómọ́nì gbà gbọ́ nínú àjíǹde?
18 Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ, Sólómọ́nì kò fi ọ̀ràn bọpo bọyọ̀. Ó mọ̀ nípa àwọn baba ńlá rẹ̀, Ábúráhámù, Aísíìkì, àti Jékọ́bù, tí kò sí àníàní pé wọ́n ti ṣe orúkọ rere pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wọn. Nítorí tí ó mọ Ábúráhámù dáradára, Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí láti bù kún un àti irú ọmọ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 18:18, 19; 22:17) Bẹ́ẹ̀ ni, Ábúráhámù ṣe orúkọ rere pẹ̀lú Ọlọ́run, ní dídi ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Kíróníkà Kejì 20:7; Aísáyà 41:8; Jákọ́bù 2:23) Ábúráhámù mọ̀ pé ìgbésí ayé òun àti ti ọmọ òun kì í wulẹ̀ ṣe apá kan ìpele ìyípo ìgbésí ayé tí kò lópin ti ìbí àti ikú. Ó dájú pé ète tí ó wà fún un ju èyí lọ. Wọ́n ní ìrètí dídájú ti wíwàláàyè lẹ́ẹ̀kan sí i, kì í ṣe nítorí tí wọ́n ní àìleèkú ọkàn, ṣùgbọ́n nítorí tí a óò jí wọn dìde. Ó dá Ábúráhámù lójú pé “Ọlọ́run lè gbé [Aísíìkì] dìde àní kúrò nínú òkú.”—Hébérù 11:17-19.
19. Ìjìnlẹ̀ òye wo ni a lè jèrè lọ́dọ̀ Jóòbù nípa ìtúmọ̀ Oníwàásù 7:1?
19 Àṣírí kan nìyẹn láti lóye bí ‘orúkọ rere ṣe dára ju òróró ìkunra; àti ọjọ́ ikú ju ọjọ́ ìbí ènìyàn lọ.’ Gẹ́gẹ́ bíi Jóòbù tí ó wà ṣáájú rẹ̀, ó dá Sólómọ́nì lójú pé, Ẹni tí ó dá ẹ̀mí ènìyàn lè mú un pa dà bọ̀ sípò. Ó lè mú àwọn ènìyàn tí ó ti kú pa dà di alààyè. (Jóòbù 14:7-14) Jóòbù olùṣòtítọ́ sọ pé: “Ìwọ [Jèhófà] yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn. Ìwọ yóò ṣàfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Jóòbù 14:15, NW) Ronú nípa ìyẹn ná! Fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin tí ó ti kú, Ẹlẹ́dàá wa ń “ṣàfẹ́rí” wọn. (“Ìwọ yóò fẹ́ láti rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ lẹ́ẹ̀kan sí i.”—The Jerusalem Bible.) Ní lílo ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, Ẹlẹ́dàá lè jí àwọn ènìyàn dìde. (Jòhánù 3:16; Ìṣe 24:15) Ní kedere, ènìyàn lè yàtọ̀ sí ẹranko lásán tí ó ti kú.
20. (a) Nígbà wo ni ọjọ́ ikú dára ju ọjọ́ ìbí lọ? (b) Báwo ni àjíǹde Lásárù ṣe gbọ́dọ̀ ti nípa lórí ọ̀pọ̀ ènìyàn?
20 Èyí túmọ̀ sí pé, ọjọ́ ikú lè dára ju ọjọ́ tí a bí ẹnì kan lọ, bí ẹni náà ṣáájú ìgbà yẹn bá ti ṣe orúkọ rere pẹ̀lú Jèhófà, tí ó lè jí àwọn olùṣòtítọ́ tí ó ti kú dìde. Sólómọ́nì Títóbi Jù náà, Jésù Kristi, fi ẹ̀rí èyí hàn. Fún àpẹẹrẹ, ó jí ọkùnrin olùṣòtítọ́ náà, Lásárù, dìde sí ìyè. (Lúùkù 11:31; Jòhánù 11:1-44) Gẹ́gẹ́ bí o ti lè finú wòye, ọ̀pọ̀ àwọn tí àjíǹde Lásárù ṣojú wọn ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà nípa gidi lé lórí, ní lílo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọkùnrin Ọlọ́run. (Jòhánù 11:45) Ìwọ ha rò pé wọ́n ronú pé àwọn kò ní ète nínú ìgbésí ayé, ní ṣíṣàìmọ ẹni tí wọ́n jẹ́ àti ibi tí wọ́n ń lọ? Ní òdì kejì, wọ́n lè rí i pé wọn kò ní láti dà bí ẹranko lásán, tí a bí, tí ó gbé ayé fún ọdún mélòó kan, tí ó sì kú. Ète wọn nínú ìgbésí ayé ní í ṣe ní tààràtà àti ní pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú mímọ Bàbá Jésù àti ṣíṣe ìfẹ́ inú Rẹ̀. Ìwọ ńkọ́? Ìjíròrò yí ha ti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí i, tàbí láti túbọ̀ rí i kedere, bí ìgbésí ayé rẹ ṣe lè ní ète gidi, àti bí ó ṣe yẹ kí ó ní in?
21. Apá wo nínú wíwá ète nínú ìgbésí ayé wa ni a ṣì fẹ́ gbé yẹ̀ wò dáradára?
21 Síbẹ̀, níní ète gidi, tí ó nítumọ̀ nínú ìgbésí ayé ju ríronú nípa ikú àti pípadà gbé ayé lẹ́yìn náà lọ. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ohun tí a ń ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé wa lójoojúmọ́. Sólómọ́nì tún mú ìyẹn ṣe kedere nínú Oníwàásù, bí a óò ti rí i nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Ìtàn Ọbabìnrin Ṣébà tẹnu mọ́ ọgbọ́n Sólómọ́nì, ọ̀pọ̀ ìgbà ni a sì ti pè é ní ìtàn àròsọ (1 Ọb. 10:1-13). Ṣùgbọ́n, àyíká ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé, ìbẹ̀wò rẹ̀ sọ́dọ̀ Sólómọ́nì ní í ṣe ni ti gidi pẹ̀lú òwò, nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu; kò sí ìdí láti ṣiyèméjì nípa òtítọ́ ìtàn náà.”—Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The International Standard Bible Encyclopedia (1988), Ìdìpọ̀ IV, ojú ìwé 567.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni ẹranko àti ènìyàn gbà jọra?
◻ Èé ṣe ti ikú fi hàn kedere pé ọ̀pọ̀ jù lọ ìsapá àti ìgbòkègbodò ènìyàn jẹ́ asán?
◻ Báwo ni ọjọ́ ikú ṣe dára ju ọjọ́ ìbí lọ?
◻ Níní ète tí ó nítumọ̀ nínú ìgbésí ayé wa sinmi lórí ipò ìbátan wo?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Báwo ni ìgbésí ayé rẹ ṣe yàtọ̀ lọ́nà títayọ tó sí ti àwọn ẹranko?