ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 11/15 ojú ìwé 18-23
  • Ǹjẹ́ Ò Ń ṣe Gbogbo Ojúṣe Rẹ Níwájú Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ò Ń ṣe Gbogbo Ojúṣe Rẹ Níwájú Ọlọ́run?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Gbogbo Nǹkan Ni Asán?
  • Ìyàsímímọ́ Wa àti Ojúṣe Wa Níwájú Ọlọ́run
  • Gbé Àwọn Ìpinnu Rẹ Yẹ̀ Wò Dáadáa!
  • Ohun Tó Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Máa Ràntí Ẹlẹ́dàá Wa Atóbilọ́lá
  • Gbogbo Ojúṣe Wa Níwájú Ọlọ́run
  • Ṣe Gbogbo Ojúṣe Rẹ
  • “Gbogbo Ojúṣe Ènìyàn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Bí A Ṣe Lè Ṣe Ojúṣe Wa Lọ́dọ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Oníwàásù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Rántí Ẹlẹ́dàá Rẹ Atóbilọ́lá!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 11/15 ojú ìwé 18-23

Ǹjẹ́ Ò Ń ṣe Gbogbo Ojúṣe Rẹ Níwájú Ọlọ́run?

“Ọlọ́run tòótọ́ tìkára rẹ̀ yóò mú gbogbo onírúurú iṣẹ́ wá sínú ìdájọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun fífarasin, ní ti bóyá ó dára tàbí ó burú.”—ONÍWÀÁSÙ 12:14.

1. Kí ni Jèhófà pèsè fáwọn ènìyàn rẹ̀?

JÈHÓFÀ máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tó bá ń rántí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ onímìísí ń fún wọn ní ìmọ̀ tí wọ́n nílò láti lè máa ṣe ohun tó wù ú lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí wọ́n sì máa ‘so èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo.’ (Kólósè 1:9, 10) Láfikún sí i, nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” Jèhófà ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí àti ìtọ́sọ́nà tó jẹ́ ti ìjọba rẹ̀. (Mátíù 24:45-47) Èyí fi hàn pé, ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ìbùkún àtọ̀runwá fi ń wá sórí àwọn ènìyàn Ọlọ́run bí wọ́n ti ń sin Jèhófà, tí wọ́n sì ń báṣẹ́ bàǹtà-banta ti wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà lọ.—Máàkù 13:10.

2. Nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn sí Jèhófà, àwọn ìbéèrè wo ló wáyé?

2 Inú àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń dùn pé ọwọ́ àwọn dí fún ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí Jèhófà. Síbẹ̀, àwọn kan lè rẹ̀wẹ̀sì, kí wọ́n sì rò pé gbogbo ìsapá àwọn kò lè mú àǹfààní kankan wá. Fún àpẹẹrẹ, nígbà mìíràn, àwọn Kristẹni tó ti ṣèyàsímímọ́ lè máa kọminú pé bóyá ni ìsapá táwọn ń fi tọkàntọkàn ṣe yóò mú àǹfààní wá. Táwọn olórí ìdílé kan bá ń ronú lórí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé àti àwọn ìgbòkègbodò mìíràn, àwọn ìbéèrè báwọ̀nyí lè wá sọ́kàn wọn: ‘Ǹjẹ́ inú Jèhófà tiẹ̀ dùn sí nǹkan tí à ń ṣe yìí? Ǹjẹ́ à ń ṣe gbogbo ojúṣe wa níwájú Ọlọ́run?’ Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tí akónijọ sọ lè ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀.

Ṣé Gbogbo Nǹkan Ni Asán?

3. Ní ìbámu pẹ̀lú Oníwàásù 12:8, kí ni asán lórí asán?

3 Àwọn kan lè rò pé ọ̀rọ̀ ọkùnrin ọlọgbọ́n yẹn kò gbé ẹnikẹ́ni ró rárá—yálà ọmọdé tàbí àgbàlagbà. “‘Asán pátápátá gbáà!” ni akónijọ wí, “Asán ni gbogbo rẹ̀.’” (Oníwàásù 12:8) Ká sòótọ́, kò sí asán tó burú tó kéèyàn má ka Ẹlẹ́dàá rẹ̀ Atóbilọ́lá sí nígbà ọ̀dọ́, kéèyàn dàgbà kó darúgbó, kó má sin Ọlọ́run, kó jẹ́ pé ọjọ́ orí nìkan ló lè sọ pé òun jèrè láyé. Kódà kírú ẹni bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ kó tó kú, kó sì lókìkí nínú ayé tó wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú nì, Sátánì Èṣù, gbogbo nǹkan ló já sásán tàbí òmúlẹ̀mófo fún un.—1 Jòhánù 5:19.

4. Èé ṣe táa fi lè sọ pé kì í ṣe gbogbo nǹkan ni asán?

4 Àmọ́ kì í ṣe gbogbo nǹkan ni asán fún àwọn tó bá to ìṣura wọn jọ sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ìrànṣẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Mátíù 6:19, 20) Wọ́n ní púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa tó lérè nínú, ó sì dájú pé irú iṣẹ́ aláápọn bẹ́ẹ̀ kì í ṣe asán. (1 Kọ́ríńtì 15:58) Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ Kristẹni tó ti ṣèyàsímímọ́ ni wá, ṣé ọwọ́ wa ń dí fún iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wa ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí? (2 Tímótì 3:1) Àbí a ti bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésí ayé tí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí tàwọn aládùúgbò wa? Wọ́n lè máa lọ sí onírúurú ilé ìsìn, kí wọ́n sì jẹ́ ẹni tí kì í fẹ̀sìn wọn ṣeré rárá, kó jẹ́ pé wọn kì í pa ilé ìjọsìn wọn jẹ, kí wọ́n sì máa gbìyànjú láti ṣe gbogbo ohun tí ẹ̀sìn wọn béèrè lọ́wọ́ wọn. Gbogbo ẹ̀ náà ńkọ́, wọn kì í ṣe olùpòkìkí iṣẹ́ Ìjọba náà. Wọn ò ní ìmọ̀ pípéye pé “àkókò òpin” la wà yìí, wọn kò sì ní òye ìjẹ́kánjúkánjú nípa àwọn ọjọ́ tí à ń gbé.—Dáníẹ́lì 12:4.

5. Bó bá jẹ́ pé gbígbé ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì ni olórí àníyàn wa, kí ló yẹ ká ṣe?

5 Jésù Kristi sọ nípa àwọn àkókò wa tó le koko pé: “Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí. Nítorí bí wọ́n ti wà ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.” (Mátíù 24:37-39) Táa bá ṣe é níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kò sí nǹkan tó burú nínú ká jẹ, ká mu, tó bá sì jẹ́ ti ìgbéyàwó ni, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló dá ètò yìí sílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:20-24) Ṣùgbọ́n, táa bá wá rí i pé gbígbé ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì ti wá di olórí àníyàn wa, kí ló dé tá ò fi sínú àdúrà? Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi ire Ìjọba rẹ̀ sípò kìíní, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́, ká sì ṣe gbogbo ojúṣe wa níwájú rẹ̀.—Mátíù 6:33; Róòmù 12:12; 2 Kọ́ríńtì 13:7.

Ìyàsímímọ́ Wa àti Ojúṣe Wa Níwájú Ọlọ́run

6. Ọ̀nà pàtàkì wo làwọn kan tí wọ́n ti ṣe batisí fi ń kùnà láti ṣe ojúṣe wọn níwájú Ọlọ́run?

6 Ó yẹ káwọn Kristẹni kan tó ti ṣe batisí lọ kúnlẹ̀ àdúrà dáadáa nítorí pé wọn ò já iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí wọ́n láwọn ó ṣe nígbà tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run kúnra mọ́. Láti ọdún mélòó kan wá, ó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] ènìyàn tó ń ṣe batisí lọ́dọọdún, ṣùgbọ́n iye àwọn ògbóṣáṣá Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fi bẹ́ẹ̀ lọ sókè. Àwọn kan tí wọ́n di akéde Ìjọba ti dáwọ́ dúró, wọn ò pòkìkí ìhìn rere náà mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, èèyàn ò lè ṣe batisí, láìjẹ́ pé ó ti kọ́kọ́ ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni lọ́nà tó jọjú. Èyí fi hàn pé àwọn wọ̀nyí mọ iṣẹ́ tí Jésù gbé lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Àyàfi tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tó lágbára gan-an ló fà á, bóyá àìlera tàbí àwọn nǹkan míì tó ga ju agbára wọn lọ, yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó ti ṣe batisí, ṣùgbọ́n tí wọn ò jẹ́ ògbóṣáṣá Ẹlẹ́rìí fún Ọlọ́run àti Kristi mọ́ kò ṣe gbogbo ojúṣe wọn níwájú Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá.—Aísáyà 43:10-12.

7. Èé ṣe tó fi yẹ ká máa pàdé déédéé fún ìjọsìn?

7 Ísírẹ́lì ìgbàanì jẹ́ orílẹ̀-èdè kan táa yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run, lábẹ́ májẹ̀mú Òfin sì rèé, àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ojúṣe kan níwájú Jèhófà. Fún àpẹẹrẹ, gbogbo ọkùnrin ló gbọ́dọ̀ pé jọ fún ayẹyẹ mẹ́ta lọ́dọọdún, ọkùnrin tó bá sì kọ̀, tí kò ṣayẹyẹ Ìrékọjá, ‘kíké ni a ó ké e kúrò.’ (Númérì 9:13; Léfítíkù 23:1-43; Diutarónómì 16:16) Láti lè ṣe ojúṣe wọn níwájú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún un, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti máa pàdé pọ̀ fún ìjọsìn. (Diutarónómì 31:10-13) Kò sí ohun kan nínú Òfin tó sọ pé, ‘Ṣe kinní yìí bó bá rọ̀ ẹ́ lọ́rùn.’ Fún àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà báyìí, ó dájú pé èyí túbọ̀ fún ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí lágbára: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Hébérù 10:24, 25) Bẹ́ẹ̀ ni, pípàdé déédéé pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni jẹ́ apá kan nínú ojúṣe tí Kristẹni kan tó ti ṣèyàsímímọ́ yóò máa ṣe níwájú Ọlọ́run.

Gbé Àwọn Ìpinnu Rẹ Yẹ̀ Wò Dáadáa!

8. Èé ṣe tó fi yẹ kí ọ̀dọ́ kan tó ti ṣèyàsímímọ́ kúnlẹ̀ àdúrà nípa iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tó ń ṣe?

8 Bóyá ọ̀dọ́ tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà ni ẹ́. Tóo bá lè fi ire Ìjọba náà sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ, ìbùkún rẹ á mà pọ̀ o. (Òwe 10:22) Pẹ̀lú àdúrà àti ìwéwèé àfẹ̀sọ̀ṣe, ó kéré tán, wàá lè lo ìgbà ọ̀dọ́ rẹ nínú apá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún kan—èyí á sì jẹ́ ọ̀nà tó dáa láti fi hàn pé o rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá. Àìjẹ́bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì lè bẹ̀rẹ̀ sí gbà ọ́ lọ́kàn, kó sì wá gba èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àkókò rẹ. Gẹ́gẹ́ bí àṣà tó wọ́pọ̀, ìwọ náà lè tètè ṣègbéyàwó ní kùtùkùtù ìgbésí ayé rẹ, kóo sì wá tọrùn bọ gbèsè torí àtikó nǹkan tara jọ. Iṣẹ́ tí ń mówó wọlé lè gba èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àkókò rẹ àti agbára rẹ. Bóo bá sì ti bímọ, gbígbọ́ bùkátà ìdílé yóò wá já lé ẹ léjìká fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún. (1 Tímótì 5:8) Ó lè jẹ́ pé o kò gbàgbé Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá, ṣùgbọ́n yóò bọ́gbọ́n mu bóo bá mọ̀ pé, bóo bá tètè bẹ̀rẹ̀ sí wéwèé ìgbésí ayé rẹ, bóò bá sì wéwèé, tóo káwọ́ gbera, èyíkéyìí tóo bá ṣe nínú méjèèjì ni yóò pinnu bí nǹkan yóò ṣe rí fún ọ nígbà tóo bá dàgbà. Bó bá dọjọ́ alẹ́, o lè wá máa dárò pé, ká ní o mọ̀ ni, bó tiẹ̀ jẹ́ ìgbà ọ̀ṣìngìn ọ̀dọ́ nìkan ni, ṣèbí oò bá ti lò ó ní kíkún nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá. Èé ṣe tóò fi kúnlẹ̀ àdúrà ti àwọn ìwéwèé rẹ báyìí, kí o bàa lè rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tóo ṣe fún Jèhófà nígbà tóo ṣì wà lọ́dọ̀ọ́?

9. Kí ló lè ṣeé ṣe fún ẹnì kan tó ti dàgbà, ṣùgbọ́n tó ti fìgbà kan rí ní ẹrù iṣẹ́ tó pọ̀ nínú ìjọ?

9 Gbé ipò mìíràn yẹ̀ wò—ìyẹn ni ti ọkùnrin kan tó ti fìgbà kan jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn “agbo Ọlọ́run.” (1 Pétérù 5:2, 3) Nítorí àwọn ìdí kan, ó fínnúfíndọ̀ fi irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ sílẹ̀. Lóòótọ́, àgbà ti wá dé sí i báyìí, ó sì wá lè túbọ̀ ṣòro fún un láti máa bá iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lọ. Àmọ́, ṣé ó lè tún nàgà fún irú àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀? Ẹ wo irú ìbùkún ńláǹlà tí irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn ká ní ó lè tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ sí i nínú ìjọ! Níwọ̀n ìgbà tó sì ti jẹ́ pé kò sí ọ̀kan nínú wa tí ó wà láàyè nípa ti ara rẹ̀ nìkan, inú àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn tó fẹ́ràn wa yóò dùn bí onítọ̀hún bá lè fi kún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, fún ògo Ọlọ́run. (Róòmù 14:7, 8) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Jèhófà ò ní gbàgbé ohun tí ẹnikẹ́ni bá ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (Hébérù 6:10-12) Nítorí náà, kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa rántí Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá?

Ohun Tó Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Máa Ràntí Ẹlẹ́dàá Wa Atóbilọ́lá

10. Èé ṣe tó fi jẹ́ pé ẹnu akónijọ náà gbà á láti fún wa ní ìtọ́sọ́nà lórí ọ̀ràn rírántí Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá?

10 Ẹnu akónijọ gbà á dáadáa láti fún wa ní ìtọ́sọ́nà nípa rírántí Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá. Jèhófà ti gbọ́ àdúrà rẹ̀ nípa fífún un ní ọgbọ́n tó gadabú. (1 Àwọn Ọba 3:6-12) Gbogbo àlámọ̀rí ẹ̀dá pátápátá ni Sólómọ́nì yẹ̀ wò fínnífínní. Láfikún sí i, Ọlọ́run mí sí i láti kọ àwọn ohun tó rí sílẹ̀ fún àǹfààní àwọn ẹlòmíràn. Ó kọ̀wé pé: “Ní àfikún sí òtítọ́ náà pé akónijọ di ọlọ́gbọ́n, ó tún ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ nígbà gbogbo, ó ronú jinlẹ̀, ó sì ṣàyẹ̀wò fínnífínní, kí ó lè ṣètò ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe lọ́nà gígún régé. Akónijọ wá ọ̀nà àtirí àwọn ọ̀rọ̀ dídùn àti àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ títọ̀nà tí ó jẹ́ òtítọ́.”—Oníwàásù 12:9, 10.

11. Èé ṣe tó fi yẹ ká gba ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Sólómọ́nì fún wa?

11 Bí ẹ̀dà ti Septuagint lédè Gíríìkì ṣe túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà nìyí: “Ní àfikún sí i, nítorí tí oníwàásù gbọ́n, nítorí tí ó kọ́ aráyé ní ọgbọ́n; kí etí lè gbọ́ ohun dídùn láti inú òwe, oníwàásù ṣàyẹ̀wò fínnífínní, kí ó bàa lè rí àwọn ọ̀rọ̀ tó dùn ún gbọ́, kí ó sì lè kọ àwọn òdodo ọ̀rọ̀ sílẹ̀.” (The Septuagint Bible, tí Charles Thomson tú) Sólómọ́nì sapá láti dénú ọkàn àwọn òǹkàwé rẹ̀ nípa lílo àwọn ọ̀rọ̀ tó dùn-ún gbọ́ àti nípa jíjíròrò àwọn kókó ẹ̀kọ́ tó fani mọ́ra, tó sì ṣe pàtàkì. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ táa rí nínú Ìwé Mímọ́ wá nípasẹ̀ ìmísí ẹ̀mí mímọ́, ó yẹ ká tẹ́wọ́ gba àwárí rẹ̀, ká sì gba ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n rẹ̀ láìjiyàn.—2 Tímótì 3:16, 17.

12. Lọ́rọ̀ ara rẹ, báwo ni wàá ṣe sọ ohun tí Sólómọ́nì wí, gẹ́gẹ́ báa ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Oníwàásù 12:11, 12?

12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọgbọ́n ìtẹ̀wé ti òde òní kò tíì sí nígbà ayé Sólómọ́nì, ìwé pọ̀ rẹpẹtẹ nígbà yẹn. Ojú wo ló yẹ kó fi wo irú ìwé bẹ́ẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún? Ó wí pé: “Ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n dà bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣó tí a gbá wọlé ni àwọn tí ó jọ̀wọ́ ara wọn fún àkójọ àwọn gbólóhùn; láti ọ̀dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn kan ni a ti fi wọ́n fúnni. Ní ti ohunkóhun yàtọ̀ sí ìwọ̀nyí, ọmọ mi, gba ìkìlọ̀: Nínú ṣíṣe ìwé púpọ̀, òpin kò sí, fífi ara ẹni fún wọn lápọ̀jù sì ń mú ẹran ara ṣàárẹ̀.”—Oníwàásù 12:11, 12.

13. Báwo lọ̀rọ̀ àwọn tó ní ọgbọ́n Ọlọ́run fi lè dà bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù, àwọn wo ló sì dà bíi “ìṣó tí a gbá wọlé”?

13 Bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù ni ọ̀rọ̀ àwọn tó ní ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe ń rí. Lọ́nà wo? Wọ́n máa ń gún ọkàn òǹkàwé tàbí ẹni tó ń fetí sílẹ̀ ní kẹ́sẹ́, kó lè tẹ̀ síwájú ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó ń kà tàbí tó ń gbọ́. Ní àfikún sí i, àwọn tó bá fara wọn fún “àkójọ àwọn gbólóhùn,” tàbí àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n àti àwọn ọ̀rọ̀ tó ní láárí, dà bí “ìṣó tí a gbá wọlé,” tàbí lédè mìíràn wọ́n jẹ́ ẹni tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. Èyí lè rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé àwọn ọ̀rọ̀ dáadáa tírú àwọn bẹ́ẹ̀ ń sọ fi ọgbọ́n Jèhófà hàn, ó sì lè mú kí àwọn òǹkàwé wọn tàbí àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn dúró gbọn-in tàbí kó gbé wọn ró. Bóo bá jẹ́ òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ṣé kò yẹ kóo sapá láti gbin irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ sọ́kàn ọmọ rẹ?—Diutarónómì 6:4-9.

14. (a) Irú àwọn ìwé wo ni kò ní dáa kí èèyàn fi ‘ara rẹ̀ fún lápọ̀jù’? (b) Àwọn ìwé wo ló yẹ ká máa kà jù lọ, èé sì ti ṣe?

14 Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí Sólómọ́nì fi sọ ohun tó sọ nípa ìwé? Tóò, táa bá fi ìwé ayé yìí wé Ọ̀rọ̀ Jèhófà, lóòótọ́ ni ìwé ayé pọ̀ rẹpẹtẹ, àmọ́, èrò ènìyàn lásán ló kúnnú ẹ̀. Èyí tó sì pọ̀ jù lọ nínú ìrònú yìí ló jẹ́ ti Sátánì Èṣù. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Nítorí náà, “fífi ara ẹni fún” irú àwọn ìwé ayé bẹ́ẹ̀ “lápọ̀jù” kò lè mú àǹfààní pípẹ́ títí wá. Ká sòótọ́, tíwèé ayé bá ti lọ pọ̀ jù, ó lè ba ipò tẹ̀mí èèyàn jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì, ẹ jẹ́ ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ìgbésí ayé. Èyí ni yóò fún ìgbàgbọ́ wa lókun, tí yóò sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Kíka àwọn ìwé mìíràn tàbí àwọn orísun ẹ̀kọ́ mìíràn lákàjù lè mú kí àárẹ̀ mú wa. Pàápàá jù lọ bírú ìwé bẹ́ẹ̀ bá lọ jẹ́ èyí tó kún fún ìrònú ayé tó ta ko ọgbọ́n Ọlọ́run, wọn ò dáa rárá, wọ́n sì lè pa ìgbàgbọ́ téèyàn ní nínú Ọlọ́run àti ète rẹ̀ kú pátápátá. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká rántí pé ìwé tó ṣàǹfààní jù lọ nígbà ayé Sólómọ́nì àti lóde ìwòyí ni ìwé tó fi ọgbọ́n “olùṣọ́ àgùntàn kan” hàn, ìyẹn ni Jèhófà Ọlọ́run. Ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin ló pèsè sínú Ìwé Mímọ́, ìwọ̀nyí ló sì yẹ ká máa kà jù lọ. Bíbélì àti àwọn ìwé tó lè ranni lọ́wọ́ tí ‘ẹrú olóòótọ́’ náà ń tẹ̀ jáde ń jẹ́ ká ní “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.”—Òwe 2:1-6.

Gbogbo Ojúṣe Wa Níwájú Ọlọ́run

15. (a) Báwo ni wàá ṣe ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì nípa “gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn”? (b) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe báa bá fẹ́ ṣe ojúṣe wa níwájú Ọlọ́run?

15 Nígbà tí akónijọ náà, Sólómọ́nì, ń ṣàkópọ̀ gbogbo ìwádìí rẹ̀, ó ní: “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn. Nítorí Ọlọ́run tòótọ́ tìkára rẹ̀ yóò mú gbogbo onírúurú iṣẹ́ wá sínú ìdájọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun fífarasin, ní ti bóyá ó dára tàbí ó burú.” (Oníwàásù 12:13, 14) Táa bá ní ìbẹ̀rù tó gbámúṣé fún Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá, tàbí táa ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un, kò ní jẹ́ kí àwa, bóyá àti ìdílé wa, máa lépa ìgbésí ayé oníranù tó lè kó ìdààmú tí kò ṣeé fẹnu sọ àti ìbànújẹ́ bá àwa àti àwọn tó fẹ́ràn wa. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́nà tó gbámúṣé jẹ́ ojúlówó ìbẹ̀rù, òun sì ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọgbọ́n àti ìmọ̀. (Sáàmù 19:9; Òwe 1:7) Báa bá ní ìjìnlẹ̀ òye táa gbé karí Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, táa sì ń fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò nínú ohun gbogbo, a ó lè ṣe “gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe” wa sí Ọlọ́run. Rárá o, kì í ṣe pé ká wá to àwọn ojúṣe wa lẹ́sẹlẹ́sẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká wonú Ìwé Mímọ́ nígbà táa bá fẹ́ yanjú ìṣòro ìgbésí ayé, ká sì máa ṣe ohun gbogbo lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́.

16. Ní ti ìdájọ́, kí ni Jèhófà yóò ṣe?

16 Ó yẹ ká mọ̀ pé kò sóhun tó ń lọ tí Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá ò rí. (Òwe 15:3) Òun “yóò mú gbogbo onírúurú iṣẹ́ wá sínú ìdájọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni, Ọ̀gá Ògo Jù Lọ yóò ṣèdájọ́ ohun gbogbo, títí kan àwọn ohun tó pa mọ́ fún ojú ènìyàn. Mímọ àwọn kókó wọ̀nyí dájú lè sún wa láti máa tẹ̀ lé àṣẹ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n olórí ohun tó yẹ kó sún wa ni ìfẹ́ fún Baba wa ọ̀run, nítorí àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Nítorí èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Níwọ̀n bí àwọn àṣẹ Ọlọ́run sì ti wà fún ire wa pípẹ́ títí, dájúdájú, kì í wulẹ̀ ṣe pé ó yẹ láti pa wọ́n mọ́, ṣùgbọ́n, ó bọ́gbọ́n mu láti pa wọ́n mọ́. Èyí ò nira fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá. Wọ́n ṣe tán láti ṣe ojúṣe wọn níwájú rẹ̀.

Ṣe Gbogbo Ojúṣe Rẹ

17. Kí la ó ṣe báa bá fẹ́ ṣe ojúṣe wa níwájú Ọlọ́run?

17 Báa bá jẹ́ ọlọgbọ́n, tó sì jẹ́ pé lóòótọ́ la fẹ́ ṣe gbogbo ojúṣe wa níwájú Ọlọ́run, lẹ́yìn táa bá ti ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, a óò tún ní ìbẹ̀rù tó kún fún ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún un, èyí tí yóò jẹ́ ká máa sá fún ṣíṣe ohun tó máa dùn ún. Òdodo ọ̀rọ̀, “ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọgbọ́n,” àwọn tó bá sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ máa ń ní “ìjìnlẹ̀ òye rere.” (Sáàmù 111:10; Òwe 1:7) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa fọgbọ́n hùwà, ká sì máa ṣègbọràn sí Jèhófà nínú ohun gbogbo. Èyí ṣe pàtàkì gan-an nísinsìnyí, nítorí pé Jésù Kristi Ọba ti wà níhìn-ín, ọjọ́ tí yóò ṣèdájọ́ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ tí Ọlọ́run yàn sì ti sún mọ́lé.—Mátíù 24:3; 25:31, 32.

18. Kí ni yóò jẹ́ èrè wa báa bá ṣe gbogbo ojúṣe wa níwájú Jèhófà Ọlọ́run?

18 Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, olúkúlùkù wa ni Ọlọ́run ń yẹ̀ wò fínnífínní. Ǹjẹ́ a nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tẹ̀mí, àbí a ti jẹ́ kí àwọn nǹkan ayé ba ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́? (1 Kọ́ríńtì 2:10-16; 1 Jòhánù 2:15-17) Ọ̀dọ́ ni wá tàbí àgbàlagbà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa sa gbogbo ipá wa láti ṣe ohun tí Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá fẹ́. Báa bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà, táa sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, a óò kọ àwọn ohun asán ti ayé ògbólógbòó tó ń kọjá lọ yìí pátápátá. Ìgbà náà la tó lè ní ìrètí pé a óò gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú ètò tuntun àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣèlérí. (2 Pétérù 3:13) Ẹ ò rí pé ìrètí ńlá lèyí jẹ́ fún gbogbo àwọn tó bá ṣe ojúṣe wọn níwájú Ọlọ́run!

Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?

◻ Èé ṣe tóo fi lè sọ pé kì í ṣe ohun gbogbo ni asán?

◻ Èé ṣe tó fi yẹ kí ọ̀dọ́ Kristẹni kan kúnlẹ̀ àdúrà nípa iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tó ń ṣe?

◻ Irú àwọn ìwé wo ni kò ní dáa kí èèyàn ‘fi ara rẹ̀ fún lápọ̀jù’?

◻ Kí ni “gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn”?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Kì í ṣe ohun gbogbo ni asán fún àwọn tó ń sin Jèhófà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Láìdàbí ọ̀pọ̀ ìwé ayé yìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń tuni lára, ó sì ń ṣeni láǹfààní

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́