ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w00 4/1 ojú ìwé 3-4
  • Kí Lo Mọ̀ Nípa Àjẹ́ Ṣíṣe?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Lo Mọ̀ Nípa Àjẹ́ Ṣíṣe?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Fà Á Táwọn Kan Fi Ń Ṣàjẹ́?
    Jí!—1999
  • Ohun Tó Yẹ Kóo Mọ̀ Nípa Àjẹ́ Ṣíṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Àṣírí Iṣẹ́ Òkùnkùn
    Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
  • Iṣẹ́ Òkùnkùn àti Ìbẹ́mìílò Kò Dára
    Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
w00 4/1 ojú ìwé 3-4

Kí Lo Mọ̀ Nípa Àjẹ́ Ṣíṣe?

ÀJẸ́! Kí ni ọ̀rọ̀ yẹn gbé wá sọ́kàn ẹ?

Lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti àlá asán ni, kì í ṣe nǹkan téèyàn ń fọwọ́ gidi mú. Lójú tiwọn, ohun tèèyàn kàn ń fi lálàá lásán ni ọ̀ràn àjẹ́—àwọn ògbólógbòó òṣòròǹgà, tí wọ́n wẹ̀wù aláràbarà, tí wọ́n lẹ ìyẹ́ àdán mọ́ àgé tómi inú rẹ̀ ń sọ pùtù, tí wọ́n ń sọ àwọn èèyàn di àkèré, tí wọ́n jókòó sórí ìgbálẹ̀ tó ń gbé wọn fò kiri lóru, tí wọ́n ń rẹ́rìn-ín kèékèé.

Lójú àwọn míì, àjẹ́ kì í ṣe ọ̀ràn ẹ̀rín rárá o. Àwọn olùwádìí kan sọ pé ó lé ní ìdajì lára àwọn olùgbé ayé tó gbà gbọ́ pé àjẹ́ wà lóòótọ́ àti pé wọ́n lè ṣe àwọn èèyàn ní jàǹbá. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló gbà gbọ́ pé nǹkan burúkú ni àjẹ́ ṣíṣe, pé ó léwu, ó sì yẹ kéèyàn bẹ̀rù ẹ̀ gan-an. Fún àpẹẹrẹ, ìwé kan tó ń sọ nípa ẹ̀sìn àwọn ará Áfíríkà sọ pé: “Ìgbàgbọ́ nínú iṣẹ́ àfọ̀ṣẹ àti iṣẹ́ oṣó àti àjẹ́ àti ewu tó wà nínú wọn, ta gbòǹgbò gan-an nínú ìgbésí ayé àwọn ará Áfíríkà . . . Àwọn èèyàn kórìíra àwọn àjẹ́ àti oṣó gan-an láwùjọ. Kódà, títí di báa ṣe ń wí yìí, láwọn ibì kan àti nígbà àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, àwọn èèyàn máa ń lù wọ́n pa ni.”

Ṣùgbọ́n láwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé, ńṣe làwọn èèyàn ń fọ̀wọ̀ wọ àwọn tó ń ṣàjẹ́ báyìí o. Àwọn ìwé, tẹlifíṣọ̀n, àti sinimá ti sapá gan-an láti mú ìbẹ̀rù àwọn àjẹ́ kúrò lọ́kàn àwọn èèyàn. David Davis, tó jẹ́ alálàyé nípa eré ìnàjú, sọ pé: “Lójijì, àwọn ọ̀dọ́ ló wá ń ṣe àjẹ́, àwọn ọmọ tó gbọ́ fáàrí, àwọn ọmọ tó ti lọ wà jù. Ilé iṣẹ́ tó ń ṣe sinimá ní Amẹ́ríkà sì tètè máa ń mọ ohun tí àwọn èèyàn ń gba tiẹ̀. . . . Tí wọ́n bá fi àwọn àjẹ́ hàn bí ẹni tó gbọ́ fáàrí tó sì túbọ̀ fani mọ́ra, ọ̀pọ̀ lára àwọn òǹwòran á lè nífẹ̀ẹ́ sí wọn, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké ò sì ní gbẹ́yìn.” Ilé iṣẹ́ tó ń ṣe sinimá ní Amẹ́ríkà ò sì kẹ̀rẹ̀ nípa ká sọ ohunkóhun tí àwọn èèyàn ń gba tiẹ̀ di òwò tó ń mérè wá.

Àwọn kan sọ pé àjẹ́ ṣíṣe ti di ọ̀kan lára àjọ ìsìn tó ń yára gbilẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, àwọn èèyàn tí iye wọn ń pọ̀ sí i, tí àwọn àjọ tó ń jà fẹ́tọ̀ọ́ obìnrin ti pọ oró sínú wọn, tí ọ̀ràn àwọn ètò ẹ̀sìn sì ti sú, ń wá ojútùú sí ohun tí wọ́n nílò nípa tẹ̀mí ní onírúurú ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà ṣe àjẹ́. Ká sòótọ́, ẹgbẹ́ àjẹ́ ti pọ̀ gan-an lóríṣiríṣi débi pé àwọn èèyàn tiẹ̀ ti ń jiyàn nípa ìtumọ̀ ọrọ̀ náà, “àjẹ́.” Ṣùgbọ́n, àwọn tí wọ́n ń sọ pé àjẹ́ làwọn sábà máa ń pe ara wọn ní ẹlẹ́sìn Wicca—tí ìwé atúmọ̀ èdè kan pè ní “ẹ̀sìn àwọn abọgibọ̀pẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní ìwọ̀ oòrùn Yúróòpù kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé, tí a sì tún ti ń mú sọjí ní ọ̀rúndún ogún yìí.” Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì fi ń pe ara wọn ní abọ̀rìṣà tàbí abọ̀rìṣà lákọ̀tun.

Nínú gbogbo ìtàn ẹ̀dá, àwọn èèyàn kórìíra àwọn àjẹ́, wọ́n máa ń fìyà jẹ wọ́n, wọ́n máa ń dá wọn lóró, wọ́n tiẹ̀ máa ń pa wọ́n. Abájọ tí àwọn tó ń ṣàjẹ́ lóde òní fi ń làkàkà láti tún orúkọ wọn ṣe. Nínú ìwádìí kan, wọ́n bi ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn àjẹ́ léèrè ohun tí wọ́n ní í sọ fún àwọn aráàlú. Olùwádìí, Margot Adler, ṣàkópọ̀ ìdáhùn wọn lọ́nà yìí, pé: “A kì í ṣe olubi. Èṣù kọ́ là ń sìn. A kì í ba tèèyàn jẹ́, a kì í sì í sún èèyàn dẹ́ṣẹ̀. A kì í wu àwọn èèyàn léwu. Èèyàn bíi tiyín làwa náà. A lẹ́bí, a níṣẹ́, a nírètí, a sì ní góńgó táà ń lépa. A kì í ṣe ẹgbẹ́ òkùnkùn. A kì í ṣe àǹjọ̀nú. . . . Ẹ má bẹ̀rù wa. . . . Ẹ lè má mọ̀ pé a ò yàtọ̀ sí yín rárá.”

Àwọn èèyàn púpọ̀ sí i ń tẹ́wọ́ gba àlàyé wọn. Ṣùgbọ́n, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò yẹ kí ọ̀ràn àjẹ́ kọ wá lóminú ni? Ẹ jẹ́ ká gbé ìbéèrè yẹn yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn lẹ́yìn èyí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́