ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 11/8 ojú ìwé 20-21
  • Kí Ló Fà Á Táwọn Kan Fi Ń Ṣàjẹ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Fà Á Táwọn Kan Fi Ń Ṣàjẹ́?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibi Tí Wọ́n Fojú sí, Ọ̀nà Ò Gbabẹ̀
  • Ipò Tẹ̀mí Àtàtà—Ibo La Ti Lè Rí I?
  • Kí Lo Mọ̀ Nípa Àjẹ́ Ṣíṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ohun Tó Yẹ Kóo Mọ̀ Nípa Àjẹ́ Ṣíṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Àṣírí Iṣẹ́ Òkùnkùn
    Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
  • Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Ha Wà Ní Tòótọ́ Bí?
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 11/8 ojú ìwé 20-21

Ojú Ìwòye Bíbélì

Kí Ló Fà Á Táwọn Kan Fi Ń Ṣàjẹ́?

“ÀJẸ́.” Kí lèrò tọ́rọ̀ yẹn gbé wá sí ẹ lọ́kàn? Ṣé àwòrán ìyá òṣòròǹgà tí ń fèèdì di àwọn ẹni ẹlẹ́ni ni, tàbí àwòrán obìnrin oníwàkiwà tí ń bá Èṣù mulẹ̀? Yàtọ̀ pátápátá sójú táwọn èèyàn fi ń wò wọ́n tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn aṣàjẹ́máàsẹ́ òde òní kò yàtọ̀ sáwọn èèyàn táa ń rí lójoojúmọ́. Àwọn kan nínú wọ́n jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ táwọn èèyàn ń gbédìí fún, àwọn èèyàn bí agbẹjọ́rò, olùkọ́, òǹkọ̀wé, àti nọ́ọ̀sì. Ní báyìí o, kárí ayé làwọn ẹ̀sìn kan ń dìde tó jọ pé wọn ò kúkú fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sáwọn aláwo, bí àwọn abọgibọ̀pẹ̀ àti àwọn onímọlẹ̀.a “Lóde òní, ibi yòówù kóo lọ ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà, wàá rí i pé ṣe ni wọ́n kàn ń gba àjẹ́ bí ẹní ń gba igbá ọtí,” ọ̀gá ọlọ́pàá kan lórílẹ̀-èdè yẹn ló sọ bẹ́ẹ̀. Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ní nǹkan bí ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [50,000] sí ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] àjẹ́, tàbí “Wiccan,”b bí wọ́n ti ń pe ara wọn.

Lóde òní, ṣe làwọn èèyàn kàn ń lo ọ̀rọ̀ náà “àjẹ́” ní ìlò wọ̀ǹdùrùkù, ohun tó bá sì wu olúkálukú ló ń túmọ̀ rẹ̀ sí. Ó jọ pé pípọ̀ táwọn àjẹ́ ń pọ̀ sí i láyé táa wà yìí jẹ́ ìmúsọjí ẹ̀sìn ìbílẹ̀ ayé àtijọ́ tí ń bọ òrìṣà abo, tí ń fáwọn èèyàn lágbára nípa wíwẹjú. Anìkànjẹ̀ làwọn àjẹ́ kan—wọn ò sí lẹ́gbẹ́ àjẹ́ kankan, ohun tí wọ́n sì ń ṣe ni pé wọ́n a máa kíyè sí bí sáà ti ń yí padà, bí òṣùpá ti ń lé, àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àbáláyé míì. Àwọn míì ń pé jọ sí ohun tí wọ́n ń pè ní ẹgbẹ́ àjẹ́, níbi tí wọ́n ti ń fèèdì di àwọn èèyàn, àjẹ́ mẹ́tàlá ló sábà máa ń wà nínú ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan.

Òótọ́ ni pé ní Ìwọ̀ Oòrùn Ayé, ojú táwọn èèyàn fi ń wo iṣẹ́ àjẹ́ lónìí ti yàtọ̀ pátápátá sí ojú ìwòye tó fa dídáná sun àwọn àjẹ́ ní Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú. Àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn èèyàn ṣì ń hùwà ìkà tó légbá kan sáwọn àjẹ́. Fún àpẹẹrẹ, ní ìbẹ̀rẹ̀ October 1998 ní Indonesia, àwọn jàǹdùkú kan yọ àdá, wọ́n sì pa àádọ́jọ èèyàn tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ àjẹ́. Ní Gúúsù Áfíríkà, láàárín 1990 sí 1998, àwọn àjẹ́ tí wọ́n hùwà ìkà sí lé ní ẹgbàá, wọ́n sì pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́rin [577]. Lójú ìwà àṣejù méjèèjì yìí—látorí nínífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ àjẹ́ dórí kíkórìíra àjẹ́—ojú wo ló yẹ káwọn Kristẹni fi wo ọ̀ràn náà?

Ibi Tí Wọ́n Fojú sí, Ọ̀nà Ò Gbabẹ̀

Kí ló ń sún àwọn èèyàn dédìí ṣíṣàjẹ́ lóde òní? Wọ́n ní torí pé àwọn fẹ́ fi ìbà fún ọba adẹ́dàá àti ìwàláàyè ni. Àní àwọn kan á tiẹ̀ tún ṣàlàyé pé àjẹ́ tàwọn kì í tilẹ̀ẹ́ fẹranko rúbọ. Àwọn míì sọ pé ìgbà táwọn ń wá èèyàn tó ṣeé finú hàn kiri, tó ṣeé fọkàn tán, táwọn sì jọ ní ìgbàgbọ́ kan náà làwọn wẹgbẹ́ àjẹ́. Àjẹ́ ìgbàlódé kan sọ pé: “Gbogbo àwọn tí mo ti rí nínú ẹgbẹ́ yìí ló ń ṣe bí ọ̀rẹ́ sí mi, tó sì ń finú hàn mí . . . Wọ́n mà dáa léèyàn o.” Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì máa ń sọ pé àwọn ò lájọṣe kankan pẹ̀lú Sátánì, wọ́n máa ń tẹnu mọ́ ọn pé ọlọ́run táwọn ń sìn kì í ṣe èṣù ọ̀dàrà rárá.

Ohun pàtàkì tó jẹ́ kí ọ̀pọ̀ nínú wọ́n di àjẹ́ ni pé wọn ò rí nǹkan kan dì mú nípa tẹ̀mí, àti pé ọ̀ràn àwọn ẹ̀sìn ayé ti sú wọn. Nígbà tí Phyllis Curott tó jẹ́ ìyálórìṣà Wicca ń sọ̀rọ̀ nípa ẹgbẹ́ tirẹ̀, ó sọ pé: “Gbogbo wa ni inú wa ò dùn sáwọn ẹ̀kọ́ àti ìwà ẹ̀sìn tí wọ́n bí wa sínú rẹ̀.” Curott tún ṣàlàyé pé àwọn àjẹ́ ìgbàlódé ń gbìyànjú láti dáhùn àwọn ìbéèrè bíi, ‘Báwo la ṣe lè padà sí ipò ìjẹ́mímọ́ ti tẹ́lẹ̀?’ Àmọ́, ṣé iṣẹ́ àjẹ́ ni ọ̀nà tí ń sinni lọ sí ojúlówó ipò tẹ̀mí?

Ipò Tẹ̀mí Àtàtà—Ibo La Ti Lè Rí I?

Bíbélì fi hàn ní kedere pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, òun sì ni Ọba Aláṣẹ Àgbáyé. (Sáàmù 73:28; 1 Pétérù 1:15, 16; Ìṣípayá 4:11) Ó ń ké sí gbogbo èèyàn pé kí wọ́n wá òun, ‘wọn yóò sì rí òun ní ti gidi.’ (Ìṣe 17:27) Fún ìdí yìí, ọ̀nà kan ṣoṣo táa lè gbà rí ojúlówó ipò tẹ̀mí ni bí a bá ń gba ìmọ̀ pípéye nípa Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, sínú. A lè rí ìmọ̀ yìí gbà nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Mímọ́, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Jákọ́bù, ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì, sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.

Àmọ́ o, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa nípa orísun burúkú kan tí àdàmọ̀dì ọ̀rọ̀ tẹ̀mí ti ń wá. (1 Jòhánù 4:1) Ó sọ pé Sátánì Èṣù, olórí ọ̀tá Jèhófà, àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ni orísun awúrúju ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀rọ̀ tẹ̀mí tó tàn kálẹ̀ lónìí.c Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, Sátánì “ti fọ́ èrò inú” ọ̀pọ̀lọpọ̀. Àní ó “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà,” títí kan àwọn àjẹ́—yálà wọ́n gbà pé Èṣù làwọn ń sìn tàbí wọn ò gbà. Èé ṣe táa fi sọ bẹ́ẹ̀?—2 Kọ́ríńtì 4:4; Ìṣípayá 12:9.

Ọ̀pọ̀ àṣà àti ààtò táwọn àjẹ́ ìgbàlódé ń ṣe kò yàtọ̀ sáwọn ààtò awo tí ń wáyé nínú ìjọsìn Sátánì. Fún ìdí yìí, kódà bó ṣe ojú-mìí-tó lásán ló sún èèyàn dédìí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, wẹ́rẹ́ ló máa bá ara rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn. Àní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti tipa báyìí kó sí akóló Sátánì.

A ò tún ní gbàgbé o, pé nígbà míì ohun tó ń sún àwọn kan wọ ẹgbẹ́ àjẹ́ lóde òní ni pé wọ́n ń wá agbára tàbí pé wọ́n fẹ́ gbẹ̀san. Àjẹ́ ìgbàlódé kan tó ń jẹ́ Jennifer sọ pé: “Àwọn kan wà tó jẹ́ pé ìkà ni wọ́n ń fi àjẹ́ tiwọn ṣe.” Èyí ó wù kó jẹ́, àti àjẹ́ tó lóun ń ṣe rere àti èyí tó ń ṣìkà, Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù ló ń darí gbogbo wọn. Àwọn àjẹ́ kan lè sọ pé irú àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú bẹ́ẹ̀ ò sí, ṣùgbọ́n èyí gan-an ni yóò jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fáwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wọ̀nyí láti tàn wọ́n jẹ.—Fi wé 1 Kọ́ríńtì 10:20, 21.

Bíbélì kórìíra iṣẹ́ wíwò, iṣẹ́ oṣó, idán pípa, fífi èèdì múni, àti gbígbìyànjú láti bá àwọn òkú sọ̀rọ̀. Ó là á mọ́lẹ̀ pé: “Gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” (Diutarónómì 18:10-12) Láìsí àní-àní, àwọn Kristẹni ń sapá láti “máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn,” wọ́n sì ti tipa báyìí ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láti gba ara wọn lọ́wọ́ onírúurú àṣà ìbẹ́mìílò. (Gálátíà 6:10; Ìṣe 16:14-18) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń yàgò fún lílọ́wọ́ nínú ìjọsìn èké, títí kan ohunkóhun tó bá jẹ mọ́ ṣíṣàjẹ́.—2 Kọ́ríńtì 6:15-17.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Èdè náà “abọgibọ̀pẹ̀” ni àwọn tó gbà gbọ́ pé ilẹ̀ ayé àti gbogbo ohun alààyè jẹ́ òrìṣà agbẹbọ àti pé gbogbo wọ́n ní ẹ̀mí kan náà; “onímọlẹ̀” ni àwọn tí ń bọ àwọn òrìṣà tó ti wà kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé.

b Gẹ́gẹ́ bí ìwé The American Heritage College Dictionary ti wí, àwọn Wiccan jẹ́ ọmọlẹ́yìn Wicca, tí í ṣe “ẹ̀sìn àwọn abọgibọ̀pẹ̀ tó ti wà ní ìwọ̀ oòrùn Yúróòpù kí ẹ̀sìn Kristẹni tó wọlé dé.”

c Ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣàlàyé “Ojú Ìwòye Bíbélì” nínú Jí! ti dáhùn àwọn ìbéèrè bí “Èṣù kan Ha Wà Niti-gidi Bí?” (July 8, 1990, ojú ìwé 12 àti 13) àti “Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Ha Wà Ní Tòótọ́ Bí?” (April 8, 1998, ojú ìwé 18 àti 19).

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 20]

Picture Book of Devils, Demons and Witchcraft/Ernst àti Johanna Lehner/Dover

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́