ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w00 4/1 ojú ìwé 23
  • “Ẹ Mọ Bíbélì Gan-an Ni”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Mọ Bíbélì Gan-an Ni”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọn Kìí Ṣe Akirità Ọ̀rọ̀ Ọlọrun
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ran Àwọn Tó Di Aláìní Lọ́wọ́?
    Jí!—2006
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí Àárín Èmi àti Olùkọ́ Mi Lè Gún?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Àwọn Olùkọ́—Èé Ṣe Tá A Fi Nílò Wọn?
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
w00 4/1 ojú ìwé 23

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

“Ẹ Mọ Bíbélì Gan-an Ni”

NÍGBÀ tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá, tó fìgboyà bá àwọn aṣáájú ìsìn sọ̀rọ̀ ní Jerúsálẹ́mù, “gbogbo àwọn tí ń fetí sí i ni wọ́n ń ṣe kàyéfì léraléra nítorí òye rẹ̀ àti àwọn ìdáhùn rẹ̀.” (Lúùkù 2:47) Bákan náà ni ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí ń fi ìgboyà bá àwọn olùkọ́ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti Bíbélì, lọ́pọ̀ ìgbà ni ìyọrísí rẹ̀ sì máa ń mú inú àwọn náà dùn.

Tiffany, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, wà lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ti ọdún, èyí tí a rí nínú Dáníẹ́lì 9:24-27. Olùkọ́ rẹ̀ ṣàlàyé díẹ̀ nípa àwọn ẹsẹ wọ̀nyẹn, ó sì tètè jánu lórí kókó náà.

Lákọ̀ọ́kọ́, Tiffany ò fẹ́ nawọ́. Ó sọ pé: “Àmọ́ mi ò mọ nǹkan tó fà á, ó sáà ń dùn mí pé kò ṣàlàyé àwọn ẹsẹ yẹn dáadáa. Àfẹ̀ẹ̀kan náà, mo kàn nawọ́ ni.” Ẹnu ya olùkọ́ náà pé ẹnì kan lè ní nǹkan láti sọ nípa kókó náà, nítorí pé ó rú ọ̀pọ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lójú.

Nígbà tó fún Tiffany láyè láti ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ náà, ó dìde, ó sì sọ̀rọ̀ geere láìjẹ́ pé ó ti múra sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Nígbà tó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kíláàsì pa rọ́rọ́ ni. Ojora mú Tiffany díẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tó ṣe díẹ̀, gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kàn bẹ̀rẹ̀ sí pàtẹ́wọ́ ni.

Olùkọ́ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ léraléra pé: “Tiffany, o káre, ọ̀rọ̀ gidi lo sọ.” Ọkùnrin náà ní òun mọ̀ pé àwọn ẹsẹ yẹn á nítumọ̀ ju bí òún ṣe ṣàlàyé wọn lọ, ṣùgbọ́n pé Tiffany lẹni tó kọ́kọ́ ṣàlàyé wọn fún òun yékéyéké. Nígbà tí wọ́n parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà, ó bi Tiffany léèrè bó ṣe mọ Bíbélì gan-an bẹ́ẹ̀.

Ó fèsì pé: “Nítorí pé mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Àwọn òbí mi ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ náà fún mi lọ́pọ̀ ìgbà kó tó yé mi.”

Ẹnu ya àwọn ọmọ kíláàsì ẹgbẹ́ rẹ̀ pé ó mọ Bíbélì tó yẹn. Akẹ́kọ̀ọ́ kan sọ fún Tiffany pé: “Mo wá mọ ìdí tí ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń lọ láti ojúlé dé ojúlé; ìdí ni pé ẹ mọ Bíbélì gan-an ni.” Àwọn yòókù ṣèlérí pé àwọn ò ní fi í ṣe yẹ̀yẹ́ mọ́ nípa àwọn ohun tó gbà gbọ́.

Nígbà tí Tiffany sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún àwọn òbí rẹ̀, wọ́n dámọ̀ràn pé kó fi ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun lọ olùkọ́ rẹ̀. Nígbà tó ṣe bẹ́ẹ̀, tó sì fi ibi tó ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì han olùkọ́ náà, kíá ló gba ìwé náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

Òótọ́ ni pé bí àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni bá lo ìgboyà, tí wọ́n sì sọ nípa ohun tí àwọn òbí wọ́n kọ́ wọn nípa Ọlọ́run àti Bíbélì, ńṣe ni wọ́n ń yin Jèhófà lógo, tí wọ́n ń fọlá fún un, wọ́n sì ń mú ìbùkún wá sórí ara wọn pẹ̀lú.—Mátíù 21:15, 16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́