Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ran Àwọn Tó Di Aláìní Lọ́wọ́?
“Mo ní in lọ́kàn pé tí mo bá jáde ilé ìwé, màá ríṣẹ́ atúnnáṣe. Mo fẹ́ máa lọ́wọ́ nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba.”— Tristan ọmọ ọdún mẹ́rìnlá.
“Mo fẹ́ fún yín ní ogún dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà yìí, mo fẹ́ kẹ́ ẹ fi kún owó ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tuntun yẹn. Owó táwọn òbí mi fún mi láti máa fi ra nǹkan tó bá wù mí ni, ṣùgbọ́n mo fún yín.” — Abby, ọmọ ọdún mẹ́sàn-án.
LÓDE òní tó jẹ́ pé ó rọrùn fáwọn kan láti máa pe àwọn ọ̀dọ́ ní onímọtara-ẹni-nìkan, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́, tó fi mọ́ àwọn tó sọ ọ̀rọ̀ tá a kọ sókè yìí, ń fi hàn pé gbogbo ọ̀dọ́ kọ́ ni onímọtara-ẹni-nìkan. Láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin ló ń lo àkókò wọn, okun wọn àtohun ìní wọn fáwọn ẹlòmíì. (Sáàmù 110:3) Wo àpẹẹrẹ díẹ̀ sí i.
Kò pẹ́ tí ìyá-ìyá ọmọkùnrin ọmọ ọdún méje kan tó ń jẹ́ Jirah, láti ilẹ̀ Ọsirélíà kú ni bàbá ìyá ọmọkùnrin yìí fún un ní àádọ́ta dọ́là ilẹ̀ Ọsirélíà. Kí wá ni Jirah fi owó ọ̀hún ṣe o? Ní ìpàdé tí wọ́n ṣe lẹ́yìn ọjọ́ yẹn, ó ju gbogbo owó yẹn sínú àpótí ọrẹ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kí ló dé tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Jirah ṣàlàyé fún ìyá ẹ̀ pé: “Mo láwọn ohun ìṣeré ọmọdé tó pọ̀, àmọ́ ìyá àgbà kan ṣoṣo ni mo ní. Mo mọ̀ pé ṣe ni màmá àgbà á fẹ́ kí n fi owó yìí ṣe ọrẹ torí pé wọ́n fẹ́ràn Jèhófà púpọ̀púpọ̀.”
Ọmọ ọdún márùn-ún ni Hannah tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó sì fẹ́ràn ẹṣin. Ó fẹ́ ra ẹṣin ìṣeré tówó ẹ̀ tó dọ́là márùndínlọ́gọ́rin ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Torí pé àwọn òbí Hannah fẹ́ kọ́ ọ kó lè máa fowó pamọ́, wọ́n máa ń fún ni owó láti fi sínú kóló tí wọ́n ṣe bí Ẹlẹ́dẹ̀. Nígbà tó yá, owó Hannah ti pọ̀ tó láti ra ẹṣin ìṣeré tó fẹ́ rà.
Àmọ́, láìpẹ́ sígbà yẹn gan-an ni Ìjì Líle Katrina jà létí òkun tó wà lápá ibi tí ilẹ̀ Mẹ́síkò ti bá apá ibì kan pààlà nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Àánú àwọn tó fara gbá àjálù náà ṣe Hannah, ló bá pinnu pé òun á fi gbogbo owó tóun ti ń tọ́jú yìí ṣe ìtọrẹ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Owó yẹn lé ní ọgọ́rùn-ún dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Hannah kọ̀wé sí orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé: “Mo fẹ́ fún yín lówó yìí torí pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà mo sì fẹ́ ṣèrànwọ́.” Ǹjẹ́ Jèhófà ń kíyè sí irú ìwà ọ̀làwọ́ bẹ́ẹ̀? Bíbélì sọ pé: “Má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.”—Hébérù 13:16.
Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Tiffany tóun náà ń gbé nílẹ̀ Amẹ́ríkà kọ̀wé sí orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn tí ìjì líle méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ jà ní ìpínlẹ̀ Florida lọ́dún 2004. Ó kọ̀wé pé: “Èmi àti Timothy àbúrò mi fẹ́ láti fi àádọ́fà [110] dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà yìí ṣe ìtọrẹ. Ìjì tó jà ò fi bẹ́ẹ̀ ba ilé wa jẹ́, àmọ́ a rí ohun tí ìjì ọ̀hún ṣe fáwọn ilé míì. A fẹ́ ran àwọn tó ṣe ní jàǹbá lọ́wọ́, torí náà a bẹ̀rẹ̀ sí í fowó wa pa mọ́. Timothy pa dọ́là mẹ́wàá níbi tó ti ń bá wọn ṣí ohun tí wọ́n fi bo ara ilé kan kúrò, ṣùgbọ́n èmi pa ọgọ́rùn-ún dọ́là ńtèmi.” Ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni Tiffany, ọmọ ọdún méje péré sì ni Timothy àbúrò rẹ̀! Èrè wo ló wà fún wa tá a bá ń fi ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì ṣíwájú tara wa? Òwe 11:25 sọ pé: “Ẹni tí ó . . . ń bomi rin àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà, a ó bomi rin òun náà ní fàlàlà.”
Àwọn ọmọ kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́rin sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún gbọ́ pé àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn nílẹ̀ Áfíríkà nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba. Torí náà, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti wá nǹkan ṣe sọ́ràn ọ̀hún. Wọ́n sọ pé: “A ṣe bisikíìtì àti kéèkì, a sì ń tà wọ́n nínú gbàgede ilé wa, ibi tá a ti rówó tó lé ní dọ́là mẹ́rìndínláàádọ́fà [106] nìyẹn. A sọ fáwọn èèyàn pé ó lè jẹ́ pé ibi táwọn ará ilẹ̀ Áfíríkà á ti máa pàdé láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni wọ́n máa fi owó yẹn kọ́. Ọ̀pọ̀ ló wá bá wa rà á. Wákàtí mẹ́sàn-án ló gbà wá láti tà á, àmọ́ ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ torí Jèhófà la ṣe é fún!”
Ìwọ Náà Lè Ṣèrànwọ́
Àwọn ọ̀dọ́ tá a kọ ohun tí wọ́n ṣe sókè yìí ti mọ bí ọ̀rọ̀ Jésù náà ṣe jẹ́ òótọ́ tó, pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ìwọ náà lè rí ayọ̀ tó wà nínú fífúnni ní nǹkan. Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà fúnni ní nǹkan?
Ǹjẹ́ o ti gbọ́ ọ nínú ìròyìn rí pé àwọn kan tí wọ́n jẹ́ Kristẹni bíi tìẹ wà nínú àìní? Bí àpẹẹrẹ, ṣé àjálù ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ níbì kan? Fojú inú wo bó ṣe máa rí lára ẹ bó o bá ṣàdédé di aláìnílélórí, tàbí tó o pàdánù àwọn dúkìá kan tàbí téèyàn ẹ kan tiẹ̀ kú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé káwọn Kristẹni “má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara [wọn] nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Ká tiẹ̀ ní ibi tí jàǹbá ti ṣẹlẹ̀ jìnnà sí ibi tó ò ń gbé, ó ṣì lè ṣeé ṣe fún ìwọ náà láti fi owó tàbí nǹkan míì ṣètìlẹ́yìn fún ètò ìrànwọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe fáwọn tí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀ sí.a
Àwọn ọ̀nà míì tún wà tó o lè gbà ran àwọn tó bá wà nínú àìní lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o ò ṣe wò yíká Gbọ̀ngàn Ìjọba yín? Ó ṣeé ṣe kó o ráwọn àgbàlagbà kan tàbí àwọn míì tó nílò ìrànlọ́wọ́? Ṣó o lè bá wọn ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn ará Róòmù pé: “Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Bó o bá rí i pé ohun kan ṣẹlẹ̀ tó nílò àbójútó, ṣe ni kó o wá nǹkan ṣe sí i láìṣe pé ẹnì kan sọ fún ẹ. Máà lọ́ tìkọ̀ tó bá dọ̀ràn iṣẹ́ tó gba agbára pàápàá. Sì rántí pé ṣíṣe àwọn ẹlòmíì lóore wà lára iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín, Òun yóò sì san ìlòsíni rẹ̀ padà fún un.”—Òwe 19:17.
Àmọ́ ṣá, ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù lọ tó o lè gbà ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ ni pé kó o máa sọ ohun tó o mọ̀ nípa Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn. Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Àkókò yìí gan-an ló ṣe pàtàkì jù lọ fáwọn èèyàn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó ń fúnni ní ìyè látinú Bíbélì. Torí náà, máa fìtara kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù, sì mọ̀ dájú pé ‘òpò rẹ kì í ṣe asán.’—1 Kọ́ríńtì 15:58.
Àwọn àpilẹ̀kọ láti inú ọ̀wọ́ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” wà nínú ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì náà www.watchtower.org/ype
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A mọrírì ẹ̀ tẹ́nì kan bá dìídì ṣe ìtọrẹ láti fi ran àwọn tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́. Àmọ́, á dáa jù tá a bá fi irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe torí pé ara ọrẹ yìí la ti ń mú owó láti fi bójú tó ìnáwó èyíkéyìí tó bá yọjú.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Ǹjẹ́ o lè rántí ẹnì kan táá nílò ìrànlọ́wọ́?
◼ Kí lo lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]
“Ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.”—Hébérù 13:16
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O MÁA FÚNNI NÍ NǸKAN?
“Mo máa ń ráwọn òbí mi tí wọ́n máa ń lo àkókò àti okunra wọn láti sin Jèhófà tí wọ́n sì ń ran àwọn aládùúgbò wa lọ́wọ́, ìyẹn mú kémi náà fẹ́ fi ìgbésí ayé mi ṣe nǹkan yẹn gan-an. Bàbá mi sọ fún mi pé: ‘Bó ti wù kí nǹkan ọ̀hún kéré tó, ohun yòówù kó o ṣe fún Jèhófà, kò ní pa run títí láé. Jèhófà wà títí láé, títí láé láá sì máa rántí ohun tó o bá ṣe. Àmọ́ tó o bá fi gbogbo ọjọ́ ayé ẹ ṣèfẹ́ ara ẹ nìkan, asán ló máa já sí. Tó o bá ti kú, gbogbo ohun tó o ṣe ti kú pẹ̀lú ẹ nìyẹn.’”—Kentaro, ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún, láti orílẹ̀-èdè Japan.
“Ká sòótọ́, ohun tí kì í wù mí ṣe rárá àti rárá ni pé kí n máa bá àwọn àgbàlagbà ṣe iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé lọ́sàn-án Sátidé. Ṣe ló máa ń wù mí kí n lọ gbádùn ara mi lọ́dọ̀ àwọn akẹgbẹ́ mi. Àmọ́ nígbà tí mo lo àkókò díẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn àgbàlagbà, mo ti lọ gbádùn ẹ̀ jù. Mo wá mọ̀ wọ́n dáadáa, pé èèyàn bíi tèmi làwọn náà, àti pé ìgbà kan wà táwọn náà wà bíi tèmi yìí. Èyí ló wá jẹ́ kí n fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́.”—John, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
“Nígbà tí mo ṣì kéré jù báyìí lọ, mo máa ń lọ́wọ́ nínú mímú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ mo sì máa ń lọ́wọ́ sáwọn nǹkan míì. Ó tún máa ń wù mí kí n máa bá àwọn míì nínú ìjọ ṣe àwọn iṣẹ́ tó gba agbára. Tó o bá ran àwọn míì lọ́wọ́, wàá rí ayọ̀ tó ń fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà témi àtàwọn kan jọ lọ lẹ pépà tí wọ́n fi ń ṣe ògiri yàrá lọ́ṣọ̀ọ́ mọ́ ilé arábìnrin àgbàlagbà kan. Inú ìyá yìí dùn dẹ́yìn! Tó o bá ṣe nǹkan tó múnú ẹlòmíì dùn, inú tìẹ náà á dùn.”—Hermann ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún láti ilẹ̀ Faransé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń fowó ṣètìlẹyìn fún àwọn tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí