Bí Hánà Ṣe Dẹni Tó Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn
HÁNÀ jẹ́ obìnrin kan tó ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà. Lọ́jọ́ kan, ó gbàdúrà sókè láti fi gbé Jèhófà ga. Ó ní Ọlọ́run ti gbé òun dìde kúrò nínú ekuru, pé ó ti sọ ẹkún òun dayọ̀.
Kí ló mú kí Hánà sọ pé Ọlọ́run ti gbé òun dìde kúrò nínú ekuru? Kí sì nìdí tínú rẹ̀ fi ń dùn gan-an nísinsìnyí? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìrírí rẹ̀? Láti lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ẹ jẹ́ ká gbé ìtàn Hánà yẹ̀ wò.
Wàhálà Nínú Ilé Wọn
Hánà jẹ́ ìyàwó ọmọ Léfì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹlikénà, tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ Éfúráímù. Ìyàwó méjì lọkùnrin yìí ní. (1 Sámúẹ́lì 1:1, 2a; 1 Kíróníkà 6:33, 34) Kò sí lára ètò Ọlọ́run pé kí ọkùnrin máa ní ju ìyàwó kan lọ nígbà tó kọ́kọ́ dá èèyàn. Àmọ́ lábẹ́ òfin Mósè, ó gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láyè láti fẹ́ ju ìyàwó kan lọ, ó sì ṣe òfin táwọn tó bá ní ju aya kan lọ á máa tẹ̀ lé. Olùjọ́sìn Jèhófà ni Ẹlikénà àti ìdílé rẹ̀, síbẹ̀ aáwọ̀ wà nílé wọn, gẹ́gẹ́ bó ṣe sábà máa ń rí nílé olórogún.
Hánà yàgàn, àmọ́ Pẹ̀nínà, tí í ṣe orogún rẹ̀, bí àwọn ọmọ.—1 Sámúẹ́lì 1:2b.
Tí obìnrin kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì bá yàgàn, á máa fojú ẹni ẹ̀gàn wo ara ẹ̀, á sì tún wò ó pé Ọlọ́run ò fojúure wo òun lóun ṣe yàgàn. Àmọ́ kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé Hánà ò rí ojúure Ọlọ́run ni ò ṣe rọ́mọ bí. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, dípò tí Pẹ̀nínà á fi máa tu Hánà nínú, ńṣe ló ń bà á lọ́kàn jẹ́ torí pé òun rọ́mọ bí.
Ìrìn Àjò Wọn sí Ibi Ìjọsìn Jèhófà
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aáwọ̀ wà nínú ìdílé Ẹlikénà, ọdọọdún ni wọ́n máa ń lọ síbi ìjọsìn ní Ṣílò láti rúbọ sí Jèhófà.a Ibi ìjọsìn yìí jìn tó nǹkan bí ọgbọ̀n kìlómítà sílé wọn, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹsẹ̀ ni wọ́n fi ń rìn ín. Ó dájú pé láwọn àkókò ìrúbọ yìí ayé á fẹ́rẹ̀ẹ́ sú Hánà nítorí ìpín kan ṣoṣo péré ló máa ń kan òun lára ẹbọ ìdàpọ̀ náà, nígbà tí èyí tó máa ń kan Pẹ̀nínà àtàwọn ọmọ rẹ̀ máa ń pọ̀ gan-an. Pẹ̀nínà máa ń mú Hánà bínú nírú àkókò bẹ́ẹ̀, ó máa ń mú kí inú rẹ̀ bà jẹ́ nítorí ó dà bíi pé Jèhófà “ti sé ilé ọlẹ̀ rẹ̀.” Àní kò sí ọdún kan tí wọ́n máa lọ síbi ìjọsìn yìí tí Pẹ̀nínà ò ní mú kí inú Hánà bà jẹ́, èyí sì máa ń mú kí Hánà sunkún débi pé kò ní jẹun. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àkókò ayọ̀ ló yẹ kírú àkókò bẹ́ẹ̀ jẹ́ fún un. Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, Hánà ò yéé lọ síbi ìjọsìn Jèhófà.—1 Sámúẹ́lì 1:3-7.
Ǹjẹ́ o ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Hánà fi lélẹ̀ fún wa? Nígbà tí inú ẹ bá bà jẹ́, báwo lo ṣe máa ń hùwà? Ṣé ńṣe lo máa ń yara rẹ láṣo, tí o kì í wà níbi táwọn ará máa ń wà, irú bí ìpàdé ìjọ? Hánà kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ńṣe ló jẹ́ kó mọ́ òun lára láti máa wà pẹ̀lú àwọn olùjọ́sìn Jèhófà. Bá a tiẹ̀ dojú kọ ipò tí kò rọgbọ, ó ṣì yẹ ká máa wà pẹ̀lú àwọn olùjọ́sìn Jèhófà.—Sáàmù 26:12; 122:1; Òwe 18:1; Hébérù 10:24, 25.
Ẹlikénà gbìyànjú láti tu Hánà nínú àti láti mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. Ó bi í pé: “Hánà, èé ṣe tí o fi ń sunkún, èé sì ti ṣe tí o kò fi jẹun, èé sì ti ṣe tí ìbànújẹ́ fi dé bá ọkàn-àyà rẹ? Èmi kò ha sàn fún ọ ju ọmọkùnrin mẹ́wàá lọ bí?” (1 Sámúẹ́lì 1:8) Ó ṣeé ṣe kí Ẹlikénà má mọ̀ pé Pẹ̀nínà ń fayé ni Hánà lára, Hánà pàápàá sì lè má fẹ́ sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀, kó kàn máa pa á mọ́ra. Èyí ó wù ó jẹ́, Hánà ṣe ohun tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́, ó gbàdúrà sí Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ náà dípò táá fi máa fa wàhálà.
Hánà Jẹ́jẹ̀ẹ́ Kan
Inú ibi ìjọsìn Jèhófà ni wọ́n ti máa ń jẹ ẹbọ ìdàpọ̀. Nígbà tí Hánà kúrò ní yàrá ìjẹun náà, ó lọ gbàdúrà sí Ọlọ́run. (1 Sámúẹ́lì 1:9, 10) Ó bẹ̀ ẹ́ pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, láìkùnà, bí ìwọ yóò bá wo ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ ẹrúbìnrin rẹ níṣẹ̀ẹ́, tí o sì rántí mi ní ti tòótọ́, tí ìwọ kì yóò sì gbàgbé ẹrúbìnrin rẹ, tí o sì fún ẹrúbìnrin rẹ ní ọmọ tí ó jẹ́ ọkùnrin ní ti tòótọ́, èmi yóò fi í fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ fẹ́lẹ́ kì yóò sì kan orí rẹ̀.”—1 Sámúẹ́lì 1:11.
Àdúrà Hánà ṣe pàtó. Ó ní kí Ọlọ́run fóun ní ọmọkùnrin kan, ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa fi ọmọ náà fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Násírì fún gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. (Númérì 6:1-5) Tí Ẹlikénà ọkọ rẹ̀ ò bá fọwọ́ sí ẹ̀jẹ́ yìí, ẹ̀jẹ́ náà ò lè lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, àmọ́ àwọn ìgbésẹ̀ tí Ẹlikénà gbé nígbà tó yá fi hàn pé ó fara mọ́ ẹ̀jẹ́ tí aya rẹ̀ ọ̀wọ́n jẹ́.—Númérì 30:6-8.
Bí Hánà ṣe gbàdúrà lọ́jọ́ náà mú kí Élì tí í ṣe àlùfáà àgbà rò pé ńṣe ló mutí yó. Ó kàn rí i pé Hánà ń jẹnu wúyẹ́wúyẹ́, àmọ́ kò gbọ́ ohun tó ń sọ nítorí kò gbàdúrà náà síta. Tọkàntara ló gbàdúrà náà. (1 Sámúẹ́lì 1:12-14) Ẹ ò rí i pé ó máa dùn ún gan-an nígbà tí Élì sọ fún un pé ó ti mutí yó! Síbẹ̀, kò yájú sí àlùfáà àgbà náà, tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ló fi fèsì. Nígbà tí Élì wá rí i pé ńṣe ni Hánà ń gbàdúrà “láti inú ọ̀pọ̀ yanturu ìdàníyàn [rẹ̀] àti ìbìnújẹ́ [rẹ̀],” ó sọ fún un pé: “Kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì . . . yọ̀ǹda ìtọrọ tí o ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀.” (1 Sámúẹ́lì 1:15-17) Bí Élì ṣe sọ̀rọ̀ yẹn tán, Hánà bá tirẹ̀ lọ, ó lọ jẹun, “ìdàníyàn fún ara ẹni kò sì hàn lójú rẹ̀ mọ́.”—1 Sámúẹ́lì 1:18.
Ẹ̀kọ́ wo lèyí kọ́ wa? Òun ni pé nígbà tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà nípa àwọn ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn, ó yẹ ká jẹ́ kí Jèhófà mọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lọ́kàn wá gẹ́lẹ́, ká sì fi tọkàntọkàn béèrè ohun tá a fẹ́ kó ṣe fún wa. Tí ò bá sí nǹkan míì tá a lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà, ẹ jẹ́ ká fi í sílẹ̀ fún Jèhófà. Ohun tó dára jù lọ láti ṣe nìyẹn.—Òwe 3:5, 6.
Lẹ́yìn tí ìránṣẹ́ Jèhófà kan bá ti gbàdúrà tọkàntọkàn, àfàìmọ̀ ni kò ní nírú ìbàlẹ̀ ọkàn tí Hánà ní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àdúrà gbígbà pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Tá a bá ti ju ẹrù ìnira wa sọ́dọ̀ Jèhófà, ó yẹ ká fi í sílẹ̀ fún un láti bá wa yanjú rẹ̀. Nígbà yẹn, á lè wá ṣe bíi ti Hánà, ká má ṣe jẹ́ kí ìdàníyàn wa hàn lójú wa mọ́.—Sáàmù 55:22.
Ó Fi Ọmọ Rẹ̀ fún Jèhófà
Ọlọ́run gbọ́ àdúrà Hánà, ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. (1 Sámúẹ́lì 1:19, 20) Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló lọ́wọ́ sí bíbí tí wọ́n bí ọmọ yìí. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mìíràn bẹ́ẹ̀ tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dìídì lọ́wọ́ sí bíbí tí wọ́n bí wọn ò pọ̀. Sámúẹ́lì, ọmọ Ẹlikénà òun Hánà, di wòlíì Jèhófà nígbà tó ṣe, ó sì kó ipa pàtàkì nínú fífi ìdí ìjọba Ísírẹ́lì múlẹ̀.
Ó dájú pé látìgbà tí Sámúẹ́lì ti wà lọ́mọdé jòjòló ni Hánà ti ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Àmọ́, ẹ̀jẹ́ tí Hánà jẹ́ ńkọ́? Ǹjẹ́ ó gbàgbé? Rárá o, kò gbàgbé! Hánà sọ pé: “Gbàrà tí a bá ti já ọmọdékùnrin náà lẹ́nu ọmú, èmi yóò mú un wá, yóò sì fara hàn níwájú Jèhófà, yóò sì máa gbé níbẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Nígbà tí wọ́n já Sámúẹ́lì lẹ́nu ọmú, bóyá nígbà tó wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ta tàbí kó fi díẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ, Hánà mú un lọ sílé ìjọsìn Jèhófà bó ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́.—1 Sámúẹ́lì 1:21-24; 2 Kíróníkà 31:16.
Nígbà tí Hánà àti ọkọ rẹ̀ rúbọ sí Jèhófà tán, wọ́n mú Sámúẹ́lì tọ Élì lọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Hánà di ọmọdékùnrin náà lọ́wọ́ mú nígbà tó sọ fún Élì pé: “Dákun, olúwa mi! Nípa ìwàláàyè ọkàn rẹ, olúwa mi, èmi ni obìnrin náà tí ó dúró pẹ̀lú rẹ ní ibí yìí láti gbàdúrà sí Jèhófà. Ọmọdékùnrin yìí ni mo gbàdúrà nípa rẹ̀ pé kí Jèhófà yọ̀ǹda ìtọrọ tí mo ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀. Èmi, ẹ̀wẹ̀, sì ti wín Jèhófà. Ní gbogbo ọjọ́ tí ó bá wà, ẹni tí a béèrè fún Jèhófà ni.” Báyìí ni Sámúẹ́lì ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn àkànṣe sí Ọlọ́run, èyí tó fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ṣe.—1 Sámúẹ́lì 1:25-28; 2:11.
Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, ó dájú pé Hánà ò kàn gbàgbé Sámúẹ́lì síbi tó wà. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ìyá rẹ̀ a ṣe aṣọ àwọ̀lékè kékeré tí kò lápá fún un, a sì mú un gòkè wá fún un láti ọdún dé ọdún nígbà tí ó bá gòkè wá pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ láti rú ẹbọ ọdọọdún.” (1 Sámúẹ́lì 2:19) Kò sí àní-àní pé Hánà ṣì máa ń gbàdúrà fún Sámúẹ́lì. Ó sì dájú pé, bí Hánà ṣe ń lọ sílé ìjọsìn lọ́dọọdún, ó máa ń gba Sámúẹ́lì níyànjú pé kó máa bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run nìṣó.
Nírú àkókò bẹ́ẹ̀ táwọn òbí Sámúẹ́lì lọ sílé ìjọsìn, Élì ṣàdúrà fún wọn, ó sì sọ fún Ẹlikénà pé: “Kí Jèhófà yan ọmọ fún ọ láti ọ̀dọ̀ aya yìí ní ipò ohun tí a wínni, tí a wín Jèhófà.” Gẹ́gẹ́ bí àdúrà tí Élì gbà, Ọlọ́run fi ọmọkùnrin mẹ́ta míì àti obìnrin méjì jíǹkí Hánà àti Ẹlikénà.—1 Sámúẹ́lì 2:20, 21.
Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ rere ni Ẹlikénà àti Hánà fi lélẹ̀ fáwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni! Ọ̀pọ̀ ìyá àti bàbá ló ti fi ọmọ wọn ọkùnrin àtọmọ wọn obìnrin fún Jèhófà nípa gbígbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún tó máa gbé wọn lọ sí ìdálẹ̀. A gbóríyìn fún irú àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ fún ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí wọ́n ní. Ó sì dájú pé Jèhófà máa bù kún wọn.
Hánà Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Jèhófà Tayọ̀tayọ̀
Ìdùnnú ṣubú lu ayọ̀ fún Hánà nígbà tó dọlọ́mọ! Ìwé Mímọ́ kì í sábà ṣe àkọsílẹ̀ àdúrà táwọn obìnrin gbà. Àmọ́, ní ti Hánà, a rí àdúrà rẹ̀ méjì nínú Ìwé Mímọ́. Àdúrà àkọ́kọ́ fi àwọn ohun tó sọ nígbà tí wọ́n mú un kẹ́dùn tí wọ́n sì fayé sú u hàn, ìkejì jẹ́ àdúrà tó gbà láti fi tayọ̀tayọ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ọba. Ó bẹ̀rẹ̀ àdúrà náà báyìí pé: “Ọkàn-àyà mi yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà.” Inú rẹ̀ dùn pé ‘àgàn pàápàá bímọ,’ ó yin Jèhófà, ó pè é ní “Agbéniga [àti] Olùgbé ẹni rírẹlẹ̀ dìde kúrò nínú ekuru.” Bẹ́ẹ̀ ni o, “láti inú kòtò eérú ni [Ọlọ́run] ti ń gbé òtòṣì sókè.”—1 Sámúẹ́lì 2:1-10.
Ìtàn Hánà yìí, tí Ọlọ́run mí sí, jẹ́ ká rí i pé nítorí àìpé tàbí ìkórìíra, àwọn ẹlòmíràn lè ṣe ohun tó máa mú kí ọkàn wa gbọgbẹ́. Síbẹ̀, kò yẹ ká gba àwọn nǹkan wọ̀nyí láyè láti bá ayọ̀ wa jẹ́ bá a ṣe ń sin Jèhófà. Jèhófà ni Olùgbọ́ àdúrà, tó máa ń gbọ́ igbe ẹkún àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́, tó máa ń yọ wọ́n nínú ìpọ́njú, tó máa ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà jíǹkí wọn, tó sì máa ń bù kún wọn láwọn ọ̀nà mìíràn.—Sáàmù 22:23-26; 34:6-8; 65:2.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Tẹ́ńpìlì” Jèhófà ni Bíbélì pe ibi tí wọ́n ti máa ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ yìí. Àmọ́ láyé ìgbà tá à ń wí yìí lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, inú àgọ́ ìjọsìn tó ṣeé gbé láti ibì kan lọ sí ibòmíràn ni àpótí májẹ̀mú máa ń wà. Ìgbà ìjọba Sólómọ́nì ni wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì àkọ́kọ́ fún Jèhófà, ìyẹn ilé ìjọsìn tó wà lójú kan, tí wọn kì í gbé kiri.—1 Sámúẹ́lì 1:9; 2 Sámúẹ́lì 7:2, 6; 1 Àwọn Ọba 7:51; 8:3, 4.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Hánà fi Sámúẹ́lì fún Jèhófà