ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 30
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nọ́ńbà

      • Ẹ̀jẹ́ àwọn ọkùnrin (1, 2)

      • Ẹ̀jẹ́ àwọn obìnrin àtàwọn ọmọbìnrin (3-16)

Nọ́ńbà 30:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 18:25

Nọ́ńbà 30:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fi ohun kan de ọkàn òun láti.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:20-22; Ond 11:30, 31
  • +Sm 132:1-5
  • +Di 23:21; Sm 116:14; 119:106; Onw 5:4; Mt 5:33
  • +Sm 50:14; 66:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 5/2021,

Nọ́ńbà 30:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn òun.”

Nọ́ńbà 30:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:12

Nọ́ńbà 30:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 7:2; 1Kọ 11:3; Ef 5:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2004, ojú ìwé 27

Nọ́ńbà 30:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 11:3; 1Pe 3:1

Nọ́ńbà 30:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “jẹ́jẹ̀ẹ́ láti pọ́n ọkàn rẹ̀ lójú.”

Nọ́ńbà 30:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 23:21

Àwọn míì

Nọ́ń. 30:1Ẹk 18:25
Nọ́ń. 30:2Jẹ 28:20-22; Ond 11:30, 31
Nọ́ń. 30:2Sm 132:1-5
Nọ́ń. 30:2Di 23:21; Sm 116:14; 119:106; Onw 5:4; Mt 5:33
Nọ́ń. 30:2Sm 50:14; 66:13
Nọ́ń. 30:5Ẹk 20:12
Nọ́ń. 30:8Ro 7:2; 1Kọ 11:3; Ef 5:22
Nọ́ń. 30:121Kọ 11:3; 1Pe 3:1
Nọ́ń. 30:15Di 23:21
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Nọ́ńbà 30:1-16

Nọ́ńbà

30 Lẹ́yìn náà, Mósè bá àwọn olórí+ ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ pé: “Ohun tí Jèhófà pa láṣẹ nìyí: 2 Tí ọkùnrin kan bá jẹ́jẹ̀ẹ́+ fún Jèhófà tàbí tó búra+ pé òun máa* yẹra fún nǹkan kan, kò gbọ́dọ̀ yẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀.+ Gbogbo ohun tó jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa ṣe ni kó ṣe.+

3 “Tí obìnrin kan bá sì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà tàbí tó jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa yẹra fún nǹkan kan nígbà tó ṣì kéré, tó ṣì ń gbé ní ilé bàbá rẹ̀, 4 tí bàbá rẹ̀ wá gbọ́ nípa ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ pé òun* máa yẹra fún nǹkan kan tí bàbá rẹ̀ kò sì lòdì sí i, kó san gbogbo ẹ̀jẹ́ náà, kó sì san gbogbo ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ láti yẹra fún ohunkóhun. 5 Àmọ́ tí bàbá rẹ̀ ò bá fara mọ́ ọn nígbà tó gbọ́ pé ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ tàbí pé ó jẹ́jẹ̀ẹ́ láti yẹra fún nǹkan kan, kó má san ẹ̀jẹ́ náà. Jèhófà máa dárí jì í torí bàbá rẹ̀ ò fara mọ́ ọn.+

6 “Àmọ́ tó bá lọ ilé ọkọ nígbà tí kò tíì san ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí tí kò tíì mú ìlérí tó ṣe láìronú jinlẹ̀ ṣẹ, 7 tí ọkọ rẹ̀ sì wá gbọ́ nípa ẹ̀jẹ́ náà tí kò sì lòdì sí i lọ́jọ́ tó gbọ́, ó máa san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ̀ àti àwọn ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ pé òun máa yẹra fún àwọn nǹkan kan. 8 Àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ ò bá fara mọ́ ọn lọ́jọ́ tó gbọ́ nípa rẹ̀, ó lè ní kó má san ẹ̀jẹ́ náà tàbí kó má ṣe mú ìlérí tó ṣe+ láìronú jinlẹ̀ ṣẹ, Jèhófà sì máa dárí jì í.

9 “Àmọ́ tí opó tàbí obìnrin kan tí òun àti ọkọ rẹ̀ ti kọ ara wọn sílẹ̀ bá jẹ́jẹ̀ẹ́, ó gbọ́dọ̀ san gbogbo ẹ̀jẹ́ tó jẹ́.

10 “Àmọ́ tó bá jẹ́ pé obìnrin kan ti wà nílé ọkọ kó tó jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí tó jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa yẹra fún nǹkan kan, 11 tí ọkọ rẹ̀ wá gbọ́ nípa rẹ̀, tí kò sì lòdì sí i tàbí kó wọ́gi lé e, ó gbọ́dọ̀ san gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí ẹ̀jẹ́ èyíkéyìí tó jẹ́ pé òun máa yẹra fún ohunkóhun. 12 Àmọ́ lọ́jọ́ tí ọkọ rẹ̀ bá gbọ́ nípa ẹ̀jẹ́ èyíkéyìí tó jẹ́ tàbí ẹ̀jẹ́ èyíkéyìí tó jẹ́ pé òun máa yẹra fún ohunkóhun, tó sì wọ́gi lé e pátápátá, obìnrin náà ò ní san ẹ̀jẹ́ náà.+ Ọkọ rẹ̀ ti wọ́gi lé e, Jèhófà sì máa dárí jì í. 13 Tó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ èyíkéyìí tàbí tó búra pé òun máa fi nǹkan du ara òun,* kí ọkọ rẹ̀ fara mọ́ ọn tàbí kó wọ́gi lé e. 14 Àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ ò bá lòdì sí i bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó ti fara mọ́ gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí gbogbo ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ pé òun máa fi nǹkan du ara òun. Ó fara mọ́ ọn torí kò ta kò ó lọ́jọ́ tó gbọ́ tó ń jẹ́jẹ̀ẹ́. 15 Àmọ́ tó bá wọ́gi lé e lẹ́yìn èyí, lẹ́yìn ọjọ́ tó gbọ́ tó ń jẹ́jẹ̀ẹ́, ọkùnrin náà máa jẹ̀bi+ lórí ọ̀rọ̀ obìnrin náà.

16 “Èyí ni àwọn ìlànà tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè nípa ọkọ àti ìyàwó rẹ̀ àti nípa bàbá àti ọ̀dọ́mọbìnrin rẹ̀ tó ṣì ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́