Ẹ̀KỌ́ 35
Hánà Gbàdúrà Pé Kí Ọlọ́run Fún Òun ní Ọmọkùnrin
Ọmọ Ísírẹ́lì kan wà tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Ẹlikénà. Ìyàwó méjì ló fẹ́. Hánà àti Pẹ̀nínà lorúkọ wọn, àmọ́ Hánà ló fẹ́ràn jù. Pẹ̀nínà máa ń fi Hánà ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé kò rọ́mọ bí, àmọ́ Pẹ̀nínà bímọ tó pọ̀ ní tiẹ̀. Lọ́dọọdún, Ẹlikénà máa ń kó ìdílé ẹ̀ lọ sí àgọ́ ìjọsìn ní Ṣílò kí wọ́n lè lọ jọ́sìn Jèhófà. Lọ́jọ́ kan tí wọ́n wà ní Ṣílò, ó kíyè sí i pé inú Hánà ìyàwó ẹ̀ ò dùn rárá. Ó wá sọ pé: ‘Hánà jọ̀ọ́ má sunkún mọ́. Bó ò bá tiẹ̀ bímọ, fọkàn balẹ̀. Mo nífẹ̀ẹ́ ẹ.’
Nígbà tó yá, Hánà lọ dá gbàdúrà. Bó ṣe ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́ ló ṣáà ń sunkún. Ó ṣèlérí pé: ‘Jèhófà, tó o bá fún mi ní ọmọkùnrin, ìwọ ni màá fún, ó sì máa fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ sìn ẹ́.’
Élì Àlùfáà Àgbà rí i pé Hánà ń sunkún, ó sì ronú pé ó ti mutí yó. Hánà dáhùn pé: ‘Rárá Olúwa mi, mi ò mutí yó. Mo níṣòro ńlá kan ni, mo sì ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.’ Élì wá rí i pé èrò òun ò dáa, ló bá sọ fún un pé: ‘Kí Ọlọ́run fún ẹ lóhun tó o tọrọ lọ́wọ́ ẹ̀.’ Ara tu Hánà, ó sì bá ọ̀nà ẹ̀ lọ. Kò pé ọdún kan lẹ́yìn náà tó fi bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ ẹ̀ ní Sámúẹ́lì. Ṣé o mọ bínú Hánà ṣe máa dùn tó?
Hánà ò gbàgbé ìlérí tó ṣe fún Jèhófà. Bí Hánà ṣe rí i pé Sámúẹ́lì ti dàgbà díẹ̀, ó mú un lọ sí àgọ́ ìjọsìn kó lè máa sin Jèhófà níbẹ̀. Ó sọ fún Élì pé: ‘Ọmọkùnrin tí mo tọrọ lọ́wọ́ Ọlọ́run nìyí. Mo ti yọ̀ǹda ẹ̀ fún Jèhófà títí láé.’ Ọdọọdún ni Ẹlikénà àti Hánà máa ń lọ wo Sámúẹ́lì, wọ́n á sì mú aṣọ kékeré tí kò lápá lọ fún un. Jèhófà tún wá fún Hánà ní ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì míì.
“Ẹ máa béèrè, a sì máa fún yín; ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí.”—Mátíù 7:7